ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 1/22 ojú ìwé 10-12
  • Ó Ha Yẹ Kí N Jẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ Mi Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Ha Yẹ Kí N Jẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ Mi Bí?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Kò Sí Ohun Tí A Fi Pa Mọ́ Láṣìírí”
  • Sísọ̀rọ̀ Jáde
  • Sísọ fún Àwọn Òbí Rẹ
  • Títọ Àwọn Alàgbà Lọ
  • ‘Ẹ̀rù Ìyọlẹ́gbẹ́ Ń Bà Mí’
  • Máa Gba Ìbáwí Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ṣé Ọlọ́run Béèrè Pé Ká Máa Jẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Kí Lo Lè Ṣe Tó O Bá Dá Ẹ̀ṣẹ̀ Tó Burú Gan-an?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ẹ̀bi Ẹ̀ṣẹ̀—‘Wẹ̀ Mí Mọ́ Kúrò Nínú Ẹ̀ṣẹ̀ Mi’
    Jọ̀wọ́ Pa Dà Sọ́dọ̀ Jèhófà
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 1/22 ojú ìwé 10-12

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Ó Ha Yẹ Kí N Jẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ Mi Bí?

“Ó ń tì mí lójú gan-an, n kò mọ ohun tí ó yẹ kí n ṣe. Mo fẹ́ẹ́ lọ bá àwọn òbí mi, ṣùgbọ́n, ó ń tì mí lójú púpọ̀ jù.”—Lisa.a

OHUN tí ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan tí ìpáyà bá kọ síwèé nìyẹn. Ó ti wọnú eré ìfẹ́ pẹ̀lú aláìgbàgbọ́ kan fún ọdún mélòó kan, ó sì bá a lò pọ̀ lọ́jọ́ kan, nígbà tí ó ti mutí yó.

Ó bani nínú jẹ́ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ látìgbàdégbà, kódà láàárín àwọn èwe Kristẹni pàápàá. Bí ọjọ́ orí wa àti ìrírí tí a ní bá ṣe kéré tó, ni a ṣe lè ṣàṣìṣe tó. Ṣùgbọ́n nígbà tí ṣíṣe àṣìṣe kékeré kan jẹ́ ohun kan, dídá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo kan, bí ìwà pálapàla takọtabo, jẹ́ ohun mìíràn tí ó yàtọ̀ gedegbe. (Kọ́ríńtì Kíní 6:9, 10) Bí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀, ó yẹ kí a ran èwe kan lọ́wọ́. Ìṣòro tí ó wà níbẹ̀ ni pé, kò rọrùn láti jẹ́wọ́ àwọn ìṣìnà ẹni.

Ọmọdébìnrin Kristẹni kan ní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó. Ó pinnu láti jẹ́wọ́ fún àwọn alàgbà nínú ìjọ tí ó wà, ó tilẹ̀ yan ọjọ́ kan tí yóò ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n ó sún ọjọ́ náà síwájú. Lẹ́yìn náà, ó tún sún ọjọ́ náà síwájú. Láìpẹ́, odindi ọdún kan kọjá lọ!

“Kò Sí Ohun Tí A Fi Pa Mọ́ Láṣìírí”

Bí o bá ti dẹ́ṣẹ̀ wíwúwo kan, ó yẹ kí o mọ̀ pé mímẹ́numọ́ jẹ́ èrò tí kò lọ́gbọ́n nínú. Ohun kan ni pé, lọ́nàkọnà, òtítọ́ sábà máa ń fara hàn. Nígbà tí Mark wà lọ́mọdé, ó fọ́ ohun ọ̀ṣọ́ ara ògiri kan tí wọ́n fi tánńganran ṣe. Ó sọ pé: “Mo gbìyànjú láti lẹ̀ ẹ́ pọ̀ mọ́ra tìṣọ́ratìṣọ́ra, ṣùgbọ́n kò pẹ́ tí àwọn òbí mi fi rí ibi tí ó sán náà.” Òtítọ́ ni pé, o kì í ṣe ọmọdé mọ́. Ṣùgbọ́n òbí púpọ̀ jù lọ sábà lè mọ̀ bí ohun kan bá kù díẹ̀ káà tó pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn.

Ann, ọmọ ọdún 15, jẹ́wọ́ pé: “Mo gbìyànjú láti fi irọ́ bo àwọn ìṣòro mi mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ńṣe ni mo túbọ̀ ń mú kí wọ́n burú sí i.” Lọ́pọ̀ ìgbà, àṣírí irọ́ ń tú. Nígbà tí àwọn òbí rẹ bá sì wáá mọ̀ pé irọ́ lo pa, ó ṣeé ṣe kí ọkàn wọn dà rú—kí ó dà rú ju bí ì bá ti ṣe bí o bá ti jẹ́wọ́ fún wọn níbẹ̀rẹ̀ lọ.

Ní pàtàkì jù bẹ́ẹ̀ lọ, Bíbélì sọ pé: “Kò sí ohun tí a fi pa mọ́ láṣìírí tí kì yóò fara hàn kedere, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohunkóhun tí a rọra fi pa mọ́ níkọ̀kọ̀ tí kì yóò di mímọ̀, tí kì yoo sì wá sí ojútáyé.” (Lúùkù 8:17) Jèhófà ń mọ ohun tí a ti ṣe àti ohun tí a ń ṣe lọ́wọ́. O kò lè fi nǹkan pa mọ́ fún un ju bí Ádámù ti lè ṣe lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 3:8-11) Láìpẹ́, àṣírí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ lè tú sọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.—Tímótì Kíní 5:24.

Mímẹ́numọ́ lè pa ọ́ lára ní àwọn ọ̀nà míràn pẹ̀lú. Onísáàmù náà, Dáfídì, kọ̀wé pé: “Nígbà tí mo dákẹ́, egungun mi di gbígbó nítorí igbe mi ní gbogbo ọjọ́. Nítorí ní ọ̀sán àti ní òru, ọwọ́ rẹ wúwo sí mi lára.” (Orin Dáfídì 32:3, 4) Bẹ́ẹ̀ ni, ipá tí ó gbà láti pa àṣírí mọ́ lè kó bá èrò ìmọ̀lára rẹ. Àníyàn àti ẹ̀bi, pa pọ̀ mọ́ ìbẹ̀rù ìtúfó, lè mú ọ rẹ̀wẹ̀sì pátápátá. O lè bẹ̀rẹ̀ sí í yẹra fún àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí. O tilẹ̀ lè nímọ̀lára pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ti yà ọ́ nípa! Èwe kan tí ń jẹ́ Andrew kọ̀wé pé: “Mo ti ń bá ẹ̀rí ọkàn ìmọ̀lára ẹ̀bi yí fún mímú Jèhófà banú jẹ́. Ó ń dà mí láàmú.”

Sísọ̀rọ̀ Jáde

Ọ̀nà kankan ha wà láti bọ́ lọ́wọ́ pákáǹleke èrò ìmọ̀lára yìí bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ó wà! Onísáàmù náà wí pé: “Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ, àti ẹ̀ṣẹ̀ mi ni èmi kò sì fi pa mọ́. . . . Ìwọ sì dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.” (Orin Dáfídì 32:5; fi wé Jòhánù Kíní 1:9.) Bákan náà ni Andrew rí ojúlówó ìtura nípa jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ó sọ pé: “Mo tọ Jèhófà lọ, mo sì fìtara ọkàn gbàdúrà sí i fún ìdáríjì.”

O lè ṣe bákan náà. Gbàdúrà sí Jèhófà. Ó mọ ohun tí o ti ṣe, ṣùgbọ́n, rọra jẹ́wọ́ rẹ̀ fún un nínú àdúrà. Bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì, má fà sẹ́yìn nítorí ìbẹ̀rù pé o ti burú jù láti rí ìrànlọ́wọ́ gbà. Jésù kú kí a lè gbádùn ipò ìdúró rere pẹ̀lú Ọlọ́run láìka ti pé a jẹ́ aláìpé sí. (Jòhánù Kíní 2:1, 2) O tún lè béèrè fún okun láti ṣe àwọn ìyípadà tí ó pọn dandan. Kíka Orin Dáfídì 51 lè ṣàǹfààní fún ọ ní pàtàkì nínú títọ Ọlọ́run lọ lọ́nà yí.

Sísọ fún Àwọn Òbí Rẹ

Bí ó ti wù kí ó rí, a nílò ju wíwulẹ̀ jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run lọ. Ó tún pọn dandan fún ọ láti sọ fún àwọn òbí rẹ. Ọlọ́run ti pàṣẹ fún wọn láti tọ́ ọ dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Wọ́n lè ṣe èyí, kìkì bí wọ́n bá mọ àwọn ìṣòro rẹ. Láfikún, sísọ fún àwọn òbí rẹ lè ṣàìrọrùn tàbí kí ó má dùn mọ́ ọ. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìhùwàpadà wọn àkọ́kọ́, ó ṣeé ṣe kí wọ́n lè kápá èrò ìmọ̀lára wọn. Ó tilẹ̀ lè dùn mọ́ wọn pé o fọkàn tán wọn débi pé o fi ìṣòro rẹ hàn wọ́n. Òwe Jésù nípa ọmọkùnrin onínàá-kúnàá sọ nípa ọ̀dọ́kùnrin kan tí ó dẹ́ṣẹ̀ ìwà pálapàla takọtabo. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wáá jẹ́wọ́ níkẹyìn, bàbá rẹ̀ fi ìmúratán gbà á pa dà! (Lúùkù 15:11-24) Kò síyè méjì pé àwọn òbí rẹ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ bákan náà. Ó ṣe tán, wọ́n fẹ́ràn rẹ síbẹ̀.

Òtítọ́ ni pé, o lè máa bẹ̀rù láti má ṣe ba àwọn òbí rẹ lọ́kàn jẹ́. Ṣùgbọ́n kì í ṣe jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ náà ló ń ba àwọn òbí rẹ lọ́kàn jẹ́; dídá ẹ̀ṣẹ̀ náà ní ń ṣe bẹ́ẹ̀! Jíjẹ́wọ́ jẹ́ ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ láti pèsè ìtura nítorí ìbàjẹ́ náà. Ann, tí a mẹ́nu bà ṣáájú, sọ fún àwọn òbí rẹ̀, ó sì ní ìtura kíkàmàmà lẹ́yìn náà.b

Síbẹ̀, ìdènà míràn fún ìjẹ́wọ́ ni ìtìjú àti ìsájú. Akọ̀wé olóòótọ́ náà, Ẹ́sírà, kò fúnra rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn Júù ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ó wí pé: “Ojú tì mí, ìsájú sì ṣe mí láti gbé ojú mi sókè sí ọ̀dọ̀ rẹ, Ọlọ́run mi.” (Ẹ́sírà 9:6) Ní gidi, ó bójú mu pé kí ojú tì ọ́ nígbà tí o bá ṣe ohun tí kò tọ́. Ó fi hàn pé ẹ̀rí ọkàn rẹ ṣì ń ṣiṣẹ́. Bí àkókò sì ṣe ń lọ, àwọn ìmọ̀lára ìtìjú wọ̀nyẹn yóò rọlẹ̀. Andrew sọ ọ́ báyìí pé: “Ó ṣòro gan-an láti jẹ́wọ́, ó sì ń tini lára. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun ìtura láti mọ̀ pé Jèhófà yóò dárí jini lọ́pọ̀lọpọ̀.”

Títọ Àwọn Alàgbà Lọ

Bí o bá jẹ́ Kristẹni, ọ̀ràn náà kò parí síbi sísọ fún àwọn òbí rẹ. Andrew sọ pé: “Mo mọ̀ pé mo ní láti fi ìṣòro mi tó àwọn alàgbà ìjọ létí. Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ìtura tó láti mọ̀ pé wọ́n wà níbẹ̀ láti ràn mí lọ́wọ́!” Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn èwe láàárín Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè tọ àwọn alàgbà lọ fún ìrànlọ́wọ́ àti ìṣírí, ó sì yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n èé ṣe tí o kò fi lè wulẹ̀ gbàdúrà sí Jèhófà, kí o sì fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀? Ó jẹ́ nítorí pé Jèhófà ti fún àwọn alàgbà ni ẹrù iṣẹ́ “[ṣíṣọ́] ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín.” (Hébérù 13:17) Wọ́n lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yẹra fún títún ẹ̀ṣẹ̀ dá.—Fi wé Jákọ́bù 5:14-16.

Má tan ara rẹ jẹ ní ríronú pé o lè ran ara rẹ lọ́wọ́. Bí o bá lókun tó láti ṣe bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ò bá ti dẹ́ṣẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́ gan-an? Ó ṣe kedere pé, o ní láti wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ ẹlòmíràn. Andrew fìgboyà ṣe bẹ́ẹ̀. Kí ni ìmọ̀ràn tí ó fúnni? “Mo rọ ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀ wíwúwo, tàbí tí ó ti ṣe bẹ́ẹ̀, láti tú ọkàn àyà rẹ̀ jáde fún Jèhófà àti ọ̀kan nínú àwọn olùṣọ́ àgùntàn rẹ̀.”

Ṣùgbọ́n, báwo ni o ṣe lè sọ fún alàgbà kan? Yan alàgbà kan tí o rò pé ara ń tù ọ́ láti bá sọ̀rọ̀. O lè bẹ̀rẹ̀ nípa sísọ pé: “Mo ní ohun kan láti bá ọ sọ” tàbí “Mo ní ìṣòro kan” tàbí kódà, “Mo ní ìṣòro kan, mo sì nílò ìrànwọ́ rẹ.” Jíjẹ́ tí o jẹ́ olóòótọ́ ọkàn, tí o kò sì fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, yóò jẹ́rìí gbe ìrònúpìwàdà rẹ àti ìfẹ́ ọkàn rẹ láti yí pa dà.

‘Ẹ̀rù Ìyọlẹ́gbẹ́ Ń Bà Mí’

Ṣíṣeéṣe yẹn ńkọ́? Òtítọ́ ni pé dídẹ́ṣẹ̀ wíwúwo ń sọ ẹnì kan di ẹni tí a lè yọ lẹ́gbẹ́, ṣùgbọ́n kì í ṣe lọ́nàkọnà. Ìyọlẹ́gbẹ́ wà fún àwọn tí wọ́n bá kọ̀ láti ronú pìwà dà—tí wọ́n foríkunkun kọ̀ láti yí pa dà. Òwe 28:13 wí pé: “Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò ṣe rere: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́wọ́, tí ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀ yóò rí àánú.” Kókó náà pé o ti tọ àwọn alàgbà lọ fún ìrànlọ́wọ́ jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ ọkàn rẹ láti yí pa dà. Ni ìpìlẹ̀, awonisàn ni àwọn alàgbà, wọn kì í ṣe ajẹniníyà. Wọ́n wà lábẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti fi inú rere àti ọ̀wọ̀ ara ẹni bá àwọn ènìyàn Ọlọ́run lò. Wọn ń fẹ́ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kí o lè ṣe “ipa ọ̀nà títọ́ fún ẹsẹ̀ [rẹ].”—Hébérù 12:13.

Láìsí sísẹ́, níbi tí ọ̀ràn bá ti ní ẹ̀tàn tàbí sísọ dídá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo dàṣà nínú, “àwọn iṣẹ́ tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà” tí ó dájú lè máà sí. (Ìṣe 26:20) Nígbà míràn, ó lè yọrí sí ìyọlẹ́gbẹ́. Kódà, níbi tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan ti ronú pìwà dà, àìgbọ́dọ̀máṣe ni fún àwọn alàgbà láti fún un ní oríṣi ìbáwí kan. Ó ha yẹ kí o bínú, kí o sì banú jẹ́ lórí ìpinnu wọn bí? Nínú Hébérù 12:5, 6, Pọ́ọ̀lù rọni pé: “Ọmọ mi, má ṣe fi ojú kékeré wo ìbáwí láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí ó bá tọ́ ọ sọ́nà; nítorí ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó máa ń bá wí; ní ti tòótọ́, ó máa ń na olúkúlùkù ẹni tí òun gbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ lọ́rẹ́.” Irú ìbáwí yòó wù kí wọ́n fún ọ, wò ó bí ẹ̀rí pé Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ. Rántí pé ojúlówó ìrònúpìwàdà yóò tún mú ọ pa dà sínú ipò ìbátan yíyẹ pẹ̀lú Bàbá wa aláàánú, Jèhófà Ọlọ́run.

Ó gba ìgboyà láti gbà pé o ṣàṣìṣe. Ṣùgbọ́n nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe kìkì pé o lè ṣàtúnṣe àwọn ọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ nìkan ni, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀. Má ṣe jẹ́ kí ìbẹ̀rù, ìgbéraga, tàbí ìtinilára fà ọ́ sẹ́yìn láti gba ìrànwọ́. Rántí pé: Jèhófà “yóò . . . fi jì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.”—Aísáyà 55:7.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

b Fún ìsọfúnni lórí bí o ṣe lè sọ fún àwọn òbí rẹ, wo orí 2 nínú ìwé náà, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]

‘Mo rọ gbogbo àwọn tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ láti tú ọkàn àyà wọn jáde fún Jèhófà.’—Andrew

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Jíjẹ́wọ́ fún àwọn òbí rẹ lè ṣamọ̀nà sí ìkọ́fẹpadà tẹ̀mí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́