“Kaaarọ O! Iwọ Ha Mọ Orukọ Ọlọrun Bi?”
NI Ẹ̀KA ọfiisi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Brazil, lẹta ti o tẹle e yii ni a rigba lati ọwọ́ awọn arabinrin ibeji ọlọdun 12 kan ni ilu Fortaleza:
“Lẹhin lọhun un ni 1990 nigba ti a wà ni ipele ẹkọ karun-un, ile-ẹkọ wa ṣeto ipatẹ imọ-ijinlẹ, ẹkọ nipa iṣẹ́-ọwọ́, ati ti ibilẹ. A ṣalaye fun olukọ naa pe a fẹ ki igbekalẹ wa jẹ eyi ti o yatọ si ohun ti awọn akẹkọọ miiran ń wewee lati murasilẹ. Niwọn bi oun ti gbọ ti a maa ń sọrọ nipa Jehofa ati Bibeli tẹlẹ, o dabaa pe: ‘Nigba naa ẹ lè kọwe nipa Ọlọrun yin!’
“A ri eleyii gẹgẹ bi anfaani lati funni ni ijẹrii kan a sì pinnu lati ṣe akopọ ìtẹ́fádá kan pẹlu iwe ikẹkọọ Bibeli eyi ti o kó afiyesi jọ sori orukọ Jehofa. A mura ẹ̀dà ti o tubọ tobi sii ti awọn ọ̀rọ̀ Orin Dafidi 83:18 silẹ a sì lẹ̀ ẹ́ mọ́ ara aworan Bibeli kan ti a ṣi silẹ. Bakan naa, a fi oniruuru awọn itumọ Bibeli ti o ni orukọ naa Jehofa ninu sori tabili. Ni ori tabili kan-naa, a pàtẹ oriṣiriṣi awọn iwe ikẹkọọ Bibeli. Ni opin tabili naa, a gbe Ẹ̀rọ ti ń gba aworan fidio ati apoti tẹlifiṣọn kan kalẹ lati fi apẹẹrẹ kan han awọn oluṣebẹwo nibi ti a ti lo orukọ naa Jehofa ninu sinima ti o lokiki kan.
“Nigba ipatẹ naa, nigba ti ẹnikan bá wá si idi tabili wa, awa yoo sọ pe: ‘Kaaarọ o! Iwọ ha mọ orukọ Ọlọrun bi?’ Lẹhin fifun oluṣebẹwo naa ni anfaani lati dahunpada, awa yoo maa baa lọ pe: ‘Wo ibi yii! Oniruuru awọn itumọ Bibeli fihàn pe orukọ rẹ̀ ni Jehofa,’ ni titọka si orukọ naa ninu oriṣiriṣi Bibeli, gẹgẹ bi ti João Ferreira de Almeida, The Jerusalem Bible, ati New World Translation. Lẹhin naa a o fi aworan fidio naa nibi ti oṣere ti o ṣe pataki ninu sinima naa ti tẹnumọ Jehofa gẹgẹ bi orukọ Ọlọrun hàn. Nigba ti awọn eniyan bá fi ọkàn-ìfẹ́ hàn, awa yoo fun wọn ni iwe-irohin tabi ìwé-àṣàrò-kúkúrú kan pẹlu awọn isọfunni sii.
“Ọ̀kan ninu awọn èwe naa ti o wá si idi tabili wa beere fun iwe naa Questions Young People Ask—Answers That Work. Olukọ wa ṣayẹwo iwe naa Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ o sì kigbe jade pe: ‘Wà-á-ò! Eyi ti jẹ́ iwe kan ti o fanimọra tó!’ Nigba ti yoo fi di opin ipatẹ naa, a ti fi iwe nla 7, ìwé-àsàrò-kúkúrú 18, ati iwe irohin 67 sode. A fun wa ni ipo kẹta nibi ipatẹ naa. Ṣugbọn leke gbogbo rẹ̀, inu wa dun jọjọ fun anfaani sisọ orukọ atọrunwa naa, Jehofa, di mímọ̀.”