Wíwo Ẹyẹ—Ìgbòkègbodò Àfipawọ́ Tí Gbogbo Ènìyàn Nífẹ̀ẹ́ Sí Ni Bí?
“Ìgbésí ayé olùwo-ẹyẹ kún fún oríṣiríṣi ohun ìyanu tí kò lópin.” W. H. Hudson—The Book of a Naturalist.
NÍBI Ìyawọlẹ̀ Omi Òkun Kosi, nítòsí ààlà tí ó wà láàárín Gúúsù Áfíríkà àti Mòsáńbíìkì, Keith, Evelyn Jannie, àti afinimọlẹ̀ wọn rin ìrìn kìlómítà 22 láti lọ wo ẹyẹ kan. Kì í ṣe ẹyẹ lásán kan! Igún jẹyìnjẹyìn—ẹyẹ ńlá aláwọ̀ funfun mọ́ dúdú kan, tí ó ní ìdéjú aláwọ̀ pupa, ni wọ́n ń wá. Òkú ẹja àti ẹyìn ni oúnjẹ rẹ̀.
Keith sọ pé: “Lẹ́yìn ìrìn jíjìn náà, a padà sí ilé pẹ̀lú ìjákulẹ̀ pé ẹyọ kan péré ni a rí—láti ọ̀nà jíjìn sì ni. Kí ni a rí ní àgọ́ wa nígbà tí a padà de ibẹ̀? Àwọn igún jẹyìnjẹyìn mẹ́ta tí wọ́n bà sórí ọ̀pẹ kan! A gbádùn wíwà níbẹ̀ wọn fún nǹkan bí wákàtí kan kí wọ́n tó fò lọ, tí wọ́n sì fi ìyẹ́ wọn tí wọ́n nà náà dárà fún wa. A tún rí òwìwí pẹjapẹja Pel ní ìgbà àkọ́kọ́ lọ́jọ́ yẹn kan náà. Bẹ́ẹ̀ ni, òwìwí tí ń pa ẹja!”
Ohun Tí Ó Lè Mú Orí Ẹnikẹ́ni Yá
Jákèjádò ayé, inú wa máa ń dùn tí a bá ń wo àwọn ẹyẹ tí a sì ń gbọ́ ìró wọn. Àwọn irú ọ̀wọ́ tí ó lé ní 9,600 náà fún olùwo-ẹyẹ tí ó bá wà lójúfò láǹfààní láti rí wọn. Ta ni orí rẹ̀ kì í yá tí ó bá kófìrí àwọ̀ mèremère ẹyẹ akùnyùnmù tàbí ẹyẹ kingfisher? Ta ni kì í tẹsẹ̀ dúró bí ọ̀wọ́ àwọn ẹyẹ mockingbird, ẹyẹ àwòko, tàbí ẹyẹ ńlá lyrebird láti Australia tàbí dídún ketekete ẹyẹ cuckoo tàbí ẹyẹ magpie láti Australia tí ń kọrin ṣáá bá fà á mọ́ra?
Wíwo ẹyẹ ni fífìṣọ́ra kíyèsí àwọn ẹyẹ ẹgàn. Bí o bá ṣe pinnu láti ṣe é ni agbára tí o nílò yóò ṣe tó. Ó lè máà sí lọ́kàn rẹ láti fẹsẹ̀ wọ́ irà kọjá tàbí láti gun àwọn òkè láti lè rí àwọn ẹyẹ tí ó ṣọ̀wọ́n. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń rí i pé wíwo ẹyẹ ní ẹ̀yìnkùlé tàbí nínú oko etílé wọn ń gbádùn mọ́ wọn, ó sì ń tù wọ́n lára. Ọ̀pọ̀ wọn ń gbé omi àti ìgò ìfẹ́yẹlóúnjẹ síta láti fa àwọn ẹyẹ ìbílẹ̀ mọ́ra. Ọdọọdún ni iye àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí i ń pọ̀ sí i. Púpọ̀púpọ̀ ènìyàn gbà gbọ́ pé ìsapá náà tó bẹ́ẹ̀.
Èé Ṣe Tí Ó Lókìkí Tó Bẹ́ẹ̀?
Bí ìwé náà, An America Challenged, tí Steve H. Murdock kọ, ṣe sọ, a retí pé kí iye àwọn olùwo-ẹyẹ yára pọ̀ sí i ju bí iye àwọn olùgbé United States ṣe ń pọ̀ sí i lọ láàárín ọdún 1990 sí 2050. Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé, “púpọ̀púpọ̀ sí i ènìyàn ní Íńdíà ní ń bẹ̀rẹ̀ wíwo ẹyẹ kiri.” Gordon Holtshausen, alága Ìgbìmọ̀ Òǹṣèwé Nípa Ẹyẹ ní Gúúsù Áfíríkà, gbà gbọ́ pé, “ní Gúúsù Áfíríkà . . . Bíbélì nìkan ló ń tà ju àwọn ìwé lórí [ẹyẹ] lọ.”
Gbàrà tí o bá ti ṣàjọpín ìmóríyá tí olùwo-ẹyẹ kan ń ní, ìwọ náà yóò wá kira bọ̀ ọ́! Wíwo ẹyẹ jẹ́ ìmọ̀lára tí ó máa ń ranni. Ó lè jẹ́ ìyàbàrá tí kò gbówó lórí, tí ń mú kí o máa fi ilé sílẹ̀ lọ sí àwọn ibi gbalasa, tí ó sì ń fún èrò orí rẹ níṣẹ́ ṣe. Ó máa ń súnni nífẹ̀ẹ́ láti wá wọn rí láìpa wọ́n. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé tọmọdétàgbà ló máa ń yára kira bọ ìgbòkègbodò náà, a lè gbádùn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé tàbí gẹ́gẹ́ bí àwùjọ àwọn ọ̀rẹ́ mélòó kan. A sì lè dá gbádùn rẹ̀. Wíwo ẹyẹ jẹ́ ìgbòkègbodò jíjọjú, tí kò lábààwọ́n, tí ó gbámúṣé, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ibi tí a kò ti lè ṣe é jálẹ̀ ọdún.
Àwọn Ohun Pàtàkì Tí A Nílò fún Wíwo Ẹyẹ
O ha máa ń rí ẹyẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, kí o sì ṣe kàyéfì nípa orúkọ tí wọ́n ń pè é? Ìmọ̀lára ìtẹ́lọ́rùn ń wá láti inú mímọ orúkọ àwọn idì títóbi, àwọn ẹyẹ ọ̀kín, àti ògbùgbú, kí a sì mọ ti àwọn ẹyẹ nightjar àti earthcreeper tí a máa ń gbójú fò. Àwọn ẹyẹ sandpiper tí wọ́n jọra àti àwọn ìbákà aláṣọ ìgbà ìwọ́wé tí ń gbé inú igi àti gbogbo àwọn tí wọ́n tan mọ́ wọn.a
Láti lè dá wọn mọ̀, ìwọ yóò nílò ìwé amọ̀nà kan láti dá àwọn ẹyẹ tí wọ́n wà ní orílẹ̀-èdè rẹ tàbí àgbègbè rẹ mọ̀. Èyí jẹ́ ìwé àtẹ̀bàpò kan tí ó ní àwòrán àti àlàyé nípa akọ àti abo irú ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan. Àwọn ìwé amọ̀nà tí ó dára tún ń sọ nípa yíyọ ìyẹ́ tí kò gbó àti èyí tó ń yọ ní àwọn ìgbà kan lọ́dún.
Kí ni ṣẹ̀ṣẹ̀bẹ̀rẹ̀ kan tún nílò? Awò awọ̀nàjíjìn olójú méjì tí ó dára ṣe pàtàkì fún olùwo-ẹyẹ bí ọ̀pá ìpẹja tàbí àwọ̀n ti ṣe pàtàkì fún apẹja. Àwọn ohun tí ó wà lára àwọn ẹyẹ tí wọ́n wà ní àdúgbò rẹ yóò yà ọ́ lẹ́nu nígbà tí o bá fi awò awọ̀nàjíjìn olójú méjì wò wọ́n. Fún àpẹẹrẹ, ní Áfíríkà, a lè tètè rí erinmi ńlá kan. Ṣùgbọ́n o lè máà rí ẹyẹ oxpecker kékeré alágòógó pupa tí ń jẹ àwọn kòkòrò àfòmọ́ bí ó ti bà sẹ́yìn erinmi náà.
Kì í ṣe gbogbo awò awọ̀nàjíjìn olójú méjì ni wọ́n ṣe fún wíwo ẹyẹ, ọ̀nà tí ó sì dára jù lọ láti mọ̀ ọ́n ni pé kí a fi bí ẹ̀yà oríṣiríṣi tí ó wà ṣe ń ṣiṣẹ́ wéra. Ẹ̀yà méjì tí àwọn olùwo-ẹyẹ máa ń lò jù ni ẹ̀yà 7 x 42 àti 8 x 40. Nọ́ńbà àkọ́kọ́ dúró fún agbára ìmúǹkantóbi rẹ̀, èkejì sì dúró fún ìwọ̀n ìdábùú òbírí awò ńlá rẹ̀ ní ìwọ̀n mìlímítà. Ìwé Field Guide to the Birds of North America ti National Geographic ṣàlàyé pé, “ní gbogbogbòò, ìṣirò ìfiwéra 1 sí 5 láàárín agbára ìmúǹkantóbi àti bí awò ṣe tóbi tó ni a kà sí èyí tí ó péye láti kó ìmọ́lẹ̀ jọ.” Èyí ń jẹ́ kí o lè rí àwọ̀, kódà bí ìmọ́lẹ̀ kò bá tó pàápàá. Nípa bẹ́ẹ̀, ìwọ̀n ìmúǹkantóbi tí ó ju ìyẹn lọ kò fi bẹ́ẹ̀ sàn. Ohun tí o ń fẹ́ ni pé kí ó ríran kedere.
Ibo Ni O Ti Máa Bẹ̀rẹ̀? Bẹ̀rẹ̀ ní Àdúgbò Rẹ
Ẹni tí ó mọ àwọn ẹyẹ tí wọ́n wà ládùúgbò rẹ̀ yóò lè múra tán fún lílọ sí àwọn ibòmíràn láti rí àwọn ẹyẹ tí kò wọ́pọ̀ tàbí àwọn tí a kò lè rí dáadáa. Ǹjẹ́ o mọ àwọn irú ọ̀wọ́ tí wọ́n fi ìtòsí ilé ṣe ibùgbé títí lọ? Àwọn wo ni wọ́n máa ń fò lójú ọ̀run tí ó jọ pé wọn kì í balẹ̀ rárá, bóyá ní ìgbà tí wọ́n bá ń lọ sí adágún tàbí àfọ̀ kan nítòsí? Àwọn ẹyẹ aṣíkiri wo ni wọ́n máa ń fò kọjá ní àwọn sáà tí wọ́n máa ń rìnrìn àjò? Christopher Leahy, kọ nínú ìwé rẹ̀ náà, The Birdwatcher’s Companion, pé: “Ní Àríwá Amẹ́ríkà, nǹkan bí ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún lára nǹkan bí 645 irú ọ̀wọ́ ẹyẹ tí ń pamọ ní ń [ṣí kiri].”
Díẹ̀ lára àwọn aṣíkiri wọ̀nyí lè tẹsẹ̀ dúró nítòsí ilé rẹ láti tún gbagbára, kí wọ́n sì sinmi. Ní àwọn àgbègbè kan, àwọn akíyànyán olùwo-ẹyẹ ti gbé ẹ̀yìnkùlé wọn mọ oríṣiríṣi irú ọ̀wọ́ ẹyẹ tí ó lé ní 210! Yóò dùn mọ́ ọ nínú, yóò sì jẹ́ ọ̀nà ìgbàkẹ́kọ̀ọ́ láti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn déètì ìgbà àkọ́kọ́ àti ìgbà tí o rí irú ọ̀wọ́ kan kẹ́yìn lọ́dọọdún.
Àwọn Ọ̀nà Tí A Lè Gbà Wo Ẹyẹ
Pẹ̀lú awò awọ̀nàjíjìn olójú méjì tí o gbé kọ́rùn àti ìwé atọ́nà kan lápò, o ti ṣe tán wàyí láti wò ré kọjá ẹ̀yìnkùlé rẹ. Ìwé ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ẹyẹ sábà máa ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àwọn ọgbà ohun alààyè àti igbó àìro ti ìṣẹ̀dá. Àwọn ìwé wọ̀nyí sábà máa ń tọ́ka sí àwọn sáà tí a máa ń rí àwọn irú ọ̀wọ́ kan níbẹ̀ àti bí ó ṣe lè ṣeé ṣe tó pé kí o rí wọn. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan yóò jẹ́ ohun èlò wíwúlò kan láti mú ohun tí o rí dá ọ lójú. Bí a bá to ẹyẹ tí o rò pé o ṣẹ̀ṣẹ̀ rí mọ́ èyí tí ó ṣọ̀wọ́n, yóò dára nígbà náà láti wò ó fínnífínní, pàápàá tí o bá jẹ́ ṣẹ̀ṣẹ̀bẹ̀rẹ̀. (Wo àpótí “Atọ́nà Síṣepàtàkì fún Ìdámọ̀.”) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí a bá tò ó mọ́ àwọn tí ó pọ̀ ládùúgbò, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ òun gan-an ni o rí.
Gbìyànjú láti gba ìwé àwòrán-ilẹ̀ kan tí ń fi ọ̀nà àti irú àwọn ibùgbé ẹ̀dá tí ìwọ yóò bá pàdé hàn. Àwọn ẹyẹ sábà máa ń pọ̀ níbi tí àwọn oríṣi ibùgbé bí méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ bá wà. Yálà o ń rìn káàkiri tàbí o dúró sójú kan, gbìyànjú láti bá àyíká rẹ mu, kí o sì dúró kí àwọn ẹyẹ náà wá bá ọ. Ìwọ sáà ní sùúrù.
Ní àwọn ibì kan, nọ́ńbà tẹlifóònù kan wà tí àwọn olólùfẹ́ ẹyẹ wíwo lè kàn sí láti gbọ́ ìròyìn àwọn tí ń mórí yá tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ní àgbègbè náà.
Ìmúrasílẹ̀ Ń Ṣàǹfààní
Ó ń ṣàǹfààní láti fojú sun àwọn ẹyẹ pàtó kan, àmọ́ àǹfààní ló jẹ́ fún ọ láti kà ṣáájú nípa àwọn tí o fẹ́ láti wò. Bí o bá wà ní àwọn ilẹ̀ Carib, bóyá o ti pinnu láti rí ẹyẹ tody, yálà ẹ̀yà ti Cuba, Puerto Rico, tàbí Jàmáíkà. Ó jẹ́ ẹ̀dá kóńkó, tí ó ní àwọn ìyẹ́ aláwọ̀ ewé mọ́ pupa títàn. Ìwé Guide to the Birds of Puerto Rico and the Virgin Islands, tí Herbert Raffaele ṣe, wí fún wa pé, ó “ṣòro láti rí, àmọ́ a sábà máa ń gbúròó rẹ̀.” A mọ àwọn ẹyẹ tody ẹ̀yà ti Cuba nítorí bí wọ́n ṣe máa ń jẹun ní ìjẹ wọ̀bìà àti bí wọ́n ṣe máa ń yára bọ́ àwọn ọmọ wọn. Lẹ́yìn ṣíṣàpèjúwe ọ̀nà tí ẹyẹ náà ń gbà jẹun, Raffaele fúnni ní ìmọ̀ràn yìí pé: “Fífi òkúta méjì gbá ara wọn sábà máa ń pe àfiyèsí wọn.”
O lè fẹ́ ṣètò bíbẹ àgbègbè àdánidá kan wò, kí o bàa lè rí àwọn ohun kan tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé irú ọ̀wọ́ kan, bí ìfaradábírà ọ̀kan lára àwọn ẹyẹ woodcock lójú ọ̀run ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìrúwé lọ́nà tí ń gbádùn mọ́ni. Tàbí kí ó jẹ́ pípọ̀ tí àwọn ẹyẹ àkọ̀ funfun pọ̀ rẹpẹtẹ ní Gibraltar tàbí tòlótòló Bosporus tí wọ́n ń múra sílẹ̀ láti fò lọ sí Áfíríkà ní ìgbà ìwọ́wé. Ó sì lẹ̀ jẹ́ ìṣíkiri àwọn ẹyẹ lọ sí Ísírẹ́lì.
Òtítọ́ ni pé ṣíṣètò láti ṣàwárí irú ẹyẹ pàtàkì kan kò dà bí ṣíṣèbẹ̀wò sí ibi ìrántí kan tí o mọ̀ pé kò níbi í rè. Àwọn ẹyẹ kì í gbé ibì kan. Orí ìrìn ni wọ́n ń wà nígbà gbogbo. Onírúurú ni wọ́n. Àgbàyanu sì ni wọ́n. Àmọ́, ìwákiri àti sùúrù náà kì í ṣe àṣedànù!
Gbogbo ohun wọ̀nyí ló ń mú kí wíwo ẹyẹ jẹ́ ohun tí ń mórí yá. Láìka ètò tí o ti ṣe sí, àwọn ẹyẹ náà lè máà sí níbẹ̀ nígbà tí o bá dé ibẹ̀—ó kéré tán, kì í ṣe àwọn ẹyẹ tí o ní lọ́kàn láti rí. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó lè sọ nípa àwọn mìíràn tí o kò retí tí ń dúró dè ọ́. Ohun kan tó dájú ni pé, àwọn ẹyẹ kò ní já ọ kulẹ̀ láé. Ìwọ sáà ní sùúrù. Gbádùn wíwo ẹyẹ náà! Má sì gbàgbé Ẹlẹ́dàá wọn!—Jẹ́nẹ́sísì 1:20; 2:19; Jóòbù 39:13-18, 27-29.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A pín àwọn ẹyẹ sí ọ̀wọ́ mẹ́jọ pàtàkì bí a ti ń rí wọn: (1) àwọn òmùwẹ̀—pẹ́pẹ́yẹ àti àwọn ẹyẹ tí wọ́n jọ ọ́, (2) àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run—àkẹ̀ àti àwọn ẹyẹ tí wọ́n jọ ọ́, (3) àwọn wọ́dòwọ́dò ẹlẹ́sẹ̀ gígùn—ẹyẹ òǹdẹ̀ àti wádòwádò, (4) àwọn wọ́dòwọ́dò kéékèèké—ẹyẹ plover àti sandpiper, (5) àwọn ẹyẹ bí adìyẹ—ẹyẹ grouse àti àparò, (6) àwọn ẹyẹ tí ń ṣọdẹ—àwòdì, idì, àti òwìwí, (7) àwọn ẹyẹ tí ń gbé inú ìtẹ́, àti (8) àwọn ẹyẹ orí ilẹ̀ tí kì í gbé inú ìtẹ́.—A Field Guide to the Birds East of the Rockies, tí Roger Tory Peterson kọ.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]
Atọ́nà Ṣíṣepàtàkì fún Ìdámọ̀
Bí o bá kọ́kọ́ rí ẹyẹ kan tí o kò mọ̀, dídáhùn díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè wọ̀nyí lè ràn ọ́ lọ́wọ́:
1. Irú àwọ̀ wo ni ẹyẹ náà ní—dídọ́gbadélẹ̀, onílà, alámì tóótòòtó àbí adíkálà ni bí?
2. Ibo ni ẹyẹ náà ń gbé—ṣé inú omi, inú irà, inú àbàtà, ilẹ̀ eléwéko tútù àbí inú igbó kìjikìji ni?
3. Báwo ni ẹyẹ náà ṣe tóbi tó? Fi wé ẹyẹ kan tí o mọ̀ dáadáa—ológoṣẹ́, olongo, ẹyẹlé tàbí àwòdì.
4. Báwo ni ìwà ẹyẹ náà ṣe rí—ṣé ó máa ń sáré lé kòkòrò, ó máa ń fò láìlo ìyẹ́, ó máa ń ju ìrù sókè sódò kánmọ́kánmọ́, ó máa ń na ìrù ró tàbí kí ó gbé e sílẹ̀, àbí ó máa ń rìn ní ilẹ̀ ni?
5. Báwo ni àgógó rẹ̀ ṣe rí—ṣé kúkúrú tí ó ṣe ṣóṣóró, kúkúrú tí ó tóbi, gígùn, títẹ̀ kọdọrọ àbí títẹ̀ bí akọ́rọ́ ni?
Nípa wíwo àwọn “Àmì Ìṣesí” wọ̀nyí àti yíyẹ àwọn atọ́nà pàtàkì kan wò, ẹni tí ó jẹ́ ọ̀gbẹ̀rì pàápàá lè bẹ̀rẹ̀ sí mọ àwọn irú ọ̀wọ́ tí ó wọ́pọ̀.—Exhibit Guide, Merrill Creek Reservoir, New Jersey, U.S.A.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn àwòrán ẹyẹ ní ojú ìwé 23 sí 27: The Complete Encyclopedia of Illustration/J. G. Heck
[Àwòrán ilẹ̀/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ẸYẸ JAY ALÁWỌ̀ BÚLÚÙ
Àríwá Amẹ́ríkà
ẸYẸ MACAW
Àáríngbùngbùn/Gúúsù Amẹ́ríkà
ẸYẸ IDÌ APÁRÍ
Àríwá Amẹ́ríkà
PẸ́PẸ́YẸ ŃLÁ INÚ YÌNYÍN
Àríwá Amẹ́ríkà
ẸYẸ AKÙNYÙNMÙ
Àríwá/Àáríngbùngbùn Amẹ́ríkà
ẸYẸ PELICAN
Àwọn ilẹ̀ Amẹ́ríkà
ẸYẸ CARDINAL
Àríwá/Àáríngbùngbùn Amẹ́ríkà
ẸYẸ IDÌ ALÁWỌ̀-ILẸ̀
Áfíríkà, Éṣíà
ẸYẸ TOUCAN
Gúúsù Amẹ́ríkà
ẸYẸ IBIS ALÁWỌ̀-RÍRẸ̀DÒDÒ
Gúúsù Amẹ́ríkà
ẸYẸ EGRET ŃLÁ
Jákèjádò ayé
ẸYẸ ÀKẸ̀ FRANKLIN
Àwọn ilẹ̀ Amẹ́ríkà
ẸYẸ CHAFFINCH
Yúróòpù, Àríwá Áfíríkà
PẸ́PẸ́YẸ MANDARIN
China
ẸYẸ ÀKỌ̀
Yúróòpù, Áfíríkà, Éṣíà
ẸYẸ WÁDÒWÁDÒ OLÓGBE-DÚDÚ
Áfíríkà
ẸYẸDÒ FLAMINGO
Àwọn ilẹ̀ Olóoru
ẸYẸ GOULDIAN FINCH
Australia
KOOKABURRA
Australia
ẸYẸ Ọ̀KÍN
Jákèjádò ayé
ẸYẸ ÒGÒǸGÒ
Áfíríkà
ẸYẸ ROSELLA
Australia
[Àwọn Credit Line]
U.S. Fish and Wildlife Service, Washington, D.C./Glen Smart
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Green Chimney’s Farm
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúuure San Diego Wild Animal Park
Àwòrán: The Complete Encyclopedia of Illustration/ J. G. Heck
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure San Diego Wild Animal Park