ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 7/1 ojú ìwé 22-26
  • “Ẹ Má Ṣe Fi Ibi San Ibi Fún Ẹnì Kankan”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Má Ṣe Fi Ibi San Ibi Fún Ẹnì Kankan”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹ jẹ́ Kí Ìfẹ́ Yín Wà Láìsí Àgàbàgebè”
  • “Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Sísúre fún Àwọn Tí Ń Ṣe Inúnibíni”
  • “Ẹ Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà Pẹ̀lú Gbogbo Ènìyàn”
  • “Ẹ Má Ṣe Gbẹ̀san Ara Yín”
  • Ìdí Tí A Kò Fi Ń Gbẹ̀san
  • “Ẹ Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà Pẹ̀lú Gbogbo Ènìyàn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ire Yoo Ha Bori Ibi Lae Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Bí Ire Ṣe Máa Borí Ibi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Kí Ló Máa Ń Mú Ká Hùwà Rere Tàbí Búburú?
    Jí!—2010
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 7/1 ojú ìwé 22-26

“Ẹ Má Ṣe Fi Ibi San Ibi Fún Ẹnì Kankan”

“Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. Ẹ pèsè àwọn ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ lójú gbogbo ènìyàn.”—RÓÒMÙ 12:17.

1. Irú ìwà wo ló wọ́pọ̀ láàárín àwọn èèyàn?

NÍGBÀ tí ọmọ kan bá ti ọmọ mìíràn, ohun tí ọmọ tí wọ́n tì náà sábà máa ń ṣe ni pé, yóò ti èkejì rẹ̀ padà. Ó bani nínú jẹ́ pé kì í ṣe àárín àwọn ọmọdé nìkan ni irú ìwà oró-tó-o-dá-mi-ni-mo-dá-ọ yìí wà. Ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà náà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wọ́n, wọ́n máa ń fẹ́ gbẹ̀san. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àgbàlagbà kò ní ti ẹni tó ṣẹ̀ wọ́n bíi ti ọmọ kékeré yẹn, àmọ́ wọ́n máa ń dọ́gbọ́n gbẹ̀san láwọn ọ̀nà mìíràn. Bóyá kí wọ́n máa ba ẹni tó ṣẹ̀ wọ́n yẹn jẹ́ kiri tàbí kí wọ́n máa wá àwọn ọ̀nà láti dènà àṣeyọrí onítọ̀hún. Ọ̀nàkọnà téèyàn ì báà gbà ṣe é, ohun kan náà làwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní lọ́kàn, ìyẹn ni láti gbẹ̀san.

2. (a) Kí nìdí táwọn Kristẹni tòótọ́ fi máa ń yẹra fún ẹ̀mí ìgbẹ̀san? (b) Àwọn ìbéèrè wo àti orí Bíbélì wo la máa gbé yẹ̀ wò?

2 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀mí ìgbẹ̀san jinlẹ̀ lọ́kàn ọmọ èèyàn, síbẹ̀ àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń yẹra fún irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Kàkà kí wọ́n gbẹ̀san, wọ́n máa ń sapá láti fi ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ sílò pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan.” (Róòmù 12:17) Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ lé ìlànà tó dára gan-an yìí nígbèésí ayé wa? Àwọn wo ní pàtàkì ni kò yẹ ká fi ibi san ibi fún? Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń yẹra fún ẹ̀mí ìgbẹ̀san? Láti rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ọ̀rọ̀ tó wà láyìíká ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí yẹ̀ wò, ká sì wá rí i bí Róòmù orí Kejìlá ṣe fi hàn pé kíkọ̀ láti gbẹ̀san ni ohun tó tọ́, tó fìfẹ́ hàn, tó sì fi hàn pé a kì í ṣe ọ̀yájú. A ò gbé apá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan.

“Nítorí Náà, Mo . . . Pàrọwà Fún Yín”

3, 4. (a) Bẹ̀rẹ̀ láti orí Kejìlá ìwé Róòmù, kí ni Pọ́ọ̀lù jíròrò, kí ló sì mú kí lílò tó lo ọ̀rọ̀ náà, “nítorí náà,” ṣe pàtàkì gan-an? (b) Ipa wo ló yẹ kí ìyọ́nú Ọlọ́run ní lórí àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Róòmù?

3 Bẹ̀rẹ̀ láti orí Kejìlá, Pọ́ọ̀lù jíròrò àwọn kókó mẹ́rin tó tan mọ́ra wọn tó ń nípa lórí ìgbésí ayé àwa Kristẹni. Ó sọ nípa àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà, pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa, pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́, àti pẹ̀lú àwọn aláṣẹ ìjọba. Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé ìdí pàtàkì kan wà tó fi yẹ ká yẹra fáwọn èrò tí kò tọ́ tó lè máa wá sọ́kàn wa, títí kan fífẹ́ láti gbẹ̀san. Ó sọ pé: “Nítorí náà, mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run pàrọwà fún yín, ẹ̀yin ará.” (Róòmù 12:1) Kíyè sí gbólóhùn náà, “nítorí náà,” èyí tó túmọ̀ sí, “pẹ̀lú gbogbo ohun tí mo ti sọ yìí.” Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé, ‘Pẹ̀lú ohun tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàlàyé fún un yín yìí, mo rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ ṣe ohun tí mo tún máa sọ lẹ́yìn èyí.’ Àlàyé wo ni Pọ́ọ̀lù ti kọ́kọ́ ṣe fáwọn Kristẹni ìlú Róòmù yẹn?

4 Nínú orí mọ́kànlá tó ṣáájú nínú lẹ́tà Pọ́ọ̀lù, ó jíròrò àǹfààní àgbàyanu tó wà fáwọn Júù àtàwọn Kèfèrí láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn sì jẹ́ ìrètí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ láti tẹ́wọ́ gbà. (Róòmù 11:13-36) Nípasẹ̀ “ìyọ́nú Ọlọ́run” nìkan ni àǹfààní yìí fi ṣeé ṣe. Ojú wo ló yẹ káwọn Kristẹni fi wo inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí gíga lọ́lá tí Ọlọ́run fi hàn sí wọn yìí? Ó yẹ kí wọ́n mọrírì rẹ̀ gan-an débi pé wọ́n á fẹ́ láti ṣe ohun tí Pọ́ọ̀lù tún sọ lẹ́yìn náà pé: “Ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín.” (Róòmù 12:1) Àmọ́, ọ̀nà wo gan-an làwọn Kristẹni yẹn lè gbà fi ara wọn fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí “ẹbọ”?

5. (a) Báwo lẹnì kan ṣe lè fi ara rẹ̀ fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí “ẹbọ”? (b) Ìlànà wo ló yẹ kó máa darí ìwà ẹni tó jẹ́ Kristẹni?

5 Pọ́ọ̀lù ń bá àlàyé rẹ̀ lọ, ó ní: “Ẹ sì jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) Dípò káwọn Kristẹni máa ronú báwọn èèyàn ayé ṣe ń ronú, ó yẹ kí wọ́n yí èrò inú wọn padà kó bá ọ̀nà tí Kristi ń gbà ronú mu. (1 Kọ́ríńtì 2:16; Fílípì 2:5) Ìlànà yìí ló yẹ kó máa darí ìwà gbogbo Kristẹni tòótọ́ lójoojúmọ́, títí kan àwa náà lónìí.

6. Gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí Pọ́ọ̀lù ṣe nínú Róòmù 12:1, 2, kí ló ń mú ká yẹra fún ẹ̀mí ìgbẹ̀san?

6 Ọ̀nà wo ni àlàyé tí Pọ́ọ̀lù ṣe nínú Róòmù 12:1, 2 lè gbà ràn wá lọ́wọ́? Bíi tàwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn tí wọ́n wà nílùú Róòmù yẹn, ẹnu wa kò gbọpẹ́ fún onírúurú ọ̀nà tí Ọlọ́run ti gbà fi ìyọ́nú rẹ̀ hàn sí wa, tó sì ń bá a nìṣó láti máa fi hàn sí wa lójoojúmọ́, ní gbogbo ìgbésí ayé wa. Nítorí náà, ọkàn wa kún fún ọpẹ́ gan-an, èyí sì ń mú ká sin Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo okun wa, ohun ìní wa, àti ẹ̀bùn tá a ní. Ìfẹ́ ọkàn wa yìí tún ń mú ká sa gbogbo ipa wa láti lè máa ronú bíi ti Kristi, kì í ṣe lọ́nà táwọn èèyàn ayé ń gbà ronú. Níní èrò tí Kristi ní sì máa ń nípa lórí bá a ṣe ń ṣe sáwọn ẹlòmíràn, ìyẹn àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ àtàwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́. (Gálátíà 5:25) Àpẹẹrẹ kan nìyí: Bá a bá ń ronú bíi ti Kristi, a ó máa yẹra fún ẹ̀mí ìgbẹ̀san.—1 Pétérù 2:21-23.

“Ẹ jẹ́ Kí Ìfẹ́ Yín Wà Láìsí Àgàbàgebè”

7. Irú ìfẹ́ wo ni Pọ́ọ̀lù jíròrò rẹ̀ nínú Róòmù orí Kejìlá?

7 Kì í ṣe nítorí pé kíkọ̀ láti fi ibi san ibi jẹ́ ohun tó tọ́ nìkan ló ń mú ká yàgò fún un, àmọ́ nítorí pé ó tún jẹ́ ohun tó fìfẹ́ hàn. Kíyè sí ọ̀nà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún gbà jíròrò ìdí tó fi yẹ ká máa ní ìfẹ́. Nínú ìwé Róòmù, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́” (a·gaʹpe lédè Gíríìkì) nígbà tó ń sọ nípa ìfẹ́ tí Ọlọ́run àti Kristi ní sí wa. (Róòmù 5:5, 8; 8:35, 39) Àmọ́ o, nínú orí Kejìlá, Pọ́ọ̀lù lo a·gaʹpe lọ́nà mìíràn tó yàtọ̀ nígbà tó ń sọ nípa fífi ìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn bíi tiwa. Lẹ́yìn tó ti sọ pé àwọn ẹ̀bùn tẹ̀mí yàtọ̀ síra àti pé àwọn kan lára àwọn onígbàgbọ́ ní in, ó wá sọ ànímọ́ kan tó jẹ́ pé gbogbo Kristẹni ló yẹ kó sapá láti ní in. Ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ yín wà láìsí àgàbàgebè.” (Róòmù 12:4-9) Fífi ìfẹ́ hàn sáwọn ẹlòmíràn ni olórí ọ̀nà tá a fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀. (Máàkù 12:28-31) Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú láti rí i dájú pé ìfẹ́ tí à ń fi hàn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni wá látọkàn wa.

8. Báwo la ṣe lè fi ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn hàn?

8 Kò tán síbẹ̀ o, Pọ́ọ̀lù tún sọ bá a ṣe lè fi ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn hàn, ó ní: “Ẹ fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú, ẹ rọ̀ mọ́ ohun rere.” (Róòmù 12:9) “Fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra” àti “rọ̀ mọ́” jẹ́ ọ̀rọ̀ tó lágbára gan-an. A lè túmọ̀ “fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra” sí “kórìíra gidigidi.” Kì í ṣe àwọn ohun tó máa tìdí ìwà ibi jáde nìkan ló yẹ ká kórìíra, a tún gbọ́dọ̀ kórìíra ibi fúnra rẹ̀. (Sáàmù 97:10) Àtinú ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì tó túmọ̀ sí “lẹ̀ mọ́” ni wọ́n ti túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà “rọ̀ mọ́.” Kristẹni tó ní ojúlówó ìfẹ́ máa ń rọ̀ mọ́ ìwà rere, débi pé á di ohun tí kò ṣeé mú kúrò nínú ìwà ẹni náà.

9. Ọ̀rọ̀ ìṣílétí wo ni Pọ́ọ̀lù sọ léraléra?

9 Léraléra ni Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà pàtàkì kan téèyàn lè gbà fi ìfẹ́ hàn. Ó ní: “Ẹ máa bá a nìṣó ní sísúre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni; ẹ máa súre, ẹ má sì máa gégùn-ún.” “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan.” “Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” “Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” (Róòmù 12:14, 17-19, 21) Àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yìí jẹ́ ká rí i kedere bó ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn aláìgbàgbọ́, kódà àwọn tó ń ṣàtakò sí wa.

“Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Sísúre fún Àwọn Tí Ń Ṣe Inúnibíni”

10. Ọ̀nà wo la lè gbà súre fáwọn tó ń ṣenúnibíni sí wa?

10 Báwo la ṣe lè fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò, èyí tó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní sísúre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni”? (Róòmù 12:14) Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín.” (Mátíù 5:44; Lúùkù 6:27, 28) Nípa báyìí, ọ̀nà kan tá à ń gbà súre fáwọn tó ń ṣenúnibíni sí wa jẹ́ nípa gbígbàdúrà fún wọn, ká máa bẹ Ọlọ́run pé bó bá jẹ́ pé àìmọ̀kan ló ń mú káwọn kan máa ṣenúnibíni sí wa, kí Jèhófà là wọ́n lójú kí wọ́n lè rí òtítọ́. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Lóòótọ́, ó lè dà bí ohun tó ṣàjèjì láti máa bẹ Ọlọ́run pé kó bù kún ẹnì kan tó ń ṣenúnibíni sí wa. Àmọ́, bí ọ̀nà tá à ń gbà ronú bá ṣe túbọ̀ ń jọ ti Kristi, bẹ́ẹ̀ la ṣe máa túbọ̀ lè fi ìfẹ́ hàn sáwọn ọ̀tá wa. (Lúùkù 23:34) Kí ló lè jẹ́ àbájáde fífi irú ìfẹ́ yìí hàn?

11. (a) Kí la lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ Sítéfánù? (b) Gẹ́gẹ́ bí ìgbésí ayé Pọ́ọ̀lù ti fi hàn, àyípadà wo ló lè ṣẹlẹ̀ sáwọn kan tó ń ṣenúnibíni?

11 Sítéfánù gbàdúrà fáwọn tó ṣenúnibíni sí i, àdúrà rẹ̀ kò sì já sásán. Kò pẹ́ lẹ́yìn ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, làwọn tó ń ṣàtakò sí ìjọ Kristẹni mú Sítéfánù, tí wọ́n wọ́ ọ jáde kúrò nílùú Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ọ́ lókùúta. Kó tó gbẹ̀mí mì, ó kígbe sí Jèhófà pé: “Jèhófà, má ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn lọ́rùn.” (Ìṣe 7:58–8:1) Ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin tí Sítéfánù gbàdúrà fún lọ́jọ́ yẹn ni Sọ́ọ̀lù. Ó wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n ń pa Sítéfánù, ó sì fọwọ́ sí i. Nígbà tó yá, Jésù tó ti jíǹde bá Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀. Ẹni tó ti ń ṣenúnibíni tẹ́lẹ̀ yẹn wá di ọmọlẹ́yìn Kristi, ó sì tún di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nígbà tó yá, òun ló sì kọ lẹ́tà tí à ń jíròrò yìí sáwọn ará Róòmù. (Ìṣe 26:12-18) Gẹ́gẹ́ bí Sítéfánù ṣe gbà á ládùúrà, Jèhófà dárí ẹ̀ṣẹ̀ inúnibíni tí Pọ́ọ̀lù ṣe jì í. (1 Tímótì 1:12-16) Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní sísúre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni”! Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí òun fúnra rẹ̀ ti jẹ́ kó mọ̀ pé àwọn kan tí wọ́n ń ṣenúnibíni lè di ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó bá yá. Lọ́jọ́ òní, àwọn kan tó ń ṣenúnibíni ti di onígbàgbọ́ bíi ti Pọ́ọ̀lù nítorí ẹ̀mí àlàáfíà táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní.

“Ẹ Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà Pẹ̀lú Gbogbo Ènìyàn”

12. Báwo ni ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wà nínú Róòmù 12:9, 17 ṣe tan mọ́ ara wọn?

12 Ọ̀rọ̀ ìṣílétí tí Pọ́ọ̀lù tún sọ nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn onígbàgbọ́ àtàwọn aláìgbàgbọ́ ni pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan.” Gbólóhùn yìí ló jẹ́ àbárèbábọ̀ ohun tó ti kọ́kọ́ sọ tẹ́lẹ̀, pé: “Ẹ fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú.” Àbí, báwo lẹnì kan á ṣe sọ pé lóòótọ́ lòun kórìíra ohun búburú tàbí ibi, tó bá ń fi ibi san ibi táwọn mìíràn ṣe sí i? Òdìkejì níní ìfẹ́ “láìsí àgàbàgebè” ni ṣíṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́. Pọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Ẹ pèsè àwọn ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ lójú gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 12:9, 17) Báwo la ṣe lè fi ohun tó sọ yìí sílò?

13. Báwo ló ṣe yẹ kí ìwà wa rí “lójú gbogbo ènìyàn”?

13 Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù ti kọ́kọ́ kọ sáwọn ará Kọ́ríńtì, ó sọ nípa inúnibíni táwọn àpọ́sítélì ń dojú kọ. Ó kọ̀wé pé: “Àwa ti di ìran àpéwò ní gbọ̀ngàn ìwòran fún ayé, àti fún àwọn áńgẹ́lì, àti fún àwọn ènìyàn. . . . Nígbà tí wọ́n ń kẹ́gàn wa, àwa ń súre; nígbà tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wa, àwa ń mú un mọ́ra; nígbà tí wọ́n ń bà wá lórúkọ jẹ́, àwa ń pàrọwà.” (1 Kọ́ríńtì 4:9-13) Bákan náà lọ̀rọ̀ rí fáwọn Kristẹni tòótọ́ lónìí, àwọn èèyàn ayé ń kíyè sí wọn. Nígbà táwọn tó wà láyìíká wa bá rí àwọn nǹkan dáadáa tí à ń ṣe, kódà nígbà táwọn kan bá ń ṣe ohun tí kò dára sí wa, èyí lè mú kí wọ́n túbọ̀ fojú tó dára wo ohun tí à ń wàásù rẹ̀.—1 Pétérù 2:12.

14. Báwo ló ṣe yẹ ká sapá tó láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn mìíràn?

14 Báwo ló ṣe yẹ ká sapá tó láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn? Ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe. Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni pé: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 12:18) “Bí ó bá ṣeé ṣe” àti “níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà” jẹ́ àwọn gbólóhùn tó ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀, wọ́n sì ń fi hàn pé wíwà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn lè má ṣeé ṣe nígbà mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, a ò ní rú òfin Ọlọ́run nítorí pé a ṣáà fẹ́ wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn. (Mátíù 10:34-36; Hébérù 12:14) Síbẹ̀síbẹ̀, a ó ṣe gbogbo ohun tó bọ́gbọ́n mu tá a bá lè ṣe láti wà ní àlàáfíà “pẹ̀lú gbogbo ènìyàn,” láìré ìlànà òdodo kọjá.

“Ẹ Má Ṣe Gbẹ̀san Ara Yín”

15. Kí la rí nínú Róòmù 12:19 tó fi hàn pé kò yẹ ká máa gbẹ̀san?

15 Pọ́ọ̀lù tún sọ ìdí pàtàkì mìíràn tí kò fi yẹ ká máa gbẹ̀san. Ìdí ọ̀hún ni pé, yóò fi hàn pé a kì í ṣe ọ̀yájú. Ó sọ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú; nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san, ni Jèhófà wí.’” (Róòmù 12:19) Tí Kristẹni kan bá ń gbìyànjú láti gbẹ̀san, ọ̀yájú ni irú ẹni bẹ́ẹ̀. Ohun tó yẹ kí Ọlọ́run ṣe ló ń gbà ṣe yẹn. (Mátíù 7:1) Ìyẹn nìkan kọ́ o, nípa fífúnra rẹ̀ gbẹ̀san, ńṣe nirú ẹni bẹ́ẹ̀ ń fi hàn pé òun ò nígbàgbọ́ nínú ohun tí Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò gbẹ̀san.” Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń fọkàn tán Jèhófà pé yóò “mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀.” (Lúùkù 18:7, 8; 2 Tẹsalóníkà 1:6-8) Nítorí pé wọn kì í ṣe ọ̀yájú, wọ́n máa ń jẹ́ kí Ọlọ́run bá wọn gbẹ̀san ohun tí kò dára táwọn mìíràn ṣe sí wọn.—Jeremáyà 30:23, 24; Róòmù 1:18.

16, 17. (a) Kí ló túmọ̀ sí láti “kó òkìtì ẹyín iná” lé ẹnì kan lórí? (b) Ǹjẹ́ ó ti ṣẹlẹ̀ lójú rẹ rí tí ìwà rere mú kí ọkàn ẹnì kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ rọ̀? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, sọ àpẹẹrẹ kan.

16 Kò sí àní-àní pé ńṣe ni gbígbẹ̀san ohun tí ọ̀tá kan ṣe yóò mú kí ọkàn ọ̀tá náà túbọ̀ le sí i. Àmọ́ ṣíṣe dáadáa sí ọ̀tá náà lè mú kí ọkàn rẹ̀ rọ̀. Kí nìdí? Kíyè sí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni tó wà nílùú Róòmù. Ó ní: “Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní ohun kan láti mu; nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò máa kó òkìtì ẹyín iná lé e ní orí.” (Róòmù 12:20; Òwe 25:21, 22) Kí lèyí túmọ̀ sí?

17 Láti “kó òkìtì ẹyín iná lé e ní orí” jẹ́ àkànlò èdè kan tí wọ́n mú jáde látinú ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà yọ́ irin tútù lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Wọ́n máa ń kó irin tútù sínú ìléru, yàtọ̀ sí pé wọ́n máa ń kó ẹ̀ṣẹ́ iná sí ìdí irin tútù náà, wọ́n tún máa ń kó o sórí rẹ̀ pẹ̀lú. Ẹ̀ṣẹ́ iná tí wọ́n wà sórí ìrìn tútù náà máa ń jẹ́ kí iná náà túbọ̀ gbóná gan-an débi pé, irin tútù náà á yọ́, ìdọ̀tí ara rẹ̀ á sì kúrò. Lọ́nà kan náà, bá a bá ń ṣe ohun tó dára sí ẹnì kan tó ń ṣe àtakò sí wa, a lè mú kí ọkàn rẹ̀ tó le “yọ́” ká sì wá rí àwọn ànímọ́ dáadáa tí onítọ̀hún ní. (2 Àwọn Ọba 6:14-23) Àní sẹ́, ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ ara ìjọ Kristẹni ló jẹ́ pé nǹkan dáadáa táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe fún wọn ló kọ́kọ́ jẹ́ kó wù wọ́n láti wá sínú ìjọsìn tòótọ́.

Ìdí Tí A Kò Fi Ń Gbẹ̀san

18. Kí nìdí tí kíkọ̀ láti gbẹ̀san fi jẹ́ ohun tó tọ́, tó fìfẹ́ hàn, tó sì fi hàn pé a kì í ṣe ọ̀yájú?

18 Nínú ìjíròrò ṣókí tá a ṣe nípa Róòmù orí Kejìlá yìí, a ti rí ọ̀pọ̀ ìdí tó ṣe pàtàkì tí kò fi yẹ ká máa “fi ibi san ibi fún ẹnì kankan.” Àkọ́kọ́, kíkọ̀ láti gbẹ̀san jẹ́ ohun tó tọ́ láti ṣe. Tá a bá ro ìyọ́nú tí Ọlọ́run ń fi hàn sí wa, ó tọ́ ó sì bọ́gbọ́n mu pé ká fi ara wa fún Jèhófà ká sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ tinútinú, títí kan àṣẹ tó pa pé ká máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wa. Èkejì, kíkọ̀ láti fi ibi san ibi jẹ́ ohun tó fi ìfẹ́ hàn tó yẹ ká máa ṣe. Tá ò bá lẹ́mìí ìgbẹ̀san, tá a sì ń wá bí àlàáfíà yóò ṣe wà, ìyẹn túmọ̀ sí pé a nífẹ̀ẹ́ a sì nírètí láti ran àwọn alátakò lọ́wọ́ láti wá jọ́sìn Jèhófà, kódà àwọn alátakò tó burú gan-an pàápàá. Ẹ̀kẹta, kíkọ̀ láti gbẹ̀san fi hàn pé a kì í ṣe ọ̀yájú. Tá a bá ń fúnra wa gbẹ̀san, ńṣe là ń kọjá àyè wa, nítorí Jèhófà sọ pé: “Tèmi ni ẹ̀san.” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún kìlọ̀ fún wa pé: “Ìkùgbù ha ti dé bí? Nígbà náà, àbùkù yóò dé; ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.” (Òwe 11:2) Tá a bá fi hàn pé a jẹ́ ọlọgbọ́n nípa jíjẹ́ kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ gbẹ̀san ìwà burúkú kan, ìyẹn fi hàn pé a kì í ṣe ọ̀yájú.

19. Kí la ó jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?

19 Pọ́ọ̀lù wá ṣàkópọ̀ gbogbo ohun tó ti jíròrò nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn èèyàn. Ó gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” (Róòmù 12:21) Àwọn ohun búburú wo ló ń kojú wa lónìí? Báwo la ṣe lè ṣẹ́gun wọn? A óò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí àtàwọn mìíràn tó jẹ mọ́ ọn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Ìmọ̀ràn wo la rí léraléra nínú Róòmù orí kejìlá?

• Nítorí àwọn ìdí wo la ò fi ní gbẹ̀san?

• Àwọn àǹfààní wo làwa àtàwọn mìíràn máa rí tí a kò bá “fi ibi san ibi”?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]

Róòmù orí Kejìlá sọ nípa àjọṣe Kristẹni kan pẹ̀lú

• Jèhófà

• àwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀

• àwọn aláìgbàgbọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù ní ìmọ̀ràn tó wúlò gan-an nínú fáwọn Kristẹni

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Kí la lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ Sítéfánù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́