Irin Iṣẹ́ Tí A Fi Ń Kọ́ni Ní Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn
ỌMỌ ọdún mẹ́tàdínlógún tó ń jẹ́ Rut Jiménez Gila, tó ń gbé nílùú Granada, ní Sípéènì, ni olùkọ́ rẹ̀ sọ fún pé kó kọ àròkọ tó dá lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn. Ní ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn tó kọ àròkọ náà, ẹgbẹ́ tó ń ṣètò ìdánwò ní ilẹ̀ Yúróòpù ní ìlú Brussels, Belgium, fi tó o létí pé wọ́n ti yan òun àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mélòó kan láti ilẹ̀ Sípéènì láti lọ ṣojú fún orílẹ̀-èdè rẹ̀. Lẹ́yìn náà ló wá kọ lẹ́tà tó wà nísàlẹ̀ yìí sí àwọn tó ń tẹ ìwé ìròyìn Jí! jáde.
“Nígbà tí mo ń wá àlàyé tó bágbà mu nípa ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, inú ẹ̀dà ‘Jí!,’ ti November 22, 1998 (Gẹ̀ẹ́sì), tó ní àkọlé náà, ‘Gbogbo Èèyàn Ha Lè Gbádùn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Bí?,’ ni mo ti rí ohun tí mo ń wá gẹ́lẹ́. Láti lè ṣàlàyé tó ṣe kedere nípa bí wọ́n ṣe ń fi ojú ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn gbolẹ̀, mo mú àwọn ìsọfúnni láti inú àwọn àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ‘Jí!’ tó ń sọ nípa ọjọ́ ọ̀la àwọn obìnrin àti èyí tó ń sọ nípa Ìpakúpa Rẹpẹtẹ. [Wo ẹ̀dà April 8, 1998, àti ti August 8, 1998.] Nígbà tí mo ń ṣe ìwádìí náà, mo rí i pé ‘Jí!’ ní àwọn ìsọfúnni tí mi ò lè rí nínú àwọn ìwé ìròyìn míì tàbí àwọn ìwé míì tí a lè ṣe ìwádìí nínú wọn. Àwọn àwòrán inú ẹ̀ tún wú mi lórí, mo sì lo díẹ̀ lára wọn nínú àròkọ tí mo kọ.
“Nítorí àròkọ tí mo gba ẹ̀bùn lé lórí náà, mo lọ lo ọ̀sẹ̀ kan ní Finland, mo sì tún sọ ohun púpọ̀ sí i nípa ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, mo sì ṣàlàyé bí ìwé ìròyìn ‘Jí!’ ṣe gbayì tó nínú ṣíṣàlàyé àwọn ọ̀ràn pàtàkì bí irú èyí.
“Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín gidigidi nítorí pé ẹ̀yin lẹ kọ́kọ́ máa ń fi àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé tó wa létí. Kí Jèhófà máa bù kún yín, kí ẹgbàágbèje èèyàn lè máa jàǹfààní láti inú àwọn ìsọfúnni wọ̀nyí.”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Rut nìyí, ìwé ẹ̀rí pé ó kópa nínú ìdíje náà ló mú dání yẹn