ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g01 3/8 ojú ìwé 11
  • Ìgbádun Tó Wà Nínú Wíwo Ẹyẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbádun Tó Wà Nínú Wíwo Ẹyẹ
  • Jí!—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wíwo Ẹyẹ—Ìgbòkègbodò Àfipawọ́ Tí Gbogbo Ènìyàn Nífẹ̀ẹ́ Sí Ni Bí?
    Jí!—1998
  • Ẹ̀kọ́ Wo Lẹlẹ́wọ̀n Lè Rí Kọ́ Lára Ẹyẹ?
    Jí!—2000
Jí!—2001
g01 3/8 ojú ìwé 11

Ìgbádun Tó Wà Nínú Wíwo Ẹyẹ

AYÉ ì bá má dùn tó báyìí ká ní kò sáwọn ẹyẹ! Bí wọ́n ṣe máa ń súfèé, bí wọ́n ṣe máa ń kọrin, bí wọ́n ṣe láwọ̀ oríṣiríṣi àti bí wọ́n ṣe máa ń fò—gbogbo èyí fi kún oríṣiríṣi àwọn ohun tó mú kí ìgbésí ayé lẹ́wà. Ṣùgbọ́n, ẹ̀ẹ̀melòó la tiẹ̀ máa ń dúró láti fetí sí wọn ká sì wò wọ́n? Bó bá jẹ́ ìgboro lò ń gbé, tí kòó-kòó jàn-án jàn-án ìgbésí ayé ojoojúmọ́ àti ariwo ojú pópó yí ọ ká, o tiẹ̀ lè máà ṣàkíyèsí àwọn ẹyẹ tí wọ́n wà ládùúgbò rẹ. Ká tiẹ̀ ní ìgbèríko lo ń gbé pàápàá, ó rọrùn láti fojú pa wọ́n rẹ́. Àmọ́ ṣé wàá fẹ́ láti túbọ̀ wo àwọn ẹyẹ tí wọ́n wà lágbègbè rẹ dáadáa sí i?

O lè rí wọn wò dáadáa bóo bá gbé ohun tí wọ́n fi ń fẹ́yẹ lóúnjẹ sẹ́yìnkùlé rẹ, kó má jìnnà sójú fèrèsé o. Lẹ́yìn náà, gbogbo ohun tóo nílò kò ju awò awọ̀nàjíjìn àti kámẹ́rà tó lè fa nǹkan sún mọ́ tòsí, kóo sì wá fara balẹ̀ díẹ̀! Rí i pé o ní ọ̀pọ̀ fíìmù tí agbára ìyàwòrán wọn pọ̀ lárọ̀ọ́wọ́tó àti ìwé tó ṣàpèjúwe oríṣiríṣi ẹyẹ kóo ba lè dá wọn mọ̀. Lẹ́yìn náà, máa wò wọ́n, fetí sí wọn, kóo sì gbádùn wọn!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́