Dídáàbòbo Òmìnira—Báwo?
NÍ ÌLÚ kékeré Rengasdengklok, Indonesia, àwọn ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ gbé pọ̀ ní àlàáfíà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ṣùgbọ́n, ohun tí ó jọ fífaradà á fún ara ẹni náà dópin ní January 30, 1997. Ó kù díẹ̀ kí agogo mẹ́ta lù lóru ọjọ́ àjọ̀dún ìsìn kan ni ìjà ìgboro bẹ́ sílẹ̀ nígbà tí onísìn kan bẹ̀rẹ̀ sí lu ìlù rẹ̀. Ọkùnrin kan tí ẹ̀sìn tirẹ̀ yàtọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bú aládùúgbò rẹ̀ náà nítorí ariwo tó ń pa. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pariwo lé ara wọn lórí, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jùkò lura wọn. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ìjà ìgboro náà le sí i nígbà tí àwọn mìíràn dara pọ̀ mọ́ wọn. Nígbà tí nǹkan rọlẹ̀, wọ́n ti ba tẹ́ńpìlì Búdà méjì àti ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù mẹ́rin jẹ́. Ìwé ìròyìn International Herald Tribune fún ìròyìn tí ó kọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ní àkọlé náà, “Arukutu Ìwà Àìfẹ́ Ti Ẹ̀sìn Mìíràn Tanná Ran Ìjà Ẹlẹ́yàmẹ̀yà.”
Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn ẹ̀yà tí kò gbajúmọ̀ tí òfin dáàbò bo ẹ̀tọ́ wọn sábà máa ń rí ara wọn nínú àṣà àìfún ẹ̀sìn lómìnira. Ó hàn kedere pé fífúnni lómìnira lábẹ́ òfin kò mú lájorí okùnfà ìwà àìfún ẹ̀sìn lómìnira kúrò. Nítorí pé àìfún ẹ̀sìn lómìnira fara sin kò túmọ̀ sí pé kò sí. Bí ipò nǹkan bá yí padà lọ́jọ́ iwájú, bóyá tí ó sì ṣamọ̀nà sí ipò ẹlẹ́tanú, àìfún ẹ̀sìn lómìnira tí ó fara sin lè tètè yọjú. Kódà bí a kò bá ṣe inúnibíni sí àwọn ènìyàn ní tààràtà, a lè ṣe kèéta sí wọn tàbí kí a tẹ èrò wọn rì. Báwo ni a ṣe lè dá èyí dúró?
Wíwádìí Okùnfà Àìfún Ẹ̀sìn Lómìnira
A sábà máa ń tẹ̀ síhà kíkọ ohun tí ó bá yàtọ̀ tàbí tí ó ṣàjèjì tàbí kí a máa ṣiyè méjì nípa rẹ̀, pàápàá àwọn èrò tó bá yàtọ̀ sí tiwa. Èyí ha túmọ̀ sí pé kò lè ṣeé ṣe láti fún ẹ̀sìn lómìnira ni bí? Ìwé tí àjọ UN ṣe náà, Elimination of All Forms of Intolerance and Discrimination Based on Religion or Belief kọ àìmọ̀kan àti àìlóye “mọ́ àwọn lájorí ohun tí ń fa àìfún ẹ̀sìn lómìnira àti ìyàsọ́tọ̀ nínú ọ̀ràn ìsìn àti ìgbàgbọ́.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a lè bá àìmọ̀kan tó jẹ́ lájorí okùnfà àìfún ẹ̀sìn lómìnira jà. Lọ́nà wo? Nípa ìlàlóye tí ó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ìròyìn Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Àjọ UN sọ pé: “Ìlàlóye lè jẹ́ olórí ohun tí a ó fi bá ìyàsọ́tọ̀ àti àìfún ẹ̀sìn lómìnira jà.”
Kí ló yẹ kí ó jẹ́ ète ìlàlóye yìí? Ìwé ìròyìn UNESCO Courier dábàá pé dípò kíkọ́wọ́ti kíkọ àwọn ìlépa onísìn sílẹ̀, “ó yẹ kí ìlàlóye nípa fífún ẹ̀sìn lómìnira fojú sun gbígbógun ti àwọn ipá agbára tí ń fa ìbẹ̀rù àti yíya àwọn mìíràn sọ́tọ̀, ó sì gbọ́dọ̀ ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti mú àwọn agbára òye wọn dàgbà láti lè dá ìpinnu ṣe, láti lè ronú jinlẹ̀, kí wọ́n sì ní èrò tí ó bá ìlànà ìwà híhù mu.”
Ó ṣe kedere pé àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde lè kó ipa pàtàkì nínú gbígbé “ìrònújinlẹ̀ àti èrò tí ó bá ìlànà ìwà híhù mu” lárugẹ. Ọ̀pọ̀ àjọ àgbáyé mọ agbára tí àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ní láti darí èrò àwọn ènìyàn àti láti fún òye tọ̀túntòsì níṣìírí. Ṣùgbọ́n bí àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde yóò bá fún ìwà fífún ẹ̀sìn lómìnira níṣìírí dípò gbígbé àìfún ẹ̀sìn lómìnira lárugẹ bí àwọn kan ti ṣe, ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n kọ ìròyìn tí ó ní láárí, tí a kò fẹ̀tanú ṣe. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn akọ̀ròyìn kò gbọ́dọ̀ fara mọ́ èrò tí gbogbo gbòò fara mọ́. Wọ́n gbọ́dọ̀ yiiri ọ̀rọ̀ wò dáadáa, kí wọ́n sì kọ ohun tí wọ́n rí láìṣègbè. Ṣùgbọ́n ìyẹn ha tó bí?
Ọ̀nà Tó Dára Jù Lọ Láti Bá Àìfún Ẹ̀sìn Lómìnira Jà
Fífún ẹ̀sìn lómìnira kò túmọ̀ sí pé gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ ní èrò kan náà. Àwọn ènìyàn lè ṣàìfohùnṣọ̀kan. Àwọn kan lè ronú gidigidi pé ohun tí àwọn mìíràn gbà gbọ́ kò tọ̀nà rárá. Wọ́n tilẹ̀ lè sọ nípa àwọn ohun tí wọn kò fohùn ṣọ̀kan lé lórí ní gbangba. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí wọn kò bá ti tan irọ́ kálẹ̀ nítorí àtisúnnásí kèéta, èyí kò túmọ̀ sí ìwà àìfẹ́ ti ẹlòmíràn. Àìfún ẹ̀sìn lómìnira máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí a bá ń ṣe inúnibíni sí ẹgbẹ́ kan, tí a gbé àwọn àkànṣe òfin kalẹ̀ nítorí wọn, tí a fọwọ́ rọ́ wọn sẹ́yìn, tí a fòfin dè wọ́n, tàbí tí a dí wọn lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ní ọ̀nà mìíràn. Nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó jẹ́ ti àṣejù àìfún ẹ̀sìn lómìnira, àwọn kan pànìyàn, àwọn mìíràn sì kú nítorí ìgbàgbọ́ wọn.
Báwo ni a ṣe lè bá àìfún ẹ̀sìn lómìnira jà? A lè sọ nípa rẹ̀ ní gbangba, bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ ní gbangba nípa ìwà àìfẹ́ ti ẹ̀sìn mìíràn tí àwọn aṣáájú ìsìn hù nígbà ayé rẹ̀. (Ìṣe 24:10-13) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí ó bá ṣeé ṣe, ọ̀nà tí ó dára jù láti bá àìfún ẹ̀sìn lómìnira jà ni láti sakun gan-an—láti gbé fífún ẹ̀sìn lómìnira lárugẹ, ìyẹn ni pé, láti kọ́ àwọn ènìyàn láti lóye àwọn ẹlòmíràn dáradára. Ìròyìn àjọ UN tó dá lórí mímú àìfún ẹ̀sìn lómìnira kúrò tí a tọ́ka sí níṣàájú sọ pé: “Níwọ̀n bí onírúurú àìfún ẹ̀sìn lómìnira àti ìyàsọ́tọ̀ tí a gbé karí ìsìn tàbí ìgbàgbọ́ ti pilẹ̀ṣẹ̀ lọ́kàn ẹ̀dá, ọkàn ẹ̀dá náà ló yẹ kí a kọ́kọ́ dojú ohun tí a fẹ́ ṣe kọ.” Irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ tilẹ̀ lè mú kí àwọn ènìyàn kan ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́.
Federico Mayor, olùdarí àgbà Àjọ Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà Ìbílẹ̀ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, kọ̀wé pé: “Fífún ẹ̀sìn lómìnira ni ìwà funfun ti onígbàgbọ́.” Àlùfáà ará Dominica náà, Claude Geffré kọ ọ́ sínú ìwé ìròyìn Réforme pé: “Fífún gbogbo ẹ̀sìn lómìnira ọgbọọgba ní gidi sinmi lórí ìgbàgbọ́ tó lágbára.” Ẹni tí ìgbàgbọ́ tirẹ̀ fi í lọ́kàn balẹ̀ lè má fòyà nípa ìgbàgbọ́ àwọn ẹlòmíràn.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí i pé ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbé àṣà fífún ẹ̀sìn lómìnira lárugẹ ni láti bá àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n jẹ́ onísìn mìíràn sọ̀rọ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí fi ọwọ́ pàtàkì mú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù náà pé, “a ó . . . wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè,” a sì mọ̀ wọ́n dáradára mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìjíhìnrere wọn. (Mátíù 24:14) Nínú iṣẹ́ yìí, wọ́n ní àǹfààní láti gbọ́ àlàyé tí àwọn mẹ́ńbà onírúurú ìsìn mìíràn—títí kan àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà pàápàá—ṣe nípa àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí múra tán láti ṣàlàyé àwọn ohun tí àwọn alára gbà gbọ́ fún àwọn tó bá fẹ́ gbọ́ wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ń mú kí àwọn ènìyàn ní ìmọ̀ àti òye púpọ̀ sí i. Irú ìmọ̀ àti òye bẹ́ẹ̀ ń mú kí ó túbọ̀ rọrùn fún fífún ẹ̀sìn lómìnira láti gbilẹ̀.
Fífún Ẹ̀sìn Lómìnira àti Jù Bẹ́ẹ̀ Lọ
Láìka èrò rere tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ní àti àwọn ipá tí àwọn kan ń sà sí, ó ṣe kedere pé àìfún ẹ̀sìn lómìnira ṣì jẹ́ ìṣòro lónìí. Kí ìyípadà gidi lè wà, ohun kan ṣì pọndandan. Ìwé ìròyìn èdè Faransé náà, Le Monde des débats, ṣàlàyé ìṣòro náà pé: “Àwùjọ ìwòyí sábà máa ń jìyà àìsí ìmọ̀lára àti ipò tẹ̀mí. Òfin lè dáàbò bo àwọn tí ń wu òmìnira ìsìn léwu. Òmìnira ìsìn lè mú níní ẹ̀tọ́ ọgbọọgba lábẹ́ òfin dáni lójú, láìsí ìyàsọ́tọ̀ tí a ṣe láìdúró gbẹ́jọ́, ó sì yẹ kí ó ṣe bẹ́ẹ̀.” Ìwé Democracy and Tolerance gbà pé: “Ọ̀nà wa ṣì jìn kí a tó lè ṣàṣeyọrí láti mú kí òye tọ̀túntòsì àti ọ̀wọ̀ di ọ̀pá ìdiwọ̀n ìhùwà jákèjádò ayé.”
Bíbélì ṣèlérí pé láìpẹ́ aráyé yóò wá ṣọ̀kan nínú ìjọsìn mímọ́ gaara ti Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà. Ìṣọ̀kan yìí yóò wá yọrí sí ẹgbẹ́ ará tòótọ́ kárí ayé, níbi tí ọ̀wọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn yóò ti gbilẹ̀. Ìwà àìmọ̀kan kò tún ní yọ aráyé lẹ́nu mọ́, níwọ̀n bí Ìjọba Ọlọ́run yóò ti fi ọ̀nà Jèhófà kọ́ àwọn ènìyàn, tí yóò wá tipa bẹ́ẹ̀ tẹ́ àìní wọn ní ti làákàyè, ìmọ̀lára, àti nípa tẹ̀mí lọ́rùn. (Aísáyà 11:9; 30:21; 54:13) Èròǹgbà jíjẹ́ ọgbọọgba àti wíwà ní òmìnira yóò bo ilẹ̀ ayé. (2 Kọ́ríńtì 3:17) Nípa jíjèrè òye pípéye nípa àwọn ète Ọlọ́run fún aráyé, o lè gbéjà ko ìwà àìmọ̀kan àti àìfún ẹ̀sìn lómìnira.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
A Wu Ìsìn Léwu
Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ìjọba ilẹ̀ Faransé ti gbìyànjú láti dọwọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà délẹ̀ ní ilẹ̀ Faransé nípa ṣíṣàìfún wọn ní àwọn àǹfààní kan náà tí wọ́n ń fún àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn. Láìpẹ́ yìí, wọ́n bu owó orí gọbọi fún wọn lórí àwọn ọrẹ tí wọ́n ń rí gbà fún ìtìlẹ́yìn àwọn ìgbòkègbodò ìjọsìn Àwọn Ẹlẹ́rìí. Àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Faransé fi àìtọ́ bu àádọ́ta mílíọ̀nù dọ́là (tíí ṣe owó orí àti owó ìtanràn), fún àwùjọ àwọn Kristẹni àti àwọn agbọ̀ràndùn wọn tí iye wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [200,000] ní ilẹ̀ Faransé, èyí tó hàn kedere pé wọ́n fẹ́ fi dọwọ́ wọn délẹ̀ ni. Ó hàn kedere pé èyí jẹ́ ìwà ẹ̀tanú ìsìn tí ó lòdì sí gbogbo ìlànà òmìnira, ẹgbẹ́ ará, àti ẹ̀tọ́ ọgbọọgba.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àìfẹ́ ti ẹ̀sìn mìíràn sábà máa ń yọrí sí ìwà ipá
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Pẹ̀lú gbogbo ìgbòkègbodò onísìn tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe, àwọn aláṣẹ kan ní ilẹ̀ Faransé sọ pé wọn kì í ṣe ẹ̀sìn!