ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 91
  • Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe sí Àyíká Tó Ń Bà Jẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe sí Àyíká Tó Ń Bà Jẹ́
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe Sí Ìṣòro Àtijẹ-Àtimu
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Nǹkan Ò Rọrùn Fáwọn Èèyàn Lọ́dún 2023—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe Sáwọn Olóṣèlú Jẹgúdújẹrá
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ojú Ọjọ́ Tó Ń Yí Pa Dà àti Ọjọ́ Ọ̀la Wa
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 91
Bíárì kan tó dọ̀tí tí inú ẹ̀ ò sì dùn jókòó sórí yìnyín tó léfòó lórí omi òkun tí pàǹtí kún inú ẹ̀.

TheCrimsonMonkey/E+ via Getty Images

Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe sí Àyíká Tó Ń Bà Jẹ́

“Ojú ọjọ́ tó ń burú sí i ń fa ọ̀pọ̀ ìṣòro kárí ayé. Bí àpẹẹrẹ, ó ti ṣàkóbá fún ọ̀pọ̀ èèyàn, ó ń dákún ìṣòro ìlú, ó sì ń ba àyíká jẹ́. Kò tán síbẹ̀ o, ó ń mú káwọn ìjì tó ń jà lásìkò yìí túbọ̀ le sí i, ìyẹn sì ń ba ilé àti ohun ìní àwọn èèyàn jẹ́ kárí ayé. Bákan náà, ó ń mú kí omi òkun máa gbóná, ìyẹn sì ń mú kí ọ̀pọ̀ ohun ẹlẹ́mìí máa kú àkúrun.”—Inger Andersen, igbá kejì àkọ̀wé àgbà Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé àti ọ̀gá àgbà Àjọ Tó Ń Rí Sọ́rọ̀ Àyíká lábẹ́ Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbàyé, July 25, 2023.

Ṣé àwọn ìjọba lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti yanjú ìṣòro tó ń bá aráyé fínra yìí? Ṣé wọ́n tiẹ̀ lágbára láti yanjú ìṣòro yìí, kó má sì gbérí mọ́?

Bíbélì sọ nípa ìjọba kan tó lágbára láti yanjú àwọn ìṣòro yìí, táá sì fòpin sí i. Ó sọ pé “Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀,” ìjọba yìí lá sì máa darí bí nǹkan ṣe ń lọ láyé. (Dáníẹ́lì 2:44) Lábẹ́ ìjọba yìí, àwọn èèyàn “ò ní fa ìpalára kankan, tàbí ìparun kankan” fáwọn míì, wọn ò sì ní ba ayé jẹ́.—Àìsáyà 11:9.

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

“Ilé Ìṣọ́” tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?”

A rọ̀ ẹ́ pé kó o ka Ilé Ìṣọ́ tí àkòrí ẹ̀ sọ pé “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?” Wàá rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè bíi:

  • Ta Ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run?

  • Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣàkóso Ayé?

  • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́