ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 7/1 ojú ìwé 18-21
  • Ìtàn Bíbélì Àkọ́kọ́ Lédè Potogí Jẹ́ Ìtàn Ìfaradà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtàn Bíbélì Àkọ́kọ́ Lédè Potogí Jẹ́ Ìtàn Ìfaradà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀dọ́mọdé Atúmọ̀ Èdè
  • Ilé Ẹjọ́ Kátólíìkì Dájọ́ Ikú Fún Un
  • Almeida àti Ìgbìmọ̀ Tó Ń Yẹ Iṣẹ́ Rẹ̀ Wò
  • Iṣẹ́ Parí Lórí Bíbélì Lédè Potogí
  • Ohun Tó Ṣe Sílẹ̀ Kò Pa Run
  • Láti Inú Ipò Òṣì Paraku, Mo Bọ́ Sínú Ọrọ̀ Tó Gadabú Jù Lọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • “Kaaarọ O! Iwọ Ha Mọ Orukọ Ọlọrun Bi?”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Wàhálà Tí Ọ̀rọ̀ Òṣèlú Ń Dá Sílẹ̀ Kárí Ayé—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Orukọ Ọlọrun ati Awọn Atumọ Bibeli
    Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 7/1 ojú ìwé 18-21

Ìtàn Bíbélì Àkọ́kọ́ Lédè Potogí Jẹ́ Ìtàn Ìfaradà

“ẸNI tó bá ní ìfaradà yóò ṣàṣeyọrí.” Gbólóhùn yìí wà lójú ìwé tí wọ́n kọ àkọlé sí nínú ìwé kékeré kan tó jẹ́ ti ìsìn. Ọ̀rúndún Kẹtàdínlógún ni wọ́n tẹ̀ ìwé yìí jáde látọwọ́ João Ferreira de Almeida. Kò dájú pé gbólóhùn mìíràn tún wà téèyàn lè fi ṣàpèjúwe ọkùnrin kan tó fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ túmọ̀ Bíbélì sí èdè Potogí, tó si ní kí wọ́n tẹ̀ ẹ́ jáde.

Ọdún 1628 ni wọ́n bí Almeida lábúlé kan tó ń jẹ́ Torre de Tavares tó wà ní àríwá ilẹ̀ Potogí. Kékeré ló wà táwọn òbí rẹ̀ ti kú, àbúrò bàbá rẹ̀ ọkùnrin kan tó jẹ́ ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ló sì tọ́ ọ dàgbà nílùú Lisbon, tó jẹ́ olú-ìlú ilẹ̀ Potogí. Ìtàn fi yé wa pé nígbà tí Almeida ń múra sílẹ̀ láti di àlùfáà, ó gba ẹ̀kọ́ tó dára gan-an, èyí sì ràn án lọ́wọ́ láti mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè nígbà tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́.

Àmọ́ o, ká ní Almeida kò kúrò nílẹ̀ Potogí ni, ó ṣeé ṣe kó má lo ẹ̀bùn tó ní yìí nínú iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ẹgbẹ́ Tó Ń Ta Ko Àwọn Ẹ̀kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ Bíbélì èdè Ìbílẹ̀ wọ àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní àríwá àti àárín gbùngbùn Yúróòpù, Ilé Ẹjọ́ Ìjọ Kátólíìkì tó ń fìyà jẹ ẹni tó bá ṣe ohun tó ta ko ẹ̀kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì náà ṣì lágbára gan-an lórí àwọn èèyàn ilẹ̀ Potogí lákòókò yẹn. Pé èèyàn tiẹ̀ ní Bíbélì èdè ìbílẹ̀ lọ́wọ́ lè mú kéèyàn fara hàn ní Ilé Ẹjọ́ yìí.a

Ó lè jẹ́ pé kí Almeida lè kúrò ní àyíká tí kò ti sí òmìnira yìí ló fà á tó fi lọ ń gbé lórílẹ̀-èdè Netherlands nígbà tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá péré, ó bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò lọ sílẹ̀ Éṣíà, ó sì gba ìlú Batavia (tó ń jẹ́ Jakarta báyìí) lórílẹ̀-èdè Indonesia kọjá. Nígbà yẹn, Batavia ni ibùjókòó ìjọba ilẹ̀ Netherlands fún bíbójútó Àjọ Ìlà Oòrùn Íńdíà ní Gúúsù Ìlà Oòrùn ilẹ̀ Éṣíà.

Ọ̀dọ́mọdé Atúmọ̀ Èdè

Nígbà tó kù díẹ̀ kí Almeida parí ìrìn àjò rẹ̀ sílẹ̀ Éṣíà, nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tó yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà. Bó ti wà nínú ọkọ̀ ojú omi tó ń lọ láti ìlú Batavia sí ìlú Malacca (tó ń jẹ́ Melaka báyìí) ní ìwọ̀ oòrùn Malaysia, ó ṣèèṣì rí ìwé ìléwọ́ kan táwọn ìjọ Pùròtẹ́sítáǹtì ṣe lédè Sípáníìṣì, àkòrí ìwé náà ni, Àwọn Ìyàtọ̀ Tó Wà Nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù. Yàtọ̀ sí pé ìwé ìléwọ́ náà ta ko àwọn ẹ̀kọ́ tí ìsìn èké fi ń kọ́ àwọn èèyàn, ó tún ní gbólóhùn kan nínú tí Almeida nífẹ̀ẹ́ sí gan-an. Gbólóhùn náà ni pé: “Lílo èdè táwọn èèyàn kò lóye ní ṣọ́ọ̀ṣì, kódà fún ògo Ọlọ́run, kò ṣe àwọn tó ń gbọ́ ọ àmọ́ tí wọn ò lóye rẹ̀ láǹfààní kankan.”—1 Kọ́ríńtì 14:9.

Ohun tí ìwé náà ń sọ yé Almeida dáadáa: Ohun náà ni pé, ọ̀nà kan ṣoṣo táwọn èèyàn fi lè mọ àṣìṣe inú ẹ̀sìn ni pé kí Bíbélì wà lédè tí gbogbo èèyàn yóò lóye rẹ̀. Nígbà tí Almeida dé ìlú Malacca, ó yí ìsìn rẹ̀ padà ó sì di ara Ìjọ Tó Ń Ta Ko Àwọn Ẹ̀kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì Nílẹ̀ Netherlands. Kíákíá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ àwọn kan lára Ìwé Ìhìn Rere láti èdè Sípáníìṣì sí èdè Potogí ó sì ń pín in fún “àwọn tó dìídì fẹ́ mọ òtítọ́.”b

Ọdún méjì lẹ́yìn náà, Almeida ti múra tán láti dáwọ́ lé iṣẹ́ ribiribi mìíràn, ìyẹn ni títúmọ̀ gbogbo Ìwé Mímọ́ Kristẹni lédè Gíríìkì látinú Bíbélì èdè Látìn tí wọ́n ń pè ní Vulgate. Kò pé ọdún kan rárá tó fi parí iṣẹ́ yìí, àṣeyọrí ńlá gbáà lèyí sì jẹ́ fọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún péré! Láìbẹ̀rù, ó fi ẹ̀dà kan ránṣẹ́ sí aṣojú ìjọba ilẹ̀ Netherlands nílùú Batavia pé kí wọ́n tẹ̀ ẹ́ jáde. Láìsí àní-àní, Ṣọ́ọ̀ṣì Alátùn-únṣe nílùú Batavia kó àwọn ẹ̀dà àfọwọ́kọ náà ránṣẹ́ sílùú Amsterdam, àmọ́ àlùfáà kan tó jẹ́ àgbàlagbà tí wọ́n kó o fún kú, ni gbogbo iṣẹ́ Almeida bá wọmi.

Nígbà tí wọ́n ní kí Almeida ṣe ẹ̀dà kan Bíbélì tó túmọ̀ yẹn fún ìjọ Alátùn-únṣe tó wà nílùú Ceylon (tó ń jẹ́ Sri Lanka báyìí) lọ́dún 1651 ló wá rí i pé àwọn tóun ti kọ́kọ́ ṣe yẹn kò sí níbi tí wọ́n ń kówèé sí nínú ṣọ́ọ̀ṣì náà mọ́. Àmọ́ kò jẹ́ kí èyí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá òun, lọ́nà kan ṣá, ó rí ẹ̀dà kan, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ èyí tó kọ́kọ́ fọwọ́ kọ, nígbà tó sì di ọdún tó tẹ̀ lé e, ó parí Ìwé Ìhìn Rere àti Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì, tó jẹ́ àtúnṣe ẹ̀dà. Ọgbọ̀n owó guilder ni ìgbìmọ̀ alákòóso Ṣọ́ọ̀ṣì Alátùn-únṣe tó wà ní Batavia yìí fún un. Ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan kọ̀wé pé owó yìí “kéré gan-an lẹ́gbẹ̀ẹ́ iṣẹ́ bàǹtàbanta tó ṣe.”

Pẹ̀lú bí wọ́n ò ṣe ka ohun tí Almeida ṣe yìí sí, ńṣe ló ń bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ, nígbà tó sì di ọdún 1654, ó parí iṣẹ́ títúmọ̀ Májẹ̀mú Titun ó sì tún gbé e fáwọn tó máa yẹ̀ ẹ́ wò. Bí ọ̀rọ̀ títẹ̀ ẹ́ jáde tún ṣe délẹ̀ nìyẹn, àmọ́ àwọn tó gbé e fún kò ṣe nǹkan gidi kan nípa rẹ̀ ju pé wọ́n kàn ṣe àwọn ẹ̀dà kan tí wọ́n fọwọ́ dà kọ, kí wọ́n lè rí wọn lò láwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan.

Ilé Ẹjọ́ Kátólíìkì Dájọ́ Ikú Fún Un

Lẹ́yìn ìgbà yẹn, odindi ọdún mẹ́wàá lọwọ́ Almeida fi dí gan-an, bó ṣe ń ṣiṣẹ́ àlùfáà ló tún ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì fún Ìjọ Alátùn-únṣe. Lọ́dún 1656, wọ́n sọ ọ́ di àlùfáà, ìlú Ceylon ló sì ti kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ níbi tó ti kù díẹ̀ kí erin tẹ̀ ẹ́ pa. Lẹ́yìn náà ló tún lọ sìn nílẹ̀ Íńdíà, ó sì wà lára àwọn míṣọ́nnárì tó kọ́kọ́ wá sí lórílẹ̀-èdè náà àmọ́ tí wọ́n kì í ṣe ẹlẹ́sìn Kátólíìkì.

Ńṣe ni Almeida yí padà di ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì, orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe tirẹ̀ ló sì ti ń sìn. Nípa báyìí, ojú apẹ̀yìndà àti ọ̀dàlẹ̀ ni ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wò ó láwọn ìlú tó lọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Potogí. Nítorí pé kì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ tó bá ń bẹnu àtẹ́ lu ìwà ìbàjẹ́ àwọn àlùfáà tó sì máa ń tú àṣírí ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì, èyí tún ń fa gbọ́nmi-sí i-omi-ò-tó o lemọ́lemọ́ láàárín òun àtàwọn míṣọ́nnárì tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì. Ìjàngbọ̀n yìí dójú ẹ̀ lọ́dún 1661 nígbà tí Ilé Ẹjọ́ Ìjọ Kátólíìkì kan nílùú Goa, lórílẹ̀-èdè Íńdíà, dájọ́ ikú fún Almeida pé ó ń sọ ohun tó ta ko ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì. Nígbà tí kò sí níbẹ̀, wọ́n ṣe ère rẹ̀, wọ́n sì dáná sun ún. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni aṣojú ilẹ̀ Netherlands ní kí Almeida padà wá sí Batavia. Bóyá jíjẹ́ tí Almeida jẹ́ ẹni tó máa ń jiyàn ló mú kí aṣojú náà ṣe bẹ́ẹ̀.

Almeida kò fọwọ́ kékeré mú iṣẹ́ míṣọ́nnárì tó ń ṣe, àmọ́ kò gbàgbé pé ó yẹ kí Bíbélì wà lédè Potogí. Kódà, báwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ ìjọ kò ṣe mọ Bíbélì, tí èyí sì hàn kedere láàárín wọn, ló mú kó túbọ̀ múra sóhun tó ní lọ́kàn láti ṣe yìí. Nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ inú ìwé ìléwọ́ kan tí Almeida ṣe lọ́dún 1668, Ohun tó sọ nínú rẹ̀ fáwọn tó máa ka ìwé náà ni pé: “Mo nírètí . . . láìpẹ́ láti fi odindi Bíbélì ní èdè tiyín gangan dá a yín lọ́lá, èyí tá á jẹ́ ẹ̀bùn tó tóbi jù lọ àti ohun ìṣúra ṣíṣeyebíye jù lọ tí ẹnikẹ́ni kò tíì fún un yín rí.”

Almeida àti Ìgbìmọ̀ Tó Ń Yẹ Iṣẹ́ Rẹ̀ Wò

Lọ́dún 1676, Almeida mú èyí tó kẹ́yìn lára àwọn ẹ̀dà ìwé “Májẹ̀mú Tuntun” tó túmọ̀ fún ìgbìmọ̀ alákòóso Ṣọ́ọ̀ṣì Alátùn-únṣe ní Jakarta kí wọ́n lè ṣàyẹ̀wò rẹ̀. Àtìbẹ̀rẹ̀ ni àárín ọkùnrin atúmọ̀-èdè yìí àtàwọn tó ń ṣàyẹ̀wò iṣẹ́ rẹ̀ kò ti gún régé. Ọ̀gbẹ́ni J. L. Swellengrebel tó máa ń kọ ìtàn ìgbésí ayé àwọn èèyàn ṣàlàyé pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn tó ń ṣàyẹ̀wò iṣẹ́ Almeida kò lóye àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ tó lò àti ọ̀nà ìgbàkọ̀wé rẹ̀ nítorí pé èdè Dutch ni wọ́n ń sọ. Bákan náà ni àìgbọ́ra-ẹni-yé tún wà nípa irú èdè tó yẹ kí wọ́n lò. Ṣé èdè Potogí tí gbogbo èèyàn ń sọ ló yẹ kí wọ́n fi túmọ̀ Bíbélì ni àbí tàwọn ọ̀mọ̀wé pọ́ńbélé tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò ní lóye rẹ̀? Paríparí rẹ̀ ni pé, bí Almeida ṣe ń sapá láti rí i pé iṣẹ́ náà tètè parí tún máa ń fa ìjà láàárín wọn nígbà gbogbo.

Iṣẹ́ náà falẹ̀ gan-an, bóyá nítorí àríyànjiyàn tó máa ń wáyé tàbí nítorí pé àwọn tó ń yẹ iṣẹ́ náà wò kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ọ̀hún. Ọdún mẹ́rin lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn ayẹ̀wéwò yìí ṣì wà láwọn orí àkọ́kọ́ nínú ìwé Lúùkù, tí wọ́n ń jiyàn lé e lórí. Bí wọ́n ṣe ń fi iṣẹ́ yìí falẹ̀ bí Almeida nínú, ló bá fi ẹ̀dà kan iṣẹ́ rẹ̀ ránṣẹ́ sílẹ̀ Netherlands pé kí wọ́n bá òun tẹ̀ ẹ́ láìjẹ́ káwọn ayẹ̀wéwò náà mọ̀.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbìmọ̀ alákòóso ṣọ́ọ̀ṣì Alátùn-únṣe gbìyànjú láti má ṣe jẹ́ kí wọ́n tẹ Májẹ̀mú Tuntun tí Almeida túmọ̀ rẹ̀ yẹn jáde, síbẹ̀ ó di èyí tí wọ́n tẹ̀ jáde lọ́dún 1681 ní Amsterdam, ọdún tó tẹ̀ lé e làwọn ẹ̀dà tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ nínú rẹ̀ sì dé sí ìlú Batavia. Wo bínú Almeida ṣe bà jẹ́ tó nígbà tó rí i pé àwọn tó tún ṣàyẹ̀wò iṣẹ́ rẹ̀ nílẹ̀ Netherlands pàápàá ti yí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan padà nínú Bíbélì tó túmọ̀ náà! Nítorí pé àwọn ayẹ̀wéwò náà kò lóye èdè Potogí, Almeida rí i pé wọ́n ti lo “àwọn ọ̀rọ̀ tó lọ́ létí, tí kò bá béèyàn ṣe ń sọ̀rọ̀ mu, èyí tí kò jẹ́ kéèyàn lè lóye ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́.”

Inú ìjọba ilẹ̀ Netherlands pàápàá kò dùn sóhun tó ṣẹlẹ̀ yìí wọ́n sì pàṣẹ pé kí wọ́n lọ dáná sun gbogbo ìwé náà. Àmọ́ Almeida rọ àwọn aláṣẹ náà pé kí wọ́n fi díẹ̀ sílẹ̀, pé òun á fọwọ́ ṣàtúnṣe àwọn àṣìṣe tó burú jù nínú rẹ̀. Wọn yóò ṣì máa lo àwọn ẹ̀dà wọ̀nyí ná títí èyí tó máa ṣàtúnṣe rẹ̀ á fi jáde.

Àwọn ayẹ̀wéwò ní Batavia tún pàdé pọ̀ láti máa báṣẹ́ lọ lórí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe lórí àwọn ìwé tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù bí Almeida ti ń túmọ̀ wọn tán. Nítorí pé ẹ̀rù ń bà wọ́n pé ọkùnrin atúmọ̀-èdè yìí lè lọ yarí mọ́ wọn lọ́wọ́, ìgbìmọ̀ náà pinnu láti lọ kó àwọn ẹ̀dà tí wọ́n ti ṣe tán síbí tí wọ́n ń kówèé pamọ́ sí nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Ó dájú pé Almeida kò fara mọ́ ìpinnu wọn yìí.

Lákòókò yìí, ọ̀pọ̀ ọdún tí Almeida ti fi ṣiṣẹ́ àṣekára àti wàhálà ìgbésí ayé nílẹ̀ olóoru ti jẹ́ kó di aláìlera. Lọ́dún 1689, nítorí ara rẹ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ le mọ́, ó fi iṣẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀ kó bàa lè ráyè gbájú mọ́ iṣẹ́ títúmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ó bani nínú jẹ́ pé ó kú lọ́dún 1691 nígbà tó ń túmọ̀ orí tó kẹ́yìn nínú ìwé Ísíkíẹ́lì lọ́wọ́.

Wọ́n tẹ àtúnṣe kejì Májẹ̀mú Tuntun tí Almeida ṣe tán ní kété kó tó kù jáde lọ́dún 1693. Síbẹ̀, ó jọ pé iṣẹ́kíṣẹ́ làwọn ayẹ̀wéwò tí kò kúnjú ìwọ̀n ṣe síbẹ̀. Nínú ìwé tí ọ̀gbẹ́ni G. L. Santos Ferreira ṣe, tó pè ní Bíbélì Lédè Potogí, ó sọ pé: “Àwọn ayẹ̀wéwò náà . . . ṣe ìyípadà ńláǹlà sí iṣẹ́ ribiribi tí Almeida ṣe, wọ́n bà á jẹ́ nípa mímú ìwọ̀nba nǹkan dáadáa tó kù níbẹ̀ kúrò, ìyẹn èyí tó ṣèèṣì bọ́ lọ́wọ́ àwọn ayẹ̀wéwò àkọ́kọ́.”

Iṣẹ́ Parí Lórí Bíbélì Lédè Potogí

Nígbà tí Almeida kú, gbogbo ipá tó ń sà kí wọ́n lè tètè ṣàyẹ̀wò Bíbélì Lédè Potogí kí wọ́n sì tẹ̀ ẹ́ jáde dópin. Àjọ kan tó wà nílùú London Tó Ń Gbé Ẹ̀kọ́ Kristi Lárugẹ ló wá gbówó kalẹ̀ lọ́dún 1711 láti fi tẹ àtúnṣe kẹta Májẹ̀mú Tuntun tí Almeida túmọ̀. Àwọn míṣọ́nnárì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Denmark tí wọ́n ń sìn nílùú Tranquebar, tó wà ní gúúsù ilẹ̀ Íńdíà, ló sọ pé àwọn fẹ́ ṣe àtúnṣe náà.

Àjọ yìí pinnu láti ṣe iṣẹ́ ìwé títẹ̀ náà nílùú Tranquebar. Àmọ́ bí wọ́n ti ń lọ sílẹ̀ Íǹdíà, àwọn jàgùdà ọmọ ilẹ̀ Faransé fipá gba ọkọ̀ òkun tí wọ́n ń fi kó àwọn ohun èlò ìtẹ̀wé náà àtàwọn ẹrù Bíbélì èdè Potogí tí wọ́n fẹ́ lọ tẹ̀. Nígbà tó wá yá, wọ́n lọ gbé ọkọ̀ òkun náà jù sétíkun ìlú Rio de Janeiro, nílẹ̀ Brazil. Ọ̀gbẹ́ni Santos Ferreira kọ̀wé pé: “Fún ìdí kan tí ẹnikẹ́ni kò lè ṣàlàyé, àti nínú ipò tí ọ̀pọ̀ gbà pé ó jẹ́ iṣẹ́ ìyanu, wọ́n rí àwọn àpótí táwọn ohun èlò ìtẹ̀wé náà wà nínú rẹ̀ nísàlẹ̀ ibi tí wọ́n ń kẹ́rù sí nínú ọkọ̀ òkun náà láìsí ohunkóhun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn, ọkọ̀ òkun yìí náà ló sì tún gbé wọn dé ìlú Tranquebar.” Àwọn míṣọ́nnárì ọmọ ilẹ̀ Denmark yìí fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ṣàtúnṣe àwọn ìwé tó kù lára Bíbélì Almeida, wọ́n sì tẹ̀ ẹ́ jáde. Ọdún 1751 ni odindi Bíbélì lédè Potogí wá jáde, èyí sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́fà ọdún lẹ́yìn tí Almeida ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí atúmọ̀ Bíbélì.

Ohun Tó Ṣe Sílẹ̀ Kò Pa Run

Láti kùtùkùtù ìgbésí ayé Almeida ló ti rí i pé ó yẹ kí Bíbélì wà lédè Potogí, káwọn gbáàtúù èèyàn lè lóye òtítọ́ lédè tiwọn. Gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ ló sì fi gbájú mọ́ iṣẹ́ yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìjọ Kátólíìkì ta kò ó, tí àwọn tí wọ́n ń bá a ṣiṣẹ́ kò ka iṣẹ́ náà sí, tó tún rí ìṣòro tó dà bíi pé kò ní dópin lọ́dọ̀ àwọn tó ń yẹ ìwé rẹ̀ wò, àti àìlera tirẹ̀ fúnra rẹ̀, síbẹ̀ ìfaradà rẹ̀ lérè.

Ọ̀pọ̀ lára àwọn agbègbè tí wọ́n ti ń sọ èdè Potogí tí Almeida ti wàásù ti pòórá, kò sì fi bẹ́ẹ̀ sí èèyàn mọ́ nínú àwọn mìíràn lára wọn, síbẹ̀ Bíbélì rẹ̀ wà dòní olónìí. Ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì Ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Ti Ilẹ̀ Òkèèrè àti Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì Ti Ilẹ̀ Amẹ́ríkà pín ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀dà Bíbélì Almeida nílẹ̀ Potogí àti láwọn ìlú tó wà létíkun ilẹ̀ Brazil. Èyí ló fi jẹ́ pé àwọn Bíbélì tí wọ́n ti lo àwọn ọ̀rọ̀ tí Almeida lò níbẹ̀rẹ̀ ṣì wà lára àwọn Bíbélì táwọn èèyàn ń kà jù lọ tó sì wà lọ́wọ́ àwọn èèyàn jù lọ láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń sọ èdè Potogí.

Láìsí àní-àní, ọ̀pọ̀ èèyàn mọrírì iṣẹ́ táwọn atúmọ̀ Bíbélì ayé ọjọ́un bíi Almeida ṣe. Àmọ́ Jèhófà gan-an lẹni tó yẹ ká fọpẹ́ fún jù lọ, nítorí pé Ọlọ́run tó máa ń báni sọ̀rọ̀ ni, ẹni tó jẹ́ “ìfẹ́ rẹ̀ pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:3, 4) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, òun ni Ẹni tó pa Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́ tó sì jẹ́ ká ní i lọ́wọ́, ká lè jàǹfààní nínú rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká mọyì “ohun ìṣúra tó ṣeyebíye jù lọ” tó wá látọ̀dọ̀ Baba wa ọ̀run yìí, ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tọkàntara.

[Àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní ìdajì ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì gbé àwọn òfin tó le kalẹ̀ pé káwọn èèyàn má ṣe lo Bíbélì ní èdè ìbílẹ̀. Wọ́n tẹ ìwé kan jáde tí wọ́n pè ní Index of Forbidden Books, (Àwọn Ìwé Tá A Kà Léèwọ̀). Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ, ìwé yìí “mú kí iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì tí ìjọ Kátólíìkì ń ṣe dáwọ́ dúró pátápátá fún igba ọdún gbáko.”

b Àwọn ẹ̀dà Bíbélì Almeida tí wọ́n ti ṣe tipẹ́ pe Almeida ní Padre, ìyẹn Fadá, èyí sì mú káwọn kan gbà pé ó ti ṣe àlùfáà ìjọ Kátólíìkì rí. Àmọ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ Netherlands tó ṣàtúnṣe sí Bíbélì Almeida ló ṣàṣìṣe, wọ́n rò pé oyè táwọn pásítọ̀ tàbí òjíṣẹ́ máa ń lò ni.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

ORÚKỌ ỌLỌ́RUN

Àpẹẹrẹ pàtàkì kan tó fi hàn pé olóòótọ́ atúmọ̀ èdè ni Almeida ni bó ṣe lo Jèhófà láti túmọ̀ lẹ́tà Mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù.

[Credit Line]

Cortesia da Biblioteca da Igreja de Santa Catarina (Igreja dos Paulistas)

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 18]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÒKUN ÀTÌLÁŃTÍÌKÌ

PORTUGAL

Lisbon

Torre de Tavares

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Bí ìlú Batavia ṣe rí ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún

[Credit Line]

From Oud en Nieuw Oost-Indiën, Franciscus Valentijn, 1724

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]

Ojú ìwé tí wọ́n kọ àkọlé sí nínú “Májẹ̀mú Tuntun” tó kọ́kọ́ jáde lédè Potogí, ọdún 1681 ni wọ́n tẹ̀ ẹ́ jáde

[Credit Line]

Courtesy Biblioteca Nacional, Portugal

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́