ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 1/22 ojú ìwé 18-20
  • Iná Mọ́ Àwọn Ilé Iṣẹ́ Tábà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iná Mọ́ Àwọn Ilé Iṣẹ́ Tábà
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìròyìn Tí Aṣojúkọ̀ròyìn Jí! Kọ Lórí Àṣà Náà
  • Lájorí Àwọn Tí Wọ́n Fojú Sùn Gan-an
  • Ṣé Kí O Máa Gbáná Mọ́rí Ni Àbí Kí O Máa Gbáyé Lọ?
  • Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Láti Jáwọ́ Nínú Sìgá Mímu?
    Jí!—2000
  • Múra Sílẹ̀ De Ìṣòro
    Jí!—2010
  • Ojú Wo ni Ọlọ́run fi Ń Wo Sìgá Mímu?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Sìgá—O Ha Máa Ń Kọ̀ Ọ́ Bí?
    Jí!—1996
Jí!—1996
g96 1/22 ojú ìwé 18-20

Iná Mọ́ Àwọn Ilé Iṣẹ́ Tábà

NÍ ÌBÁMU pẹ̀lú ìròyìn kan tí ó jáde nínú ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ti July 26, 1995, “Ẹ̀ka Ìdájọ́ ti gbé ìgbìmọ̀ àwọn adájọ́ tí ń wádìí ẹ̀sùn ọ̀daràn kan kalẹ̀ ní New York láti ṣèwádìí bóyá àwọn ilé iṣẹ́ tábà ń parọ́ èròjà tí ó wà nínú sìgá àti àwọn àbájáde búburú tí wọ́n ní, fún àwọn òṣìṣẹ́ Orílẹ̀-Èdè tí wọ́n ń ṣàyẹ̀wò rẹ̀. Àfàìmọ̀ kí ẹ̀ka náà máà gbé ìgbìmọ̀ àwọn adájọ́ mìíràn kalẹ̀ níhìn-ín láti ṣèwádìí bóyá àwọn ṣàràkí àwọn ilé iṣẹ́ náà parọ́ fún àwọn ìgbìmọ̀ Àpérò nípa àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe jáde.”

Kí ló fa èyí? Ìròyìn náà mú kí ó ṣe kedere. Ní oṣù April 1994, àwọn sàràkísàràkí ilé iṣẹ́ tábà ńláńlá méje ní United States ti fẹ̀rí hàn nípa jíjẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú ìgbìmọ̀ Àpérò kan pé, “àwọn kò rò pé èròjà nicotine jẹ́ ohun tí ń di bárakú, tàbí pé sìgá ń fa àrùn, tàbí pé ilé iṣẹ́ àwọn ń múkan mọ́kan pẹ̀lú ìwọ̀n èròjà nicotine tí ó wà nínú àwọn ohun tí a fi tábà ṣe.”

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí páńsá fi já síná—tí àṣírí sísọ tí wọ́n sọ pé àwọn kò mọwọ́ mẹsẹ̀ fi tú síta—nígbà tí ẹgbẹ̀rún méjì ìwé àkọsílẹ̀ kan tí ń ṣàkóbá bọ́ sí gbangba, ní oṣù June 1995. Àwọn ìwé àkọsílẹ̀ yìí fi hàn pé àwọn olùṣèwádìí nípa tábà ti lo ọdún 15 níbi ìwádìí ipa “oògùn” tí èròjà nicotine ń ní lórí ara, ọpọlọ àti ìhùwàsí àwọn amusìgá. Dókítà Victor DeNoble, tí ó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ olùṣèwádìí fún ọ̀kan nínú àwọn ilé iṣẹ́ náà, ṣàpèjúwe lájorí àwárí ìwádìí náà pé: “Ilé iṣẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí í mọ̀ pé àwọn lè dín oró èéfín náà kù, àmọ́ kí àwọ́n mú kí èròjà nicotine lọ sókè sí i, kí àwọn amusìgá ṣì tẹ́wọ́ gba sìgá náà síbẹ̀. Lẹ́yìn gbogbo ìwádìí tí wọ́n ṣe, wọ́n wá mọ̀ pé kì í ṣe kìkì pé èròjà nicotine ń rọ ènìyàn lára tàbí ru ènìyàn sókè nìkan ni, ṣùgbọ́n ó ń ní ipa rẹ̀ tí ó pọ̀ jù lọ nínú ara, nínú ọpọlọ, àti pé àwọn ènìyàn ń mu sìgá kí ó baà lè nípa lórí ọpọlọ wọn.”

Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ, àwọn ìwádìí tí ilé iṣẹ́ ṣe fi hàn pé “ìyówù irú sìgá tí àwọn ènìyàn mu, ó jọ pé wọ́n máa ń rí ìwọ̀n èròjà nicotine tí wọ́n nílò nípa fífà á sínú sí i, tí wọn yóò sì jẹ́ kí èéfín náà pẹ́ lẹ́nu wọn, tàbí kí wọ́n máa mu sìgá púpọ̀ sí i.” Àwọn olùṣèwádìí ilé iṣẹ́ gbìdánwò láti ṣe sìgá tí oró tar rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, tí ó sì ní ìwọ̀n èròjà nicotine tí ó pọ̀ tó nínú láti fún àwọn amusìgá ní ìtẹ́lọ́rùn.

Ìwé àkọsílẹ̀ náà tún fi hàn síwájú sí i pé ilé iṣẹ́ tábà ń fi ìfẹ́ ọkàn mímúná hàn nínú àwọn oníbàárà rẹ̀. Ó ti dójú sun àwọn ọmọ kọ́lẹ́ẹ̀jì fún ohun tí ó ti lé ní ọdún 15. A bèèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ń gbé ìlú Iowa, títí kan àwọn amusìgá tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún 14, nípa àṣà sìgá mímu wọn.

A rí ohun tí ìwé àkọsílẹ̀ ìwádìí wọ̀nyí fi hàn gẹ́gẹ́ bí àǹfààní kan fún àwọn agbẹjọ́rò láti kóra jọ pọ̀ láti bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀sùnkàn alájùmọ̀ṣe kan lòdì sí àwọn ilé iṣẹ́ tábà méje. Wọ́n fẹ̀sùn kàn wọ́n pé, àwọn ilé iṣẹ́ tábà ń fi ohun tí wọ́n mọ̀ nípa sísọ tí èròjà nicotine ń sọ ara rẹ̀ dí bárakú fún ènìyàn pamọ́, wọ́n sì ń yí ọwọ́ ìwọ̀n èròjà nicotine padà kí ó baà lè di bárakú fún àwọn ènìyàn. Agbẹjọ́rò kan sọ pé, kò sí agbo àwọn agbẹjọ́rò tí yóò gbà á gbọ́ láyé yìí pé, àwọn ilé iṣẹ́ wọ̀nyí ń fi ìwádìí ṣe eré lásán ni.

Nígbà tí a fínná mọ́ wọn lójú méjéèjì ní àwọn apá ilẹ̀ ayé tí ó ti gòkè àgbà, tábà ń rọ́wọ́ mú ní àwọn apá ilẹ̀ ayé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Ní 40 ọdún sẹ́yìn, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kò sí obìnrin kankan tí ń mu sìgá ní ìhà Gúúsù, tàbí ní apá ilẹ̀ ayé tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, kìkì ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọkùnrin ní ń mu ún. Ṣùgbọ́n lónìí, ìpín 8 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo àwọn obìnrin àti ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ní ń mu sìgá—iye yẹn sì ń lọ sókè. Àwọn olùṣèwádìí sọ pé: “Èéfín sìgá ti ń fẹ́ gba ọ̀nà ìhà Gúúsù.”

Ìròyìn Tí Aṣojúkọ̀ròyìn Jí! Kọ Lórí Àṣà Náà

Òǹkọ̀wé wa tí ó wà ní Brazil sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó kó gbogbogbòò pọ̀ lórí ipò nǹkan ní ìhà Gúúsù. Ìwádìí tí a ṣe ní àwọn apá ayé tí ó ní ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ ńláńlá ṣàpèjúwe ewu ikú tí ó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí amutábà. Ó ní ipa tirẹ̀. Ètò Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) ròyìn pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti mọ ìjẹ́pàtàkì fífún gbogbo àwọn ará ìlú ní ìsọfúnni ti ń rí ìbẹ̀rẹ̀ ìlọsílẹ̀ nínú iye àwọn ènìyàn tí ń mu sìgá.” Panos, èto kan tí ń pèsè ìsọfúnni, tí ó fìdí kalẹ̀ sí London, fi kún un pé: “Ní ìhà Àríwá, sìgá mímu kì í ṣe ohun tí ó lòde mọ́ ní ọ̀pọ̀ àwọn ilé, àwọn ibi tí ó wà fún gbogbogbòò àti ní àwọn ibi iṣẹ́,” ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn sì ti wá ń mọ̀ nísinsìnyí pé “sìgá mímu lè pa àwọn.” “Ilé iṣẹ́ tábà ti ń wọ́ lọ sí ìhà Gúúsù.”

Ní òdì kejì, ní ìhà Gúúsù, ṣíṣí ọjà tuntun máa ń dà bí èyí tí ó rọrùn bíi ṣíṣí páálí sìgá. Fún àwọn ilé iṣẹ́ tábà, ipò nǹkan ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà mìrìngìndìn. Kò sí ìfòfindè kankan lórí ìpolówó sìgá ní 3 nínú 4 àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, nígbà kan náà, àwọn ènìyàn kò sì fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ewu sìgá mímu. Panos sọ pé: “Àwọn ènìyàn kò mọ̀ nípa àwọn ewu náà nítorí pé, kò sí ẹni tí ó sọ fún wọn.”

Láti lè rọ àwọn ọ̀dọ́bìnrin—ọ̀kan lára ibi pàtàkì tí ilé iṣẹ́ náà dójú sùn jù lọ—láti tanná ran sìgá wọn àkọ́kọ́, àwọn ìpolówó ọjà “ń fi sìgá mímu hàn bí eré amóríyá oníyòyòyinyin kan tí àwọn obìnrin tí ó lómìnira ń gbádùn.” Àwọn ìpolówó ọjà tábà dọ́gbọ́n fẹ́ fara jọ èyí tí wọ́n lò ní àwọn apá ilẹ̀ ayé tí ó ní ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ ńláńlá ní 50 ọdún sẹ́yìn. Nígbà náà lọ́hùn-ún, àwọn ìpolówó ọjà náà ṣiṣẹ́. Ẹnì kan sọ pé, kò pẹ́ tí 1 nínú àwọn obìnrin 3 “fi ń ṣáná sí sìgá pẹ̀lú ìháragàgà bí ọkùnrin.”

Lónìí, ìpolówó ọjà alájàkú-akátá tí ó múná tí a dójú rẹ̀ sọ àwọn obìnrin tí wọ́n wà ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà fi dá wọn lójú pé, “àṣeyọrí” ìpolówó ọjà ti àwọn ọdún 1920 àti 1930 tún ti fẹ́ ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Nítorí bẹ́ẹ̀, ohun pípani láyà tí à ń fojú sọ́nà fún ni pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọdébìnrin tí wọ́n wà ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tòṣì jù ní ayé wà nínú ewu dídi “ọmọbìnrin òrenté nígbà èròjà nicotine wọn,” gẹ́gẹ́ bí olùṣàkíyèsí kan ti sọ ọ́.

Lájorí Àwọn Tí Wọ́n Fojú Sùn Gan-an

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn obìnrin ni ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ènìyàn tí ilé iṣẹ́ tábà dójú sọ ní pàtàkì, àwọn ọ̀dọ́ ni lájorí ènìyàn tí wọ́n dójú sọ. Wọ́n ń rí èrè níbi àwọn ìpolówó ọjà tí wọ́n ń fi àwọn àwòrán ẹ̀fẹ̀ ṣe àti níbi àwọn àwòrán sìgá tí wọ́n ń fi sára àwọn ohun ìṣeré ọmọdé, bákan náà sì ni níbi ṣíṣe tí wọ́n ń ṣonígbọ̀wọ́ àwọn ètò eré ìdárayá.

Ní China, ìwé ìròyìn Panoscope ròyìn pé, àwọn ọ̀dọ́ “ti bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ.” Nǹkan bí ìpín 35 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ ọlọ́dún 12 sí 15 àti ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ ọlọ́dún 9 sí 12 ni wọ́n jẹ́ amusìgá. Ní Brazil, ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ Folha de S. Paulo ròyìn pé, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́wàá àwọn èwe ni a fojú díwọ̀n pé wọ́n jẹ́ amusìgá. Ṣé wọn kò mọ̀ nípa ewu rẹ̀ ni? Rafael, ọmọdékùnrin ará Brazil kan, tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 15, tí ń mu sìgá páálí kan àti àbọ̀ lójúmọ́ sọ pé: “Mo mọ̀ pé sìgá mímu léwu, àmọ́ ó dára gan-an.” Kí ní ń jẹ́ ìyọrísí ìrònú kò-kàn-mí yìí? Panos ròyìn pé: “Lójoojúmọ́, ó kéré tán, àwọn 4,000 ọ̀dọ́ mìíràn ń bẹ̀rẹ̀ sìgá mímu.”

Àwọn ilé iṣẹ́ tábà ń kó àwọn ọjà wọn kan wá sí ìhà Gúúsù, tí ó ní ìwọ̀n oró èéfín àti èròjà nicotine tí ó ga nínú ju irú àwọn tí à ń tà ní ìhà Àríwá. Ìdí tí ó fi rí bẹ́ẹ̀ ṣe kedere. Òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ tábà kan sọ, ní bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn pé: “N kò lè túúbá nítorí èròjà nicotine. Òun ní ń mú kí ọjà máa yá. Òun ní ń jẹ́ kí àwọn ènìyàn máa padà wá rà sí i.” Ó ń ṣiṣẹ́. Ìtẹ̀jáde ilẹ̀ Netherlands kan, Roken Welbeschouwd (Sìgá Mímu—Tí A Bá Yiiri Gbogbo Rẹ̀ Wò), mú un dájú pé: “Nítorí gíga tí ìwọ̀n èròjà nicotine ga, àwọn ènìyàn tètè máa ń fi pẹ̀lú ìrọ̀rùn gbára lé sìgá, èyí sì máa ń fún àwọn ènìyàn ní àǹfààní láti mu púpọ̀ sí i, kí iye tí wọ́n ń tà sì lọ sókè sí i nípa rírọra máa dín ìwọ̀n èròjà nicotine kù.”

Panos parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ilé iṣẹ́ tábà ń wo ìhà Gúúsù gẹ́gẹ́ bí ọjà tí yóò mú kí ilé iṣẹ́ náà máa bá òwò lọ.”

Ṣé Kí O Máa Gbáná Mọ́rí Ni Àbí Kí O Máa Gbáyé Lọ?

Bí o bá ń gbé ní orílẹ̀-èdè kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, kí ni ìwọ yóò ṣe? Òtítọ́ náà ṣe kedere. Títí tí ó fi di 1950, ikú tí àwọn àrùn tí ó tan mọ́ sìgá ń fà kò tó nǹkan, ṣùgbọ́n lónìí, àádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ní ń kú ní ìhà Gúúsù lọ́dọọdún nítorí àwọn àrùn tí ó tan mọ́ sìgá mímu. Bí ó ti wù kí ó rí, àjọ WHO kìlọ̀ pé láàárín ẹ̀wádún mẹ́ta, iye àwọn tí ń kú lọ́dọọdún nítorí sìgá mímu ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà yóò lọ sókè sí mílíọ̀nù méje. Ní òdì kejì sí ohun tí àwọn ìpolówó tábà ń sọ fún ọ, sìgá ń ṣokùnfà ikú.

Ṣé ohun tí o sọ ni pé o mọ nípa ewu rẹ̀? Ìyẹ́n mà dára o, àmọ́, kí ni ìwọ yóò ṣe pẹ̀lú ìmọ̀ yẹn? Ìwọ yóò ha dà bí amusìgá kan tí ó ti ka àìmọye nǹkan nípa sìgá mímu tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi pinnu láti má ṣe ka nǹkan kan mọ́? Àbí ìwọ yóò lo ọgbọ́n inú tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ láti jádìí ẹ̀tàn tí àwọn ìpolówó sìgá ń gbé kalẹ̀, kí o sì sọ pé, rárá sí sìgá mímu? Òtítọ́ ni pé èéfín sìgá ti ń fẹ́ gba ọ̀nà ìhà Gúúsù—àmọ́ kò di dandan kí ó fẹ́ gba ọ̀nà ọ̀dọ̀ rẹ!

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]

China—Òléwájú

Zhang Hanmin, ẹni ọdún 35 kan tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ ní China, rọra tẹ ọwọ́ rẹ̀ kọdọrọ, ó sì ṣáná sí sìgá kan. Ó sọ pé: “Kí ń sọ òtítọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo lè fi bá ènìyàn ṣeré, àmọ́ kì í ṣe bíi ti sìgá.” Ó dà bíi pé ohun kan náà ni a lè sọ nípa àwọn 300 mílíọ̀nù míràn tí wọ́n jẹ́ ẹlẹgbẹ́ Zhang. Láti àwọn ọdún 1980, China ti “ṣe sìgá, ó ti ta sìgá, ó sì ti mu sìgá tí ó pọ̀ ju ti orílẹ̀-èdè èyíkéyìí mìíràn lọ.” Ní ọdún kan láìpẹ́ yìí, “àìmọye bílíọ̀nù sìgá ni wọ́n tà fún àwọn amusìgá tí sìgá mímu ti di ẹran ara wọn,” èyí sì mú kí China jẹ́ “òléwájú orílẹ̀-èdè nínú òwò tábà ní gbogbo ayé.”—Ìwé ìròyìn Panoscope.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]

Ṣé Sìgá Máa Ń Ní “Ẹ̀rí Ìfọwọ́sọ̀yà Àìséwu”?

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àádọ́ta ọ̀kẹ́ mẹ́ta àwọn ènìyàn ní ń kú lọ́dọọdún nítorí àwọn àrùn tí ó tan mọ́ tábà, àwọn ìpolówó sìgá ṣáà ń sọ fún àwọn amusìgá pé, ohun tí wọ́n ń ṣe kò léwu, ni. Fún àpẹẹrẹ, ìpolówó sìgá lọ́ọ́lọ́ọ́ kan nínú ìwé ìròyìn Brazil kan fọn rere ìgorí àtẹ ẹ̀yà sìgá tuntun kan tí ó “dé pẹ̀lú ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà àìséwu ilé iṣẹ́ náà.” Ìpolówó sìgá náà mú un dá wọn lójú pé: “Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ ń ní ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà àìséwu; tẹlifíṣọ̀n rẹ ní ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà àìséwu; aago rẹ ní ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà àìséwu. Sìgá rẹ pẹ̀lú ní.” Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí ìpolówó sìgá náà ti mú kí a lóye, tí àwọn amusìgá páálí sì lè jẹ́rìí sí i, kìkì ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà àìséwu tí ó wà ni pé “sìgá mímu ń ṣe ìpalára fún ìlera.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Lájorí àwọn ènìyàn tí wọ́n dójú sọ—àwọn obìnrin ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà

[Credit Line]

Fọ́tò WHO láti ọwọ́ L. Taylor

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Ṣé wọn kò mọ̀ nípa ewu rẹ̀ ni?

[Credit Line]

WHO

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́