Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì Lè Mú Ayé Rẹ Dùn
ÌRÁRAGBAǸKAN dà bíi ṣúgà nínú ife kọfí kan. Ìwọ̀n yíyẹ rẹ̀ lè mú kí ìgbésí ayé dùn dé àyè kan. Ṣùgbọ́n nígbà tí a lè fi ìwà ọ̀làwọ́ bu ṣúgà, a sábà máa ń háwọ́ bí ó bá kan ìráragbaǹkan. Èé ṣe?
Arthur M. Melzer, amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní Yunifásítì Ìpínlẹ̀ Michigan, kọ̀wé pé: “Ẹ̀dá ènìyàn kì í fẹ́ẹ́ mú nǹkan mọ́ra. Ìtẹ̀sí àdánidá wọn ni láti ní . . . ẹ̀tanú.” Nítorí náà, àìrára-gbaǹkan kì í ṣe àbùkù ìwà tí ó kan àwọn ẹni kéréje; híhùwà àìgbatẹnirò máa ń wá fún gbogbo wa lọ́nà àdánidá, nítorí pé gbogbo ìran ènìyàn jẹ́ aláìpé.—Fi wé Róòmù 5:12.
Àwọn Tí Ó Lè Di Alátojúbọ̀
Ní 1991, ìwé ìròyìn Time ròyìn nípa àìgbatẹnirò tí ń pọ̀ sí i ní United States. Àpilẹ̀kọ náà ṣàpèjúwe “àwọn tí ṣíṣe àtojúbọ̀ jẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé wọn,” àwọn ènìyàn tí ń sapá láti fi dandan ti ọ̀nà ìgbésí ayé tiwọn mọ́ gbogbo ènìyàn lọ́rùn. Wọ́n ti fìyà jẹ àwọn tí kò fara mọ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n gba iṣẹ́ lọ́wọ́ obìnrin kan ní Boston nítorí pé ó kọ̀ láti lo àwọn èròjà ìṣaralóge. Wọ́n lé ọkùnrin kan kúrò lẹ́nu iṣẹ́ ní Los Angeles nítorí pé ó ti sanra jù. Èrèdí ìtara láti mú kí àwọn ẹlòmíràn fara mọ́ tẹni náà?
Àwọn aláìgba-tẹni-rò jẹ́ aláìfòye-bánilò, onímọtara-ẹni-nìkan, olóríkunkun, àti apàṣẹwàá. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn kì í ha í ṣe oníwà àìbọ́gbọ́nmu, onímọtara-ẹni-nìkan, olóríkunkun, tàbí apàṣẹwàá dé ìwọ̀n kan bí? Bí àwọn àbùdá wọ̀nyí bá fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú ìgbésí ayé wa, a óò jẹ́ aláìgba-tẹni-rò.
Ìwọ ńkọ́? Ǹjẹ́ o máa ń gbọnrí sí irú oúnjẹ tí ẹlòmíràn nífẹ̀ẹ́ sí bí? Nínú ìjíròrò, ǹjẹ́ o máa ń fẹ́ láti sọ̀rọ̀ kí abẹ sì gé e bí? Bí o bá ń bá àwùjọ kan ṣiṣẹ́, ǹjẹ́ o máa ń retí pé kí wọ́n ronú lọ́nà kan náà bíi tìrẹ bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, yóò dára láti fi ṣúgà díẹ̀ sí kọfí rẹ!
Ṣùgbọ́n, bí a ṣe mẹ́nu bà á nínú àpilẹ̀kọ ìṣáájú, àìrára-gbaǹkan lè jẹ yọ lọ́nà ẹ̀tanú rírorò. Kókó kan tí ó lè mú kí àìrára-gbaǹkan di rẹpẹtẹ ni ìṣàníyàn ní ìwọ̀n gíga.
“Ìmọ̀lára Àìdánilójú Jíjinlẹ̀”
Àwọn onímọ̀ àfiwéra àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ti wádìí ìtàn ìran ènìyàn láti mọ ìgbà tí ẹ̀tanú ẹ̀yà ìran bẹ̀rẹ̀ àti ibi tí ó ti bẹ̀rẹ̀. Wọ́n rí i pé irú àìrára-gbaǹkan yìí kì í fara hàn nígbà gbogbo, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í fara hàn ní gbogbo ilẹ̀ ní ìwọ̀n kan náà. Ìwé ìròyìn sáyẹ́ǹsì àdánidá ní ilẹ̀ Germany náà, GEO, ròyìn pé ìforígbárí ẹ̀yà ìran máa ń yọjú nígbà yánpọnyánrin, nígbà tí “àwọn ènìyàn ń ní ìmọ̀lára àìdánilójú jíjinlẹ̀, tí wọ́n sì nímọ̀lára pé a ń wu ìdánimọ̀ àwọn léwu.”
Irú “ìmọ̀lára àìdánilójú jíjinlẹ̀” bẹ́ẹ̀ ha gbòde kan lónìí bí? Dájúdájú. Ìran ènìyàn ń kojú àwọn yánpọnyánrin léraléra ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Àìríṣẹ́ṣe, iye owó ìgbọ́bùkátà tí ń pọ̀ sí i, àpọ̀jù iye ènìyàn, ìparun ìpele ozone, ìwà ipá ní àwọn ìlú ńlá, ìsọdìbàjẹ́ omi mímu, mímóoru ilẹ̀ ayé—bíbẹ̀rù èyíkéyìí lára àwọn nǹkan wọ̀nyí láìdábọ̀ ń fi kún àníyàn. Yánpọnyánrin ń fa àníyàn, àníyàn tí kò yẹ sì ń yọrí sí àìrára-gbaǹkan.
Bí àpẹẹrẹ, irú àìrára-gbaǹkan bẹ́ẹ̀ ń fara hàn níbi tí àwọn ẹ̀yà ìran àti ẹ̀yà ìbílẹ̀ bá ti wọnú ara wọn, bí ó ṣe rí ní àwọn ilẹ̀ Europe kan. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan nínú ìwé ìròyìn National Geographic ṣe sọ ní 1993, àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn Europe gba àwọn aṣíwọ̀lú tí ó lé ní mílíọ̀nù 22 lálejò nígbà náà. Ọ̀pọ̀ àwọn ará Europe “ni ìrọ́wọlé àwọn àjèjì” tí èdè, àṣà ìbílẹ̀, tàbí ìsìn wọn yàtọ̀ “mú kí ọkàn wọn pòrúurùu.” Ìmọ̀lára lòdì sí àwọn àjèjì ti pọ̀ sí i ní Austria, Belgium, Britain, Faransé, Germany, Ítálì, Sípéènì, àti Sweden.
Àwọn aṣáájú nínú ayé ńkọ́? Láàárín àwọn ọdún 1930 àti 1940, Hitler sọ àìrára-gbaǹkan di ìpinnu ìjọba. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn aṣáájú ìṣèlú àti ti ìsìn mélòó kan lónìí ń lo àìrára-gbaǹkan láti mú ète ara wọn ṣẹ. Ọ̀ràn ti rí báyìí ní àwọn ilẹ̀ bí Austria, Faransé, Ireland, Rọ́ṣíà, Rwanda, àti United States.
Yẹra fún Ìdẹkùn Ẹ̀mí Ìdágunlá
A ń nímọ̀lára pé nǹkan kan kò tó bí ṣúgà inú kọfí wa bá kéré jù; a sì ń mọ adùn tí kò gbádùn mọ́ wa lẹ́nu bí ṣúgà náà bá pọ̀ jù. Bákan náà ló rí ní ti ìráragbaǹkan. Ṣàgbéyẹ̀wò ìrírí ọkùnrin kan tí ń kọ́ni ní kọ́lẹ́ẹ̀jì kan ní United States.
Ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, David R. Carlin, Kékeré, ṣàwárí ọ̀nà rírọrùn kan, síbẹ̀ tí ó gbéṣẹ́, láti mú kí ìjíròrò máa dùn mọ́ni ní kíláàsì. Yóò sọ gbólóhùn kan tí ó pète láti pe ojú ìwòye àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ níjà, ní mímọ̀ pé wọn yóò gbiná jẹ. Àbájáde rẹ̀ ni pé, ìjíròrò yóò múni lára yá. Bí ó ti wù kí ó rí, ní 1989, Carlin kọ̀wé pé ọ̀nà ìgbàṣe kan náà kò gbéṣẹ́ dáradára mọ́. Èé ṣe? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kò fara mọ ohun tí ó sọ, síbẹ̀, wọn kò wulẹ̀ yọnu mọ́ láti bá a jiyàn. Carlin ṣàlàyé pé, wọ́n ti gba ẹ̀mí ìrònú “fàyè gba elérò àìdánilójú”—ẹ̀mí ìdágunlá, kòkànmí.
Ẹ̀mí ìrònú kòkànmí ha dọ́gba pẹ̀lú àìrára-gbaǹkan bí? Bí kò bá sí ẹni tí ó bìkítà nípa ohun tí ẹnikẹ́ni ń rò tàbí tí ó ń ṣe, kò sí ìlànà kankan. Àìsí ìlànà kankan ni ẹ̀mí ìdágunlá—àìní ìfẹ́ ọkàn rárá. Báwo ni irú ipò nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe ń ṣẹlẹ̀?
Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Melzer ṣe sọ, àgunlá lè gbilẹ̀ nínú àwùjọ tí ó bá ń tẹ́wọ́ gba ọ̀pọ̀ ìlànà ìwà híhù ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn ènìyàn wá ń gbà gbọ́ pé gbogbo ọ̀nà ìhùwà ló ṣètẹ́wọ́gbà, àti pé, gbogbo rẹ̀ wulẹ̀ jẹ́ ọ̀ràn yíyàn ara ẹni ni. Kàkà kí wọ́n kọ́ láti ronú, kí wọ́n sì ṣàyẹ̀wò nípa ohun tí ó ṣètẹ́wọ́gbà tàbí tí kò ṣètẹ́wọ́gbà, àwọn ènìyàn “sábà máa ń kọ́ láti má ṣe ronú rárá.” Wọ́n ṣàìní okun ìwà rere tí ń sún ẹnì kan láti fìgboyà kojú àìrára-gbaǹkan àwọn ẹlòmíràn.
Ìwọ ńkọ́? O ha máa ń rí ara rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí o ń lo ẹ̀mí ìrònú kòkànmí bí? O ha máa ń fi àwọn àwàdà ọlọ́rọ̀ rírùn tàbí ti ẹlẹ́yà ìran rẹ́rìn-ín bí? O ha máa ń gba ọ̀dọ́langba ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ láyè láti máa wo àwọn fídíò tí ń ṣagbátẹrù ìwọra tàbí ìwà pálapàla bí? O ha rò pé ó tọ́ fún àwọn ọmọ rẹ láti máa ṣe àwọn eré àṣedárayá oníwà ipá lórí ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà bí?
Bí ìráragbaǹkan bá pọ̀ lápọ̀jù, ìdílé tàbí àwùjọ kan yóò kórè làásìgbò, níwọ̀n bí ẹnikẹ́ni kò ti mọ̀—tàbí bìkítà—nípa ohun tí ó tọ́ tàbí ohun tí kò tọ́. Aṣòfin Àgbà Dan Coats ti United States kìlọ̀ nípa “ìdẹkùn fífi ìdágunlá pe ìráragbaǹkan.” Ìráragbaǹkan lè yọrí sí jíjẹ́ ọlọ́kàn ṣíṣípayá; àpọ̀jù ìráragbaǹkan—àgunlá—lè yọrí sí jíjẹ́ aláìlọ́gbọ́n-lórí.
Nítorí náà, kí ni a gbọ́dọ̀ mú mọ́ra, kí ni a sì gbọ́dọ̀ kọ̀ jálẹ̀? Kí ni àṣírí jíjèrè ìwọ̀ntúnwọ̀nsì? Èyí ni yóò jẹ́ kókó àpilẹ̀kọ tí ó kàn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Dù láti hùwà pa dà sí àwọn ipò níwọ̀ntúnwọ̀nsì