ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 1/22 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ìpakúpa Ní Ìdákẹ́ Jẹ́ẹ́”
  • O Léwu Púpọ̀ Ju Sìgá Lọ
  • Ipa Ìdarí Ìmọ̀ọ́kọmọ̀ọ́kà Lórí Àwọn Ìyá
  • Ìgbẹ́kẹ̀lé Tí A Fọ́ Yángá
  • Ìgbésí Ayé Ìdílé Ń Yìnrìn
  • Ewu Tí Ó Wà Nínú Ìfinifọ́kọ Láti Orílẹ̀-Èdè Kan Sí Òmíràn
  • Àmódi Ìrìn Àjò
  • Bíba Afẹ́fẹ́ Jẹ́ Ń Burú Sí I ní Ilẹ̀ Faransé
  • Àrùn Àìlèsọ̀rọ̀ Dáradára Láàárín Àwọn Ọmọdé
  • Mímọyì Àwọn Obìnrin àti Iṣẹ́ Wọn
    Jí!—1998
  • Àwọn Abiyamọ Wàhálà Àṣekúdórógbó Tí Wọ́n Ń Ṣe
    Jí!—2002
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
  • Òbí Tó Ń Dá Tọ́mọ Túbọ̀ Ń Pọ̀ Sí I
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 1/22 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

“Ìpakúpa Ní Ìdákẹ́ Jẹ́ẹ́”

Lójú ìwòye Oxfam, ẹgbẹ́ afẹ́dàáfẹ́re onítẹ̀síwájú kan tí ó gba iwájú jù lọ, ìjìyà àwọn òtòṣì àgbáyé pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí a fi lè pè é ní, “ìpakúpa ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́,” gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Guardian Weekly ti Britain ti sọ. Nínú ìròyìn kan tí ń ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìgbétáásì ọdún márùn-ún láti ran àwọn òtòṣì àgbáyé lọ́wọ́, ẹgbẹ́ Oxfam ṣàwárí pé, ìdá kan nínú márùn-ún nínú àwọn olùgbé ayé ń gbé ní àwọn 50 orílẹ̀-èdè tí ó tòṣì jù lọ. Àwọn orílẹ̀-èdè kan náà yẹn rí ìpín wọn nínú ohun tí ń wọlé fún àgbáyé tí ó dín kù gan-an sí ìpín 2 nínú ọgọ́rùn-ún. Àlàfo tí ó wà láàárín àwọn olówó àti àwọn òtòṣì láàárín àwọn orílẹ̀-èdè sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Fún àpẹẹrẹ, Mexico ti jìyà yánpọnyánrin ìnáwó àti ipò òṣì líle koko, ṣùgbọ́n lẹ́sẹ̀ kan náà, ó tún ti ní ìdàgbàsókè yíyára kánkán jù lọ nínú iye àwọn olówó tabua. Obìnrin agbẹnusọ kan fún ẹgbẹ́ Oxfam sọ pé: “Ó dà bí pé . . . àwọn aṣáájú ayé àti àjọ UN ti ṣìnà. A nílò ọ̀nà àbójútó tuntun fún ẹgbẹ̀rúndún tuntun.”

O Léwu Púpọ̀ Ju Sìgá Lọ

Èyí ni ìpinnu tí ìgbìmọ̀ onídàájọ́ kan dórí rẹ̀ ní India nípa bidi, tí a tún mọ̀ sí sìgá tálákà. A fojú díwọ̀n rẹ̀ pé, èyí tí ó ju mílíọ̀nù mẹ́rin àwọn ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ọmọdé ń pèsè èyí tí ó ju 300 mílíọ̀nù bidi ní ọjọ́ kan, ní dídi ekuru kátabá sínú ewé tendu tí wọ́n sì ń fi okùn di ìdì kéékèèké náà pọ̀. Ní ìbámu pẹ̀lú ìwé agbéròyìnjáde The Times of India, ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ kan fi hàn pé bidi lágbára láti fa àrùn jẹjẹrẹ ní ìlọ́po méjì àbọ̀ ju sìgá lọ, ó lè fa àrùn silicosis àti ikọ́ fée, ó sì ní ìpín 47 nínú ọgọ́rùn-ún oró tar àti ìpín 3.7 nínú ọgọ́rùn-ún nicotine tí a bá fi wéra pẹ̀lú ojúlówó sìgá India tí ó ní ìpín 36 nínú ọgọ́rùn-ún oró èéfín pẹ̀lú ìpín 1.9 nínú ọgọ́rùn-ún nicotine. Kì í ṣe kìkì àwọn tí ń mú un ni ó wà nínú ewu. Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ènìyàn tí ń pèsè bidi sábà máa ń ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ wákàtí nínú ipò tí kò mọ́ tónítóní, tí wọ́n sì ń fa ekuru kátabá náà sínú nínú àwọn ahéré tí afẹ́fẹ́ kì í ti í fẹ́ dáradára. Àwọn ọmọdé alágbàṣe tilẹ̀ ń jìyà ní pàtàkì.

Ipa Ìdarí Ìmọ̀ọ́kọmọ̀ọ́kà Lórí Àwọn Ìyá

Àwọn ògbógi nípa ìlera gbogbo ará ìlú gbà gbọ́ tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn pé àwọn ọmọdé ní àwọn ilẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ní àǹfààní tí ó dára jù láti wà láàyè, bí àwọn òbí wọn bá mọ̀ọ́kọmọ̀ọ́kà—ṣùgbọ́n wọn kò tí ì lè tọ́ka sí kíkàwé gẹ́gẹ́ bí kókó abájọ fún èyí. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn New Scientist ti sọ, ìwádìí kan tí a ṣe ní Nicaragua “ni ó kọ́kọ́ fi hàn pé àwọn obìnrin tí wọ́n ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ní ipa ìdarí tààràtà lórí ìlera àwọn ọmọ wọn.” Ìwádìí náà ṣàyẹ̀wò àwọn obìnrin tí kò mọ̀ọ́kọmọ̀ọ́kà, tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà tí wọ́n sì kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ aládàá ńlá ti Nicaragua fún mímọ̀ọ́kọmọ̀ọ́kà láàárín ọdún 1979 sí 1985. Ní apá ìparí àwọn ọdún 1970, ìṣírò iye ikú àwọn ọmọdé tí àwọn ìyá wọn kò mọ̀ọ́kọmọ̀ọ́kà jẹ́ nǹkan bí ìpín 110 nínú 1,000 ọmọ tí a ń bí. Ní 1985, ìṣírò iye ikú fún àwọn ọmọ tí àwọn ìyá wọn ti kọ́ láti kàwé níbi ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà dín kù sí ìpín 84 nínú ẹgbẹ̀rún. Wọ́n tún bọ́ àwọn ọmọ wọn dáradára jù. Àwọn ògbógi kò tí ì mọ̀ dájú síbẹ̀, ìdí tí àwọn ọmọ ìyá tí wọ́n mọ̀ọ́kọmọ̀ọ́kà ṣe sàn jù.

Ìgbẹ́kẹ̀lé Tí A Fọ́ Yángá

A ti gbo ìlú kékeré Chesterfield Inlet tí ó wà ní Hudson Bay ní Àwọn Àgbègbè Ìpínlẹ̀ Àríwá Ìwọ̀ Oòrùn Canada jìgìjìgì nípasẹ̀ ẹ̀sùn bíbá àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ lò nílòkulò tí ó gbalẹ̀ kan. Bí ìwé ìròyìn Maclean’s ṣe sọ, ìròyìn dáńfó kan tí ìjọba àkóso fi sóde láìpẹ́ ṣàwárí àwọn ọ̀ràn bíbá àwọn ọmọdé ìbílẹ̀ Inuit ṣèṣekúṣe àti fífìyà jẹ wọ́n fún ohun tí ó ju sáà ọdún 17 lọ láàárín àwọn ọdún 1950 sí àwọn ọdún 1960 ní ilé ẹ̀kọ́ Sir Joseph Bernier Federal Day School àti ní ilé ibùgbé tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ń ṣàkóso tí ó wà nítòsí rẹ̀. Àwọn ọlọ́pàá parí ìwádìí olóṣù 21 lórí àwọn ìfẹ̀sùnkanni 236 nípa ìbániṣèṣekúṣe, wọ́n sì pinnu láti má ṣe pẹjọ́—nínú àwọn ọ̀ràn mélòó kan, nítorí pé, ìwọ̀n àkókò tí òfin fàyè gbà ti kọjá; nínú àwọn mìíràn, nítorí pé àwọn ọ̀daràn tí a fẹ̀sùn kàn jẹ́ àgbàlagbà tàbí tí wọ́n tilẹ̀ ti kú; nínú àwọn mìíràn, nítorí pé díẹ̀ nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tẹ́lẹ̀ rí kò lè fi àwọn arúfin náà hàn pẹ̀lú ìdánilójú. Ìwé ìròyìn Maclean’s sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò tí ó ti kọjá túbọ̀ mú kí fífìyà jẹ àwọn arúfin náà ṣòro dájúdájú, kò tí ì mú ìrora àwọn òjìyà ìpalára náà kúrò.”

Ìgbésí Ayé Ìdílé Ń Yìnrìn

Báwo ni ìgbésí ayé ìdílé ṣe ń kẹ́sẹ járí tó lónìí? Gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀ka Ìsọfúnni Gbogbogbòò ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti sọ, kárí ayé, àwọn bàbá ń lo èyí tí ó dín sí wákàtí kan ní ìpíndọ́gba pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn ní ọjọ́ kan—ní Hong Kong, ó jẹ́ kìkì ìṣẹ́jú mẹ́fà ní ìpíndọ́gba. Òbí ẹlẹ́nì kan ṣoṣo ń pọ̀ sí i. Fún àpẹẹrẹ, ní United Kingdom, ìdajì ìbímọ tí ó wáyé ní 1990 jẹ́ nípasẹ̀ àwọn obìnrin tí kò ṣègbéyàwó. Ìwà ipá nínú ìdílé ń pọ̀ sí i pẹ̀lú. A fojú díwọ̀n rẹ̀ pé ìpín 4 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ tí ń gbé ní United States àti Ìhà Ìwọ̀ Oòrùn Europe ń nírìírí ìwà ipá líle koko láàárín ilé ní ọdún kọ̀ọ̀kan. Àwọn arúgbó pẹ̀lú ń ní ìṣòro. Ìròyìn UN sọ pé: “Kódà ní àwọn orílẹ̀-èdè Ìṣọ̀kan Ilẹ̀ Europe (EU) tí a sọ pé, ‘wọ́n ti gòkè àgbà’ pàápàá, ìpín kan nínú márùn-ún gbogbo àgbàlagbà ń gbé nínú ipò òṣì, tí wọ́n sábà máa ń dá nìkan wà ní àwọn ibi àdádó nínú ìlú ńlá láìsí ìtìlẹyìn àwọn ìdílé àti ìbátan wọn.”

Ewu Tí Ó Wà Nínú Ìfinifọ́kọ Láti Orílẹ̀-Èdè Kan Sí Òmíràn

Òmìnira púpọ̀ sí i láti lọ láti Ìhà Ìlà Oòrùn Europe sí Ìhà Ìwọ̀ Oòrùn Europe ti ní ìyọrísí tí kò gbádùn mọ́ni: ìfinifọ́kọ láti orílẹ̀ èdè kan sí òmíràn. Láti 1991, èyí tí ó tó 15,000 àwọn obìnrin ti lọ láti Ìhà Ìlà Oòrùn Europe sí Ìhà Ìwọ̀ Oòrùn Europe gẹ́gẹ́ bí ìyàwó tí a kọ̀wé béèrè fún. Ọ̀pọ̀ obìnrin ń gbé nínú ipò òṣì, wọ́n sì ń lálàá nípa ìgbésí ayé tí ó sàn jù, nítorí náà, wọ́n dáhùn sí ìpolówó ẹgbẹ́ tí ń fini fọ́kọ. Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé, àlá náà máa ń yọrí sí ìbànújẹ́ nígbà tí obìnrin kan bá bá ara rẹ̀ ní àdádó ní ilẹ̀ òkèèrè, níbi tí òǹrorò ọkọ kan ti jẹ gàba lé e lórí. Ní Germany, ìyàwó kan tí ó jẹ́ ará Poland ni ọkọ rẹ̀ lù bátabàta tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi sá lọ sínú igbó, tí ó sì fara pamọ́ fún ọjọ́ méjì ní ibi tí ó tutù nini. Nítorí ara rẹ̀ tí ó di yìnyín, a ní láti gé àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ òsì àti ẹsẹ̀ rẹ̀ ọ̀tún kúrò. Ìwé agbéròyìnjáde Guardian Weekly lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ẹgbẹ́ tí ń fini fọ́kọ tún ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ aṣẹ́wó. Wọ́n ń tan àwọn obìnrin lọ sí òkè òkun, wọ́n sì ń fi agbára tì wọ́n sí ilé aṣẹ́wó. A sì máa ń pa àwọn tí wọ́n bá ṣàtakò.”

Àmódi Ìrìn Àjò

Àmódi ìrìn àjò ha máa ń ṣe ọ́ bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ìwọ nìkan. Ìwé agbéròyìnjáde International Herald Tribune ròyìn pé, odidi 9 nínú gbogbo ènìyàn 10 ní ìtẹ̀sí láti ní àmódi ìrìn àjò dé ìwọ̀n yíyàtọ̀. Àwọn ajá, pàápàá jù lọ, àwọn ọmọ wọn, lè ní i. Kódà àwọn ẹja lè ṣàìsàn omi nígbà tí a bá ń kó wọn káàkiri nínú ọkọ̀ ojú omi lórí omi òkun tí kò fara rọ! Kí ni ojútùú rẹ̀? Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń yíjú sí oògùn, tí a lè rí rà ní ọ̀pọ̀ ilé ìpòògùn. Àwọn àbá mìíràn tí ó lè ṣèrànwọ́ nìyí: Má ṣe kàwé nínú ọkọ̀ tí ó wà lórí ìrìn. Jókòó lórí ibi tí ìyíbiribiri kò ti pọ̀—fún àpẹẹrẹ, ní ìjókòó iwájú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tàbí lórí apá ọkọ̀ òfuurufú. Máa wo ohun tí ó wà ní ọ̀nà jíjìn, irú bíi òkèèrè réré. Bí o kò bá fẹ́ ṣe ìyẹn, di ojú rẹ.

Bíba Afẹ́fẹ́ Jẹ́ Ń Burú Sí I ní Ilẹ̀ Faransé

Láìka ìsapá àjùmọ̀ṣe láti kápá rẹ̀ sí, bíba afẹ́fẹ́ jẹ́ túbọ̀ ń burú sí i, ó sì ń fi ìlera ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ènìyàn tí ń gbé ní Paris àti àwọn ìlú Faransé yòókù sínú ewu. Nígbà tí ó jẹ́ pé, nígbà tí ó kọjá sẹ́yìn, àwọn ilé iṣẹ́ ńlá ni igi wọ́rọ́kọ́ tí ń daná rú, lónìí àwọn ohun ìrìnnà ń ṣokùnfà ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún ìbafẹ́fẹ́jẹ́ ní àwọn ìlú ńlá. Láti ọdún 1970, àwọn ọkọ̀ tí ń bẹ ní Faransé ti di ìlọ́po méjì, ní lílọ sókè láti orí mílíọ̀nù 12 sí mílíọ̀nù 24, pẹ̀lú èyí tí ó tó mílíọ̀nù 3.2 ní ẹkùn ìlú Paris nìkan ṣoṣo. Ìwé agbéròyìnjáde ti Paris náà, Le Monde, sọ pé, ìwádìí tí ìjọba ṣe láìpẹ́ fi hàn pé, fún gbogbo ìbísí kọ̀ọ̀kan nínú iye ìwọ̀n èròjà onímájèlé ní ẹkùn ìlú Paris, ìlọsókè tí ó ṣe wẹ́kú nínú iye ikú àti ìgbàtọ́jú ìwòsàn nítorí àrùn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú èémí wà pẹ̀lú. Ìgbésẹ̀ pàtó díẹ̀ ni a tí ì gbé. Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn òṣèlú ń bẹ̀rù pé, ìgbésẹ̀ èyíkéyìí tí ó lágbára tó láti gbéṣẹ́ kì yóò dùn mọ́ àwọn olùdìbò wọn tí ń wakọ̀ nínú.

Àrùn Àìlèsọ̀rọ̀ Dáradára Láàárín Àwọn Ọmọdé

Àwọn olùṣèwádìí ní Ilé Ìwòsàn ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga fún Àìlèsọ̀rọ̀ Dáradára ní Mainz, Germany, ti ṣàwárí pé, ọ̀kan nínú mẹ́rin àwọn ọmọ tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ti àwọn ọmọ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé ní àrùn àìlèsọ̀rọ̀ dáradára. Ọ̀jọ̀gbọ́n Manfred Heinemann, tí ó jẹ́ olùdarí ilé ìwòsàn náà jẹ́wọ́ pé: “N kò lè gba iye náà gbọ́.” Ẹgbẹ́ oníṣègùn ṣèwádìí lórí àwọn ọmọdé ọlọ́dún mẹ́ta àti mẹ́rin, wọ́n sì rí i pé ìpín 18 sí 34 nínú ọgọ́rùn-ún ní àrùn àìlèsọ̀rọ̀ dáradára. Iye tí ó ṣe wẹ́kú ní ọdún 1982 jẹ́ kìkì ìpín mẹ́rin nínú ọgọ́rùn-ún. Kí ni ó fa ìlọsókè náà? Ìwé agbéròyìnjáde Der Steigerwald-Bote ti Germany ròyìn pé: “Àwọn ìdílé ń wo tẹlifíṣọ̀n láwòjù, wọ́n kì í sì í sọ̀rọ̀ púpọ̀.” Ó dà bí ẹni pé fídíò, tẹlifíṣọ̀n àti àwọn eré orí kọ̀m̀pútà ti ń gba ẹrú iṣẹ́ àwọn òbí ṣe nínú ọ̀pọ̀ ìdílé. Àwọn olùwádìí ṣàkíyèsí pé, bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ kan tí wọ́n fẹ́rẹ̀ má lè sọ̀rọ̀ jẹ́ “ayára-bí-àṣá” tí ó bá kan àwọn eré kọ̀m̀pútà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́