MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jèhófà Ń Dáàbò Bo Àwọn Èèyàn Rẹ̀
Àkókò mánigbàgbé ni Ìrékọjá tó kọ́kọ́ wáyé jẹ́. Lẹ́yìn tí Fáráò rí i pé àkọ́bí òun ti kú lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ó sọ fún Mósè pé: “Ẹ gbéra, ẹ kúrò láàárín àwọn èèyàn mi, ẹ̀yin àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù. Ẹ lọ sin Jèhófà bí ẹ ṣe sọ.” (Ẹk 12:31) Jèhófà jẹ́ kó ṣe kedere pé òun máa ń dáàbò bo àwọn èèyàn òun.
Bákan náà lónìí, ìtàn àwa èèyàn Jèhófà jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà ṣì ń tọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ sọ́nà, ó sì ń dáàbò bò wọ́n. A rí ẹ̀rí èyí níbi àfihàn kan tá a pè ní “Àwọn Èèyàn fún Orúkọ Jèhófà” ní oríléeṣẹ́ wa.
WO FÍDÍÒ NÁÀ IBI TÁ À TI Ń ṢÀFIHÀN ÌṢẸ́ WA NÍ ORÍLÉEṢẸ́ FI HÀN PÉ A JẸ́ “ÀWỌN ÈÈYÀN FÚN ORÚKỌ JÈHÓFÀ,” LẸ́YÌN NÁÀ, DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Fídíò mánigbàgbé wo làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbé jáde lọ́dún 1914 káwọn èèyàn lè túbọ̀ nígbàgbọ́ nínú Bíbélì, àṣeyọrí wo sì ni èyí mú wá?
Àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1916 àti 1918 tó dán àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wò, kí ló sì jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà ló ń darí ètò yìí?
Báwo láwọn èèyàn Jèhófà ṣe dúró gbọin-in láìka àtakò sí?
Òye tuntun wo làwọn èèyàn Jèhófà ní lọ́dún 1935, kí lèyí sì mú kí wọ́n ṣe?
Tó bá jẹ́ pé o ti ṣèbẹ̀wò síbi àfihàn yìí rí tàbí o ti lọ sí èyí tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì yín, kí lo rí níbẹ̀ tó mú kó o túbọ̀ nígbàgbọ́ pé Jèhófà ló ń darí àwọn èèyàn rẹ̀, tó sì ń dáàbò bò wọ́n?