Irà Oníkoríko Ti Florida—Ìpè Kíkankíkan Láti Inú Igbó
Ó MÁA ń fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù kan àlejò tí ń rọ́ lọ sí àgbàyanu párádísè ilẹ̀ olóoru yìí lọ́dọọdún láti wo àwọn ìyanu iṣẹ́ ọwọ́ Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá. Níhìn-ín, kò sí àwọn òkè àfonífojì olómi jíjìn gan-an tàbí àwọn bèbè òkè ńlá gíga fíofío tí ó lè múni bẹ̀rù jìnnìjìnnì, kò sí ìtàkìtì omi ńlá tí a lè ya fọ́tò rẹ̀, kò sí ẹranko moose alárìnká kan tàbí àwọn béárì tí ń rìn nínú ọláńlá tí a lè wò nítòsí láìséwu. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọgbà Irà Oníkoríko ti Orílẹ̀-Èdè ni ọgbà orílẹ̀-èdè tí a kọ́kọ́ gbé kalẹ̀ lágbàáyé nítorí ọ̀pọ̀ yanturu ohun alààyè inú rẹ̀ dípò ìran kíkàmàmà.
Àwọn apá kan rẹ̀ jẹ́ ilẹ̀ oníkoríko, àwọn apá yòó kù jẹ́ irà ilẹ̀ olóoru, a ti pè é ní “odò oníkoríko.” Àwọn ohun alààyè tí ń gbé inú rẹ̀ ń bá ìgbésí ayé wọn lọ bí wọ́n ti ń bá a bọ̀ láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá. Àwọn ẹlẹ́gungùn tí wọ́n gùn ní mítà mẹ́ta ń gbádùn oòrùn àti ooru tí ń yọruku, bí wọ́n ti ń fojú ṣọ́ ìjẹ ńlá tí yóò wá. Ní alẹ́, ìbúramúramù wọn máa ń gba inú irà náà kan, ilẹ̀ sì máa ń mì tìtì nígbà tí wọ́n bá ń tage láti gùn. Àwọn ìjàpá òkun tí wọ́n tóbi tó ọpọ́n ìwẹ̀ ń túlẹ̀ láàárín koríko ní wíwá oúnjẹ kiri. Àwọn ṣeréṣeré ẹranmi otter ayára-bí-àṣá ń ṣàjọpín ibùgbé àdánidá kan náà. A lè rí ipa ẹsẹ̀ àwọn àmọ̀tẹ́kùn Florida tí ń wá ìjẹ, tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọjá lórí ẹrẹ̀. Àwọn ìgalà abìrù-funfun ní láti máa wà lójúfò nígbà gbogbo, nítorí pé àwọn apágúlọ́gúlọ́-dọdẹ-ìjẹ wọ̀nyí yóò fi wọ́n lánu nígbà gbogbo tí wọ́n bá rí àǹfààní rẹ̀. Àwọn ẹranko raccoon, tí a sábà máa ń yàwòrán wọn bí ẹni tí ń fọ oúnjẹ wọn nínú àwọn odò ìtòsí, ń gbé ní àlàáfíà nínú Irà Oníkoríko náà, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tí ń wá tààràtà láti inú Irà náà.
Àwọn ohun alààyè tún wà rẹpẹtẹ tí àwọn àlejò tí wọ́n wá síbi Irà Oníkoríko náà fẹ́rẹ̀ẹ́ máà rí. Oríṣiríṣi àkèré fara pa mọ́, wọ́n sì jókòó sórí àwọn ewé lórí ilẹ̀, sórí àwọn ewé òṣíbàtà, àti sórí àwọn ewéko hyacinth ojú omi, tí ó lẹ́wà, nínú àwọn odò lílà. Àwọn ìgbín apple—àwọn ìgbín tí wọ́n jẹ́ ìwọ̀n bọ́ọ̀lù àfọ̀págbá, tí wọ́n ní àwọn ìjàgbọ̀n àti ìwọ̀nba ẹ̀dọ̀fóró kan, tí ń jẹ́ kí wọ́n lè máa mí nínú omi àti lókè omi—ń rọra fà lọ láàárín àwọn ewéko inú omi. Edé, alákàn, àti oríṣiríṣi ẹja kún inú àwọn omi tí kò jìn náà. Ejò pọ̀ jaburata, àwọn kòkòrò àti àwọn ohun afàyàfà kò lóǹkà—gbogbo wọn ń retí ohun tí wọn óò jẹ tàbí ohun tí yóò jẹ wọ́n.
Lára àwọn ẹ̀dá abìyẹ́ tí a óò rí ni àwọn ẹyẹ spoonbill rírẹwà, tí wọ́n fàwọ̀ jọ òdòdó rose, ibis funfun, àti àwọn àkọ̀ onírìísí òjò dídì, tí ń yí po lókè níwọ̀n bí àwọn ẹlẹ́gbẹ́ wọn ti lè máà fẹ́ẹ́ fò, kí wọ́n baà lè mú àwọn ẹyin tí àwọn ọmọ wọn tí wọ́n ń retí wà nínú rẹ̀ móoru. A óò máa rántí ìran agbàfiyèsí àwọn àkọ̀ ńlá aláwọ̀ búlúù lókè, tí wọ́n ń yára fò lọ́nà tí a kò fi lè kà wọ́n, fún ìgbà pípẹ́. Àwọn ẹyẹ àkẹ̀ òkun, àkàlà, àti àwọn ẹyẹ gallinule aláwọ̀ elésè àlùkò ń ṣàjọpín òfuurufú pẹ̀lú apárí idì ọlọ́lá ńlá, tí ó jẹ́ àmì orílẹ̀-èdè America.
Lẹ́yìn náà, àwọn ẹyẹ cormorant ọlọ́rùn gígùn, àti ẹyẹ anhinga, tàbí ẹyẹ ejò, tí a ń pè bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó máa ń rí bí ẹranko afàyàfà ju bí ẹyẹ lọ nígbà tí ó bá na ọrùn rẹ̀ gígùn tí ó ní ìrísí S lórí omi. Àwọn oríṣi ẹyẹ méjèèjì, tí wọ́n jẹ́ ọ̀yánnú fún oúnjẹ, máa ń jìjàdù fún oúnjẹ nínú àwọn omi tí kò jìn nínú Irà Oníkoríko náà. Bí ara wọn bá tutù, àwọn méjèèjì máa ń na apá wọn, wọ́n sì máa ń fẹ àwọn ìyẹ́ ìdí wọn, tí èyí sì ń fa ìfarapidán aláṣerégèé bíi pé wọ́n ń dẹ́ńgẹ̀ láti ya fọ́tò. Kìkì ìgbà tí ìyẹ́ wọn bá gbẹ pátápátá ni àwọn ẹyẹ náà tóó lè fò.
Kí a má baà gbójú fo ẹyẹ limpkin tí ó dà bíi wádòwádò dá, igbe rẹ̀ yóò mú àwọn àlejò ta gìrì. Ẹyẹ ńlá aláwọ̀ ilẹ̀ òun funfun tóótòòtó yìí ni a ti pè ní ẹyẹ ẹlẹ́kún nítorí pé ìró rẹ̀ dà bíi ti ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀, tí ń pohùnréré ẹkún láìnírètí. Àwọn àṣá Irà Oníkoríko tí wọ́n ṣọ̀wọ́n, tí a sì wu léwu, ẹyẹ adọdẹ, tí ó tóbi tó àkùkọ—tí wíwà nìṣó wọn sinmi lórí wíwà ìgbín apple—jẹ́ ìran mánìígbàgbé fún àwọn òǹwòran ẹyẹ. Ní wíwo òkè, àwọn àlejò yóò ṣe háà nítorí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ẹyẹ tí wọ́n wọ̀ sórí àwọn igi àpádò ọlọ́láńlá tí kò tí ì kú, tí àwọn ewé títutù yọ̀yọ̀ tí ń dán gbinrin kún orí rẹ̀, tí fọ́nrán àwọn ewéko moss ti ilẹ̀ Sípéènì lọ́ mọ́. Àwọn yẹtuyẹtu òdòdó aláwọ̀ ewé àti pupa tó so kọ́ sára àwọn àjàrà ṣíṣẹlẹgẹ́ tí ó yí àwọn igi náà ká dọ́gba pẹ̀lú àwọ̀ àwọn ẹyẹ náà. Níhìn-ín, àwọn àlejò lè gbàgbé orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà àti orí kọ́ńtínẹ́ǹtì tí wọ́n wà. Áà, ayé kan lèyí fúnra rẹ̀, párádísè kan ní kedere, tí ó wà bí a ṣe dá a, tí ó sì lẹ́wà.
Ní paríparí rẹ̀, ìfèèféé aláwọ̀ góòlù—ohun tí a fi ń dá Irà Oníkoríko mọ̀—ń hù nínú àwọn omi tí kò jìn náà. Ibi tí ojú lè rí nǹkan dé ni a ń rí odò oníkoríko píparọ́rọ́ tí ń kọ mànà, tí ó sì ń bù yẹ̀rì, tí ó ṣe pẹrẹsẹ bí orí tábìlì, tí ó dà gẹ̀ẹ̀rẹ̀ ní ìwọ̀n tí kò tó sẹ̀ǹtímítà mẹ́rin ní kìlómítà kọ̀ọ̀kan, yìí dé. Bí ohun tí kò ṣeé finú wòye, láìsí ìṣàn tí ó ṣeé fojú rí, omi náà rọra ń ṣàn lọ sínú òkun. Òun ni ẹ̀mí Irà Oníkoríko náà; láìsí i, Irà náà kì yóò sí.
Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, kí ẹ̀dá ènìyàn tóó ṣe Irà Oníkoríko náà níṣekúṣe, kí wọ́n sì tó ṣèpalára fún un, ilẹ̀ oníkoríko rẹpẹtẹ yìí gùn tó 80 kìlómítà láti ìhà ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn, ó sì tó 500 kìlómítà láti Odò Kissimmee dé Ìyawọlẹ̀ Omi Òkun Florida. Ọkùnrin kan tí ó mọ níwọ̀n lè gba àárín rẹ̀ kọjá, omi inú rẹ̀ kì yóò sì kàn án léjìká. Àwọn ọkọ̀ ẹlẹ́ńjìnì ń fò fẹ̀rẹ̀ la ojú omi tí kò jìn náà kọjá gba àárín ìfèèféé aláwọ̀ góòlù, gígùn kọjá ní ìwọ̀n ìyára púpọ̀ jọjọ, tí ó sì ń fún àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ sí yàà ní ìmóríyá mánìígbàgbé. Àwọn afìwọ̀pẹja ń wá láti pa ẹja bass àti àwọn ẹja odò tí kò níyọ̀ àti ẹja odò oníyọ̀, bí wọ́n ti ń ṣe láti ayébáyé.
Ìpè fún Ìrànlọ́wọ́ Lọ́nà Ìgbékútà
Lápá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, àwọn òṣèlú àti àwọn oníṣòwò ní Florida ka Irà Oníkoríko náà sí àbàtà ibùgbé àwọn ohun alààyè tí a kò fẹ́ tí a gbọ́dọ̀ pa rẹ́ kúrò láti pèsè àyè fún ìfilọ́lẹ̀ dúkìá ìní, ìmúgbòòrò ìlú ńlá, àti ìdàgbàsókè iṣẹ́ àgbẹ̀. “Ẹ sé e pa, ẹ mọ ògiri dí i, ẹ fà á gbẹ, ẹ darí rẹ̀ gba ibòmíràn” wá di ọ̀rọ̀ tí a ń fìgbà gbogbo gbọ́ lẹ́nu wọn. Ní 1905, kí wọ́n tó fìbò yan N. B. Broward sípò gómìnà Florida, ó jẹ́jẹ̀ẹ́ láti gbẹ “àbàtà tí ó kún fún àjàkálẹ̀ àrùn” yẹn.
Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn kì í ṣe ìlérí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Wọ́n gbé àwọn ẹ̀rọ akólẹ̀ ràgàjìràgàjì àti ohun èlò ìgbẹ́lẹ̀ wá. Lábẹ́ ìdarí àti àbójútó Ikọ̀ Àwọn Onímọ̀ Iṣẹ́ Ẹ̀rọ ti Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun United States, wọ́n gbẹ́ àwọn odò lílà oníkìlómítà 90 tí wọn jìn ní mítà 9, wọ́n sì ba ilẹ̀ àbàtà tí ó tóbi ju mílíọ̀nù kan mítà níbùú-lóròó jẹ́ nígbà tí wọ́n ń ṣe é. Wọ́n kọ́ àwọn èbúté ọkọ̀, àwọn ògiri ìsédò, àti àwọn ibùdó ìfami ńláńlá, àwọn odò lílà àti ọ̀nà púpọ̀ sí i sì lọ káàkiri Irà Oníkoríko náà. Wọ́n darí omi afúnniníyè, ṣíṣeyebíye kúrò ní àgbègbè tí ó kún fún ohun alààyè yí, láti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn oko ńláńlá, tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá. Àwọn ìlú ńlá etíkun tún fẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, tí wọ́n sì sáré jẹ Irà Oníkoríko náà nítorí àwọn àwùjọ ilé gígọntiọ, títì márosẹ̀, àwọn ibùdó ìrajà, àti ibi ìṣeré bọ́ọ̀lù àfọ̀págbá.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n sọ apá kan Irà Oníkoríko náà di ọgbà orílẹ̀-èdè ní 1947, fífa omi gbẹ àti dídarí omi gba ibòmíràn ń tẹ̀ síwájú níbẹ̀ ní ìwọ̀n ìyára tí ń ṣèparun. Àwọn onímọ̀ nípa àyíká gbà pé fífa omi Irà Oníkoríko náà gbẹ—tí wọ́n sì ń ná àràádọ́ta ọ̀kẹ́ dọ́là láti ṣe é—jẹ́ àṣìṣe ńlá tí àìgbọ́n fà. Ìwọ̀nba ènìyàn ló lóye pé dídí ṣíṣàn omi lọ́wọ́ yóò ní ipa tí ń ṣèparun lórí àwọn ohun alààyè tí wọ́n wà nínú Irà Oníkoríko náà. Ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún kọjá lọ kí àwọn ìpalára náà tó fara hàn.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní àárín àwọn ọdún 1980, àwọn onímọ̀ nípa àyíká àti àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè ń ké gbàjarè pé Irà Oníkoríko náà ń tán lọ. Ó jọ pé gbogbo ohun alààyè tí ó wà níbẹ̀ ń ráhùn, wọ́n ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́. Àwọn ihò omi tí àwọn ẹlẹ́gungùn ń gbé bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ nígbà ọ̀dá. Nígbà tí òjò bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀, tí àgbègbè ibẹ̀ sì kún àkúnya, omi gbá àwọn ìtẹ́ àti ẹyin wọn lọ. Nísinsìnyí, iye wọn ń yára kéré sí i. A gbọ́ pé àwọn ẹlẹ́gungùn ń pa àwọn ọmọ ara wọn jẹ. Àwọn ẹyẹ ṣíṣàrà ọ̀tọ̀, tí ń wọ omi, tí iye wọn lé ní mílíọ̀nù kan nígbà kan rí ní àgbègbè yẹn ti dín kù sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún—ní ìwọ̀n ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún. Iye àwọn ẹyẹ spoonbill rírẹwà, tí wọ́n fàwọ̀ jọ òdòdó rose, tí wọ́n ń dí òfuurufú nígbà kan rí, nígbà tí wọ́n bá ń pa dà lọ sínú ìtẹ́ wọn, ti dín kù gan-an sí ìwọ̀nba kéréje ní ìfiwéra. Láti àwọn ọdún 1960 ni iye àwọn àkọ̀ inú igi ti kéré sí i láti orí 6,000 tí ó ní ìtẹ́ sí 500 péré, tí a ń tipa bẹ́ẹ̀ wu irú ọ̀wọ́ náà léwu. Wọ́n tún ń fewu wu àwọn ibi ìdọ́sìn ẹranmi Ìyawọlẹ̀ Omi Òkun Florida tí ó kún fọ́fọ́ nítorí ilé iṣẹ́ ìṣáwùrú ti ìpínlẹ̀ náà. Ẹnì kan sọ pé, iye gbogbo àwọn ẹ̀dá eléegun ẹ̀yìn míràn, láti orí ìgalà dé orí àwọn ìjàpá òkun, ti dín kù sí àárín ìpín 75 nínú ọgọ́rùn-ún àti ìpín 95 nínú ọgọ́rùn-ún.
Àwọn ohun aṣèbàjẹ́ láti inú ajílẹ̀ àti oògùn apakòkòrò tí ń dé inú odò, tí ń rọra sọ ilẹ̀ àti omi di eléèérí, ń bá iṣẹ́ àgbẹ̀ àti àwọn ìgbòkègbodò ẹ̀dá ènìyàn míràn tí ń ra kaka láìdábọ̀ rìn. Ìpele gíga èròjà mẹ́kúrì ni a ti rí dájú ní gbogbo ìpele ìṣèmújáde oúnjẹ, láti orí ẹja ní àwọn àfọ̀ títí dé orí ẹranko raccoon àti àwọn ẹlẹ́gungùn àti ìjàpá òkun. A ti rọ àwọn apẹja láti má ṣe jẹ ẹja bass àti catfish tí wọ́n bá mú nínú àwọn omi kan tí wọ́n ní èròjà mẹ́kúrì tí ó yọ sínú wọn láti inú ilẹ̀ nínú. Àwọn àmọ̀tẹ́kùn pẹ̀lú ti jẹ́ òjìyà ìpalára ogun tí ènìyàn gbé, kì í ṣe mẹ́kúrì nìkan ló ń pa wọ́n, àmọ́ àwọn apẹran láìgbàṣẹ pẹ̀lú ń pa wọ́n. Ẹranko yìí wà nínú ewu gan-an débi pé a gbà gbọ́ pé gbogbo èyí tí ó wà ní ìpínlẹ̀ náà kò tó 30, tí 10 sì wà nínú ọgbà ẹranko náà. Àwọn irúgbìn ìbílẹ̀ inú Irà Oníkoríko náà bíi mélòó kan pẹ̀lú wà ní bèbè àkúrun.
Àwọn òǹwòran àti àwọn onímọ̀ nípa àyíká kan gbà gbọ́ pé Irà Oníkoríko náà lè ti dépò tí kò ti ní ìrètí ìkọ́fẹpadà mọ́. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àti ti ọgbà orílẹ̀-èdè àti ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ nípa àyíká gbà gbọ́ pé pẹ̀lú nínáwó sórí rẹ̀ àti ìgbésẹ̀ yíyá kánkán láti ìhà ọ̀dọ̀ àwọn aṣojú ìjọba ìpínlẹ̀ àti ti ìjọba àpapọ̀, a ṣì lè dáàbò bo Irà Oníkoríko náà. Òṣìṣẹ́ kan sọ pé: “Kò sí ẹni tí ó mọ ìgbà tí ohun tí ó tóbi tí ó sì díjú tó báyìí ń dépò tí kò ti ní ìrètí ìkọ́fẹpadà ní gidi. Ó lè ti ṣẹlẹ̀ ná.” Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè náà, John Ogden, gbà pé ìṣeéṣe àtigba Irà Oníkoríko náà pa dà kò dájú, àmọ́ ó fojú sọ́nà fún un. Ó wí pé: “Mo ní láti fojú sọ́nà fún un. Ohun mìíràn tí a lè ṣe ni aṣálẹ̀ ohun alààyè, tí ó ní àṣẹ́kù ọgbà ẹranko tí ó ní àwọn ẹlẹ́gungùn díẹ̀ níbì kan, àwọn ìtẹ́ ẹyẹ díẹ̀ níbòmíràn àti ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí dáradára kan tí a fi awọ àmọ̀tẹ́kùn kan ṣe ọ̀ṣọ́ sáàárín rẹ̀.”
Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ àti àwọn òṣèlú ní Washington, títí kan ààrẹ àti igbákejì ààrẹ United States, ti gbọ́ ariwo ìkégbàjarè àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ní Florida, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè, àti àwọn onímọ̀ nípa àyíká jákèjádò orílẹ̀-èdè náà. Nísinsìnyí, ó ti bọ́ sójú ọpọ́n ohun ìwéwèé-dáwọ́lé Ikọ̀ Àwọn Onímọ̀ Iṣẹ́ Ẹ̀rọ ti Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun United States, tí àwọn aṣáájú wọn ṣe iṣẹ́ tí wọ́n tẹ́wọ́ gbà náà ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn báṣubàṣu. Wọ́n ń wo ara wọn bí ẹni tí ń ṣiṣẹ́ láti dáàbò bo Irà Oníkoríko náà àti àwọn ẹ̀dá alààyè inú rẹ̀, dípò fífà á gbẹ, sísé e pa, àti dídarí rẹ̀ gba ibòmíràn.
Ní kedere, omi ni ìṣòro ibẹ̀. Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé: “Ìpìlẹ̀ fún àṣeyọrí ni omi mímọ́ tónítóní—tí ó sì pọ̀, ìyẹn sì lè wá kìkì nípa dídín ìpèsè omi tí ń lọ sí àwọn àgbègbè oníṣẹ́ àgbẹ̀ àti àgbègbè ìgboro ìlú kù. Àwọn oko ìrèké àti oko ẹ̀fọ́ Gúúsù Florida ni ó jọ pé wọ́n tún dájú sọ.” Alábòójútó Ọgbà Irà Oníkoríko, Robert Chandler, sọ pé: “Fífètò pín omi yóò ṣòro, àmọ́ a ti pèsè omi tí ó pọ̀ tó, a kò sì lè pèsè sí i mọ́.” Ó sọ pé: “Àwọn mìíràn ní láti ṣe ìdáàbòbò tìṣọ́ratìṣọ́ra.” Àwọn alátìlẹ́yìn ìdámọ̀ràn ìkọ́fẹpadà Irà Oníkoríko ń fòyà pé ìjà títóbi jù lọ tí àwọn yóò jà nítorí ìwéwèédáwọ́lé náà yóò wá láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ṣàgbẹ̀ ìrèké ní Florida àti àwọn àgbẹ̀ tí wọ́n ní ilẹ̀ títóbi níbi Irà Oníkoríko náà. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ omi ni wọ́n ti fà lọ láti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn àìní wọn, tí èyí sì ti fi àwọn ẹ̀dá alààyè tí wọ́n wà nínú Irà náà sínú ewu.
Ìgbàpadà àti ìdáàbòbo Irà Oníkoríko náà yóò jẹ́ ìwéwèé ìmúpadàbọ̀-sípò aláìṣojo, tí ó sì ń múni náwónára jù lọ nínú ìtàn. Òṣìṣẹ́ tí ń bójú tó iṣẹ́ Irà Oníkoríko náà sọ níbi Àjọ Abójútó Àwọn Ohun Alààyè Inú Igbó Lágbàáyé pé: “A ń sọ̀rọ̀ nípa owó rẹpẹtẹ, a ń sọ̀rọ̀ nípa ilẹ̀ rẹpẹtẹ, a sì ń sọ̀rọ̀ nípa ìmúpadàbọ̀-sípò ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká ní ìwọ̀n kan tí a kò tí ì rí rí níbikíbi lágbàáyé.” Ìwé ìròyìn Science ṣàlàyé pé: “Láàárín ọdún 15 sí 20 ọdún tí ń bọ̀, Ikọ̀ Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun náà àti ìjọba ìpínlẹ̀ àti àwọn aṣojú ìjọba àpapọ̀ míràn wéwèé láti ṣàtúnṣe gbogbo ìgbékiri omi fún ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn níbi Irà Oníkoríko Florida, títí kan àwọn àbàtà àti ọ̀nà omi tí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀rọ là tí ó jẹ́ 14,000 kìlómítà [5,400 máìlì] níbùú-lóròó, tí iye owó rẹ̀ tó nǹkan bíi bílíọ̀nù 2 dọ́là.”
Ní àfikún sí i, ìwéwèé náà béèrè fún ríra nǹkan bí 40,000 sarè ilẹ̀ oko nítòsí Adágún Okeechobee àti yíyí i pa dà sí ilẹ̀ àfọ̀ tí yóò sẹ́ àwọn ohun aṣèbàjẹ́ jáde nínú ilẹ̀ oko tó ṣẹ́ kù. Àwọn tí ń ṣàgbẹ̀ ìrèké ń yarí tìbínútìbínú nípa sẹ́ǹtì kan lórí owó ìwọ̀n lára owó tí ìjọba ń wéwèé láti ge lára owó tí wọ́n ń gbà lọ́wọ́ àwọn onílé iṣẹ́ ẹ̀rọ láti lè ní owó púpọ̀ sí i láti ṣàtúnṣe Irà Oníkoríko náà. Ìwé agbéròyìnjáde USA Today sọ nínú àyẹ̀wò fínnífínní nípa rẹ̀ pé: “Àwọn tí wọ́n jàǹfààní jù lọ nínú bíbà á jẹ́ ni ó yẹ kí wọ́n sanwó fún ìmúpadàbọ̀-sípò rẹ̀: ìyẹn ni àwọn tí ń ṣàgbẹ̀ ìrèké, àti àwọn tí wọ́n ń fi ìrèké ṣe nǹkan mìíràn ní Florida.” A fojú díwọ̀n pé yíyọ sẹ́ǹtì kan lórí owó ìwọ̀n ṣúgà Florida yóò mú mílíọ̀nù 35 dọ́là wọlé lọ́dọọdún.
A retí pé ìjàkadì náà—láàárín àwọn àgbẹ̀ àti àwọn tí ń ṣọ̀gbìn ìrèké ní ìdojúkọ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè, àwọn onímọ̀ nípa àyíká, àti àwọn olùfẹ́ ìṣẹ̀dá—yóò máa bá a lọ bí ó ti wà ní àwọn apá ibòmíràn ní United States, níbi tí àwùjọ àwọn ènìyàn kan náà ti ń kẹ̀yìn síra wọn. Igbákejì Ààrẹ Gore pe ìpè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀. Ó wí pé: “Nípa ṣíṣiṣẹ́ pọ̀, a lè wo ìpínyà yí sàn, kí a sì mú àyíká jíjọjú àti ètò ọrọ̀ ajé tí ó jọjú dájú. Àmọ́, ìsinsìnyí ni àkókò tí ó yẹ kí a gbégbèésẹ̀. Kò sí Irà Oníkoríko mìíràn ní àgbáyé mọ́.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ẹlẹ́gungùn
[Credit Line]
USDA Forest Service
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Apárí idì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ẹyẹ “ibis” funfun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ẹyẹ “anhinga,” tàbí ẹyẹ ejò méjì nínú ìtẹ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ẹranko “raccoon” mẹ́ta tí ń wọ́dò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àkọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Àkọ̀ ńlá aláwọ̀ búlúù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ẹyẹ “limpkin,” wọ́n tún ń pè é ní ẹyẹ ẹlẹ́kún
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àwọn ọmọ ẹyẹ “cormorant”