ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 1/22 ojú ìwé 3-4
  • Ìráragbaǹkan—Láti Ìpẹ̀kun Kan sí Èkejì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìráragbaǹkan—Láti Ìpẹ̀kun Kan sí Èkejì
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Láti Ìráragbaǹkan sí Àìgba Ojú Ìwòye Ẹlòmíràn
  • Láti Orí Ìráragbaǹkan sí Orí Ìwà Pálapàla
  • Dídáàbòbo Òmìnira—Báwo?
    Jí!—1999
  • Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì Lè Mú Ayé Rẹ Dùn
    Jí!—1997
  • Jíjẹ́ Aláìrinkinkin, Síbẹ̀ Tí Ó Rọ̀ Mọ́ Ìlànà Àtọ̀runwá
    Jí!—1997
  • Àmúmọ́ra
    Jí!—2015
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 1/22 ojú ìwé 3-4

Ìráragbaǹkan—Láti Ìpẹ̀kun Kan sí Èkejì

ẸWÀ ìrísí Àfonífojì Kashmir sún ọlọ́gbọ́n èrò orí kan ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún láti polongo pé: “Bí párádísè bá wà níbikíbi, ibí ni!” Ní kedere, kò ní èrò kankan nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà ní apá yẹn nínú ayé. Láàárín ọdún márùn-ún tí ó kọjá, àwọn ènìyàn tí a ti pa níbẹ̀ nínú ogun láàárín àwọn olùyapa àti Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Íńdíà kò dín sí 20,000. Ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Germany náà, Süddeutsche Zeitung, ṣàpèjúwe ẹkùn ilẹ̀ yẹn nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí “àfonífojì omijé.” Àfonífojì Kashmir kọ́ni ní ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n kan, tí ó rọrùn, síbẹ̀ tí ó níye lórí, pé: Àìrára-gbaǹkan lè pa ohun tí ì bá jẹ́ párádísè kan run.

Kí ni ó túmọ̀ sí láti rára gba nǹkan? Ní ìbámu pẹ̀lú ìwé atúmọ̀ èdè náà, Collins Cobuild English Language Dictionary, “bí o bá rára gba nǹkan, ìwọ yóò máa gba àwọn ẹlòmíràn láyè láti tẹ̀ lé ọ̀nà ìṣarasíhùwà àti ìgbàgbọ́ tiwọn, tàbí láti hùwà lọ́nà pàtó kan, kódà, bí ìwọ kò bá fara mọ́ ọn tàbí tí o kò fọwọ́ sí i.” Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ìwà ànímọ́ dáradára tó láti fi hàn! Ó dájú pé ara máa ń tù wá láti wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n bá bọ̀wọ̀ fún ojú ìwòye àti ìṣarasíhùwà wa, àní nígbà tí ìwọ̀nyí bá yàtọ̀ sí tiwọn pàápàá.

Láti Ìráragbaǹkan sí Àìgba Ojú Ìwòye Ẹlòmíràn

Òdì kejì ìráragbaǹkan ni àìrára-gbaǹkan, tí ó ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìwọ̀n bí ó ṣe jinlẹ̀ tó. Àìrára-gbaǹkan lè bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àìfara mọ́ ìhùwàsí tàbí ọ̀nà ìṣeǹkan ẹlòmíràn, nítorí àìgbatẹnirò. Àìgbatẹnirò lè fún ayọ̀ pa nínú ìgbésí ayé, kí ó sì sé èrò inú ẹni pa sí àwọn ìrònú tuntun.

Bí àpẹẹrẹ, amúǹkankoko kan lè fà sẹ́yìn fún ìyáramọ́ni tí ọmọ kékeré kan fi hàn. Àwọn ọ̀nà onírònújinlẹ̀ tí àgbàlagbà kan tí ó ju ọ̀dọ́ kan lọ ń gbà ṣe nǹkan lè sú ọ̀dọ́ náà. Bí a bá sọ pé kí ẹnì kan tí ó níṣọ̀ọ́ra gidigidi bá olófìn-íntótó kan ṣe nǹkan pọ̀, àwọn méjèèjì yóò sì máa bínú. Èrèdí ìfàsẹ́yìn, ìsúni, àti ìbínú náà? Ó jẹ́ nítorí pé, nínú ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan, ó ń ṣòro fún èkíní láti mú àwọn ìṣarasíhùwà àti ìṣesí èkejì mọ́ra.

Níbi tí àìrára-gbaǹkan bá wà, àìgbatẹnirò lè tẹ̀ síwájú di ẹ̀tanú, tí ó jẹ́ yíyẹra fún àwùjọ, tàbí ẹ̀yà ìran, tàbí ìsìn kan. Ọ̀kan tí ó tún jinlẹ̀ ju ẹ̀tanú lọ ni àìgba ojú ìwòye ẹlòmíràn, tí ó lè fi ara rẹ̀ hàn nípasẹ̀ ìkórìíra oníwà ipá. Àbájáde rẹ̀ ni ìsoríkọ́ àti ìtàjẹ̀sílẹ̀. Ronú lórí ohun tí àìrára-gbaǹkan fà nígbà àwọn Ogun Ìsìn! Lónìí pàápàá, àìrára-gbaǹkan jẹ́ kókó abájọ kan nínú àwọn ìforígbárí ní Bosnia, Rwanda, àti Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn.

Ìráragbaǹkan béèrè ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, kò sì rọrùn láti ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ńṣe la dà bí ẹpọ̀n agogo, tí ń fì láti ẹ̀gbẹ́ kan sí èkejì. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a ń ní ìwọ̀n ìráragbaǹkan kíkéré jù; nígbà míràn, ó ń pọ̀ jù.

Láti Orí Ìráragbaǹkan sí Orí Ìwà Pálapàla

Ó ha ṣeé ṣe láti tàṣejù bọ ìráragbaǹkan bí? Nígbà tí Aṣòfin Àgbà Dan Coats ti United States ń sọ̀rọ̀ ní 1993, ó ṣàpèjúwe “àríyànjiyàn kan lórí ìtúmọ̀ àti ìṣe ìráragbaǹkan.” Kí ni ó ní lọ́kàn? Aṣòfin àgbà náà kédàárò pé, lórúkọ ìráragbaǹkan, àwọn kan “pa ìgbàgbọ́ nínú òtítọ́ ìwà rere—nínú ohun rere àti búburú, nínú ohun títọ́ àti àìtọ́—tì.” Irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ rò pé àwùjọ kò lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tí ó jẹ́ ìwà rere àti ohun tí ó burú.

Ní 1990, òṣèlú ọmọ ilẹ̀ Britain kan, Alàgbà Hailsham, kọ̀wé pé, “ọ̀tá búburú jù lọ tí ìwà rere ní kì í ṣe àìgbọlọ́rungbọ́, ìgbàgbọ́ àìlèmọlọ́run, ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì, ìwọra tàbí èyíkéyìí lára àwọn okùnfà tí a ti tẹ́wọ́ gbà tẹ́lẹ̀. Ojúlówó ọ̀tá ìwà rere ni àìnígbàgbọ́, ní olówuuru, àìní ìgbàgbọ́ nínú ohunkóhun.” Ní kedere, bí a kò bá gba ohunkóhun gbọ́, a kò ní ọ̀pá ìdíwọ̀n ìwà yíyẹ, a sì lè mú gbogbo nǹkan mọ́ra. Ṣùgbọ́n, ó ha tọ́ láti mú gbogbo onírúurú ọ̀nà ìwà híhù mọ́ra bí?

Ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ gíga kan ní Denmark kò rò bẹ́ẹ̀. Ó kọ àpilẹ̀kọ kan sínú ìwé agbéròyìnjáde ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1970, nínú èyí tí ó ti ráhùn nípa àwọn ìpolówó ọjà ẹ̀ka ìgbéròyìnjáde tí ó níí ṣe pẹ̀lú àfihàn àwòrán tí ń rùfẹ́ ìṣekúṣe sókè, tí ń fi ìbálòpọ̀ láàárín àwọn ẹranko àti àwọn ènìyàn hàn. Wọ́n fàyè gba àwọn ìpolówó ọjà wọ̀nyí nítorí “ìráragbaǹkan” tí Denmark ní.

Ó ṣe kedere pé, ríráragbaǹkan díẹ̀ ṣín-ún ń fa ìṣòro, títàṣejù bọ̀ ọ́ pẹ̀lú ń ṣe bẹ́ẹ̀. Èé ṣe tí kò fi rọrùn láti yẹra fún ṣíṣàṣejù, kí a sì ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì? Jọ̀wọ́, ka àpilẹ̀kọ tí ó kàn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Híhùwàpadà ju bó ṣe yẹ lọ sí àṣìṣe àwọn ọmọdé lè pa wọ́n lára

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Mímú gbogbo ohun tí àwọn ọmọdé bá ń ṣe mọ́ra kò níí múra wọn sílẹ̀ fún ẹrù iṣẹ́ ìgbésí ayé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́