Tábà ati Awujọ-alufaa
NI EYI ti o ju 115 ọdun lọ sẹhin, dokita iṣegun John Cowan kọ iwe kan ti o ni àkọlé naa The Use of Tobacco vs. Purity, Chastity and Sound Health. Ni oju-iwoye ohun ti a ti kọ nipa iyọrisi lilewu ti tábà ní awọn ọdun lọọlọọ, awọn akiyesi rẹ̀ lori lilo ti awọn alufaa ń lò ó jẹ eyi ti o jinlẹ ti o si jẹ eyi ti o ṣekoko fun ẹnikẹni ti o bá ń wa lati jọsin Ọlọrun lonii. Ni akori 4, ti o niiṣe pẹlu ipa oniwarere ti lilo tábà, Dokita Cowan sọ pe:
“Bi ilo tábà ba ṣaitọ lọna ti ara ìyára—gẹgẹ bi a ti fihàn ni kedere—ohun ti o pọndandan ni pe ó gbọdọ ṣaitọ lọna ti iwarere; nitori pe o jẹ ofin ẹkọ nipa iṣiṣẹ-ara-ẹda-alaaye pe ‘ohunkohun yoowu ti o bá ń ba ara jẹ́ tabi ń dabaru rẹ̀, nipa bayii ń ba eto-igbekalẹ iṣan imọlara jẹ́, ati nipa rẹ̀ ọpọlọ, ati nipa bẹẹ ọkàn.’ Ọkàn ẹnikan—awọn èrò rẹ̀, awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, awọn iṣe rẹ̀, ni a ń nipa lé lori ni ọ̀nà ti oun gba ń lo tabi ba ìwàsí rẹ̀ nipa ti ara ìyára jẹ́. Tábà, ni orukọ ti ń jẹ́ gan-an ati lapapọ jẹ́ ẹlẹgbin, ati pe—lai ka ipalara ti o ń ṣe si—bawo ni awọn imọlara ati igbegbeesẹ ti o mọ́ tonitoni, ti o mọ́ gaara, ti o bojumu, ti o sì jẹ ti oniwarere ṣe lè pilẹṣẹ tabi jẹ jade ninu ọkàn. Bi ẹnikan bá ń ronuwoye—bi iru nǹkan bẹẹ bá jẹ́ eyi ti a lè ronuwoye—pe Kristi, nigba ti o ń gbe igbesi-aye awofiṣapẹẹrẹ Rẹ̀ lori ilẹ̀-ayé—ni kikọni ati wiwaasu imọgaara, aileeeri, ifẹ ati ìyọ́nú—bá mu tábà, fín aáṣáà simu tabi jẹ tábà. Ero yii gan-an kò ha dún bi alailọwọ fun ibi mimọ bi? Sibẹ awọn iranṣẹ—awọn ọmọlẹhin, awọn oniwaasu, ati awọn alalaye awọn ofin ati ẹkọ isin Rẹ́—ń sọ ara wọn di ẹlẹgbin wọn sì ń sọ ọkàn wọn di alábàwọ́n pẹlu eweko ẹlẹgbin, ati onimajele naa. Ǹjẹ́ iru awọn ọkunrin bẹẹ, tabi awọn ọmọlẹhin wọn ha ń gbe igbesi-aye ti o jọ ti Kristi—igbesi-aye oniwarere giga bi? Emi kò rò bẹẹ.
“Gbiyanju, bi o bá lè ṣe bẹẹ lati ronu nipa alajẹki kan, oku ọ̀mùtí kan, tabi alotábà kan, ni isopọ pẹlu ijẹmimọ ọkan-aya? Ohun kan wà ti o jẹ alaiba iwa ẹ̀dá mu, amunitakiji, akoni ni irira ninu isopọ naa. Gan-an bi o ti jẹ́ pe ìdálọ́rùn ti inú ara ati ọgbọ́n làákàyè ti o lè farahan lode ara ní ń bajẹ, bẹẹ ni ẹni ti a jẹ́ ni inu lọhun-un, iṣẹda ti iwarere, ń di eyi ti o buru jáì sii. Ẹmi mimọgaara kì yoo, kò sì lè, gbé ninu ibugbe ẹlẹ́gbin. Iṣọkan lọna ti iṣẹda wà laaarin awọn ohun ti ara ati ti ẹmi, ki o baa lè jẹ́ pe awọn animọ ọ̀kan ń tọka si iwa ekeji. Ọjọgbọn isin kan ati ẹrú tábà . . . Oun lè gbà, ninu gbogbo aiṣẹtan ati iṣotitọ, pe lilo tábà jẹ aṣa aṣekupani, eyi ti o ṣaitọ lọna ti iwarere; sibẹ o lè rí isunniṣe kan ninu lọhun-un, ofin awọn ẹya ara rẹ̀, ti o mujade lọna atọwọda, eyi ti ń sún un pẹlu awọn ikundun ti kò ṣetẹlọrun lati maa ba aṣa naa lọ, ofin atọwọda yii sì lè di eyi ti o tubọ lagbara ju apapọ ironu rẹ̀ lọna ti ẹda ati ẹ̀rí-ọkàn lapapọ. Lilo tábà kìí ha ṣe imọọmọ tàpá si ọ̀kan ninu awọn ofin Ọlọrun ti a fi sinu iṣetojọ ara wa bi? Riru eyikeyii ninu awọn ofin Ọlọrun kìí ha ṣe irekọja ati ẹṣẹ bi? Bi ọkunrin kan ba si ń gbe igbesi-aye lọna aṣa ni rírú ọ̀kan ninu awọn ofin Ọlọrun, iyipada naa kì yoo ha rọrun ki o si jẹ lọna adanida si riru awọn ofin miiran bi? Ati ni paripari rẹ̀, bawo ni a ṣe lè ka ọkunrin kan si olukọ iwarere, ẹni ti, ninu iwa tirẹ funraarẹ, ń júwe igbesi-aye hihuwa lemọlemọ lodisi ofin iwa ẹda funraarẹ fun awọn ẹda ẹlẹgbẹ rẹ̀?”