Àìsí Ẹ̀tọ́ Ọgbọọgba Ti Di Àjàkálẹ̀ Àrùn Lóde Òní
“Òtítọ́ yìí kò ṣeé já ní koro pé, báa ṣe bí ẹrú la ṣe bí ọmọ, gbogbo èèyàn pátá ni Ẹlẹ́dàá fún láwọn Ẹ̀tọ́ kan pàtó, lára wọn ni, ẹ̀tọ́ sí Ìwàláàyè, Òmìnira àti Ìlépa Ayọ̀.”—Ìpolongo Òmìnira, èyí tí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣàmúlò lọ́dún 1776.
“Gbogbo ènìyàn la bí lómìnira, tí wọ́n sì ní ẹ̀tọ́ ọgbọọgba.”—Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ènìyàn àti ti Aráàlú, tí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Faransé ṣàmúlò lọ́dún 1789.
“Gbogbo ènìyàn la bí lómìnira, tí wọ́n sì dọ́gba ní ti iyì àti ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn.”—Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lágbàáyé, èyí tí Àpéjọ Gbogbo Gbòò ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣàmúlò lọ́dún 1948.
KÒ SÍ iyèméjì nípa rẹ̀. Láàárín àwọn ènìyàn, ìfẹ́ fún ẹ̀tọ́ ọgbọọgba wà kárí ayé. Àmọ́ ṣá o, pé à ń gbọ́ táwọn èèyàn ń sọ ọ́ lemọ́lemọ́ pé àparò kan ò ga jùkan lọ, ti fi hàn pé, ẹ̀tọ́ ọgbọọgba ti di àléèbá fún ìran ènìyàn.
Nísinsìnyí tí ọ̀rúndún ogún ti ń parí lọ, ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè fi tọkàntọkàn sọ pé nǹkan ti yí padà sí rere bí? Ǹjẹ́ gbogbo àwọn aráàlú ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà àti ní ilẹ̀ Faransé, tàbí àwọn tó jẹ́ ti èyíkéyìí nínú orílẹ̀-èdè márùnlélọ́gọ́sàn-án [185] tó jẹ́ mẹ́ńbà Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ló ń gbádùn ẹ̀tọ́ ọgbọọgba tó yẹ kó jẹ́ tiwọn láti ìgbà táa ti bí wọn?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èrò nípa ẹ̀tọ́ ọgbọọgba láàárín àwọn ènìyàn lè “fara hàn kedere,” ẹ̀tọ́ sí “Ìwàláàyè, Òmìnira àti ìlépa Ayọ̀” kò dọ́gba rárá láàárín àwọn ènìyàn. Fún àpẹẹrẹ, ẹ̀tọ́ ọgbọọgba ní ti ìwàláàyè wo la lè sọ pé ó wà nígbà tí ọmọ kan ní Áfíríkà bá ń gbàtọ́jú lọ́dọ̀ dókítà tó ń tọ́jú ẹgbẹ̀tàlá-dín-mọ́kànlélọ́gbọ̀n [2,569] ènìyàn mìíràn, tó sì jẹ́ pé ọ̀dọ̀ dókítà tó ń tọ́jú ẹni mọ́kànládínlọ́ọ̀ọ́dúnrún [289] péré ni ọmọ kan ti ń gbàtọ́jú ní Yúróòpù? Àbí ẹ̀tọ́ ọgbọọgba wo la lè sọ pé ó wà ní ti òmìnira àti ìlépa ayọ̀ nígbà tí ìdámẹ́ta àwọn ọmọkùnrin àti ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn ọmọbìnrin ní Íńdíà ń dàgbà di púrúǹtù, nígbà tó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ọmọdé pátá láǹfààní àtikàwé ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi Japan, Germany, àti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì?
Ṣé àwọn ènìyàn tó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè Àárín Gbùngbùn Amẹ́ríkà níbi tí ìpíndọ́gba owó tí ń wọlé fún ẹnì kọ̀ọ̀kan láàárín ọdún kan ti jẹ́ okòódínlégbèje [1,380] dọ́là ń gbádùn “iyì àti ẹ̀tọ́” ọgbọọgba bíi ti àwọn ará ilẹ̀ Faransé, níbi ti ìpíndọ́gba owó tí ń wọlé fún ẹnì kọ̀ọ̀kan láàárín ọdún kan ti jẹ́ dọ́là mẹ́wàá dín lẹ́gbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [24,990]? Àǹfààní ọgbọọgba wo ni ọmọbìnrin táa ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ní Áfíríkà tó jẹ́ pé kò lè lò ju ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta láyé ń gbádùn táa bá fi wéra pẹ̀lú ọmọdébìnrin Àríwá Amẹ́ríkà tó lè lò tó ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin láyé?
Oríṣiríṣi ọ̀nà ni àìsí ẹ̀tọ́ ọgbọọgba pín sí, kò sì séyìí tó fani mọ́ra nínú gbogbo rẹ̀. Lára wọn ni àìsí ẹ̀tọ́ ọgbọọgba ní ti àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí-ayé àti àǹfààní ètò ìlera àti ẹ̀kọ́ ìwé. Ọ̀nà tí ìjọba gbà ń ṣàkóso, ẹ̀yà tó yàtọ̀ síra, tàbí ìsìn tí kò bára mu máa ń kópa tó lágbára nínú fífi ẹ̀tọ́ iyì àti òmìnira àwọn ènìyàn dù wọ́n nígbà mí-ìn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ò dẹ́kun sísọ̀rọ̀ lórí ẹ̀tọ́ ọgbọọgba, síbẹ̀síbẹ̀, a ń gbé nínú ayé tí wọ́n ti ń fi ẹ̀tọ́ ọgbọọgba duni. Bí ọ̀rọ̀ náà àjàkálẹ̀ àrùn, tó túmọ̀ sí “àìsàn tí ń gbèèràn” ṣe rí, bẹ́ẹ̀ náà ni àìsí ẹ̀tọ́ ọgbọọgba tí ń jà rànyìn láàárín gbogbo àwùjọ ènìyàn. Àwọn ìrora tó ń fà, bíi ipò òṣì, àìsàn, àìmọ̀kan, àìríṣẹ́ṣe, àti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ń gúnni dé ọkàn-àyà.
“Báa ṣe bí ẹrú lá ṣe bí ọmọ.” Ó mà dùn ún gbọ́ o! Àmọ́ ó dunni pé ohun tó yàtọ̀ pátápátá là ń rí.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
FỌ́TÒ UN 152113/SHELLEY ROTNER