Ẹ̀kọ́ Wo Lẹlẹ́wọ̀n Lè Rí Kọ́ Lára Ẹyẹ?
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ GÚÚSÙ ÁFÍRÍKÀ
GẸ́GẸ́ bí ìwé ìròyìn Sunday Tribune ti ìlú Durban, ní Gúúsù Áfíríkà ti sọ, àwọn ẹyẹ ń kópa nínú mímú ọkàn àwọn ẹlẹ́wọ̀n rọ̀ ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Pollsmoor. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ẹlẹ́wọ̀n mẹ́rìnlá kópa nínú ètò kan tó ní í ṣe pẹ̀lú títọ́jú àwọn oríṣi ayékòótọ́ tí wọ́n ń pè ní cockatiel àti lovebird nínú iyàrá wọn, lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.
Báwo ni ètò náà ṣe lọ? Wọ́n ṣe ibi ìsàba ẹyẹ sínú iyàrá ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó ń kópa nínú ètò náà. Wọ́n mú ọmọ ẹyẹ kọ̀ọ̀kan fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà láti máa tọ́jú, ọmọ ẹyẹ kékeré tí ò mọ nǹkankan náà á sì máa jẹun lọ́wọ́ ẹlẹ́wọ̀n náà ní wákàtí kọ̀ọ̀kan tàbí wákàtí méjì-méjì, tọ̀sántòru, fún nǹkan bí ọ̀sẹ̀ márùn-ún. Lẹ́yìn náà ni yóò wá lọ fi ọmọ ẹyẹ náà sínú àgò kan tó wà nínú iyàrá ẹlẹ́wọ̀n náà. Tí ẹyẹ náà bá dàgbà, wọ́n á wá tà á fún àwọn aráàlú. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan fẹ́ràn ẹyẹ wọn débi pé ńṣe ni wọ́n máa ń sunkún tí wọ́n bá fẹ́ mú ẹyẹ náà kúrò lọ́dọ̀ wọn.
Kódà, wọ́n ti ṣàkíyèsí pé àwọn ọ̀daràn paraku pàápàá ti túbọ̀ di oníwà jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ẹni pẹ̀lẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti bá àwọn ẹyẹ sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì fojoojúmọ́ ṣètọ́jú wọn. Ẹlẹ́wọ̀n kan sọ pé: “Mo kọ́ àwọn ẹyẹ yẹn níwà pẹ̀lẹ́, ṣùgbọ́n àwọn náà tún kọ́ mi níwà pẹ̀lẹ́.” Òmíràn sọ pé àwọn ẹyẹ náà kọ́ òun ní sùúrù àti ìkóra-ẹni-níjàánu. Olè kan tó ń ṣẹ̀wọ̀n sọ pé títọ́jú ẹyẹ mú kí òun mọ̀ pé “iṣẹ́ ńlá gbáà ni” láti jẹ́ òbí—iṣẹ́ yìí lòun ò sì ṣe lórí àwọn ọmọ òun kí òun tó dèrò ẹ̀wọ̀n.
Títọ́jú àwọn ẹyẹ yìí lè ṣàǹfààní mìíràn fáwọn ẹlẹ́wọ̀n. Wikus Gresse, tó fi ètò náà lọ́lẹ̀ sọ pé: “Pẹ̀lú ohun tí wọ́n kọ́ náà, tí wọ́n bá jáde lẹ́wọ̀n, wọ́n lè ríṣẹ́ lọ́dọ̀ àwọn tó ń sin ẹyẹ tàbí lọ́dọ̀ àwọn tó ń tọ́jú ẹranko tó ń ṣàìsàn.”