Ìgbàgbọ́ Tí Kò Yingin Nígbà Ìpọ́njú
ÓTI fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́ta ọdún báyìí tí Mina Esch rí káàdì ìkíni kan gbà látọ̀dọ̀ Peter, ọkọ rẹ̀. Ṣókí ni ìsọfúnni tó fọwọ́ kọ, kò sì lọ́rọ̀ gidi nínú. Síbẹ̀síbẹ̀, inú obìnrin náà dùn, eéwo rẹ̀ sì tú. Nígbà yẹn, àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ni ọkọ Mina wà nílùú Buchenwald tó ń fimú dánrin, ìjọba Násì ló fi í síbẹ̀ torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Wọ́n kọ àwọn gbólóhùn ṣàkó sẹ́yìn káàdì náà, tó kà pé: “Ẹlẹ́wọ̀n yìí jẹ́ olóríkunkun Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì [ìyẹn orúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn] . . . Nítorí èyí nìkan la fi gba àǹfààní kíkọ lẹ́tà àti rírí lẹ́tà gbà lọ́wọ́ rẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé a kì í fi àǹfààní yìí duni.” Ìsọfúnni yìí ló jẹ́ kí Mina mọ̀ pé ìgbàgbọ́ Peter kò yingin.
Káàdì ìkíni náà ti gbó jíájíá báyìí, ó sì ti ń pọ́n ràkọ̀ràkọ̀, àmọ́ Ibi Ìkóhun Ìṣẹ̀ǹbáyé Àwọn Júù Sí—Ohun Ìrántí Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Náà, tó wà ní Battery Park, ní New York City, ti yá a lọ́wọ́ wọn. Káàdì ìkíni náà, àti fọ́tò Peter Esch, wà lára àwọn nǹkan tó ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ díẹ̀ lára ọ̀ràn gòdògbà tó dé bá aráyé nígbà Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà, nígbà tí mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn Júù ṣègbé. Àwọn ohun pàtàkì-pàtàkì inú ìpàtẹ tó wà níbi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí náà lé ní ẹgbàá fọ́tò àti ẹgbẹ̀rin ohun èlò ìbílẹ̀ tó ń fi nǹkan kan hàn nípa ohun tójú àwọn Júù rí látọdún 1880 títí dòní, títí kan Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà. Ó ṣe wá jẹ́ pé Ibi Ìkóhun Ìṣẹ̀ǹbáyé Àwọn Júù Sí ni wọ́n lọ pàtẹ lẹ́tà Peter Esch sí?
Ọ̀jọ̀gbọ́n Jud Newborn, tí í ṣe òpìtàn tó ń ṣiṣẹ́ níbi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí náà sọ pé: “Olórí ète táa fi kọ́ ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí yìí ni láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa ìtàn àwọn Júù. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fojú winá inúnibíni nítorí pé wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Gbogbo nǹkan tó fà á tí wọ́n fi ṣenúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí kò ju nítorí ìgbàgbọ́ wọn àti nítorí pé wọ́n kórìíra ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, àti nítorí pé wọ́n kọ̀ láti lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú òṣónú aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀, tí kò lẹ́mìí ẹ̀sìn. Wọn ò sì fẹ́ bá a lọ́wọ́ sógun tó ń jà. . . . Àwọn Júù jà raburabu láti má pàdánù ànímọ́ wọn àti ìgbàgbọ́ wọn lójú àtakò gbígbóná janjan. Ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí yìí gbóríyìn fún irú ìdúró gbọn-in tẹ̀mí yìí. Nítorí náà, àjọ yìí pẹ̀lú gbà pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo ìgbàgbọ́ nígbà ìjọba Násì, a sì kan sáárá sí wọn.”
Fúngbà díẹ̀ tí lẹ́tà yìí yóò fi wà ní Ibi Ìkóhun Ìṣẹ̀ǹbáyé Àwọn Júù Sí, yóò fi akitiyan ọkùnrin kan hàn, bó ṣe dúró ṣinṣin ti Jèhófà nígbà àdánwò. Peter Esch kojú ìdánwò líle koko tó dé bá a nínú àgọ́ Násì, ìgbàgbọ́ rẹ̀ ò sì yingin.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ibi Ìkóhun Ìṣẹ̀ǹbáyé Àwọn Júù Sí, ní New York City
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Wọ́n sọ Esch, tí í ṣe ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, sẹ́wọ̀n láti ọdún 1938 sí 1945 nítorí pé ó kọ̀ láti sẹ́ ìgbàgbọ́ rẹ̀