ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 8/1 ojú ìwé 6-8
  • Kíkápá Àjàkálẹ̀ Àrùn Àìsí Ẹ̀tọ́ Ọgbọọgba

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kíkápá Àjàkálẹ̀ Àrùn Àìsí Ẹ̀tọ́ Ọgbọọgba
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lo Àǹfààní Tóo Ní Dáadáa!
  • Gbígbádùn Ẹ̀tọ́ Ọgbọọgba Láàárín Àwọn Ará
  • Àìsí Ẹ̀tọ́ Ọgbọọgba—Ṣé Ọlọ́run Ló Fẹ́ Ẹ Bẹ́ẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Àìsí Ẹ̀tọ́ Ọgbọọgba Ti Di Àjàkálẹ̀ Àrùn Lóde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ṣé Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Táwọn Èèyàn Ò Ní Máa Gbé Ẹ̀yà Kan Ga Ju Ẹ̀yà Míì Lọ?—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe Sí Ìṣòro Àtijẹ-Àtimu
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 8/1 ojú ìwé 6-8

Kíkápá Àjàkálẹ̀ Àrùn Àìsí Ẹ̀tọ́ Ọgbọọgba

Láìpẹ́ sígbà táa wà yìí, Ẹlẹ́dàá yóò mú ẹ̀tọ́ ọgbọọgba tí gbogbo ènìyàn ń yán hànhàn fún wá. Kó tó dìgbà náà, a lè gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan, ó kéré tán láti kápá àjàkálẹ̀ àrùn àìsí ẹ̀tọ́ ọgbọọgba tó ń bá àwa àti àwọn ìdílé wa jà. Gẹ́gẹ́ bí Nelson Mandela, tó jẹ́ ààrẹ Gúúsù Áfíríkà tẹ́lẹ̀, ṣe sọ, “àrà tí ẹnì kan bá fi ohun tó ní dá ló ń mú kó yàtọ̀ sí ẹlòmíràn, kì í ṣe ohun tí a fún onítọ̀hún.”

ÌTÀN ti jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọkùnrin àtobìnrin ló wà tó jẹ́ pé atàpáta-dìde ni wọ́n, àmọ́, tó jẹ́ pé bí wọ́n ṣe lo ẹ̀bùn tí wọ́n ní dáadáa mú kí wọ́n ṣàṣeyọrí, ó mú kí wọ́n tayọ àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn tó ju tiwọn. Àwọn mìíràn sì rèé, tó jẹ́ pé ilé ọlá, ilé ọlà la bí wọn sí, wọ́n ti fi gbogbo ogún wọn polúkúrúmuṣu, wọn ò sì lo ẹ̀bùn tí wọ́n ní dáadáa.

Lo Àǹfààní Tóo Ní Dáadáa!

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ nínú ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti jèrè ìmọ̀ nípa àwọn ète Ọlọ́run nípasẹ̀ kíkọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n gbà pé, lọ́nàkọnà, kí àwọn ènìyàn tó lè jàǹfààní kíkún nínú ọ̀rọ̀ Bíbélì, wọ́n gbọ́dọ̀ mọ̀ ọ́n kọ, kí wọ́n sì mọ̀ ọ́n kà. Nítorí ìdí yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ́ ẹgbẹẹgbàárùn-ún ènìyàn láti mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà, títí kan àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún ènìyàn (ìyẹn láàárín àwọn ọdún 1990) ní orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Nígbà tí ìwé ìròyìn San Francisco Examiner ń tọ́ka sí iṣẹ́ afẹ́dàáfẹ́re tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe fáwùjọ, ó sọ pé: “O lè kà wọ́n sí àwọn aráàlú tí wọ́n jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ. Wọ́n ń san owó orí wọn déédéé, wọ́n ń tọ́jú aláìsàn, wọ́n sì ń gbógun ti àìmọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà.”

Láfikún sí i, nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ lórí bí a ti ń sọ̀rọ̀ ní gbangba tí wọ́n ń kọ́ni, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn láti di sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńgájíá, tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó já gaara ní gbangba. Àwọn tí wọ́n ti fìgbà kan rí ní ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ wà lára àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún wọ̀nyí. Gbé ọ̀rọ̀ ọkùnrin tó wá láti Gúúsù Áfíríkà yẹ̀ wò, ẹni tó kọ̀wé pé: “Ìkólòlò mi burú débi pé mo wá di ẹni tí kò lè dá sọ̀rọ̀, tí mo máa ń fi gbogbo ìgbà gbára lé àwọn ẹlòmíràn láti gbẹnu sọ fún mi. . . . Nígbà tí mo forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, tí wọ́n sì fún mi ní Bíbélì kíkà níwájú àwùjọ kékeré kan . . . , mo kólòlò gan-an débi pé n kò lè parí iṣẹ́ náà láàárín àkókò táa yàn fún mi. Lẹ́yìn ìpàdé náà, [olùfúnni-nímọ̀ràn] rọra fún mi ní àmọ̀ràn tó wúlò. Ó gbà mí nímọ̀ràn pé kí n máa fi kíkàwé sétígbọ̀ọ́ ara mi dánra wò. Ohun tí mo ṣe gan-an nìyí, mo ń lo àkókò lójoojúmọ́ láti ka Bíbélì àti ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sókè ketekete.” Ọkùnrin yìí ti tẹ̀ síwájú gan-an báyìí débi pé ó ń sọ àwíyé fún àwùjọ tí iye wọn ń lọ sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún, kódà ẹgbẹẹgbẹ̀rún pàápàá.

Gbígbádùn Ẹ̀tọ́ Ọgbọọgba Láàárín Àwọn Ará

Tó bá kan ọ̀rọ̀ nípa ẹ̀kọ́ ìwé, àbójútó ìlera, àti ipò ìṣúnná owó àti ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ipò tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà yàtọ̀ síra gan-an. Àwọn ìyàtọ̀ wọ̀nyí wúlẹ̀ ń fi ipò àìpé tó wà nínú ayé tí wọ́n ń gbé hàn ni. Àmọ́ tí a bá fi wọ́n wé àwọn ẹ̀sìn mìíràn, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹ̀tanú ẹ̀yà, ti ipò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, àti ti ìṣúnná owó láàárín wọn.

Wọ́n ṣàṣeyọrí èyí nípa sísà tí wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti fi ohun tí wọ́n ń kọ́ nínú Bíbélì sílò. Wọ́n fi tọkàntọkàn gba àwọn ìlànà Bíbélì, bí èyí tó sọ pé: “Kì í ṣe ọ̀nà tí ènìyàn gbà ń wo nǹkan ni Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan, nítorí pé ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.” (1 Sámúẹ́lì 16:7) “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. Ẹ pèsè àwọn ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ lójú gbogbo ènìyàn. Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”—Róòmù 12:17, 18; tún wo 1 Tímótì 6:17-19; Jákọ́bù 2:5, 9.

Nípa rírọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ àwọn ìlànà Bíbélì tó ń gbé ìṣọ̀kan lárugẹ wọ̀nyí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò fàyè gba ẹ̀mí fífi ẹ̀tọ́ ọgbọọgba duni, ì báà jẹ́ ní ti ẹ̀yà, àjọṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, tàbí ti ipò ìṣúnná owó tó yàtọ̀ síra. Fún àpẹẹrẹ, àwọn kókó wọ̀nyí kò ní ohunkóhun ṣe nípa pípinnu ẹni tí a óò fún ní ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ Kristẹni. Jíjẹ́ ẹni tó tóótun nípa tẹ̀mí la gbé ipò ẹrù iṣẹ́ bí kíkọ́ni àti ṣíṣe àbójútó kà.—1 Tímótì 3:1-13; Títù 1:5-9.

Inú àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀tọ́ ọgbọọgba dù nínú ayé ẹlẹ́tanú yìí yóò mà dùn o, láti rí àwọn ẹlòmíràn tó ń bá wọn lò bí arákùnrin àti arábìnrin, àwọn tí wọ́n jọ ní ipò tó dọ́gba níwájú Ẹlẹ́dàá wọn! Martina lè jẹ́rìí sí èyí. Lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ pa ìdílé wọn tì, a wá tọ́ ọ dàgbà nínú ìdílé olóbìí kan, tó jẹ́ ìdílé tálákà. Gbogbo ìgbà ni àwọn ènìyàn máa ń hùwà sí i bí ẹni tí kò bẹ́gbẹ́ jọ, kò wá fi bẹ́ẹ̀ fọkàn tán ara rẹ̀ mọ́, kì í sì í fẹ́ bá àwọn ẹlòmíràn da nǹkan pọ̀. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí hùwà àìbìkítà nìyẹn. Àmọ́, nǹkan yí padà nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sọ pé: “Mo ṣì ní láti sapá gidigidi láti má ṣe ní èrò òdì nípa àwọn èèyàn, ṣùgbọ́n ó rọrùn fún mi láti kojú ìṣòro náà báyìí. Mo ti wá túbọ̀ ń fojú iyì wo ara mi, mo sì ti ń fìgboyà sọ̀rọ̀ fàlàlà. Òtítọ́ ti jẹ́ kí n lóye pé èmi pẹ̀lú tóó fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́. Nísinsìnyí, mo mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi, àti pé ó dára láti wà láàyè.”

Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ Kristẹni tó kárí ayé, ní àwọn orílẹ̀-èdè tó lé ní ọgbọ̀nlénígba [230], àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ẹ̀tọ́ ọgbọọgba láàárín ara wọn, àǹfààní tí kò lẹ́gbẹ́ nínú ayé. Ǹjẹ́ àwọn ètò ẹ̀sìn mìíràn lè sọ pé àwọn ní irú ẹ̀tọ́ bẹ́ẹ̀ láàárín ara wọn, kí wọ́n sì fẹ̀rí tì í lẹ́yìn?

Kò sí àní-àní pé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀. Wọ́n gba pé àyíká aláìpé tí wọ́n bá ara wọn kò lè jẹ́ kí àwọn lè ṣe ohunkóhun láti mú ẹ̀mí fífi ẹ̀tọ́ ọgbọọgba duni, èyí tó wà láàárín àwọn ènìyàn, kúrò pátápátá ju bí àwọn tó ti gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀ ti ṣe ní àwọn ọ̀rúndún tó ti kọjá—tí wọ́n sì kùnà. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n láyọ̀ pé láàárín ara wọn, àwọn ti ṣe gudugudu méje láti rí i pé àwọn kápá àjàkálẹ̀ àrùn burúkú yìí. Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ lílágbára tí wọ́n ní nínú ìlérí Ọlọ́run, wọ́n ń wọ̀nà fún ayé tuntun òdodo níbi tí fífi ẹ̀tọ́ ọgbọọgba duni yóò ti di ohun àtijọ́.

Dájúdájú, láìpẹ́, gbogbo ènìyàn onígbọràn yóò wà lọ́gbọọgba “ní ti iyì àti ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn” tí Ẹlẹ́dàá wọn ti pète fún wọn láti gbádùn níbẹ̀rẹ̀. Èrò yìí mà dára o! Lọ́tẹ̀ yìí sì rèé, yóò rí bẹ́ẹ̀ dandan!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbógun ti àìmọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà nípa kíkọ́ ẹgbẹẹgbàárùn-ún ènìyàn láti mọ̀ ọ́n kọ, kí wọ́n sì mọ̀ ọ́n kà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Òtítọ́ Bíbélì ń ṣèrànwọ́ láti mú ẹ̀tanú ẹ̀yà, ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, àti ti ipò ìṣúnná owó kúrò

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́