ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 93
  • Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe Sí Ìṣòro Àtijẹ-Àtimu

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe Sí Ìṣòro Àtijẹ-Àtimu
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe sí Àyíká Tó Ń Bà Jẹ́
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe Sáwọn Olóṣèlú Jẹgúdújẹrá
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Àìsí Ẹ̀tọ́ Ọgbọọgba—Ṣé Ọlọ́run Ló Fẹ́ Ẹ Bẹ́ẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìjọba Ọlọ́run
    Jí!—2013
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 93
Àwọn ilé àtijọ tó ti ń wó lọ wà nílùú ńlá kan tó dọ̀tí gan-an.

Kim Steele/The Image Bank via Getty Images

Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe Sí Ìṣòro Àtijẹ-Àtimu

Àtijẹ-àtimu túbọ̀ ń nira fáwọn èèyàn kárí ayé, òótọ́ ibẹ̀ sì ni pé ṣe ló túbọ̀ ń le sí i.

  • Ìròyìn kan tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí jẹ́ ká rí i pé,a “Owó tó ń wọlé fáwọn èèyàn ò tó ra nǹkan tí wọ́n nílò mọ́.” Ìròyìn náà tún fi kún un pé tí wọn ò bá wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ yìí, “ìyàtọ̀ tó máa wà láàárín olówó àtàwọn tálákà máa pọ̀ gan-an,” àti pé “nǹkan á túbọ̀ nira ju ti tẹ́lẹ̀ lọ fáwọn ìdílé míì.”

Ṣé ìjọba kan wà tó lè yanjú ìṣòro àtijẹ- àtimu?

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìjọba kan tó máa fòpin sí ìṣòro ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀, ìjọba náà á sì jẹ́ kí gbogbo èèyàn ní nǹkan lọ́gbọọgba. Ó sọ pé “Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀,” ìjọba yìí lá sì máa ṣàkóso gbogbo ayé. (Dáníẹ́lì 2:44) Lábẹ́ ìjọba yẹn, Ọlọ́run ò ní gbàgbé ẹnì kankan a ò sì ní pa ẹnikẹ́ni tì. (Sáàmù 9:18) Gbogbo àwọn tó bá wà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ló máa ní gbogbo ohun tí wọ́n nílò. Gbogbo èèyàn ló sì máa gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ wọn dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́.—Àìsáyà 65:21, 22.

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

“Ilé Ìṣọ́” tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?”

A rọ̀ ẹ́ pé kó o ka Ilé Ìṣọ́ tí àkòrí ẹ̀ sọ pé “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?” Wàá rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè bíi:

  • Ta Ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run?

  • Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣàkóso Ayé?

  • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe?

a Ìròyìn àjọ International Labour Organization tó dá lórí iye tó ń wọlé fáwọn èèyàn lóṣooṣù

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́