ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 4/22 ojú ìwé 15-27
  • Tábà Tí Kò Ní Èéfín Ó Ha Léwu Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Tábà Tí Kò Ní Èéfín Ó Ha Léwu Bí?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọ́n Ń Dáhùn Padà
  • Ìròyìn Ìbànújẹ́
  • Ó Ti Di Bárakú!
  • Lo Làákàyè
  • Múra Sílẹ̀ De Ìṣòro
    Jí!—2010
  • Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Láti Jáwọ́ Nínú Sìgá Mímu?
    Jí!—2000
  • Iná Mọ́ Àwọn Ilé Iṣẹ́ Tábà
    Jí!—1996
  • Tí mo bá ń mu sìgá tàbí àwọn nǹkan tí wọ́n fi tábà ṣe ǹjẹ́ ó tiẹ̀ kan Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 4/22 ojú ìwé 15-27

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Tábà Tí Kò Ní Èéfín Ó Ha Léwu Bí?

‘NÍGBÀ tí Cord, ọmọ ọdún 13 kó lọ sí àárín gbùngbùn ìhà ìwọ̀ oòrùn United States, kò pẹ́ tí ó fi mọ̀ pé òun kò mú ohun èèlò kan tí ó jẹ́ kòseémánìí fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ọkùnrin tí wọ́n wà ní ìpele ẹ̀kọ́ kẹjọ dání: agolo áṣáà, irú ẹ̀ya tábà kan tí kò ní èéfín. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tuntun ni wọ́n jẹ́ “amu-únṣáà,” tàbí afín-ínṣáà, Cord sì fẹ́ bẹ́gbẹ́ mu. Nítorí náà, nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fi ìdì áṣáà kan lọ̀ ọ́, ó gbà á, ó sì fi áṣáà díẹ̀ sáàárín ètè rẹ̀ ìsàlẹ̀ àti èrìgì rẹ̀ tẹtẹrẹ bí àwọn ọ̀mu ṣe máa ń ṣe.’—Ìwé ìròyìn Listen.

Ọ̀ràn náà kò mọ sórí Cord tí ó jẹ́ ọ̀dọ́ nìkan. Dókítà Christopher A. Squier, tí ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nípa kòkòrò ẹnu, sọ pé iye tí ń pọ̀ sí i lára àwọn èwe ọkùnrin ní ń bẹ̀rẹ̀ áṣáà mímu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iye tábà tí kò ní èéfín tí wọ́n ń tà ní apá ìparí àwọn ọdún 1980 ń lọ sílẹ̀, Dókítà Squier sọ pé, “lílò tí àwọn ènìyàn ń lo áásà tútù tún ti ń lọ sókè.”a Fún àpẹẹrẹ, àwọn olùṣèwádìí ròyìn pé, ìdá 1 nínú 5 lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin ní United States àti ìdá 1 nínú 3 lára àwọn ọkùnrin màjèṣín ní Sweden—àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọ̀dọ́—ní ń lo tábà tí kò ní èéfín báyìí. Èé ṣe tí èyí fi ń ṣẹlẹ̀?

“Ó láàbò ju mímu sìgá lọ.” “Kò sí ẹ̀rí tí ó lè fi hàn pé ó léwu.” “Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń lò ó. Kì í sì í ṣe ohun kankan fún wọn.” “Mímu díẹ̀ lóòrèkóòrè kò lè pa mi lára.” “Kò sí ẹni tí ó pa rí.” Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Ẹgbẹ́ Ìgbógunti Àrùn Jẹjẹrẹ ti America sọ, àwọn ìdí díẹ̀ tí àwọn ọ̀dọ́ máa ń sọ pé ó ń fà á tí àwọ́n fi ń yíjú sí tábà tí kò ní èéfín nìyí.

Kí ló mú kí àwọn ọ̀dọ́ ronú pé mímu-únṣà kò léwu bíi mímu sìgá? Bí ọ̀ràn ti rí ha nìyẹn bí?

Wọ́n Ń Dáhùn Padà

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ilé iṣẹ́ tábà alágbára ti rọ̀jò ìpolówó ọjà tí ń fi hàn pé tábà tí kò ní èéfín kò léwu gan-an bí ṣingọ́ọ̀mù kò ṣe léwu, àti pé ó jẹ́ kòṣeémánìí bíi bàtà tẹníìsì tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde, sórí àwọn èwe. Àwọn àkọlé bíi “Gba ìdì áṣáà kan, dípò kí o gbá èéfín mọ́rí,” “Mò ń gbádùn tábà gan-an láìtanná ran nǹkan kan,” àti “Ṣínkínní ti tó” ń dọ́gbọ́n sọ fún àwọn èwe pé lílo áṣáà dára ju mímu sìgá lọ.

Lẹ́yìn tí wọ́n tí fòfin de irú àwọn àkọlé bẹ́ẹ̀ lórí tẹlifíṣọ̀n àti rédíò ní United States, ilé iṣẹ́ tábà bẹ̀rẹ̀ síí polówó ọjà wọn kíkan kíkan nínú àwọn ìwé ìròyìn. Àwọn àwòrán tí ń dán tí ń ṣàfihàn àwọn jagunlabí tí wọ́n síngbọnlẹ̀, tí wọ́n ń gbádùn ṣíṣọdẹ ẹran, tí wọ́n ń pọ́nkè, tí wọ́n sì ń tukọ̀ lórí ibi tí omi ti ń ya wùúwùú—wọ́n lè fi tábà há àpò ẹ̀yìn wọn lọ́nà tí ènìyàn fi lè rí i dáradára—sọ ọ̀rọ̀ tí ó jákè tí ó sì ṣe kedere pé: “Tábà tí kò ní èéfín dára, ó jẹ́ àdánidá, ó sì ń jẹ́ kí ènìyàn di ọkùnrin!”

Ìròyìn olórí dókítà oníṣẹ́ abẹ United States ti ọdún 1994, tí ó ní àkọlé náà, Preventing Tobacco Use Among Young People, sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló gbà gbọ́ pé “àwọn ohun èèlò tábà tí kò ní èéfín kò léwu, wọ́n sì gbayì láwùjọ.” Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fi hàn pé “nǹkan bí ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga tí wọ́n ṣì wà ní ìpele ẹ̀kọ́ tí ó rẹlẹ̀ tí ń lò ó àti ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga tí wọ́n wà ní ìpele ẹ̀kọ́ gíga tí ń lò ó ló gbà gbọ́ pé kò sí ewu kankan nínú lílo tábà tí kò ní èéfín déédéé, tàbí kí ó jẹ́ pé kìkì ewu díẹ̀ ló wà níbẹ̀.” Àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga tí ń lò ó tí wọ́n tilẹ̀ mọ̀ pé tábà tí kò ní èéfín lè léwu pàápàá “kò rò pé ewu rẹ̀ pọ̀.” Ìpolówó ọjà náà ń ṣiṣẹ́. Àmọ́ àwọn ìpolówó ọjà náà ha jẹ́ òtítọ́ bí?

Òwe Bibeli kan sọ pé, “òpè ènìyàn gba ọ̀rọ̀ gbogbo gbọ́: ṣùgbọ́n amòye ènìyàn wo ọ̀nà ara rẹ̀ rere.” Tàbí bí òwe mìíràn ti sọ ọ́ pé: ‘Gbogbo amòye ènìyàn ní ń fi ìmọ̀ ṣiṣẹ́.’ (Owe 13:16; 14:15) Nígbà náà, kí ni àwọn òkodoro ọ̀rọ̀ fi hàn nípa tábà tí kò ní èéfín?

Ìròyìn Ìbànújẹ́

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìpolówó ọjà máa ń fi hàn pé mímu tábà tí kò ní èéfín yóò jẹ́ kí o gbayì láwùjọ, àti pé kò léwu fún ara rẹ, òkodoro ọ̀rọ̀ fi òdì kejì rẹ̀ hàn. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, lílo tábà tí kò ní èéfín kò ní jẹ́ kí o dára ju bí o ṣe rí lọ. Bí o kò bá gbà á gbọ́, fi ahọ́n rẹ taari ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ kí o sì wo dígí. “Ṣe fún-wọn-tán ni”? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Bí ó sì ti máa ń jẹ́ kí o rí nìyẹn! Ohun tí ó tilẹ̀ wá ń ṣe fún ọ nínú burú ju èyíinì lọ.

Fún àpẹẹrẹ, ètè àwọn tí ń jẹ tábà tàbí tí wọ́n ń mu ún déédéé lè bẹ́, kí eyín wọn dúdú, kí ẹnu wọn máa rùn, kí èrìgì sì máa dùn wọ́n—kì í ṣe ohun tíí múni fẹyín síta. Ní àfikún, agbára ìtọ́wò àti ìgbóòórùn wọn máa ń lọ sílẹ̀, nígbà tí ó sì jẹ́ pé ìlùkìkì ọkàn wọn máa ń lọ sókè tí ẹ̀jẹ̀ wọn sì máa ń ru—ìròyìn ìbànújẹ́ gbáà ni. Bí ó ti wù kí ó rí, ìròyìn tí ó báni nínú jẹ́ jù lọ ni pé ìwádìí tí wọ́n ṣe ní ilẹ̀ Europe, India, àti ní United States fi hàn pé tábà tí kò ní èéfín máa ń fa àrùn jẹjẹrẹ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́, èrìgì, àti ọ̀nà ọ̀fun. Àwọn àwárí yìí kò ya àwọn ògbógi lẹ́nu. Ìwádìí kan sọ pé: “Áṣáà ló ní ìwọ̀n èròjà tí ń fa àrùn jẹjẹrẹ jù lọ nínú gbogbo àwọn nǹkan tí à ń fà sínú ara.” Abájọ “tí ó fi ṣeé ṣe kí àwọn tí ó ti pẹ́ tí wọ́n ti ń lo áṣáà ní àrùn jẹjẹrẹ ẹnu ní ìlọ́po méjì ju àwọn tí kì í lò ó lọ.”

Nígbà ti àrùn jẹjẹrẹ ẹnu bá wọ̀ ọ́, àbáyọrí rẹ̀ kì í dára. Kì í ṣe kìkì pé ara ẹni tí ń lò ó náà kò ní le mọ́ ni, àmọ́ ẹ̀mí rẹ̀ kò ní gùn pẹ̀lú. Ìtẹ̀jáde kan láti ọ̀dọ̀ Ẹgbẹ́ Ìgbógunti Àrùn Jẹjẹrẹ ti America sọ ìtàn bíbani nínú jẹ́ yìí pé: ‘Sean bẹ̀rẹ̀ sí í lo tábà tí kò ní èéfín nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún 13. Ó ronú pé kò léwu tó sìgá mímu. Lẹ́yìn ọdún márùn-ún tí ó ti ń mu tábà agolo kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lójúmọ́, ọgbẹ́ kan jáde lórí ahọ́n rẹ̀. Àrùn jẹjẹrẹ ẹnu ni. Àwọn dókítà gé díẹ̀ lára ahọ́n rẹ̀ kúrò, àmọ́ jẹjẹrẹ náà ràn dé ọrùn rẹ̀. Wọ́n tún ṣe iṣẹ́ abẹ tí ó tilẹ̀ wá jẹ́ kí wọ́n tún gé púpọ̀ lára rẹ̀, ṣùgbọ́n pàbó ló já sí—ó kú nígbà tí ó pé ọmọ ọdún 19. Kí Sean tóó kú, ó kọ ọ̀rọ̀ ṣókí kan sórí abala ìdì ìwé kan pé: “Má ṣe mu áṣáà.”’

Ó Ti Di Bárakú!

Lẹ́yìn tí Cord, tí ó jẹ́ ọ̀dọ́, tí a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀, kà nípa ìròyìn apániláyà yìí nípa Sean, ọ̀rọ̀ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ wá kó sí i lọ́pọlọ. Ó pinnu láti pa á tì. Bí ó ti wù kí ó rí, kò rọrùn láti pa á tì. Cord sọ fún ìwé ìròyìn Listen pé: “Ó ń ṣe mí bíi pé kí n ṣáà mu ún. Àní nísinsìnyí pàápàá, tí ọ̀pọ̀ oṣù tí kọjá lọ lẹ́yìn tí mo sọ pé mo pa á tì, mo ṣì máa ń rí i tí mò ń fọwọ́ rú àpò mi wò láti wá ìdì tábà mi. Mò ń jẹ ọ̀pọ̀ ṣingọ́ọ̀mù. Ìyẹ́n ń ràn mí lọ́wọ́, àmọ́, kò sọ pé kí ọkàn mi má fà sí i.”

Ìwé ìròyìn Ca-A Cancer Journal for Clinicians jẹ́rìí sí i pé: “Nínú ìwádìí tí a ṣe nípa àwọn èwe tí wọ́n ń gbìyànjú láti pa lílo tábà tí kò ní èéfín tì, kìkì ìpín díẹ̀ nínú ọgọ́rùn-ún ló lè ṣe bẹ́ẹ̀.” Bí ó ti wù kí ó rí, kí ló jẹ́ kí ó le tó bẹ́ẹ̀ láti pa tábà tí kò ní èéfín tì? Oògùn líle kan náà tí ó mú kí pípa sìgá mímu tì le gan-an ni: oró nicotine.

Oró nicotine, oògùn líle tí ó máa ń wà nínú sìgá àti nínú tábà tí kò ní èéfín, jẹ́ májèlé olóró tí ó máa ń mú kí ẹni tí ń lò ó ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́. Tí ó bá ti tó nǹkan bí 30 ìṣẹ́jú, ẹni tí ó lò ó náà gbọ́dọ̀ tọ́ áṣáà díẹ̀ míràn sẹ́nu kí ìmọ̀lára náà má baà tán níbẹ̀. Oró nicotine máa ń di bárakú fún ọ. Ó máa ń di bárakú fún àwọn kan tí ń lò ó débi pé, áṣáà ṣínkínní máa ń wà lẹ́nu wọn lọ́sàn-án àti lóru—tí wọ́n bá tilẹ̀ ń sùn pàápàá.

Ní òdì kejì sí ohun tí àwọn ọ̀dọ́ lè rò, mímu áṣáà kò dín ìwọ̀n oró nicotine tí ń wọnú ara kù. Agolo kan tábà tí kò ní èéfín lójúmọ́ ń jẹ́ kí oró nicotine tí ó pọ̀ tó ti 60 sìgá wọnú ara! Ìwé ìròyìn Preventing Tobacco Use Among Young People sọ pé: ‘Àwọn tí ń mu tábà tí kò ní èéfín’ ń fa, ó kéré tán, oró nicotine tí ó pọ̀ tó èyí tí ẹni tí ń mu sìgá ń fà—bóyá tí ó tilẹ̀ fi ìlọ́po méjì jù ú lọ pàápàá.’ (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Yàtọ̀ sí oró nicotine, tábà tí kò ní èéfín ní ọ̀pọ̀ oró nitrosamine (èròjà alágbára tí ń fa àrùn jẹjẹrẹ) ní ìlọ́po mẹ́wàá ju sìgá lọ.

Lo Làákàyè

Dókítà Roy Sessions, tí ó jẹ́ oníṣẹ́ abẹ orí àti ọrùn, sọ pé: “Kò sí àní-àní pé àwọn èròjà wọ̀nyí léwu. Wọ́n máa ń jẹ́ kí ènìyàn nímọ̀lára òmìnira ọkàn tí ọ̀pọ̀ ènìyàn rò pé ó nira láti dáwọ́ rẹ̀ dúró ju sìgá mímu lọ.” Ògbógi kan nípa àrùn jẹjẹrẹ ẹnu, Dókítà Oscar Guerra, parí ọ̀rọ̀ nípa sísọ pé: “Ara kò tilẹ̀ fẹ́ràn kiní ọ̀hún rárá ni.” Àwọn ògbógi káàkiri àgbáyé gbà pẹ̀lú rẹ̀ pé: Mímu áṣáà ju wàhálà ṣínkínní kan lásán lọ. Ó lè fín ọ tán!

Àwọn èwe Kristian tilẹ̀ wá ni ìdí tí ó lágbára lórí wọn ju ti ìdàníyàn nípa ìlera lọ láti yẹra fún àwọn ohun tí a fi tábà ṣe—ìfẹ́ ọkàn wọn láti mú inú Jehofa Ọlọrun dùn. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pa á láṣẹ pé: “Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò ninu gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran-ara ati ti ẹ̀mí, kí a máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé ninu ìbẹ̀rù Ọlọrun.”—2 Korinti 7:1.

Ìwé ìròyìn Aviation, Space, and Environmental Medicine parí ọ̀rọ̀ náà dáradára, ní sísọ pé: “Tábà jẹ́ ewéko tí ń rinni lọ́kàn tí ó jẹ́ pé kìkì àwọn ẹ̀dá méjì ní ń jẹ ẹ́—kòkòrò tọọrọ kékeré, aláwọ̀ ewé àti ènìyàn. Kòkòrò tọọrọ aláwọ̀ ewé náà kò kúkú mọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

Àmọ́ ìwọ́ mọ̀. Nítorí náà, lo làákàyè—má bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Oríṣi tábà méjì tí kò ní èéfín ló wọ́pọ̀: áṣáà àti tábà jíjẹ. Áásà gbígbẹ àti tútù wà. Láàárín àwọn ọ̀dọ́, áṣáà tútù—tí wọ́n lọ̀ kúnná, tí wọ́n sì fi àwọn àádùn, àwọn nǹkan atasánsán, àti àwọn òórùn dídùn sí, tí ó máa ń wà nínú agolo tàbí nínú ìdì tí ó dà bíi ti tíì—ni oríṣi tábà tí kò ní èéfín tí ó gbajúmọ̀ jù lọ. “Mímu-únṣà” túmọ̀ sí fífi ìwọ̀n díẹ̀—ìwọ̀nba áṣáà tí ó máa ń wà láàárín àtàǹpàkò àti ìka ìlábẹ̀—sáàárín ètè tàbí ẹ̀rẹ̀kẹ́ àti èrìgì.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]

‘Kí Sean tóó kú, ó kọ ọ̀rọ̀ ṣókí kan sílẹ̀: “Má ṣe mu áṣáà”’

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Jíjẹ tábà ti wá di ohun tí ó gbajúmọ̀ láàárín àwọn èwe. Ó ha yẹ kí o dán an wò bí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́