Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
A ha lè sọ pé òye tí a mú sunwọ̀n sí i lẹ́nu àìpẹ́ yìí nípa ọ̀rọ̀ náà, “ìran,” nínú Mátíù 24:34, yọ̀ǹda fún èrò náà pé, ó di ọjọ́ iwájú tí ó jìnnà réré kí òpin náà tó dé bí?
Ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí òye wa àìpẹ́ yìí tí a mú sunwọ̀n sí i lórí ọ̀ràn yí ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa fojú sọ́nà fún òpin náà ni. Èé ṣe tí a fi sọ bẹ́ẹ̀?
Ó dára, gẹ́gẹ́ bí Ilé-Ìṣọ́nà ti November 1, 1995, ti ṣàlàyé, Jésù lo ọ̀rọ̀ náà, “ìran yìí,” láti tọ́ka sí àwọn ènìyàn búburú tí wọ́n jẹ́ alájọgbáyé rẹ̀. (Mátíù 11:7, 16-19; 12:39, 45; 17:14-17; Ìṣe 2:5, 6, 14, 40) Kì í ṣe àlàyé nípa àkókò kan pàtó, tí ó bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà kan pàtó.
Ní tòótọ́, “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé,” tí ó wà nínú ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà kan náà yẹn, pe àfiyèsí sí kókó pàtàkì méjì: “A kò lè fojú wo ìran àwọn ènìyàn kan gẹ́gẹ́ bí sáà kan tí ó ní iye ọdún kan pàtó” àti pé, “Àwọn ènìyàn ìran kan ń gbé fún sáà kúkúrú ní ìfiwéra.”
A sábà máa ń lo “ìran” ní irú ọ̀nà yí. Fún àpẹẹrẹ, a lè sọ pé, ‘Àwọn ìran Napoléon, tí wọ́n jẹ́ ológun, kò mọ nǹkan kan nípa ọkọ̀ òfuurufú àti bọ́ǹbù átọ́míìkì.’ A ha ń tọ́ka sí kìkì àwọn jagunjagun tí a bí ní ọdún kan náà tí a bí Napoléon bí? A ha ń tọ́ka sí kìkì àwọn jagunjagun ọmọ ilẹ̀ Faransé tí wọ́n kú ṣáájú Napoléon bí? Rárá, àwọn nìkan kọ́; bẹ́ẹ̀ sì ni lílo “ìran” ni irú ọ̀nà yẹn kò ní gbin àwọn ọdún kan pàtó sí wa lọ́kàn. Ṣùgbọ́n, a ń tọ́ka sí àkókò kúkúrú kan ní ìfiwéra, kì í ṣe ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún láti àkókò Napoléon síwájú.
Ó rí bákan náà pẹ̀lú òye tí a ní nípa ohun tí Jésù sọ nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tí ó sọ ní orí Òkè Ólífì. Ìmúṣẹ apá ẹ̀ka ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn jẹ́rìí sí i pé, òpin ètò ìgbékalẹ̀ yí ti sún mọ́lé. (Mátíù 24:32, 33) Rántí pé, ní ìbámu pẹ̀lú Ìṣípayá 12:9, 10, pẹ̀lú Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run, tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní 1914, a lé Sátánì kúrò ní ọ̀run wá sí sàkáání ilẹ̀ ayé. Ìṣípayá fi kún un pé, Sátánì ń bínú gidigidi nísinsìnyí. Èé ṣe? Nítorí tí ó mọ̀ pé “sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.”—Ìṣípayá 12:12.
Ó bá a mu wẹ́kú, nígbà náà pé, Ilé-Ìṣọ́nà November 1 ní ìsọ̀rí orí ọ̀rọ̀ náà tí ó sọ pé, “Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Ṣíṣọ́nà”! Ohun tí ìpínrọ̀ tí ó tẹ̀ lé e sọ bá a mu nígbà náà pé: “A kò ní láti mọ àkókò náà pàtó tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yóò ní ìmúṣẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, àfiyèsí wa gbọ́dọ̀ jẹ́ lórí ṣíṣọ́nà, mímú ìgbàgbọ́ lílágbára dàgbà, àti mímú kí ọwọ́ wa dí nínú iṣẹ́ ìsìn Jehofa—kì í ṣe lórí ṣíṣírò ọjọ́.” Lẹ́yìn náà, ó fa ọ̀rọ̀ Jésù yọ pé: “Ẹ máa wọ̀nà, ẹ máa wà lójúfò, nitori ẹ̀yin kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yànkalẹ̀ jẹ́. Ṣùgbọ́n ohun tí mo wí fún yín ni mo wí fún gbogbo ènìyàn, Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.”—Máàkù 13:33, 37.