ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g03 1/8 ojú ìwé 31
  • ‘Àwa Ń Ṣègbọràn sí Ọlọ́run Dípò Àwọn Ènìyàn’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Àwa Ń Ṣègbọràn sí Ọlọ́run Dípò Àwọn Ènìyàn’
  • Jí!—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Tó Bá Jẹ́ Ẹni Pípé Ni Ádámù, Báwo Ló Ṣe Wá Dẹ́ṣẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ọlọ́run Dá Ọkùnrin àti Obìnrin Àkọ́kọ́
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Gẹ́gẹ́ Bí Ọ̀tá Ìkẹyìn, Ikú Di Ohun Asán
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ikú àti Àjíǹde Jésù—Àǹfààní Tó Ṣe fún Ẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Jí!—2003
g03 1/8 ojú ìwé 31

‘Àwa Ń Ṣègbọràn sí Ọlọ́run Dípò Àwọn Ènìyàn’

Nígbà tí Adam wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹni mẹ́ta tó yege nínú ìdíje kan tí Ibùdó Tí Wọ́n Ń Kó Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Sí Nílẹ̀ Amẹ́ríkà ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀. Àwọn tó fi àkọsílẹ̀ wọn ránṣẹ́ fún ìdíje náà—tí gbogbo wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún márùn-ún—lo iṣẹ́ ọnà tàbí ìwé kíkọ láti fi bí àwọn èèyàn ṣe lo ìgboyà lábẹ́ ìnilára ìjọba Násì hàn. Adam jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì pinnu láti ṣe iṣẹ́ ọnà kan nípa lílẹ onírúurú bébà aláwòrán àti fọ́tò sórí aṣọ, èyí tó ń fi ìpọ́njú táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan dojú kọ lábẹ́ ìṣàkóso Násì hàn. Adam sọ pé, kì í ṣe àìnírètí tàbí ìbànújẹ́ ni iṣẹ́ ọnà náà ń fi hàn, àmọ́ ó ń fi ìdùnnú tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní hàn pé wọ́n borí gbogbo àtakò àti ìnilára ìjọba Násì. Ó fi àwòrán ọmọdé kan sínú iṣẹ́ ọnà náà. Kí nìdí tó fi ṣe èyí? Adam sọ pé: “Láti fi hàn pé kódà àwọn ọmọdé pàápàá dúró gbọn-in lójú inúnibíni ìjọba Násì.”

Káàkiri ayé làwọn èèyàn ti mọ̀ pé nígbà ìṣàkóso Násì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ láti bọlá fún Hitler tàbí láti ṣètìlẹyìn fún ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀. Adam ṣàpèjúwe ìpinnu àìdásí-tọ̀tún-tòsì wọn nínú iṣẹ́ ọnà rẹ̀, lápá ọ̀tún lókè pátápátá. Níbẹ̀, ó fa ọ̀rọ̀ inú lẹ́tà kan yọ, èyí tí gbogbo ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ránṣẹ́ sí ìjọba orílẹ̀-èdè Jámánì ní October 7, 1934. Lẹ́tà náà kà lápá kan pé: “Ìforígbárí tó hàn gbangba wà láàárín òfin yín àti òfin Ọlọ́run, àti pé, láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn àpọ́sítélì olùṣòtítọ́, ‘ó yẹ ká ṣègbọràn sí Ọlọ́run dípò àwọn ènìyàn,’ ohun tá a sì máa ṣe nìyẹn. (Ìṣe 5:29) . . . Níwọ̀n bí ìjọba yín àtàwọn aláṣẹ sì ti ń gbìyànjú láti fipá mú wa ká lè ṣàìgbọràn sí òfin gíga jù lọ lágbàáyé, ó di dandan fún wa láti jẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ nísinsìnyí pé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, àwa yóò ṣègbọràn sí Jèhófà Ọlọ́run, a ó sì gbẹ́kẹ̀ lé E ní kíkún láti gbà wá lọ́wọ́ gbogbo ìnilára àtàwọn aninilára.”

Inú Adam dùn gan-an fún ogún tẹ̀mí tó ní yìí. Ó sọ pé: “Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pẹ̀lú ìdánilójú pé ó lòdì láti ṣèpalára fún ọmọnìkejì wa, àti pé Ọlọ́run nìkan ṣoṣo la gbọ́dọ̀ jọ́sìn, kódà bí èyí bá máa yọrí sí ikú pàápàá.” Ipò fífẹsẹ̀múlẹ̀ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dì mú yìí fara hàn nínú àkọlé tí Adam fún iṣẹ́ ọnà rẹ̀, ìyẹn ni: “Àwa Yóò Ṣègbọràn sí Ọlọ́run Dípò Àwọn Ènìyàn!”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́