“Ẹ Ti Yí Èrò Mi Nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Padà”
OHUN tí wọ́dà kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Poland sọ nípa àpilẹ̀kọ tó sọ nípa iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn, gẹ́gẹ́ báa ti ròyìn rẹ̀ nínú ìtẹ̀jáde wa ti October 15, 1998. Àpilẹ̀kọ náà, “Nígbà Tí Àwọn Ọkàn Yíyigbì Bá Yí Padà,” sọ nípa àṣeyọrí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe nínú wíwàásù fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà ní Wołów, nílẹ̀ Poland.
Kó tó di pé a tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yẹn jáde, a ti kọ́kọ́ ṣètò ìpàdé àkànṣe kan pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní September 13, 1998, nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n Wołów. Lára àwọn táa pè wá síbẹ̀ ni àwọn Ẹlẹ́rìí àgbègbè náà, àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó ti ṣèrìbọmi àti àwọn tó jẹ́ olùfìfẹ́hàn, àti àwọn wọ́dà díẹ̀. Ohun tí àwọn kan lára àwọn tó wà ní ìpàdé náà ṣàkíyèsí nìyí.
Jerzy, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ṣèrìbọmi lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ní ohun tó lé ní ọdún márùn-ún sẹ́yìn, wí pé: “Inú mi dùn púpọ̀ pé, lónìí, èmi náà lè ka ohun tí a kọ nípa ìsapá tí àwọn arákùnrin tó wà láwọn ìjọ itòsí ti ṣe láti ràn wá lọ́wọ́.” Ó fi kún un pé: “Mò ń làkàkà láti tún ìwà mi ṣe, mo sì rí bí Jèhófà ṣe ń mọ mí.”
Ẹlẹ́wọ̀n mìíràn, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Zdzisław, sọ nípa iṣẹ́ ìjẹ́rìí nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà pé: “Ní báyìí, ẹlẹ́wọ̀n mẹ́rin ló ń múra àtiṣe ìrìbọmi, àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fìfẹ́ hàn sì ń wá sípàdé déédéé nínú gbọ̀ngàn wa. Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ irin iṣẹ́ lílágbára láti mú kí iṣẹ́ yìí tẹ̀ síwájú ní ibi yìí.” Ẹ ò rí i pé ẹ̀mí tó dára lèyí jẹ́, táa bá ro ti pé Zdzisław ṣì ní ọdún mọ́kàndínlógún láti lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n!
Lẹ́yìn tí wọ́dà kan ka àpilẹ̀kọ náà tí a gbé karí ọgbà ẹ̀wọ̀n Wołów, ó wí pé: “Wọ́n bọlá fún wa gan-an ni. N kò ronú rẹ̀ rí pé a lè gbé ọgbà ẹ̀wọ̀n yìí sáyé lọ́nà rere bẹ́ẹ̀, tí a ó fi kà nípa rẹ̀ ní èdè àádóje lágbàáyé. Mo fẹ́ràn yin gan-an ni o, mo sì mọrírì ìsapá yín lórí àwọn ẹlẹ́wọ̀n.” Wọ́dà mìíràn wí pé: “Ẹ ti yí èrò mi nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà padà. Tẹ́lẹ̀ rí, agbawèrèmẹ́sìn ni mò ń pè yín. Àmọ́ nísinsìnyí, mo ti wá rí i pé èèyàn tó ní ìlànà ni yín.”
Marek Gajos, tó jẹ́ ọ̀gá àgbà ọgbà ẹ̀wọ̀n Wołów, bú sẹ́rìn-ín, ó sì wí pé: “Nígbà tẹ́ẹ bẹ̀rẹ̀, a rò pé ẹ ò lè fi bẹ́ẹ̀ ṣàṣeyọrí. A rò pé ẹ̀sìn mìíràn tó kàn fẹ́ fi Bíbélì sọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n di ẹni tó níṣẹ́ lọ́wọ́ ni yín. Ṣùgbọ́n, nígbà táa rí ìyọrísí ìgbòkègbodò yín àkọ́kọ́, a pinnu láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú yín dáadáa. Ọdún kẹsàn-án tẹ́ẹ ti ń pààrà ibi nìyí láìsinmi, mo sì mọrírì ohun tẹ́ẹ ti ṣe gidigidi.”
Àmọ́, ojú wo ni àwọn ẹlẹ́wọ̀n Wołów lápapọ̀ fi wo àpilẹ̀kọ náà? Àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà fẹ́ràn rẹ̀ gan-an débi pé gbogbo ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà ló tán pátápátá. Àwọn wọ́dà tún fi ìfẹ́ hàn nípa bíbéèrè fún ogójì ẹ̀dà sí i fún ara wọn. Láti lè tẹ́ àwọn tí ń béèrè fún ẹ̀dà púpọ̀ sí i lọ́rùn, àwọn ìjọ àdúgbò ṣèrànwọ́, wọ́n sì pèsè ọgọ́rùn-ún ẹ̀dà fún àwọn ará tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Lọ́wọ́ kan náà, àwọn tó ń wá sípàdé lọ́gbà ẹ̀wọ̀n pọ̀ sí i.
Piotr Choduń, wọ́dà kan tó fọwọ́ sowọ́ pọ̀ dáadáa pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wí pé: “A pinnu láti lẹ àpilẹ̀kọ yìí mọ gbogbo ojú pátákó ìsọfúnni tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n wa. A lérò pé gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọn kò tí ì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ yín yóò ka ìwé ìròyìn yìí.”
Àpẹẹrẹ tó dára tí àwọn Ẹlẹ́rìí fi lélẹ̀ àti ìpinnu wọn láti wàásù ṣì ń so èso rere. Yàtọ̀ sí àwọn ẹlẹ́wọ̀n mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tó ti tẹ̀ síwájú dórí ṣíṣe ìrìbọmi, àwọn wọ́dà méjì ti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́dà kan sì ti ní ká máa wá bá òun ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ ṣá o, Jèhófà Ọlọ́run ni àwọn ará tó ń wàásù ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Wołów fi ìyìn fún, fún gbogbo àṣeyọrí tí wọ́n ṣe.—Fi wé 1 Kọ́ríńtì 3:6, 7.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Àwọn mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí àti ẹlẹ́wọ̀n kan níbi tí wọ́n ti fi ìwé ìròyìn náà hàn nínú gbọ̀ngàn ọgbà ẹ̀wọ̀n