ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 7/8 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Òmìnira Ìsìn Wà Nínú Ewu ní Yúróòpù
  • Àwọn Fèrèsé Adáṣiṣẹ́
  • Ipa Tí Tẹlifísọ̀n Ń Ní Lórí Àwọn Ọmọdé
  • Ìrìn Rírìn Lè Mú Kí Ẹ̀mí Gùn
  • Orin Ń Ran Àwọn Ọmọdé Lọ́wọ́
  • Àjọṣepọ̀ Àwọn Ohun Alààyè Etíkun
  • Agbada Oúnjẹ Wa Lágbàáyé
  • Àwọn Ẹja Àdàgbá Ń Jára Mọ́ṣẹ́
  • Bẹ́líìtì Ààbò àti Ikú Mọ́tò
  • Àwọn Tí Tábà Ń Pa
  • Sìgá—O Ha Máa Ń Kọ̀ Ọ́ Bí?
    Jí!—1996
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1996
  • Wíwo Ayé
    Jí!—2005
  • Iná Mọ́ Àwọn Ilé Iṣẹ́ Tábà
    Jí!—1996
Jí!—1998
g98 7/8 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Òmìnira Ìsìn Wà Nínú Ewu ní Yúróòpù

Níbi àpérò kan tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí ní Washington, D.C., U.S.A., Massimo Introvigne, tí ó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Roman Kátólíìkì láti Turin, Ítálì, sọ pé, a ṣàkójọ àwọn àkọsílẹ̀ tàbí ìròyìn nípa gbígbógunti ẹ̀ya ìsìn ní àwọn orílẹ̀-èdè bí mélòó kan. Ìjọ Onítẹ̀bọmi, ìsìn Búdà, àwọn ìjọ Kátólíìkì aṣèwòsàn, ẹ̀ya Hassid ti Júù, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn Ẹlẹ́mìí, àti Ẹgbẹ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Obìnrin Kristẹni wà lára àwọn ètò àjọ tí wọ́n dájú sọ pé wọ́n jẹ́ “ẹ̀ya tí ó léwu.” Ìròyìn kan láti ilẹ̀ Germany tọ́ka sí 800 ẹgbẹ́, ọ̀kan ní Belgium tọ́ka sí 187, ọ̀kan ní ilẹ̀ Faransé sì tọ́ka sí 172. Introvigne kọ̀wé pé ní ilẹ̀ Faransé, “wọ́n ti lé àwọn olùkọ́ dànù lẹ́nu iṣẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn kìkì nítorí pé wọ́n jẹ́ ara Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Bí àjọ ìròyìn Compass Direct ti sọ, Introvigne sọ ohun tí ń jẹ ẹ́ lọ́kàn nípa kí àwọn ará ìlú máa ṣonígbọ̀wọ́ àwọn àjọ tí ń gbógun ti ẹgbẹ́ òkùnkùn. Ó wí pé: “Ó ṣe kedere gan-an pé àwọn àjọ wọ̀nyí ló ń fa ìtànkálẹ̀ àwọn ìsọfúnni tí ń ṣini lọ́nà, tí ó sì sábà máa ń jẹ́ èké nípa àwọn ìsìn tí kò ní èrò púpọ̀, àti ojú ìwòye àìráragbaǹkan tí àwọn ènìyàn ń ní.”

Àwọn Fèrèsé Adáṣiṣẹ́

Àwọn olùwádìí ní Yunifásítì Sydney ní Australia ti hùmọ̀ fèrèsé kan tí ó máa ń tì fúnra rẹ̀ nígbà tí ọkọ̀ òfuurufú kan tí ń fò níbàǹbalẹ̀ bá sún mọ́ ìtòsí. Lẹ́yìn tí ohun tí ń fa ariwo aṣèdíwọ́ náà bá ti lọ, fèrèsé náà yóò tún ṣí. Ẹ̀rọ gbohùngbohùn kan tí ó wà ní ìta, tí ìgbékalẹ̀ ìṣiṣẹ́ ẹ̀rọ tí a gbé sí inú fèrèsé náà ń bá ṣiṣẹ́, lè dá irú àwọn ìgbì ìró ariwo mìíràn, bí ìró àwọn ọkọ̀ akẹ́rù ńlá kan, tí ń ṣèdíwọ́ mọ̀, pẹ̀lú. Àwọn àyẹ̀wò fi hàn pé àwọn fèrèsé wọ̀nyí lè dín ariwo kù tó ìwọ̀n 20 decibel, tí a lérò pé ó tó ìwọ̀n tí kò ní dí ẹni tí ń sùn lọ́wọ́. Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn àǹfààní ńlá tí ìgbékalẹ̀ náà ní ni pé ó lè mú kí ariwo má wọlé, kí ó sì jẹ́ kí afẹ́fẹ́ máa wọlé dáadáa láìsí pé a ní láti gbé ẹ̀rọ amúlétutù olówó iyebíye sílé.”

Ipa Tí Tẹlifísọ̀n Ń Ní Lórí Àwọn Ọmọdé

Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Mexico náà, El Universal, sọ pé: “Àwọn ère aláwòrán àfiṣènìyàn àti àwọn eré àṣedárayá orí tẹlifíṣọ̀n ń ní ipa lórí ìwà àwọn ọmọdé ọlọ́dún 6 sí 12 ju bí ilé ẹ̀kọ́ ti ń ṣe lọ, níwọ̀n bí wọ́n ti ń lo ohun tí ó tó wákàtí 38 lọ́sẹ̀ nídìí tẹlifíṣọ̀n ní ìfiwéra pẹ̀lú wákàtí 23 tí wọ́n ń lò ní iyàrá ìkàwé.” Olùwádìí Omar Torreblanca sọ pé, tẹlifíṣọ̀n ń kọ́ ọmọdé ní ohun tí yóò ṣe nínú ipò pàtàkì kan—àmọ́, ọmọ náà kì í mọ̀ bóyá àwọn ìṣesí yẹn dára tàbí kò dára. Ó ṣàlàyé pé: “Bí ọmọ náà bá ń wo eré aláwòrán àfiṣènìyàn tàbí fíìmù kan tí wọ́n ti so ọ̀kan lára àwọn tí ń ṣe eré náà mọ́lẹ̀, tí ó sì jà bọ́, ó ṣeé ṣe pé kí ọmọ náà gbìyànjú irú ohun kan náà.” Ìwádìí tí Torreblanca ṣe fi hàn pé, “àwọn ọmọdé máa ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ nínú tẹlifíṣọ̀n lójoojúmọ́ sílò nínú ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́, àmọ́ wọn kì í fi èyí tí wọ́n ń kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ sílò, níwọ̀n bí wọ́n ti ń ka ilé ẹ̀kọ́ sí ohun àìgbọdọ̀máṣe lásán.”

Ìrìn Rírìn Lè Mú Kí Ẹ̀mí Gùn

Ìwé ìròyìn Asiaweek sọ pé, rírìn lójoojúmọ́ lè mu kí ẹ̀mí ẹni gùn. Ìwádìí kan tí wọ́n fi ọdún 12 ṣe dá lórí àwọn ọkùnrin 707 tí wọn kì í mu sìgá, tí ọjọ́ orí wọ́n wà láàárín ọdún 61 sí 81, tí wọ́n lè rìn. Ìròyìn náà sọ pé, àwọn “tí wọ́n ń rin kìlómítà 3.2 (ibùsọ̀ méjì) péré lójúmọ́—kódà ní ìrìn gbẹ̀fẹ́—dín ewu kí onírúurú nǹkan pa wọ́n kù sí ìdajì.” Onírúurú àrùn jẹjẹrẹ lè tètè pa àwọn tí wọn kì í rìn ṣáájú àwọn tí wọ́n ń rin ìrìn nǹkan bí ibùsọ̀ méjì [kìlómítà 3.2] lóòjọ́, ní ìlọ́po 2.5. Ìwádìí náà, tí a tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn náà, The New England Journal of Medicine, ṣàwárí pé, rírin ibi tí ó kéré tó ìdajì ibùsọ̀ [800 mítà] lóòjọ́ pàápàá ń mú kí ẹ̀mí gùn. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn ògbógi nínú eré ìmárale ṣiyè méjì nípa ìníyelórí irú eré ìmárale tí kò gba agbára bẹ́ẹ̀. Nísinsìnyí, ìwádìí tuntun náà sọ pé: “Rírọ àwọn àgbàlagbà láti rìn lè ṣe ìlera wọn láǹfààní.”

Orin Ń Ran Àwọn Ọmọdé Lọ́wọ́

Gordon Shaw, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ físíìsì ní Yunifásítì California, Irvine, sọ pé, kíkọ́ àwọn ọmọ ọdún mẹ́ta tàbí mẹ́rin bí a ṣe ń fi ohun ìkọrin kọrin lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ronú. Ní ọjọ́ orí kékeré yìí, àwọn iṣan ọpọlọ tètè máa ń gbára jọ, àwọn olùwádìí sì ti fi hàn pé ṣíṣe é déédéé, kódà, fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá péré, lóòjọ́ lè ṣèrànwọ́ láti mú kí “ọ̀nà tí ọmọdé kan ń gbà ronú sunwọ̀n sí i fún ìgbà pípẹ́.” Nínú àyẹ̀wò olóṣù mẹ́sàn-án kan, a fi àwọn ọmọdé tí a ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ fífi dùrù kọrin wéra pẹ̀lú àwọn tí a ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ nípa lílo kọ̀ǹpútà tàbí tí a kò dá lẹ́kọ̀ọ́ rárá. Ìwé ìròyìn náà, The Sunday Times, ti London sọ pé máàkì lórí àyẹ̀wò làákàyè tí àwọn tí wọ́n ti kọ́ nípa fífi dùrù kọrin gbà fi ìpín 35 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i, tí ti àwọn ẹgbẹ́ méjì yòókù sì gbé pẹ́ẹ́lí díẹ̀ tàbí kí ó máà sí ìyàtọ̀ rárá nínú wọn.

Àjọṣepọ̀ Àwọn Ohun Alààyè Etíkun

A ha lè pa etíkun kan run nípa títún un ṣe jù bí? Ìwádìí kan níbi Ìyawọlẹ̀ Omi Òkun Swansea ní Wales, fi hàn pé, ó ṣeé ṣe. Ohun tí ó lè mú kí etíkun jọjú ni ojúkò omi àti bèbè òkun, níbi tí àwọn pàǹtírí ń kóra jọ sí lẹ́ẹ̀mejì lójúmọ́ nígbà tí omi bá kún rẹ́rẹ́. Àwọn igi, pákó tí omi gbé, èèhọ̀n, koríko, àti òkú ẹranko pàápàá, tí gbogbo wọn dà pọ̀ mọ́ koríko etíkun lè wà lára àwọn pàǹtírí náà. Àdàlú yìí ni ilé àwọn ẹ̀dá aláìléegun-ẹ̀yìn tín-tìn-tín tí ń mú kí àwọn ewéko máa jẹrà, tí afẹ́fẹ́ àti ìgbì yóò wá fún ká láti ṣiṣẹ́ bí ohun tí ń ṣu yanrìn pọ̀. Ojúkò omi àti bèbè òkun náà tún ń pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ àti ẹranko bí vole, èkúté, ehoro, àti kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ pàápàá. Dídín tí àwọn ẹyẹ wọ́dòwọ́dò tí ń jẹun ní ojúkò omi àti bèbè òkun ń dín kù ló mú kí àwọn alágbàwí ààbò ẹ̀dá fiyè sí òtítọ́ náà pé pípalẹ̀ pàǹtírí etíkun náà mọ́ láti ìgbà dé ìgbà ló ń jin ìwàdéédéé àjọṣepọ̀ ṣíṣẹlẹgẹ́ ti àwọn ohun alààyè àti etíkun náà lẹ́sẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ etíkun ń lá àlá tí kò ní lè ṣẹ ti níní etíkun tí ó mọ́. Ìwé ìròyìn náà, The Times, ti London sọ pé àlejò kan tilẹ̀ retí pé kí wọ́n ṣa àwọn òkúta wẹ́ẹ́wẹ̀ẹ̀wẹ́ kúrò nínú yanrìn.

Agbada Oúnjẹ Wa Lágbàáyé

O ha ti ṣe kàyéfì rí nípa bí àwọn olùgbé ayé ṣe ń jẹun tó lójoojúmọ́? Ìwé ìròyìn Gíríìkì náà, To Vima, ròyìn àwọn àkọsílẹ̀ amúnitagìrì díẹ̀ nípa oúnjẹ tí a ń jẹ lóòjọ́. Jákèjádò ayé, a ń ṣèmújáde bílíọ̀nù méjì ẹyin, a sì ń jẹ wọ́n—iye náà tó láti fi dín ẹyin tí ó tóbi tó erékùṣù Kípírọ́sì! Ayé ń jẹ mílíọ̀nù 1.6 tọ́ọ̀nù àgbàdo. Ọ̀dùnkún tún wọ́pọ̀, a ń jẹ 727,000 tọ́ọ̀nù rẹ̀! Ìrẹsì ni lájorí oúnjẹ fún ọ̀pọ̀ olùgbé ayé, a ń ṣèmújáde mílíọ̀nù 1.5 tọ́ọ̀nù rẹ̀ lóòjọ́. Àwọn ará China ló ń jẹ 365,000 tọ́ọ̀nù lára rẹ̀. Tọ́ọ̀nù 7,000 ewé tíì tí a ń pọn ń kún nǹkan bí bílíọ̀nù mẹ́ta ife. Àwọn tí wọ́n wà ní ipò gíga láyé ń gbádùn mílíọ̀nù 2.7 tọ́ọ̀nù ẹja caviar. Àgbàlagbà kan tí a lè mú bí àpẹẹrẹ ní ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ayé ń jẹ 4,000 èròjà afúnnilágbára lóòjọ́—ní ìfiwéra pẹ̀lú 2,500 èròjà afúnnilágbára tí a dámọ̀ràn—nígbà tí ìpíndọ́gba rẹ̀ jẹ́ 1,800 péré ní Áfíríkà.

Àwọn Ẹja Àdàgbá Ń Jára Mọ́ṣẹ́

Ìwé ìròyìn náà, The Daily Yomiuri, sọ pé, wọ́n ti ń lo àwọn ẹja àdàgbá láti ṣàyẹ̀wò bí omi ṣe dára sí ní Japan. Ní ọdún márùn-ún sẹ́yìn, Ọ̀jọ̀gbọ́n Kenji Namba láti Yunifásítì Hiroshima ṣàwárí pé àwọn ẹja àdàgbá máa ń hùwà padà bí ìníyelórí omi bá yí padà níwọ̀nba. Àwọn èròjà tí ó lè pani lára bí cadmium tàbí cyanide ń jẹ́ kí ìlùkìkì ọkàn-àyà ẹja àdàgbá fawọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé èròjà trichloroethylene tí ń fa àrùn jẹjẹrẹ tètè máa ń jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ̀ máa yára lù kìkì. Wọ́n ti ń ta ẹ̀rọ kan tí ń lo irú agbára ìmọ̀lára àrà ọ̀tọ̀ yìí nísinsìnyí. Ẹja àdàgbá náà yóò wà nínú ọ̀pá tí ó ní èròjà acrylic tí ó wà nínú ẹ̀rọ náà. Bí omi náà ti ń ṣàn gba inú ọ̀pá náà kọjá, àwọn ẹ̀yà agbanámọ́ra tí a so mọ́ ọ̀pá náà ń yẹ ìwọ̀n ìlùkìkì ọkàn-àyà ẹja àdàgbá náà wò, ìyípadà èyíkéyìí tó bá sì wà ni ìhùmọ̀ ahangooro yóò gbé ìsọfúnni nípa rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ amojú-ẹ̀rọ kan. Àwọn ẹja àdàgbá tí a mú láti inú omi tí ó mọ́ tónítóní ni a ṣà fún iṣẹ́ yìí, a sì ń dá wọn padà lóṣooṣù kí o bàa lè pé pérépéré.

Bẹ́líìtì Ààbò àti Ikú Mọ́tò

Ìwé ìròyìn náà, The Tico Times, ti San José, Costa Rica, sọ pé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilé Ẹjọ́ Gígajùlọ ti Costa Rica fagi lé òfin kan tí ó kan lílo bẹ́líìtì ààbò nípá láìpẹ́ yìí, ní sísọ pé ó tẹ òmìnira ara ẹni lójú. Láti ìgbà tí wọ́n ti ṣe ìpinnu náà, iye àwọn awakọ̀ tí ń lo bẹ́líìtì ààbò ní orílẹ̀-èdè náà ti dín kù láti ìpín 87 nínú ọgọ́rùn-ún sí ìpín 44 nínú ọgọ́rùn-ún péré, nígbà tí ìjàǹbá àti iye àwọn tí ó ń pa sì ti pọ̀ sí i. Ìròyìn náà sọ pé, Ìgbìmọ̀ Aláàbò Ojú Títì ní Costa Rica ti gbé ìgbésẹ̀ pàjáwìrì kan láti dín bí ó ṣe ń ṣèpalára tó kù, àmọ́ àwọn èrò ọkọ̀ máa ń fi orí ìsapá náà ṣánpọ́n nígbà tí wọn kò bá lo bẹ́líìtì ààbò. Aṣojú Ìgbìmọ̀ náà, Manfred Cervantes, sọ pé: “A ń gbìyànjú gan-an láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀ pé wọ́n lè dáàbò bo ara wọn, kí wọ́n sì gba ẹ̀mí wọn là nípa jíjẹ́ awakọ̀ tí ó mọ iṣẹ́ níṣẹ́.”

Àwọn Tí Tábà Ń Pa

Ọ̀jọ̀gbọ́n Judith Mackay, ti Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe Lórí Àkóso Tábà Lílò ní Éṣíà, sọ pé, nǹkan bí bílíọ̀nù 1.1 ènìyàn jákèjádò ayé ní ń lò tábà. Gẹ́gẹ́ bí a ti ròyìn rẹ̀ nínú ìwé ìròyìn British Medical Journal, níbi àpérò àgbáyé lórí tábà àti ìlera, irú rẹ̀ kẹwàá, a fojú díwọ̀n pé mílíọ̀nù mẹ́ta ènìyàn ni tábà pa ní 1990. A retí pé kí iye yẹn lọ sókè sí mílíọ̀nù mẹ́wàá láàárín ọdún 2025 sí 2030. Ìwé ìròyìn Journal náà sọ pé láàárín ẹ̀wádún mẹ́ta tí ń bọ̀, pípọ̀ tí àwọn tí sìgá mímu ń pa ń pọ̀ sí i yóò nasẹ̀ kúrò ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti gòkè àgbà lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Richard Peto, ọ̀jọ̀gbọ́n nípa àkọsílẹ̀ oníṣirò nínú ìmọ̀ ìṣègùn ní Yunifásítì Oxford, ṣe sọ, “àwọn tí tábà ń pa ní ilẹ̀ China ti pọ̀ ju ti orílẹ̀-èdè èyíkéyìí lọ ná.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́