Àpótí Ìbéèrè
◼ Àwọn ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ wo ló yẹ ká máa fi sọ́kàn nígbà tá a bá ń jẹ́rìí fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n?
Kárí ayé, iye àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n tó mílíọ̀nù mẹ́jọ, ó kéré tán, àwọn kan lára wọn sì ń fìfẹ́ hàn sí ìhìn rere náà. (1 Tím. 2:4) Ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa kan máa ń gba nǹkan bí egbèje [1,400] lẹ́tà lóṣooṣù látọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n àtàwọn mọ̀lẹ́bí wọn, tí wọ́n ń béèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí tí wọ́n ń béèrè pé kí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojúlówó ìfẹ́ làwọn ẹlẹ́wọ̀n kan ń fi hàn, ìrírí ti fi hàn pé ńṣe làwọn kan ń díbọ́n, wọ́n ń gbìyànjú láti lo àwọn èèyàn Ọlọ́run fún àǹfààní ara wọn. Nípa báyìí, gbogbo wa ní láti máa fi àwọn ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí sọ́kàn nígbà tá a bá ń jẹ́rìí fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n.
Lọ́pọ̀ ìgbà, lẹ́tà la fi ń jẹ́rìí fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n. A ò dá a lámọ̀ràn rárá pé kí àwọn arábìnrin máa kọ lẹ́tà sí àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọkùnrin, kódà bí ète lẹ́tà náà bá jẹ́ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí fún wọn. Àwọn arákùnrin tó tóótun nìkan ló gbọ́dọ̀ bójú tó ẹrù iṣẹ́ yẹn. A lè yan àwọn arábìnrin tó tóótun láti máa kọ lẹ́tà sí àwọn ẹlẹ́wọ̀n obìnrin tí wọ́n ní ìfẹ́ àtọkànwá sí òtítọ́ Bíbélì. A kò gbọ́dọ̀ fi owó tàbí ẹ̀bùn èyíkéyìí ránṣẹ́ sí àwọn ẹlẹ́wọ̀n, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè máa béèrè fún irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀.
Bí ẹlẹ́wọ̀n kan bá fi ìfẹ́ hàn, kí a mú àkọsílẹ̀ nípa orúkọ àti àdírẹ́sì rẹ̀ fún ìjọ tó wà lágbègbè tí ọgbà ẹ̀wọ̀n náà wà. Àwọn arákùnrin tó tóótun níbẹ̀ sábà máa ń mọ bí wọ́n ṣe lè bójú tó onírúurú ipò tó lè jẹ yọ. Bí a kò bá mọ ìjọ tó wà níbẹ̀, kí a fi ìsọfúnni náà ránṣẹ́ sí ẹ̀ka iléeṣẹ́.
Kò sóhun tó burú nínú kí àwọn arákùnrin tí a yàn náà ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́wọ̀n, kó bàa lè ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ lára wọn láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ nígbà kan náà. Àmọ́ ṣá o, a kò gbọ́dọ̀ ṣètò ayẹyẹ àkànṣe kankan nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n níbi tí àwọn akéde á ti máa ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́wọ̀n. Síwájú sí i, kò bọ́gbọ́n mu kí àwọn akéde kàn máa ṣèbẹ̀wò sí ọgbà ẹ̀wọ̀n nígbàkigbà, kí wọ́n máa ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́wọ̀n.
Ẹ jẹ́ ká jẹ́ “oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò, síbẹ̀ kí [a] jẹ́ ọlọ́rùn-mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà” bí a ti ń wàásù ìhìn rere fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n.—Mát. 10:16.