ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 1/22 ojú ìwé 7-9
  • Jíjẹ́ Aláìrinkinkin, Síbẹ̀ Tí Ó Rọ̀ Mọ́ Ìlànà Àtọ̀runwá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jíjẹ́ Aláìrinkinkin, Síbẹ̀ Tí Ó Rọ̀ Mọ́ Ìlànà Àtọ̀runwá
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹlẹ́dàá Náà—Àpẹẹrẹ Títóbi Jù Lọ fún Wa
  • Dídúró Gbọnyin, Síbẹ̀ Láìrinkinkin
  • Ìdẹkùn Ṣíṣàṣejù Nínú Ìráragbaǹkan
  • Ipò Ìbátan Lílágbára Pẹ̀lú Jèhófà
  • Ìgbà Ń Yí Pa Dà
  • Ìráragbaǹkan—Láti Ìpẹ̀kun Kan sí Èkejì
    Jí!—1997
  • Bíbélì Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Ká Lè Máa Bọ̀wọ̀ fún Èrò Àwọn Míì
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Àmúmọ́ra
    Jí!—2015
  • Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì Lè Mú Ayé Rẹ Dùn
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 1/22 ojú ìwé 7-9

Jíjẹ́ Aláìrinkinkin, Síbẹ̀ Tí Ó Rọ̀ Mọ́ Ìlànà Àtọ̀runwá

ÒWE ilẹ̀ China kan sọ pé: “Àwọn aráragbaǹkan kì í ṣe sùgọ́mù, àwọn sùgọ́mù kì í sì í mú nǹkan mọ́ra.” Òtítọ́ gidi ni òwe náà, níwọ̀n bí jíjẹ́ aráragbaǹkan ti jẹ́ ìpèníjà, tí ń béèrè pé kí a fara jin àwọn ìlànà ìhùwàsí bíbẹ́tọ̀ọ́mu. Ṣùgbọ́n àwọn ìlànà wo ni ó yẹ kí a fara wa jìn? Kì yóò ha bọ́gbọ́n mu láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà tí Olùṣẹ̀dá ìran ènìyàn gbé kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé wọn nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì Mímọ́? Ọlọ́run fúnra rẹ̀ fi àpẹẹrẹ dídára jù lọ lélẹ̀ ní rírọ̀ mọ́ àwọn ìlànà rẹ̀.

Ẹlẹ́dàá Náà—Àpẹẹrẹ Títóbi Jù Lọ fún Wa

Ọlọ́run Olódùmarè, Jèhófà, wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì pípé ní ti ìráragbaǹkan, kò ní ju bí ó ti yẹ lọ, kò sì ṣàìnító. Fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, ó ti fàyè gba àwọn tí ń pẹ̀gàn orúkọ rẹ̀, tí wọ́n ń ba aráyé jẹ́, tí wọ́n sì ń ṣe ilẹ̀ ayé níṣekúṣe. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ nínú Róòmù 9:22, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé Ọlọ́run “fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpamọ́ra fàyè gba àwọn ohun ìlò ìrunú tí a mú yẹ fún ìparun.” Èé ṣe tí Ọlọ́run fi fàyè gbà á pẹ́ tó bẹ́ẹ̀? Nítorí pé ìráragbaǹkan rẹ̀ ní ète kan ni.

Ọlọ́run ń mú sùúrù fún aráyé “nítorí pé òun kò ní ìfẹ́ ọkàn pé kí ẹnikẹ́ni pa run, ṣùgbọ́n ó ní ìfẹ́ ọkàn pé kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (Pétérù Kejì 3:9) Ẹlẹ́dàá ti fún aráyé ní Bíbélì, ó sì ti yanṣẹ́ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti sọ àwọn ìlànà rẹ̀ lórí ìhùwàsí di mímọ̀ níbi gbogbo. Àwọn Kristẹni tòótọ́ ti fara jin àwọn ìlànà wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n, èyí ha túmọ̀ sí pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní láti máa rin kinkin nínú gbogbo ọ̀ràn bí?

Dídúró Gbọnyin, Síbẹ̀ Láìrinkinkin

Jésù Kristi fún àwọn tí ń wá ìyè ayérayé níṣìírí láti “gba ẹnubodè tóóró wọlé.” Ṣùgbọ́n gbígba ẹnubodè tóóró wọlé kò túmọ̀ sí níní ìrònú tóóró. Bí a bá máa ń ní ìtẹ̀sí láti máa jẹ gàba léni lórí tàbí láti máa pàṣẹ wàá nígbà tí a bá wà pẹ̀lú àwọn mìíràn, ó dájú pé ohun tí yóò mú kí ìgbésí ayé túbọ̀ tu ẹni gbogbo lára ni kí a kápá ìtẹ̀sí yìí. Ṣùgbọ́n báwo?—Mátíù 7:13; Pétérù Kíní 4:15.

Theofano, akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì kan, tí ó ṣàlàyé pé àkókò tí òun lò pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ipò wọn yàtọ̀ síra ran òun lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye wọn dáradára sí i, wí pé: “Ó ṣe pàtàkì pé kí a gbìyànjú ọ̀nà ìrònú wọn, dípò kí a fipá mú wọn tẹ̀ sí tiwa.”

Nítorí náà, nípa títúbọ̀ mọ ẹnì kan dáradára sí i, a lè rí i pé irú oúnjẹ tí ó fẹ́ràn, kódà, ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ pàápàá, kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ tó bí a ṣe rò. Kàkà kí a máa ní èyí tí ó pọ̀ jù lọ láti sọ tàbí kí a máa rin kinkin mọ́ kí abẹ gé èyí tí a bá sọ, ọ̀pọ̀ ohun tí ó wúlò ni a ń rí kọ́ nípa fífetí sí ojú ìwòye tirẹ̀. Ní gidi, ìgbésí ayé túbọ̀ ń ṣàǹfààní fún àwọn ènìyàn olótìítọ́ ọkàn.

Nígbàkígbà tí ọ̀ràn bá kan ohun tí a fẹ́ fúnra ẹni, kò yẹ kí a rin kinkin, ó yẹ kí a jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn gbádùn ohun tí wọ́n yàn. Ṣùgbọ́n, nígbà tí ìhùwàsí bá jẹ́ ọ̀ràn ìgbọ́ràn sí Ẹlẹ́dàá wa, a gbọ́dọ̀ rin kinkin. Ọlọ́run Olódùmarè kì í gbọ̀jẹ̀gẹ́ fún gbogbo onírúurú ìhùwàsí. Ó fi èyí hàn nínú ọ̀nà tí ó gbà bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lò látijọ́.

Ìdẹkùn Ṣíṣàṣejù Nínú Ìráragbaǹkan

Élì, àlùfáà àgbà kan ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì, jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan tí ó kó sínú ìdẹkùn àṣejù ìráragbaǹkan. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti bá Ọlọ́run wọnú ìbátan onímájẹ̀mú kan, wọ́n sì gbà láti ṣègbọ́ràn sí àwọn òfin rẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọkùnrin Élì méjèèjì, Hófínì àti Fíníhásì, jẹ́ oníwọra àti oníwà pálapàla, wọ́n sì ṣàìbọ̀wọ̀ fún Olódùmarè lọ́nà kíkàmàmà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Élì mọ Òfin Ọlọ́run dunjú gan-an, ìbáwí fẹ́ẹ́rẹ́ lásán ló fún wọn, ó sì dẹwọ́ ní bíbániwí. Ó ṣe àṣìṣe ní rírò pé Ọlọ́run yóò fàyè gba ìwà ibi. Ẹlẹ́dàá fi ìyàtọ̀ hàn láàárín àìlera àti ìmọ̀ọ́mọ̀ṣebi. Nítorí pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ rú Òfin Ọlọ́run, a fìyà jẹ àwọn ọmọkùnrin oníwà ibi tí Élì bí gidigidi—ó sì tọ́ bẹ́ẹ̀.—Sámúẹ́lì Kíní 2:12-17, 22-25; 3:11-14; 4:17.

Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ọ̀ràn ìbànújẹ́ tó fún wa láti tàṣejù bọ ìráragbaǹkan nínú ìdílé wa nípa ṣíṣàìka ìwà àìtọ́ tí àwọn ọmọ wa ń hù léraléra sí! Ẹ wo bí ó ti sàn jù tó láti tọ́ wọn dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà”! Èyí túmọ̀ sí pé àwa fúnra wa ní láti rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà àtọ̀runwá lórí ìwà híhù, kí a sì tẹ̀ wọ́n mọ́ àwọn ọmọ wa lọ́kàn.—Éfésù 6:4.

Lọ́nà kan náà, ìjọ Kristẹni kò lè fàyè gba ìmọ̀ọ́mọ̀ṣebi. Bí mẹ́ńbà kan bá ń hùwà ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo, tí ó sì kọ̀ láti ronú pìwà dà, a ní láti yọ ọ́ kúrò. (Kọ́ríńtì Kíní 5:9-13) Bí ó ti wù kí ó rí, yàtọ̀ sí nínú agbo ìdílé àti ìjọ, àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í gbìyànjú láti yí ẹgbẹ́ àwùjọ lódindi pa dà.

Ipò Ìbátan Lílágbára Pẹ̀lú Jèhófà

Àìrára-gbaǹkan ń yọrí sí àyíká oníhílàhílo. Bí ó ti wù kí ó rí, bí a bá ní ipò ìbátan ara ẹni tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, a óò gbádùn ìmọ̀lára ààbò tí ń mú kí a lè ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. A kà nínú Òwe 18:10 pé: “Orúkọ Olúwa, ilé ìṣọ́ agbára ni: Olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì là.” Dájúdájú, ibi kankan, tí Ẹlẹ́dàá kì yóò lè bójú tó ní àkókò tirẹ̀, kò lè ṣẹlẹ̀ sí àwa tàbí àwọn olólùfẹ́ wa.

Ẹnì kan tí ó jàǹfààní gidigidi láti inú ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Gẹ́gẹ́ bíi Júù kan tí a mọ̀ sí Sọ́ọ̀lù, ó ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi, ó sì jẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀. Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ wáá di Kristẹni, ó sì kó wọnú iṣẹ́ ìjíhìnrere alákòókò kíkún lẹ́yìn náà, nígbà tí a wáá mọ̀ ọ́n sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Pọ́ọ̀lù fi ìṣarasíhùwà olótìítọ́ ọkàn hàn ní wíwàásù fún gbogbo ènìyàn, “[fún] àwọn Gíríìkì àti àwọn Aláìgbédè, [fún] àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn òpònú.”—Róòmù 1:14, 15; Ìṣe 8:1-3.

Báwo ló ṣe rọ́nà yí pa dà? Nípa níní ìmọ̀ pípéye nípa Ìwé Mímọ́ àti nípa mímú ìfẹ́ dàgbà fún Ẹlẹ́dàá, tí kì í ṣe ojúsàájú. Pọ́ọ̀lù kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú ní ti pé Òun kì í ṣèdájọ́ ẹni lórí àṣà ìbílẹ̀ tàbí ẹ̀yà ìran, ṣùgbọ́n ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí olúwarẹ̀ jẹ́, tí ó sì ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ohun tí a ṣe ni ó ṣe pàtàkì sí Ọlọ́run. Pétérù sọ pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo, ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Ọlọ́run Olódùmarè kò ní ẹ̀tanú. Èyí yàtọ̀ sí ti àwọn kan nínú àwọn aṣáájú ayé, tí wọ́n lè mọ̀ọ́mọ̀ lo àìrára-gbaǹkan fún ète ti ara wọn.

Ìgbà Ń Yí Pa Dà

Gẹ́gẹ́ bí John Gray, láti Yunifásítì Oxford, ní England, ṣe sọ, ìráragbaǹkan jẹ́ “ìwà funfun kan tí ó ti ṣọ̀wọ́n ní lọ́ọ́lọ́ọ́.” Ṣùgbọ́n èyí yóò yí pa dà. Ìráragbaǹkan tí ọgbọ́n àtọ̀runwá mú kí ó wà déédéé yóò borí.

Nínú ayé tuntun Ọlọ́run tí ó dé tán, kì yóò sí àìrára-gbaǹkan mọ́. Àwọn àfihàn àìrára-gbaǹkan tí ó lọ ré kọjá ààlà, irú bí ẹ̀tanú àti àìgba ojú ìwòye ẹlòmíràn, kì yóò sí mọ́. Àìgbatẹnirò kì yóò há ìjẹ̀gbádùn ìwàláàyè lọ́rùn mọ́. Nígbà náà, a óò ní párádísè kan tí ó tóbi lọ́lá gidigidi ju èyí tí ó tí ì wà ní Àfonífojì Kashmir nígbà kankan rí lọ.—Aísáyà 65:17, 21-25.

O ha ń fojú sọ́nà láti gbé nínú ayé tuntun yẹn bí? Ẹ wo irú àǹfààní tí ìyẹn yóò jẹ́ àti bí yóò ṣe múni láyọ̀ tó!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìwọ̀ntúnwọ̀nsì hàn nítorí pé ó ní ipò ìbátan kan pẹ̀lú Ọlọ́run

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́