Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 2
Kí ló mú kí Jèhófà fi omi pa àwọn èèyàn burúkú run láyé àtijọ́? Ọjọ́ pẹ́ tó ti jẹ́ pé báwọn kan ṣe ń ṣe rere làwọn kan ń hùwà burúkú. Bí àpẹẹrẹ, Ádámù, Éfà àti ọmọ wọn tó ń jẹ́ Kéènì yàn láti máa ṣe búburú. Àmọ́ àwọn èèyàn bí Ébẹ́lì àti Nóà yàn láti máa ṣe rere. Ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà yẹn ló yàn láti máa hùwà burúkú, ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi pa wọ́n run. Apá yìí máa jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń mọ̀ tá a bá ń ṣe rere tàbí búburú àti pé Jèhófà ò ní jẹ́ káwọn èèyàn burúkú borí àwọn èèyàn rere.