Ire Yoo Ha Bori Ibi Lae Bi?
NI NǸKAN bi ẹgbẹrun ọdun meji sẹhin, Jesu Kristi, ọkunrin alaimọwọmẹsẹ kan, ni a ń ba ṣẹjọ ti o lè ná an ni iwalaaye rẹ̀. Awọn ọkunrin buburu ń pète lati pa a run nitori pe o sọ otitọ. A fẹsun èké ti iṣọtẹ si ijọba kan an, awọn awujọ sì pariwo gèè fun fifiya-iku jẹ ẹ́. Gomina Romu kan, ẹni ti o ka ipò-oyè oṣelu rẹ̀ si iyebiye lọna giga ju iwalaaye gbẹnagbẹna onirẹlẹ kan lọ, dá Jesu lẹbi iku oníwà-òǹrorò kan. De ibi ti ojú lè ri de, ó dabi ẹni pe ibi ti lékè.
Bi o ti wu ki o ri, ni alẹ́ ti o ṣiwaju fifiya-iku jẹ ẹ́, Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Mo ti ṣẹgun ayé.” (Johannu 16:33) Ki ni ó ni lọ́kàn? Ni apa kan, pe ibi ninu ayé kò mú ki ọkàn rẹ̀ koro, bẹẹ ni kò mú ki o gbẹsan ni ọ̀nà kan-naa. Ayé kò tíì sọ ọ́ di dà bi mo ṣe dà niti ìwà ibi. (Fiwe Romu 12:2, Phillips.) Àní nigba ti o ń ku lọ paapaa, o gbadura nitori awọn olufiya-iku-jẹni rẹ̀ pe: “Baba, dariji wọn; nitori ti wọn kò mọ ohun ti wọn ń ṣe.”—Luku 23:34.
Jesu fihàn—titi ti o fi gbẹ́mìí mi—pe a lè ṣẹgun ibi. Ó rọ awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati ja ogun tiwọn funraawọn lodisi ibi. Bawo ni wọn ṣe lè ṣe iyẹn? Nipa fifetisi imọran Iwe Mimọ naa lati “maṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni” ati lati “fi rere ṣẹgun buburu,” gẹgẹ bi Jesu ti ṣe. (Romu 12:17, 21) Ṣugbọn iru ipa-ọna bẹẹ ha ń ṣiṣẹ niti gidi bi?
Bíbá Ibi Jà Ni Dachau
Else jẹ obinrin ara Germany kan ti a fi sẹwọn ni Dachau ẹni ti o fun ọmọdebinrin ará Russia ọlọdun 14 kan ni ẹbun ti o ṣeyebiye, ẹbun igbagbọ ati ireti.
Dachau jẹ ọgbà iṣẹniniṣẹẹ ti o lokiki buruku nibi ti a ti pa ẹgbẹẹgbẹrun kú a sì fipa mu ọgọrọọrun, eyi ti o ni ninu ọdọmọdebinrin ará Russia yii, lati la awọn aṣeyẹwo iṣegun akojinnijinni-bani kọja. Dachau dabi ẹdaya-apẹẹrẹ ibi. Bi o tilẹ ri bẹẹ, àní ninu ilẹ ti o jọ alailemesojade bẹẹ, ire rú soke ó sì tún bí sii paapaa.
Else káàánú jọjọ fun ọmọdebinrin alaito-ọmọ-ogun-ọdun yii ti a ti fipa mú oun naa pẹlu lati woran awọn oluṣọ SS ti wọn fi ìwà ẹhanna fipa bá ìyá rẹ̀ lòpọ̀. Else, ni fifi iwalaaye oun funraarẹ wewu, ń wá ọ̀nà fun anfaani lati sọrọ pẹlu ọmọdebinrin naa nipa ire ati ibi ati nipa ireti Iwe Mimọ nipa ajinnde kan. O kọ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀dọ́ lati nifẹẹ dipo kikoriira. Ọmọdebinrin ará Russia naa si la awọn ẹrujẹjẹ Dachau já, ọpẹ́lọpẹ́ Else.
Else ṣe ohun ti o ṣe nitori pe o fẹ́ lati tẹle apẹẹrẹ alainimọtara-ẹni nikan ti Kristi. Gẹgẹ bi ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, o ti kọ́ lati maṣe fi buburu san buburu, igbagbọ rẹ̀ sì sún un lati ran awọn ẹlomiran lọwọ lati ṣe bakan naa. Bi o tilẹ jẹ pe o jiya ni Dachau, o gba iṣẹgun niti iwarere lori ijọba buburu kan. Kìí sii ṣe oun nikanṣoṣo.
Paul Johnson, ninu iwe rẹ̀ A History of Christianity, ṣakiyesi pe “[Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa] kọ ifọwọsowọpọ eyikeyii pẹlu ipinlẹ Nazi eyi ti wọn fibu gẹgẹ bi ibi patapata. . . . Mẹtadinlọgọrun-un ninu ipin ọgọrun un jiya inunibini ni ọ̀nà kan tabi omiran.” O ha jẹ ijakadi òmúlẹ̀mófo kan bi? Ninu iwe naa Values and Violence in Auschwitz, Onimọ-ijinlẹ nipa ajọṣepọ ẹgbẹ-oun-ọgba ara Poland Anna Pawelczynska sọ nipa awọn Ẹlẹ́rìí pe: “Awujọ awọn ẹlẹwọn kekere yii jẹ́ agbara niti ijẹwọ-ero ti o le korankoran wọn sì bori ogun wọn lodisi ijọba Nazi.”
Fun eyi ti o pọ julọ ninu wa, bi o ti wu ki o ri, ogun ti o ṣekoko julọ ni a ń ja lodisi ibi ninu lọhun-un dipo agbara-idari buburu tìta. O jẹ ijakadi ninu araawa.
Ṣiṣẹgun Ibi Ti O Wà Ninu Wa
Aposteli Paulu ṣapejuwe ija yii ni ọ̀nà ti o tẹle e yii pe: “Kìí ṣe rere ti mo ń fẹ lati ṣe ni mo ń se niti gidi; buburu ti emi kò fẹ́ lati ṣe ni mo ń baa lọ lati maa se.” (Romu 7:19, The New Testament, lati ọwọ William Barclay) Gẹgẹ bi Paulu ti mọ daradara, ṣiṣe rere kò figba gbogbo maa ń wá lọna adanida.
Eugenioa jẹ́ ọdọmọkunrin ọmọ Spain kan ẹni ti, fun odidi ọdun meji jálẹ̀, wọ ijakadi pẹlu itẹsi buburu ti ara rẹ̀. “Mo nilati lekoko mọ araami,” ni oun ṣalaye. “Lati kekere, ni mo ti ni itẹsi lati jẹ oniwa-palapala. Gẹgẹ bi ọ̀dọ́ alaito-ọmọ-ogun-ọdun kan, mo fi imuratan lọwọ ninu awọn ariya-ẹhanna onibaalopọ laaarin ẹ̀yà kan-naa, ati lati sọ oju abẹ nikoo, mo gbadun iru ọ̀nà ìgbà-gbé igbesi-aye bẹẹ.” Ki ni ohun ti o mu un fẹ́ lati yipada ni asẹhinwa-asẹhinbọ?
“Mo fẹ lati tẹ́ Ọlọrun lọ́rùn, mo sì kẹkọọ lati inu Bibeli pe oun kò tẹwọgba ọ̀nà ti mo gbà ń gbé igbesi-aye,” ni Eugenio sọ. “Nitori naa mo pinnu lati jẹ́ iru eniyan kan ti o yatọ, lati maa gbé ni ibamu pẹlu awọn ilana Ọlọrun. Lojoojumọ, mo nilati jà lodisi awọn ero òdì, ati onídọ̀tí eyi ti o ṣi ń rọ́ wá sinu ọkàn mi sibẹ. Mo pinnu lati bori ijakadi yii, mo sì gbadura laisinmi fun iranlọwọ Ọlọrun. Lẹhin ọdun meji pátápinrá pin, bi o tilẹ jẹ pe mo ṣì jẹ́ alaigbagbẹrẹ pẹlu araami sibẹ. Ṣugbọn ijakadi naa ṣe pataki. Mo ni ọ̀wọ̀ ara-ẹni nisinsinyi, igbeyawo rere, ati, lékè gbogbo rẹ̀, ibatan rere pẹlu Ọlọrun. Mo mọ lati inu iriri ti ara-ẹni pe èrò buburu ni a lè lé kuro ki wọn tó so eso—bi iwọ bá ṣe isapa naa nitootọ.”
Ire bori ibi ni gbogbo ìgbà ti a bá kọ ero buburu silẹ, gbogbo ìgbà ti a bá kọ̀ jalẹ lati fi buburu san buburu. Sibẹ, iru awọn iṣẹgun bẹẹ, bi wọn ti ṣe pataki tó, kò mú orisun ibi ṣiṣepataki meji naa kuro. Bi o ti wu ki a gbiyanju kárakára tó, a kò lè bori awọn ailera wa ti a ti jogunba patapata, Satani si ń lo agbara-idari buburu sibẹ lori iran eniyan. Nitori naa ipo yii yoo ha yipada lae bi?
Pipa Eṣu Run
Iduroṣinṣin Jesu titi dé oju iku jẹ́ ìṣẹ́gunṣẹ́tẹ̀ kan fun Satani. Eṣu kùnà ninu ìgbìdánwò rẹ̀ lati ba iwatitọ Jesu jẹ, ikuna yẹn sì samisi ibẹrẹ opin fun Satani. Gẹgẹ bi Bibeli ṣe ṣalaye, Jesu tọ́ iku wò ki o baà lè ‘ti ipa iku pa Eṣu run.’ (Heberu 2:14) Lẹhin ajinde rẹ̀ Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Gbogbo agbara ni ọrun ati ni ayé ni a fifun mi.” (Matteu 28:18) Ọla-aṣẹ yii ni a o si lò lati sọ awọn iṣẹ́ Satani di òfo.
Iwe Ìfihàn ṣapejuwe ọjọ naa nigba ti Jesu yoo lé Satani jade kuro ninu awọn ọrun. Olori-oluṣebi yii, papọ pẹlu awọn ẹmi eṣu rẹ̀, ni a nilati fimọ si kiki sakani ori ilẹ̀-ayé. Gẹgẹ bi abajade rẹ̀, Bibeli kilọ pe, ibi yoo gbilẹ: “Ègbé ni fun ayé ati fun okun! Nitori Eṣu sọkalẹ tọ̀ yín wá ni ibinu nla, nitori o mọ̀ pe ìgbà kukuru ṣa ni oun ni.”—Ìfihàn 12:7-9, 12.
Asọtẹlẹ Bibeli fihan pe iṣẹlẹ ọlọ́rọ̀ ìtàn yii ti ṣẹlẹ ná—ni deedee ìgbà Ogun Agbaye Kin-in-ni.b Iyẹn ṣalaye ilọsoke hihan kedere ninu ibi ti a ti ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ ni akoko wa. Ṣugbọn laipẹ Satani ni a o kalọwọko patapata ki o lè jẹ pe kò ni lè nipa lori ẹnikẹni mọ.—Wo Ìfihàn 20:1-3.
Ki ni ohun ti gbogbo eyi yoo tumọsi fun gbogbo eniyan?
“Wọn Kò Ni Ṣe Ibi”
Gẹgẹ bi Ọba Ijọba Ọlọrun, Jesu yoo lo “agbara” rẹ̀ ‘lori ilẹ̀-ayé’ laipẹ lati ṣeto itolẹsẹẹsẹ itunnikọlẹkọọ nipa tẹmi kan. “Awọn ti ń bẹ ni ayé yoo kọ́ ododo.” (Isaiah 26:9) Awọn anfaani naa yoo ṣe kedere si gbogbo eniyan. Bibeli mú un dá wa loju pe: “Wọn kì yoo panilara [“wọn kò ni ṣe ibi,” Interlinear Hebrew/Greek English Bible ti Green] bẹẹ ni wọn kì yoo panirun . . . nitori ayé yoo kun fun imọ Oluwa gẹgẹ bi omi ti bo okun.”—Isaiah 11:9.
Àní nisinsinyi paapaa, ọpọlọpọ ninu awọn itẹsi buburu wa ni a lè bori. Nigba ti agbara idari ẹlẹmii-eṣu kò ba si mọ́, yoo rọrun pupọ, pupọ sii lati “yà kuro ninu ibi, ki o si maa ṣe rere.”—1 Peteru 3:11.
A ní gbogbo idi lati ni idaniloju pe ire yoo ṣẹgun ibi nitori pe rere ni Ọlọrun, ati pẹlu iranlọwọ rẹ̀ gbogbo awọn wọnni ti wọn fẹ lati ṣe rere lè bori ibi, gẹgẹ bi Jesu ti fẹ̀rìí rẹ han nipa apẹẹrẹ tirẹ funraarẹ. (Orin Dafidi 119:68) Awọn wọnni ti wọn muratan nisinsinyi lati bá ibi jijakadi lè wọna fun gbigbe ninu ilẹ̀-ayé mimọ tonitoni kan eyi ti Ijọba Ọlọrun ń ṣakoso, iṣakoso kan ti o pọkan pọ sori mimu ibi kuro patapata titilae. Olorin naa ṣapejuwe abajade naa pe: “Aanu ati otitọ padera; òdodo ati alaafia ti fi ẹnu ko araawọn ni ẹnu. Otitọ yoo rú jade lati ilẹ wa: òdodo yoo si bojuwo ilẹ lati ọrun wa.”—Orin Dafidi 85:10, 11.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kìí ṣe orukọ rẹ̀ gan-an.
b Fun alaye siwaju sii, wo oju-iwe 20 si 22 ninu iwe Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, ti a tẹjade lati ọwọ́ Watch Tower Bible and Tract Society of New York, Inc.