Ẹ̀KỌ́ 2
Ọlọ́run Dá Ọkùnrin àti Obìnrin Àkọ́kọ́
Jèhófà gbin ọgbà kan tó pè ní ọgbà Édẹ́nì. Àwọn igi lóríṣiríṣi, ewéko, òdòdó àtàwọn ẹranko ló wà nínú ọgbà náà. Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run fi iyẹ̀pẹ̀ mọ ọkùnrin àkọ́kọ́ tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Ádámù, ó sì mí sí ihò imú ẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Ó bẹ̀rẹ̀ sí í rìn, ó ń sọ̀rọ̀, ó sì tún lè ṣe àwọn nǹkan táwa èèyàn máa ń ṣe! Jèhófà wá sọ pé kí Ádámù máa tọ́jú ọgbà yẹn, ó tún sọ pé kó sọ gbogbo àwọn ẹranko lórúkọ.
Jèhófà fún Ádámù ní òfin pàtàkì kan. Ó sọ fún un pé: ‘Gbogbo igi tó wà nínú ọgbà yìí lo lè jẹ èso wọn. Àmọ́, igi kan wà tí o kò gbọ́dọ̀ jẹ èso rẹ̀. Ọjọ́ tó o bá jẹ lára èso igi yẹn lo máa kú.’
Nígbà tó yá, Jèhófà sọ pé: ‘Mo máa dá ẹnì kan táá máa ran Ádámù lọ́wọ́.’ Torí náà, Ọlọ́run mú kí Ádámù sun oorun àsùnwọra, ó wá mú ọ̀kan lára egungun ẹ̀gbẹ́ Ádámù, ó sì fi dá Éfà. Ọlọ́run wá ní kí Ádámù fi Éfà ṣe aya. Bí Ádámù àti Éfà ṣe di tọkọtaya àkọ́kọ́ nìyẹn. Báwo ló ṣe rí lára Ádámù nígbà tó rí ìyàwó ẹ̀? Inú ẹ̀ dùn gan-an. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó sọ? Ó ní: ‘Ẹ wo bí Jèhófà ṣe fi egungun mi dá èèyàn! Ọpẹ́ o! Èmi náà ti wá ní ẹni tó jọ mí.’
Jèhófà sọ fún Ádámù àti Éfà pé kí wọ́n bímọ káwọn ọmọ wọn sì kún ayé. Jèhófà fẹ́ kí inú wọn máa dùn, kí wọ́n sì jọ máa ṣe nǹkan. Ó fẹ́ kí wọ́n sọ ayé di Párádísè, kí gbogbo ayé sì lẹ́wà bí ọgbà Édẹ́nì. Àmọ́ nǹkan ò rí bẹ́ẹ̀. Ṣé o mọ ohun tó fà á? A máa ṣàlàyé ohun tó fà á nínú orí tó kàn.
“Ẹni tó dá wọn ní ìbẹ̀rẹ̀ dá wọn ní akọ àti abo.”—Mátíù 19:4