Àìsí Ẹ̀tọ́ Ọgbọọgba—Ṣé Ọlọ́run Ló Fẹ́ Ẹ Bẹ́ẹ̀?
Lọ́rọ̀ kan, bẹ́ẹ̀ kọ́ ni ìdáhùn rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.
ỌLỌ́RUN fẹ́ kí gbogbo ènìyàn ní àǹfààní ọgbọọgba láti lè gbádùn ìwàláàyè, kí wọ́n sì láyọ̀. Ní sísọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá ènìyàn, a kà á pé: “Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí pé: ‘Jẹ́ kí a ṣe ènìyàn ní àwòrán wa, ní ìrí wa, kí wọ́n sì máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti àwọn ẹran agbéléjẹ̀ àti gbogbo ilẹ̀ ayé àti olúkúlùkù ẹran tí ń rìn ká, tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.’” Lẹ́yìn tó parí dídá àwọn nǹkan sórí ilẹ̀ ayé, “Ọlọ́run rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an ni.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 31.
Ọlọ́run ha lè sọ pé ipò àìsí ẹ̀tọ́ ọgbọọgba, èyí tí ń bani nínú jẹ́ lónìí, “dára gan-an”? Ó dájú pé kò jẹ́ sọ bẹ́ẹ̀, nítorí pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé òun “kì í fi ojúsàájú bá ẹnikẹ́ni lò” àti pé “pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; olódodo àti adúróṣánṣán ni.” (Diutarónómì 10:17; 32:4; fi wé Jóòbù 34:19.) Àpọ́sítélì Pétérù tún là á mọ́lẹ̀ pé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.
Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti jẹ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́, tí kì í ṣe ojúsàájú, tó jẹ́ onídàájọ́ òdodo, adúróṣánṣán, àti olódodo, báwo ni yóò ṣe wá dá ẹ̀mí fífi ẹ̀tọ́ ọgbọọgba duni mọ́ni, tí yóò pa ẹ̀tọ́ wọn sí ayọ̀ lára? Láti fàyè gba ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà láàárín àwọn ènìyàn, kí a sì tún wá fi wọn sípò tẹ́nì kan á ti máa fi ẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n yóò jẹ́ ohun tó lòdì pátápátá sí irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. Ó fẹ́ kí gbogbo wa jẹ́ ẹni tí a “bí lómìnira, tí [a] sì dọ́gba ní ti iyì àti ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn.” Àmọ́, ó dájú pé nǹkan ò rí bẹ́ẹ̀ lónìí. Èé ṣe?
Bí Àìsí Ẹ̀tọ́ Ọgbọọgba Ṣe Bẹ̀rẹ̀
Pé Ọlọ́run dá gbogbo èèyàn láti wà lọ́gbọọgba kò túmọ̀ sí pé ó fẹ́ kí wọ́n dọ́gba ní gbogbo ọ̀nà. Ẹ̀bùn àbínibí wọn, ohun tí wọ́n fẹ́, àti àkópọ̀ ìwà wọ́n lè yàtọ̀ síra. Wọ́n tún lè yàtọ̀ ní ti ipò tí wọ́n wà àti ọlá àṣẹ tí wọ́n ní. Fún àpẹẹrẹ, ọkùnrin àtobìnrin kò dọ́gba ní gbogbo ọ̀nà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run dá obìnrin “gẹ́gẹ́ bí àṣekún” fún ọkùnrin. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Ó sì tún ṣe kedere pé, ọlá àṣẹ àwọn òbí yàtọ̀ sí ti àwọn ọmọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìka ò dọ́gba lóòótọ́, gbogbo èèyàn pátá—lọ́kùnrin, lóbìnrin, àtọmọdé pàápàá—ló yẹ kó jàǹfààní ẹ̀tọ́ ọgbọọgba tí Ọlọ́run fúnni láti lè ní àwọn ohun tó ṣe pàtàkì, tó ń máyọ̀ wá. Gbogbo wọn ló yẹ kó ní iyì ọgbọọgba àti ipò kan náà níwájú Ọlọ́run.
Bákan náà la fún àwọn ọmọ ẹ̀mí ti Ọlọ́run, tí a dá kí a tó dá ènìyàn, ní ẹrù iṣẹ́ tó yàtọ̀ síra. (Jẹ́nẹ́sísì 3:24; 16:7-11; Aísáyà 6:6; Júúdà 9) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, dé ibi tí a fún wọn ní àyè dé, gbogbo wọn ló ń gbádùn ìpèsè Ọlọ́run fún ìyè àti ayọ̀ dé ìwọ̀n tó jẹ́ ọgbọọgba. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n gbé àìṣojúsàájú Ọlọ́run yọ lọ́nà gígalọ́lá.
Ó bani nínú jẹ́ pé, ìṣètò tí kò ní ojúsàájú tí Ọlọ́run ṣe yìí kò tẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí kan lọ́rùn. Ó ń wá ohun tó ju èyí tí Ọlọ́run fún un lọ, ó yán hànhàn fún ipò gíga, tó ga gan-an. Nípa mímú èrò òdì yìí dàgbà, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá Jèhófà díje, ẹni tó jẹ́ pé gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá, òun ló wà ní ipò tó ga jù lọ. Lẹ́yìn náà, ọlọ̀tẹ̀ ẹni ẹ̀mí tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run yìí wá sún àwọn ènìyàn láti sọ pé kí Ọlọ́run ṣe ju àwọn nǹkan tí Ó ti ṣe fún wọn lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; fi wé Aísáyà 14:12-14.) Nípa bẹ́ẹ̀, ìpèsè tí Jèhófà ṣe fún ènìyàn láti gbádùn ìwàláàyè, kí wọ́n sì láyọ̀ di èyí tí a gbé jù nù. Ọlọ̀tẹ̀ tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí yìí, tí Ìṣípayá 20:2 pè ní “Èṣù àti Sátánì,” ló di olubi tó dá ìṣòro àìsí ẹ̀tọ́ ọgbọọgba sílẹ̀ láàárín ìran ènìyàn.
Ṣé Nǹkan Máa Yí Padà?
Lọ́rọ̀ kan, bẹ́ẹ̀ ni! ni ìdáhùn rẹ̀.
Ṣùgbọ́n ta ló lè mú ìyípadà tí a ń fẹ́ wá? Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni àwọn aṣáájú ènìyàn ti fi tọkàntọkàn sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ìwọ̀nba ni àṣeyọrí tí wọ́n lè ṣe, èyí wá mú kí ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà pé àlá tí kò lè ṣẹ ni kí a máa retí pé ìṣòro àìsí ẹ̀tọ́ ọgbọọgba láàárín ẹ̀dá ènìyàn yóò yanjú. Bó ti wù kó rí, ojú ìwòye Ọlọ́run ni a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Aísáyà 55:10, 11 pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀yamùúmùú òjò ti ń rọ̀, àti ìrì dídì, láti ọ̀run, tí kì í sì í padà sí ibẹ̀, bí kò ṣe pé kí ó rin ilẹ̀ ayé gbingbin ní tòótọ́, kí ó sì mú kí ó méso jáde, kí ó sì rú jáde, tí a sì fi irúgbìn fún afúnrúgbìn àti oúnjẹ fún olùjẹ ní tòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde yóò já sí. Kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.”
Ó mà tuni nínú gan-an o, láti mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run ti sọ ọ́ kedere pé òun yóò mú ète òun ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣẹ láti pèsè àǹfààní ọgbọọgba ti ìwàláàyè àti ayọ̀ fún gbogbo ènìyàn! Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run òtítọ́, ó ti sọ ọ́ di dandan fún ara rẹ̀ láti mú àwọn ìlérí tó ti ṣe ṣẹ. Ó jẹ́ ayọ̀ wa pé, ó fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì ní agbára láti ṣe é. Báwo ni yóò ṣe ṣe èyí?
Yóò ṣeé ṣe nípasẹ̀ Ìjọba náà tí Jésù Kristi kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà fún pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, . . . Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:9, 10) Dájúdájú, Ìjọba Ọlọ́run ni ohun tí Jèhófà yóò lò láti “fọ́ ìjọba wọ̀nyí [àwọn tó wà nísinsìnyí] túútúú, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:44.
Lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba ti ọ̀run náà, àwùjọ tuntun ti ẹ̀dá ènìyàn yóò yọjú. Nítorí ìdí èyí, àpọ́sítélì Jòhánù kọ ọ́ sínú ìwé tó kẹ́yìn nínú Bíbélì, ìyẹn Ìṣípayá pé: “Mo sì rí ọ̀run tuntun kan àti ilẹ̀ ayé tuntun kan; nítorí ọ̀run ti ìṣáájú àti ilẹ̀ ayé ti ìṣáájú ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:1) Gbogbo ìbànújẹ́ tí ìṣòro àìsí ẹ̀tọ́ ọgbọọgba ń fà, àwọn nǹkan bí, ipò òṣì, àìsàn, àìmọ̀kan, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, àti àwọn ipò ìnira mìíràn tó ń bá ènìyàn fínra yóò kọjá lọ.a
Ó ti lé ní ọ̀rúndún kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń darí àfiyèsí àwọn ènìyàn sí Ìjọba yẹn. (Mátíù 24:14) Nípasẹ̀ àwọn ìwé tí wọ́n ń tẹ̀ jáde àti ìrànlọ́wọ́ tí àwọn fúnra wọn ń ṣe, wọ́n ti sa gbogbo agbára wọn láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìmọ̀ nípa ète Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú Bíbélì. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe kìkì ìrètí pé àwọn ènìyàn yóò lè gbé ìgbésí ayé kan lọ́jọ́ iwájú, níbi tí ẹ̀tọ́ ọgbọọgba yóò ti wà fún gbogbo gbòò, tí wọn yóò sì ní ayọ̀ nìkan ni iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń ṣe jákèjádò ayé ń fún wọn, àmọ́, ó tún ń fún wọn láǹfààní nísinsìnyí láti kápá àjàkálẹ̀ àrùn àìsí ẹ̀tọ́ ọgbọọgba. Ẹ jẹ́ kí a wò bó ṣe rí bẹ́ẹ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìjíròrò kíkúnrẹ́rẹ́ nípa bí Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe mú ìṣòro àìsí ẹ̀tọ́ ọgbọọgba kúrò fún gbogbo ènìyàn láìpẹ́, jọ̀wọ́ wo orí 10 àti 11 ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tí Watch Tower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo ènìyàn ní àǹfààní ọgbọọgba láti lè gbádùn ìwàláàyè, kí wọ́n sì láyọ̀