Dídúró Gbọn-in Nígbà Tí Ìjọba Násì Gba Netherlands
ILÉ Ìrántí Ìgbà Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Tí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà Kọ́ (USHMM) pàtẹ àwọn ohun èlò àti fíìmù tó pọ̀ jù lọ láyé, tí ń ṣàfihàn ìwà ìkà tí ìjọba Násì hù nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Látìgbà tí wọ́n ti ṣí ilé ohun ìṣẹ̀ǹbáyé náà lọ́dún 1993, àwọn èèyàn bíi mílíọ̀nù méjìlá ló ti lọ fójú wọn lóúnjẹ níbi ìpàtẹ yìí tó túbọ̀ ń gbajúmọ̀ sí i, nílùú Washington, D.C.
Ilé ohun ìṣẹ̀ǹbáyé náà tún pàtẹ àwọn ìsọfúnni kan tó dá lé inúnibíni gbígbóná janjan tí ìjọba Násì ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní àfikún sáwọn ohun díẹ̀ tó máa wà lórí àtẹ títí lọ, USHMM ti ṣe ọ̀wọ́ àwọn ètò pàtàkì kan tó dá lé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ètò wọ̀nyí gbé àwọn àpẹẹrẹ kan pàtó jáde, tó fi hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo ìfaradà àti pé wọ́n pa ìwà títọ́ mọ́. Ní April 8, 1999, ilé ohun ìṣẹ̀ǹbáyé náà ṣe onígbọ̀wọ́ àkànṣe ètò kan tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní “Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Netherlands Nígbà Tí Ìjọba Násì Gba Ibẹ̀.” Inú gbọ̀ngàn méjì tó tóbi jù nínú ilé ohun ìṣẹ̀ǹbáyé náà ni wọ́n ti ṣe ètò náà.
Obìnrin kan tó ń jẹ́ Sara Jane Bloomfield, gíwá USHMM, ló kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ níbi ètò náà. Obìnrin náà sọ pé ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wọ òun lọ́kàn gan-an. Nígbà tí Jí! fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, ó ṣàlàyé pé iṣẹ́ ribiribi ń lọ lọ́wọ́ láti túbọ̀ jẹ́ káwọn aráàlú mọ̀ nípa bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe pa ìwà títọ́ mọ́ nígbà inúnibíni. Ó sọ pé: “Irú ìṣẹ̀lẹ̀ báwọ̀nyí kò kẹ̀rẹ̀ rárá sí gbogbo ètò pàtàkì míì táa ń polongo pé ó ń wáyé nínú ilé ohun ìṣẹ̀ǹbáyé yìí.”
Àwọn òpìtàn péjú-pésẹ̀, wọ́n sì nípìn-ín nínú ètò náà lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Ọ̀kan lára wọn ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Lawrence Baron, ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìtàn ilẹ̀ Jámánì àti ti Júù òde òní, ẹni tó wá láti Yunifásítì Ìpínlẹ̀ San Diego. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Baron sọ pé “ìwúrí gbáà ló jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ jálẹ̀ pé àwọn kò ní bá Ìjọba Násì dòwò pọ̀.” Ó ṣàlàyé pé àwọn Ẹlẹ́rìí “gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba Násì ń dún mọ̀huru-mọ̀huru mọ́ wọn. Lójú tiwọn, fífi ipò aṣíwájú Hitler ṣe ohun àgbọ́kànlé jẹ́ irú ìjọsìn kan tí kò ka Ọlọ́run kún, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi kọ̀ pé àwọn ò ní bá ẹnikẹ́ni lọ́wọ́ sí sísọ Hitler dòrìṣà àkúnlẹ̀bọ, ìdí sì nìyẹn tí wọ́n fi kọ̀ láti máa kí ìjọba Násì pé ‘Ti Hitler ni ìgbàlà.’ . . . Wọ́n sì kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun nítorí pé Ọlọ́run ti pa á láṣẹ pé kí wọ́n fẹ́ràn àwọn aládùúgbò wọn, kí wọ́n má sì pa ẹnikẹ́ni . . . Nígbà tí Ìjọba Násì sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣèpàdé mọ́, ohun táwọn Ẹlẹ́rìí fi fèsì ni, ‘Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.’” Nítorí èyí, wọ́n kó ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí láti àwọn orílẹ̀-èdè Yúróòpù mélòó kan lọ sáwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, wọ́n dá wọn lóró, kódà wọ́n pa nínú wọn.
USHMM ní kí àwọn olùwádìí ará Netherlands àti àwùjọ àwọn kan tó la Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà já, mú àwọn àpẹẹrẹ wá nípa bí ìjọba Násì ṣe ṣenúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Netherlands. Ní May 29, 1940, gẹ́rẹ́ lẹ́yìn tí ìjọba Násì gba Netherlands, ni wọ́n fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí iye wọ́n tó nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lórílẹ̀-èdè yẹn. Ní àwọn oṣù tó tẹ̀ lé e, wọ́n fọlọ́pàá mú ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí. Àwọn aláṣẹ dá àwọn tí wọ́n mú lóró nítorí pé wọ́n fẹ́ kí wọ́n sọ orúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn fáwọn. Nígbà tí ogun náà fi máa parí, ó lé ní àádọ́ta lé nírínwó àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n fọlọ́pàá mú. Ó lé ní ọgọ́fà lára wọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn nítorí inúnibíni náà.
Olùwádìí ará Netherlands kan ṣàlàyé pé ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Society lórílẹ̀-èdè náà ní “ju àádọ́sàn-án ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí wọ́n ká sórí fídíò àti igba àkọsílẹ̀ ìtàn ìgbésí ayé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ará Netherlands tó la Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà já. Gbogbo èyí fi hàn pé ohun tó mú káwọn Ẹlẹ́rìí fara dà á ni ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run àti fún ọmọnìkejì wọn.”
Ọ̀pọ̀ olùbánisọ̀rọ̀ ló tẹnu mọ́ òtítọ́ náà pé, láìdàbí àwọn àwùjọ míì tí ìjọba Násì dójú sọ, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ì bá ti gba òmìnira nípa wíwulẹ̀ fọwọ́ sí ìwé kan tó polongo pé wọ́n ti sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn. Síbẹ̀, àwọn olùbánisọ̀rọ̀ àtàwọn táa fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ṣàlàyé pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe ìpinnu tó fi hàn pé wọ́n ti rò ó láròjinlẹ̀ àti pé àwọn mọ nǹkan táwọn ń ṣe nígbà tí wọ́n yàn láti fojú winá inúnibíni kàkà kí wọ́n juwọ́ sílẹ̀. Ìwọ̀nba díẹ̀ ló fọwọ́ sí i nítorí pé wọn kò fẹ́ bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àjọṣepọ̀ mọ́.
Àwọn kan fọwọ́ sí ìwé náà nítorí ìdàrú ọkàn. Kì í ṣe pé àwọn wọ̀nyí fẹ́ pa ẹ̀sìn wọn tì. Àwọn díẹ̀ nínú wọ́n nímọ̀lára pé àwọn ò rí nǹkan tó burú nínú ṣíṣi àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí wọn lọ́nà kí àwọn lè gba òmìnira láti lè padà sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wọn. Nígbà tó yá lẹ́yìn tí wọ́n tú wọn sílẹ̀, wọ́n wá rí i pé ohun yòówù kí ète wọn jẹ́, fífọwọ́ sí ìwé náà lòdì.
Àṣìṣe yẹn ò wá ní ká tìtorí èyí yọ wọ́n lẹ́gbẹ́. Bí wọ́n ṣe padà sí ilé àti ìjọ wọn, wọ́n rí ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí gbà. Lẹ́tà kan láti ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Society ní Netherlands, táa kọ ní June 1942, rọ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní ilẹ̀ yẹn pé kí wọ́n ro ti ipò tí àwọn tó fọwọ́ sí ìwé náà wà tí wọ́n fi fọwọ́ sí i, kí wọ́n sì káàánú wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba Násì ṣì wà nílùú, kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn táwọn tẹ̀wọ̀ndé wọ̀nyí tún ń bá iṣẹ́ ìwàásù lọ ní pẹrẹu, láìfọ̀tá pè. Wọ́n tún mú àwọn kan lẹ́ẹ̀kejì. Wọ́n tiẹ̀ pa ọ̀kan lára wọn nítorí pé ó kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun.
Láìka gbogbo ìjìyà àti àwọn ọdún eléwu, tó tún le koko, tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ lábẹ́lẹ̀ sí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Netherlands pọ̀ sí i látorí nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ní 1940 dórí iye tó ju ẹgbàá lọ ní 1945, tí ìjọba Násì dópin. Ìgboyà àti ìpinnu wọn láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run jẹ́ ẹ̀rí ńláǹlà títí di òní olónìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn olùwádìí ń bá àwùjọ tó kóra jọ sọ̀rọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Fífọ̀rọ̀ wá àwọn ará Netherlands tó la Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà já lẹ́nu wò