ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 1/8 ojú ìwé 13
  • Ẹ̀tọ́ Ha Lè Wà Láìsí Ojúṣe Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀tọ́ Ha Lè Wà Láìsí Ojúṣe Bí?
  • Jí!—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Fipá Mú Káwọn Èèyàn Yí Ẹ̀sìn Wọn Pa Dà?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Irin Iṣẹ́ Tí A Fi Ń Kọ́ni Ní Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn
    Jí!—2000
  • Àìsí Ẹ̀tọ́ Ọgbọọgba Ti Di Àjàkálẹ̀ Àrùn Lóde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Èé Ṣe Tí A Fi Dá Ilé Ẹjọ́ Jákèjádò Àwọn Orílẹ̀-èdè Europe Sílẹ̀?
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 1/8 ojú ìwé 13

Ẹ̀tọ́ Ha Lè Wà Láìsí Ojúṣe Bí?

“BÍBỌ̀WỌ̀ fún iyì àbímọ́ni àti ẹ̀tọ́ ọgbọọgba tí a kò lè yà sọ́tọ̀ tí gbogbo ẹ̀dá ní jẹ́ ìpìlẹ̀ fún òmìnira, ìdájọ́ òdodo àti àlàáfíà nínú ayé.” Ohun tó wà nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lágbàáyé, tí àyájọ́ àádọ́ta ọdún rẹ̀ wáyé ní December 1998, nìyẹn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn mẹ́rìnlélógún kan tí wọ́n ti jẹ́ ààrẹ tàbí olórí ìjọba tẹ́lẹ̀ rí, tí wọ́n ń ṣojú fún gbogbo kọ́ńtínẹ́ǹtì, ti dámọ̀ràn pé ó yẹ kí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣàmúlò ìpolongo àgbáyé nípa àwọn ojúṣe ọmọnìyàn ní àfikún sí ìpolongo yẹn. Èé ṣe tí ọ̀pọ̀ ènìyàn fi lérò pé ó yẹ kí a dáwọ́ lé irú nǹkan bẹ́ẹ̀?

Ọ̀jọ̀gbọ́n Jean-Claude Soyer, mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe Ilẹ̀ Yúróòpù fún Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ṣàlàyé pé: “Ẹ̀tọ́ àti ojúṣe kò ṣeé yà sọ́tọ̀. Ó bani nínú jẹ́ pé, ní àádọ́ta ọdún lẹ́yìn náà, òtítọ́ ọ̀rọ̀ yìí ti di ohun ìgbàgbé tàbí èyí tí kò bágbà mu mọ́. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ń jà fún ẹ̀tọ́ wọn láìronú pé ó yẹ kí àwọn ṣe ojúṣe tó bá a rìn.” Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fara gbá ohun tó tìdí yíyẹ ojúṣe ẹni sílẹ̀ yìí wá. Ìwé ìròyìn International Herald Tribune ti Paris sọ pé: “Ní pàtàkì láàárín àwọn ọ̀dọ́, ó rọrùn láti tètè rí ìyánhànhàn fún irú ìfojúsọ́nà amúniṣọ̀kan, ọ̀wọ́ àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n pípé tí a tẹ́wọ́ gbà láti fi fòpin sí àwọn ohun tí ń darí ìwọra, ìmọtara-ẹni-nìkan, àìsí ẹ̀mí àjọṣe, tí ó jọ pé ó ń darí ayé. . . . Àríyànjiyàn tí ń peléke yìí nípa àìní fún ìlànà ìwà híhù jẹ́ gbígbà pé a kò ní ohun kan.” Ní àbáyọrí èyí, àwọn òṣèlú, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, àti àwọn ọlọ́gbọ́n èrò orí ti ń jíròrò ohun tí Àjọ Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà Ìbílẹ̀ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè pè ní “ìdáwọ́lé ìlànà ìwà híhù lágbàáyé,” láti dí àlàfo náà kí wọ́n sì pinnu àwọn ohun tó jẹ́ ojúṣe ẹ̀dá. Àmọ́, wọ́n ti bá àwọn ìṣòro kan pàdé.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó rọrùn dé ìwọ̀n kan láti pinnu èyí tó yẹ kí a dáàbò bò lára àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti pinnu èyí tó yẹ kí a tẹ́wọ́ gbà lára àwọn ojúṣe ẹ̀dá lágbàáyé. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a lè tọpa díẹ̀ lára àwọn ìlànà tó wà nínú Ìpolongo Àwọn Ojúṣe tí a dábàá náà padà lọ sórí Òfin Oníwúrà tí ìlò rẹ̀ kò mọ sí sáà kan, tí ó sì wà kárí ayé, tí Jésù fúnni ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn pé: “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.”—Mátíù 7:12.

Níwọ̀n bí Bíbélì ti sábà máa ń jẹ́ agbára ìsúnniṣe tí ó wà lẹ́yìn àwọn òfin tí ń dáàbò bo àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, ó tẹnu mọ́ èrò ojúṣe tí ẹnì kọ̀ọ̀kan ní. Ọmọlẹ́yìn náà, Jákọ́bù, sọ pé: “Bí ẹnì kan bá mọ bí a ti ń ṣe ohun tí ó tọ́, síbẹ̀ tí kò ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni fún un.” (Jákọ́bù 4:17) Gan-an bí Jésù ṣe wá ọ̀nà láti ṣe oore fún àwọn ẹlòmíràn, àwọn Kristẹni tòótọ́ pẹ̀lú ń gbìyànjú láti ṣe oore fún ọmọnìkejì wọn. Níwọ̀n bí wíwulẹ̀ ṣe ẹ̀tọ́ wọn kò ti tó, wọ́n mọ̀ pé àwọn ojúṣe kan máa ń bá ẹ̀tọ́ rìn àti pé olúkúlùkù wa ni yóò jíhìn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ fún Ọlọ́run.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́