ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 7/8 ojú ìwé 30
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 7/8 ojú ìwé 30

Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Ààbò Ohun Ọ̀sìn Nínú àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọmọdé Ha Wà Láàbò Lọ́dọ̀ Ajá Rẹ Bí?” (July 8, 1997), ẹ dámọ̀ràn gbígbé ibùsùn ajá sí ilé ìgbọ́únjẹ. Àmọ́, nínú àwọn àpilẹ̀kọ tí ó ti jáde tẹ́lẹ̀ rí, ẹ sọ pé kí a máà máa gbé àwọn ohun ọ̀sìn sí ibi tí a ti ń gbọ́únjẹ nítorí ìmọ́tótó.

R. H., Sípéènì

A mọrírì àkíyèsí yìí. Àpilẹ̀kọ wa náà dá lórí ààbò àwọn ọmọdé, kì í ṣe ọ̀rọ̀ nípa ìmọ́tótó ni a ń sọ. Nítorí náà, a óò dámọ̀ràn pé kí àwọn òǹkàwé ṣàyẹ̀wò àpilẹ̀kọ náà, “Mú Kí Jíjẹun Rẹ Wà Láìséwu” (December 22, 1989), tí ó sọ pé: “Awọn ohun-ọ̀sìn ilé ati awọn ẹranko mìíràn ni a gbọ́dọ̀ múfàsẹ́yìn-takété kúrò ní àgbègbè-àyíká ìpèsè ounjẹ.” Ilé ajá tí a kọ́ síta tàbí iyàrá kan níbi tí kì í ṣe ilé ìgbọ́únjẹ lè jẹ́ ibi tí ó dára jù kí ajá máa sùn.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.

Ìgbésí Ayé Nísàlẹ̀ Lọ́hùn-ún Mo fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ yín gan-an fún àpilẹ̀kọ wíwọnilọ́kàn, tí ó sì ń ṣíni lórí náà nípa Australia, tí ẹ pè ní “Ìgbésí Ayé Yàtọ̀ ní Ìsàlẹ̀ Lọ́hùn-ún.” (October 8, 1997) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ka ohun púpọ̀ nípa orílẹ̀-èdè jíjojúnígbèsè, tí ń fani lọ́kàn mọ́ra náà, àpilẹ̀kọ yín ràn mí lọ́wọ́ láti lóye bí ó ṣe yẹ kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó fún àwọn ohun àgbàyanu tí ó dá.

L. K., Germany

Párádísè Láìsí Wàhálà Inú mi dùn sí ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Párádísè Kan Láìsí Wàhálà—Nígbà Wo?” (October 8, 1997) Kí wọ́n tó bí mi ni ìyá bàbá mi ti kú. Àrùn jẹjẹrẹ ló pa á. Àmọ́, kò ní sí àìsàn mọ́ nínú Párádísè. Àpilẹ̀kọ yìí fún mi níṣìírí láti máa bá ìṣòtítọ́ mi lọ kí n bàa lè rí ìyá bàbá mi nínú Párádísè.

M. J., Trinidad

Oorun Ẹranko Mo fẹ́ fi ìmọrírì mi hàn fún àpilẹ̀kọ náà, “Àṣírí Oorun Ẹranko.” (October 8, 1997) Ó pani lẹ́rìn-ín—mo sì kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ohun àgbàyanu kan nípa ìṣẹ̀dá.

J. G., Puerto Rico

Mo ní ẹja kan tí mo ń sìn, ó sì ti pẹ́ tí mo ti ń fẹ́ mọ̀ bóyá àwọn ẹja máa ń sùn. Ìyẹn ló fà á tí inú mi fi dùn nígbà tí mo mọ̀ pé nígbà tí mo bá rí i tí ó dúró sójú kan, ńṣe ló kàn ń sinmi.

A. P. L. M., Brazil

Ẹsẹ̀ Ríro Ó jọ pé àwọn obìnrin nìkan ni ẹ torí wọn kọ àpilẹ̀kọ yín “Ìrànwọ́ fún Ẹsẹ̀ Ríro.” (October 8, 1997) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kò pẹ́ lẹ́yìn tí mo ka àpilẹ̀kọ náà ni ọkọ mi bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé ẹsẹ̀ ń ro òun—bí ó ti máa ń sọ láti ọdún méje sẹ́yìn. Ní fífi ohun tí àpilẹ̀kọ náà sọ sọ́kàn, a gba ṣọ́ọ̀bù bàtà kan lọ. Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé bàtà oníwọ̀n ìtóbi 8 alábọ́ọ́dé ló ń wọ̀ dípò oníwọ̀n ìtóbi 9 fífẹ̀! Ara ti tù ú báyìí, ọpẹ́lọpẹ́ Jí!

S. J., United States

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé látòwúrọ̀ṣúlẹ̀ ni mo fi ń wà ní ìdúró níbi iṣẹ́, mo sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ìṣòro nítorí wíwọ bàtà onígìgìrísẹ̀ gogoro. Mo ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ (ajíhìnrere alákòókò kúkúrú) lóṣù yìí, ọpẹ́lọpẹ́ àpilẹ̀kọ náà, mo ra bàtà oríṣi mẹ́ta tí kò fún mi níṣòro. Ẹ ṣeun tí ẹ ní ìlera wa lọ́kàn, ti ẹ sì ń fi àwọn nǹkan tó wa létí.

C. L., Germany

Ogun àti Àwọn Ọmọdé Ẹ ṣeun gan-an fún ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Ohun Tí Ogun Ń Ṣe fún Àwọn Ọmọdé.” (October 22, 1997) Ó ràn wá lọ́wọ́ láti rí bí a ṣe nílò Ìjọba Jèhófà tó láti fi òpin sí ìyọrísí amúnibanújẹ́ tí ogun ń ní. Ní ti gidi, àwọn àpilẹ̀kọ náà ń lani lóye gbáà, wọ́n sì ń fi ìwà òǹrorò tí púpọ̀ lára wa kò mọ̀ pé ó ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn ilẹ̀ mìíràn hàn wá.

Y. C., England

N kì í fẹ́ máa kà nípa ìfìyàjẹ àwọn ọmọdé. Ní báyìí, omijé ti fẹ́ máa bọ́ lójú mi. Ó máa ń kó mi nírìíra láti rí bí ayé ṣe ń di àwùjọ aláìní-làákàyè tí àwọn ènìyàn ẹlẹ́mìí ìdágunlá kún inú rẹ̀. Mo yìn yín nítorí pé ẹ kò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ ní kíkọ àpilẹ̀kọ tí ń lani lóye yìí.

K. E., United States

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́