ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 7/1 ojú ìwé 8-13
  • Lórí Tábìlì Wo Ni Ìwọ Ti Ń Jẹun?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lórí Tábìlì Wo Ni Ìwọ Ti Ń Jẹun?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Yíyẹra fún “Tábìlì Àwọn Ẹ̀mí-Èṣù”
  • ‘Olùṣòtítọ́ Ẹrú’ Ni Ó Ń Gbóúnjẹ Sórí Tábìlì Jehofa
  • Ṣọ́ra fún Oúnjẹ Onímájèlé tí Ń Bẹ Lórí Tábìlì Àwọn Ẹ̀mí-Èṣù
  • Tábìlì Jehofa Nìkanṣoṣo Ni Yóò Dúró
  • Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2024
  • Agbára Jésù Ju Ti Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Lọ
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Ní Ìdojú Ìjà Kọ Ẹ̀kọ́ Àwọn Ẹ̀mí Èṣù
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Kí La Lè Ṣe Táwọn Ẹ̀mí Èṣù Ò Fi Ní Lè Borí wa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 7/1 ojú ìwé 8-13

Lórí Tábìlì Wo Ni Ìwọ Ti Ń Jẹun?

“Ẹ̀yin kò lè máa ṣalábàápín ‘tábìlì Jehofa’ ati tábìlì awọn ẹ̀mí-èṣù.” ​—⁠1 KORINTI 10:⁠21, NW.

1. Àwọn tábìlì wo ni a gbékalẹ̀ níwájú wa, ìkìlọ̀ wo sì ni aposteli Paulu fúnni nípa wọn?

ÀWỌN ọ̀rọ̀ onímìísí ti aposteli Paulu wọ̀nyí fihàn pé àwọn tábìlì ìṣàpẹẹrẹ méjì ni a gbékalẹ̀ níwájú aráyé. Tábìlì kọ̀ọ̀kan ni a ń dámọ̀ nípasẹ̀ oúnjẹ ìṣàpẹẹrẹ tí a bá gbékarí rẹ̀, gbogbo wa sì ń jẹun lórí ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì. Bí ó ti wù kí ó rí, bí a bá fẹ́ láti mú inú Ọlọrun dùn, a kò lè máa jẹun lórí tábìlì rẹ̀ kí a sì tún máa bu oúnjẹ jẹ lórí tábìlì àwọn ẹ̀mí-èṣù. Aposteli Paulu kìlọ̀ pé: “Awọn nǹkan tí awọn orílẹ̀-èdè fi ń rúbọ wọ́n fi ń rúbọ sí awọn ẹ̀mí-èṣù, kì í sì í ṣe sí Ọlọrun; emi kò sì fẹ́ kí ẹ̀yin di alájọpín pẹlu awọn ẹ̀mí-èṣù. Ẹ̀yin kò lè máa mu ife Jehofa ati ife awọn ẹ̀mí-èṣù; ẹ̀yin kò lè máa ṣalábàápín ‘tábìlì Jehofa’ ati tábìlì awọn ẹ̀mí-èṣù.”​—⁠1 Korinti 10:​20, 21, NW.

2. (a) Tábìlì Jehofa wo ni ó wà ní ọjọ́ àwọn ọmọ Israeli ìgbàanì, àwọn wo ni wọ́n sì ń ṣàjọpín nínú àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ náà? (b) Kí ni ṣíṣalábàápín tábìlì Jehofa túmọ̀sí lónìí?

2 Àwọn ọ̀rọ̀ Paulu rán wa létí àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ tí àwọn ọmọ Israeli ìgbàanì rú lábẹ́ Òfin Jehofa. Pẹpẹ Ọlọrun ni a pè ní tábìlì, ẹni náà tí ó sì ń mú ẹran wá láti fi ṣèrúbọ ni a ń sọ pé ó ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú Jehofa àti pẹ̀lú àwọn àlùfáà. Báwo? Èkínní, Jehofa ṣàjọpín nínú ẹbọ náà nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni a ń wọ́n sórí pẹpẹ rẹ̀, ọwọ́-iná tí ó wà nísàlẹ̀ ni ó sì ń jó ọ̀rá. Èkejì, àlùfáà ń ṣàjọpín níti pé òun (àti ìdílé rẹ̀) ń jẹ igẹ̀ díndín àti ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹran náà tí a fi rúbọ. Àti ẹ̀kẹta, olùṣèrúbọ náà ń ṣàjọpín nípa jíjẹ èyí tí ó bá ṣẹ́kù lára rẹ̀. (Lefitiku 7:​11-⁠36) Lónìí, ṣíṣalábàápín tábìlì Jehofa túmọ̀sí pé a ń fi irú ìjọsìn kan tí òun lẹ́tọ̀ọ́sí fún un, gẹ́gẹ́ bí Jesu àti àwọn aposteli rẹ̀ ti fi àpẹẹrẹ rẹ̀ lélẹ̀. Láti ṣe èyí, a gbọ́dọ̀ jẹun nípa tẹ̀mí láti inú ohun tí Jehofa bá pèsè nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ àti ètò-àjọ rẹ̀. Àwọn ọmọ Israeli, tí wọ́n gbádùn àkànṣe ìdàpọ̀ pẹ̀lú Jehofa nídìí tábìlì rẹ̀, ni a kà á léèwọ̀ fún láti máṣe rúbọ sí àwọn ẹ̀mí-èṣù nídìí tábìlì wọn. Israeli tẹ̀mí àti “àwọn àgùtàn mìíràn” tí wọ́n jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn wà lábẹ́ ìkàléèwọ̀ àtọ̀runwá kan náà.​—⁠Johannu 10:⁠16.

3. Báwo ni ẹnìkan ṣe lè jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ṣíṣalábàápín tábìlì àwọn ẹ̀mí-èṣù ní ọjọ́ wa?

3 Báwo ni ẹnìkan ṣe lè jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ṣíṣalábàápín tábìlì àwọn ẹ̀mí-èṣù ní ọjọ́ wa? Nípa ṣíṣiṣẹ́sìn fún ire ohunkóhun tí ó wà ní ìlòdìsí Jehofa. Tábìlì àwọn ẹ̀mí-èṣù wémọ́ gbogbo ìgbékèéyíde ẹlẹ́mìí eṣu, tí a ṣètò láti ṣì wá lọ́nà àti láti darí wa kúrò lọ́dọ̀ Jehofa. Ta ni yóò fẹ́ láti fi irú májèlé bẹ́ẹ̀ bọ́ ọkàn-àyà àti iyè-inú rẹ̀? Àwọn Kristian tòótọ́ kọ̀ láti ṣàjọpín nínú àwọn ẹbọ tí ọ̀pọ̀ jùlọ ènìyàn lónìí ń rú sí àwọn ọlọrun ogun àti ọrọ̀.​—⁠Matteu 6:⁠24.

Yíyẹra fún “Tábìlì Àwọn Ẹ̀mí-Èṣù”

4. Ìbéèrè wo ni gbogbo wa dojúkọ, èésìtiṣe tí àwa kì yóò mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ láti ṣalábàápín tábìlì àwọn ẹ̀mí-èṣù?

4 Ìbéèrè náà tí gbogbo wa dojúkọ ni, Lórí tábìlì wo ní èmi ti ń jẹun? Àwa kò lè bọ́ lọ́wọ́ òtítọ́ náà pé ó jẹ́ ohun àìgbọ́dọ̀máṣe fún wa láti jẹun lórí tábìlì kan tàbí èkejì. (Fiwé Matteu 12:30.) Àwa kì yóò mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ láti máa ṣalábàápín tábìlì àwọn ẹ̀mí-èṣù. Láti ṣe ìyẹn yóò mú kí a pàdánù ojúrere Ọlọrun òtítọ́ àti alààyè kanṣoṣo náà, Jehofa. Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, láti ṣalábàápín oúnjẹ lórí tábìlì Jehofa nìkanṣoṣo yóò ṣamọ̀nà wa lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayọ̀! (Johannu 17:⁠3) Wọn a máa pa á lówe pé irú oúnjẹ ni irú ènìyàn. Nígbà náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti pa ìlera ti ara àti ti èrò-orí dídára mọ́ níláti kíyèsí ètò oúnjẹ rẹ̀. Gan-⁠an bí ó ti jẹ́ pé pàrùpárù oúnjẹ tí ó kún fún ọ̀rá kò ti lè pakún ìlera ti ara tí ń báa lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a pèsè rẹ̀ lọ́nà tí ó ládùn pẹ̀lú àwọn èròjà egbòogi, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ìgbékèéyíde ayé yìí tí a múládùn pẹ̀lú àwọn èrò ẹlẹ́mìí eṣu jẹ́ pàrùpárù oúnjẹ ìṣàpẹẹrẹ tí yóò sọ ọkàn wa dìbàjẹ́.

5. Báwo ni a ṣe lè yẹra fún gbígba ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí-èṣù sínú lónìí?

5 Aposteli Paulu sọtẹ́lẹ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, a óò mú àwọn ènìyàn ṣáko lọ nípasẹ̀ “ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí-èṣù.” (1 Timoteu 4:⁠1) Kìí ṣe pé a ń rí irúfẹ́ ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí-èṣù bẹ́ẹ̀ nínú èrò ìgbàgbọ́ ìsìn èké nìkan ni ṣùgbọ́n wọ́n tún ń tàn án kálẹ̀ ní àwọn ọ̀nà mìíràn pẹ̀lú. Fún àpẹẹrẹ, ó yẹ kí a ṣàyẹ̀wò kí a sì gbé àwọn ìwé àti ìwé ìròyìn tí àwa àti àwọn ọmọ wa ń kà, àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹlifíṣọ̀n tí a ń wò, àti irú àwọn eré àti àwòrán sinimá tí a ń wò karí ìwọ̀n. (Owe 14:15) Bí a bá ń ka àwọn ìtàn àròsọ fún eré ìtura, ó ha ń gbé àwọn ìwà-ipá tí kò mọ́gbọ́ndání, ìbálòpọ̀ tí kò tọ́ sófin, tàbí ṣíṣe àwọn ohun ìjìnlẹ̀ awo jáde bí? Bí a bá ń ka àwọn ìwé tí kìí ṣe ìtàn àròsọ kí a baà lè kẹ́kọ̀ọ́, ó ha ń ṣe ìgbéjáde ọgbọ́n ìmọ̀ ọ̀ràn tàbí ọ̀nà ìgbésí-ayé kan “tí kìí ṣe bíi ti Kristi”? (Kolosse 2:⁠8) Ó ha ṣe ìgbékalẹ̀ àwọn àbá-ìméfò asán bí, tàbí lílọ́wọ́ nínú àwọn àjọ ìgbòkègbodò ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà ti ayé ni a gbẹnusọ fún? Ó ha ń mú ìpinnu náà láti di ọlọ́rọ̀ jaburata dàgbà bí? (1 Timoteu 6:⁠9) Ó ha jẹ́ ìtẹ̀jáde kan tí ń fi ọgbọ́n àyínìke gbé àwọn ẹ̀kọ́ apínniníyà tí wọn kò dàbí ti Kristi kalẹ̀ bí? Bí ìdáhùn náà bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ni tí a sì ń báa lọ láti máa kà tàbí láti máa wo irú àwọn àkójọpọ̀-ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, a ń fi ara wewu jíjẹun lórí tábìlì àwọn ẹ̀mí-èṣù. Lónìí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìtẹ̀jáde ní ń bẹ tí ń gbé àwọn ọgbọ́n ìmọ̀ ọ̀ràn ayé tí ó dàbí èyí tí ń lanilóye tí ó sì bágbàmu lárugẹ. (Oniwasu 12:12) Ṣùgbọ́n kò sí èyíkéyìí nínú àwọn ìgbékèéyíde wọ̀nyí tí ó jẹ́ titun nítòótọ́; bẹ́ẹ̀ sì ni kò ṣiṣẹ́ fún àǹfààní àti ire dídára jù ẹnìkan, bí ohun tí Satani fi ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí sọ fún Efa kò ti ṣiṣẹ́ fún ire rẹ̀ dídára jù.​—⁠2 Korinti 11:⁠3.

6. Nígbà tí Satani bá késí wa láti tọ́ pàrùpárù oúnjẹ ẹlẹ́mìí èṣù rẹ̀ wò, níti gàsíkíá, báwo ni ó ṣe yẹ kí a hùwàpadà?

6 Nítorí náà, nígbà tí Satani bá rọ̀ wá láti tọ́ pàrùpárù oúnjẹ ẹlẹ́mìí eṣu rẹ̀ wò, báwo ni a ṣe gbọ́dọ̀ hùwàpadà? Gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ṣe nígbà tí Satani dán an wò láti sọ òkúta di àkàrà. Jesu fèsì pé: “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, Ènìyàn kì yóò wàláàyè nípa àkàrà nìkan, bíkòṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu Ọlọrun jáde wá.” Nígbà tí Eṣu sì fi “gbogbo ilẹ̀ ọba ayé àti gbogbo ògo wọn han” Jesu bí òun yóò bá wólẹ̀ kí ó sì jọ́sìn Satani, Jesu fèsìpadà pé: “Padà kúrò lẹ́yìn mi, Satani: nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé, Oluwa Ọlọrun rẹ ni kí ìwọ kí ó foríbalẹ̀ fún, òun nìkanṣoṣo ni kí ìwọ máa sìn.”​—⁠Matteu 4:​3, 4, 8-⁠10.

7. Èéṣe tí a fi ń ṣi araawa lọ́nà bí a bá ronú pé a lè jẹun lórí tábìlì Jehofa àti tábìlì àwọn ẹ̀mí-èṣù lọ́nà yíyọrísírere?

7 Tábìlì Jehofa àti tábìlì tí àwọn ẹ̀mí-èṣù tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá rẹ̀ tẹ́ sílẹ̀ ni a kò lè mú báradọ́gba láé! Óò, bẹ́ẹ̀ni, a ti gbìyànjú rẹ̀ rí. Rántí Israeli ìgbàanì ní àwọn ọjọ́ wòlíì Elija. Àwọn ènìyàn náà jẹ́wọ́ pé àwọn ń sin Jehofa, ṣùgbọ́n wọ́n gbàgbọ́ pé àwọn ọlọrun mìíràn, bíi Baali, ṣèlérí aásìkí. Elija tọ àwọn ènìyàn náà lọ ó sì wí pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin ó máa ṣiyèméjì? Bí Oluwa bá ni Ọlọrun, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn: ṣùgbọ́n bí Baali bá ni ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn!” Láìṣeésẹ́, àwọn ọmọ Israeli ń tẹ̀ yẹ́ńkẹ́yẹ́ńkẹ́ “lákọ̀ọ́kọ́ lórí ẹsẹ̀ kan àti lẹ́yìn náà lórí ẹsẹ̀ kejì.” (1 Awọn Ọba 18:21; The Jerusalem Bible) Elija pe àwọn àlùfáà Baali níjà láti fi ẹ̀rí jíjẹ́ ọlọrun ti ọlọrun àjọ́sìnfún wọn hàn. Ọlọrun tí ó bá lè mú kí iná ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá sórí ẹbọ ni yóò jásí Ọlọrun òtítọ́. Láìka ọ̀pọ̀ ìsapá sí, àwọn àlùfáà Baali kùnà. Nígbà náà ni Elija gbàdúrà ní tààràtà pé: “Oluwa, gbọ́ ti èmi, kí àwọn ènìyàn yìí kí ó lè mọ̀ pé, Ìwọ Oluwa ni Ọlọrun.” Lójú-ẹsẹ̀ iná láti ọ̀dọ̀ Jehofa wá bọ́ sílẹ̀ láti ọ̀run wá ó sì jó ẹbọ ẹran tí ó rin gbingbin fún omi náà run. Bí a ti ru wọ́n sókè nípasẹ̀ àṣefihàn tí ń múnigbàgbọ́ nípa jíjẹ́ Ọlọrun Jehofa, àwọn ènìyàn náà ṣègbọràn sí Elija wọ́n sì pa gbogbo 450 àwọn wòlíì Baali. (1 Awọn Ọba 18:​24-⁠40) Nítorí náà lónìí, a gbọ́dọ̀ mọ Jehofa gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun òtítọ́ kí a sì fi pẹ̀lú ìpinnu yíjú sí jíjẹun lórí tábìlì tirẹ̀ nìkanṣoṣo bí a kò bá tíì máa ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀.

‘Olùṣòtítọ́ Ẹrú’ Ni Ó Ń Gbóúnjẹ Sórí Tábìlì Jehofa

8. Ẹrú wo ni Jesu sọtẹ́lẹ̀ pé òun yóò lò láti fi oúnjẹ bọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn òun nípa tẹ̀mí nígbà wíwàníhìn-⁠ín òun, kí sì ni a fi mọ ẹrú náà yàtọ̀?

8 Oluwa náà Jesu Kristi sọtẹ́lẹ̀ pé nígbà wíwàníhìn-⁠ín òun “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” yóò pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀: “Aláyọ̀ ni ẹrú naa bí ọ̀gá rẹ̀ nígbà tí ó bá dé bá rí i tí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ní òótọ́ ni mo wí fún yín, Oun yoo yàn án sípò lórí gbogbo awọn nǹkan ìní rẹ̀.” (Matteu 24:​45-⁠47, NW) Ẹ̀rí ti fihàn pé ẹrú yìí kìí ṣe ènìyàn kanṣoṣo èyíkéyìí, bíkòṣe ẹgbẹ́ àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró tí a ti yàsímímọ́. Ẹgbẹ́ yìí ti gbé oúnjẹ tẹ̀mí tí ó dára jùlọ sórí tábìlì Jehofa fún àwọn àṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró àti “ogunlọ́gọ̀ ńlá.” Nísinsìnyí àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá náà tí iye wọn rékọjá million mẹ́rin ti mú ìdúró wọn pẹ̀lú àṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró fún ipò ọba aláṣẹ àgbáyé ti Jehofa Ọlọrun àti fún Ìjọba rẹ̀ nípasẹ̀ èyí tí òun yóò sọ orúkọ mímọ́ rẹ̀ di mímọ́.​—⁠Ìfihàn 7:​9-⁠17.

9. Irin-iṣẹ́ wo ni ẹgbẹ́ ẹrú náà ti ń lò láti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, báwo ni a sì ṣe fi àsọtẹ́lẹ̀ ṣàpèjúwe àsè jíjẹ tẹ̀mí náà?

9 Ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ ẹrú yìí ti ń lo Watch Tower Bible and Tract Society láti pèsè oúnjẹ àfibọ́ni tẹ̀mí fún gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Nígbà tí ó jẹ́ pé Kristẹndọm àti ìyókù ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí ń jìyà lọ́wọ́ ebi nítorí àìní oúnjẹ tẹ̀mí tí ń fúnni ní ìyè, àwọn ènìyàn Jehofa ń jàsè. (Amosi 8:11) Èyí jẹ́ ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tí ó wà ní Isaiah 25:6: “Oluwa àwọn ọmọ ogun yóò se àsè ohun àbọ́pa fún gbogbo orílẹ̀-èdè, àsè ọtí-wáìnì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀, ti ohun àbọ́pa tí ó kún [fún] ọ̀rá, ti ọtí-wáìnì tí ó tòrò lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ̀ 7 àti 8 ti fihàn, àsè yìí yóò máa báa lọ láìnípẹ̀kun. Ẹ sì wo bí ó ti jẹ́ ìbùkún tó fún gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú ètò-àjọ Jehofa tí ó ṣeéfojúrí nísinsìnyí, ẹ tún wo bí yóò ti máa báa lọ láti jẹ́ ìbùkún tó ní ọjọ́ ọ̀la!

Ṣọ́ra fún Oúnjẹ Onímájèlé tí Ń Bẹ Lórí Tábìlì Àwọn Ẹ̀mí-Èṣù

10. (a) Irú oúnjẹ wo ni ẹgbẹ́ ẹrú olubi náà ń pín fúnni, kí sì ni ó ń sún wọn ṣiṣẹ́? (b) Báwo ni ẹgbẹ́ ẹrú olubi náà ṣe bá àwọn ẹrú ẹlẹgbẹ́ wọn tẹ́lẹ̀rí lò?

10 Oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì àwọn ẹ̀mí-èṣù jẹ́ onímájèlé. Fún àpẹẹrẹ, gbé oúnjẹ tí ẹgbẹ́ ẹrú olubi àti àwọn apẹ̀yìndà ń pín fúnni yẹ̀wò. Kìí fáralókun tàbí gbéniró; kò níláárí. Kò lè níláárí, nítorí pé àwọn apẹ̀yìndà ti ṣíwọ́ láti máa jẹun lórí tábìlì Jehofa. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, ohunkóhun yòówù tí wọ́n ti lè mú dàgbà nínú àkópọ̀ ànímọ́ titun náà ti pòórá. Ohun tí ń sún wọn ṣiṣẹ́ kìí ṣe ẹ̀mí mímọ́, bíkòṣe ìbínú kíkorò. Góńgó kanṣoṣo péré ni ó gbà wọ́n lọ́kàn​—⁠lílu àwọn ẹrú ẹlẹgbẹ́ wọn tẹ́lẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí Jesu ti sọtẹ́lẹ̀.​—⁠Matteu 24:​48, 49.

11. Kí ni C. T. Russell kọ nípa yíyàn oúnjẹ tẹ̀mí tí ẹnìkan ṣe, báwo ni ó sì ṣe ṣàpèjúwe àwọn wọnnì tí wọ́n kọ tábìlì Jehofa sílẹ̀?

11 Fún àpẹẹrẹ, nígbà náà lọ́hùn-⁠ún ní ọdún 1909, ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà, C. T. Russell, kọ̀wé nípa àwọn wọnnì tí wọ́n yípadà kúrò nídìí tábìlì Jehofa tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn ẹrú ẹlẹgbẹ́ wọn tẹ́lẹ̀rí níṣekúṣe. Ile-Iṣọ Na (Gẹ̀ẹ́sì) ti October 1, 1909, wí pé: “Gbogbo àwọn tí wọ́n já ìdè àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Society àti iṣẹ́ rẹ̀, dípò kí wọ́n ṣe araawọn lóore tàbí kí wọ́n gbé àwọn ẹlòmíràn ró nínú ìgbàgbọ́ àti nínú oore-ọ̀fẹ́ ti ẹ̀mí, ni ó jọbí ẹni pé wọ́n ń ṣe òdìkejì​—⁠wọ́n gbìdánwò ìṣeléṣe fún Orísun náà tí wọ́n ti ṣiṣẹ́sìn rí, àti pé, lẹ́yìn awuyewuye díẹ̀ kan, wọ́n di ìgbàgbé ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ní pípa kìkì araawọn àti àwọn mìíràn tí wọ́n ní irú ẹ̀mí asọ̀ kan náà bíi tiwọn lára. . . . Bí àwọn kan bá ronú pé àwọn lè rí oúnjẹ tí ó dára bí èyí tàbí tí ó dára ju èyí lọ lórí tábìlì mìíràn, tàbí pé wọ́n lè pèsè èyí tí ó dára tó o tàbí tí ó dára jù ú lọ fúnraawọn​—⁠ẹ jẹ́ kí àwọn wọ̀nyí máa bá ọ̀nà tiwọn lọ. . . . Ṣùgbọ́n nígbà tí àwa ko sọ pé kí àwọn ẹlòmíràn máṣe lọ sí ibikíbi àti sí ibi gbogbo láti wá oúnjẹ àti ìmọ́lẹ̀ sí ìtẹ́lọ́rùn araawọn, ó yanilẹ́nu pé, ọ̀nà kan tí ó yàtọ̀ ni àwọn tí wọ́n kọjúùjàsí wa forílé. Dípò kí wọ́n sọ̀rọ̀ lọ́nà akin bíi ti àwọn ènìyàn ayé pé, ‘Ọwọ́ mi ti tẹ ohun tí mo ń wá; ó dìgbòóṣe!’ àwọn wọ̀nyí fi ìbínú, àránkàn, ìkórìíra, gbólóhùn asọ̀, ‘iṣẹ́ ti ara àti ti eṣu’ hàn dé ìwọ̀n àyè tí a kò tíì rí i kí àwọn ènìyàn ayé fi wọ́n hàn. Ó dàbí ẹni pé a ti gún wọn ní abẹ́rẹ́ ìṣiwèrè, ti ágànná [àrùn dìgbòlugi] Satani. Àwọn kan nínú wọn lù wá wọ́n sì sọ lẹ́yìn náà pé àwa ni a lù wọ́n. Wọ́n múratán láti sọ àti láti kọ̀wé àwọn irọ́ aláìníláárí àti láti fi inú burúkú hàn.”

12. (a) Báwo ni àwọn apẹ̀yìndà ṣe lu àwọn ẹrú ẹlẹgbẹ́ wọn? (b) Èéṣe tí ó fi léwu láti fi ìwé tí àwọn apẹ̀yìndà kọ bọ́ araawa nítorí ìfẹ́ ìtọpinpin?

12 Bẹ́ẹ̀ni, àwọn apẹ̀yìndà tẹ àwọn ìwé tí ó wá jásí yíyí òtítọ́ po, màgòmágó, àti èké pọn-ran-⁠un. Wọ́n tilẹ̀ ń fẹsẹ̀ palẹ̀ káàkiri ní àpéjọpọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí, ní gbígbìyànjú láti dẹ páńpẹ́ mú àwọn tí kò wà lójúfò. Nípa báyìí, yóò jẹ́ ohun tí ó léwu láti jẹ́ kí ìfẹ́ ìtọpinpin wa sún wa láti fi irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ bọ́ araawa tàbí láti fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ èébú wọn! Nígbà tí a lè má ronú pé ó jẹ́ ewu fún wa gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan, jàm̀bá náà ṣì wà síbẹ̀. Èéṣe? Ohun kan ni pé, díẹ̀ nínú ìwé àwọn apẹ̀yìndà náà ń gbé èké kalẹ̀ nípasẹ̀ “ọ̀rọ̀ dídùndídùn” àti “ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.” (Romu 16:17, 18; 2 Peteru 2:⁠3) Kí ni ìwọ yóò retí pé kí ó ti orí tábìlì àwọn ẹ̀mí-èṣù wá? Bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn apẹ̀yìndà lè gbé àwọn òtítọ́ pàtó kan jáde, ìwọ̀nyí ni wọ́n sábà máa ń lo láìgbé àyíká ọ̀rọ̀ náà yẹ̀wò pẹ̀lú góńgó náà láti fa àwọn ẹlòmíràn lọ kúrò nídìí tábìlì Jehofa. Gbogbo ìwé wọn wulẹ̀ ń ṣe lámèyítọ́ tí ó sì ń banijẹ́! Kò sí ohun kan tí ń gbéniró.

13, 14. Kí ni èso àwọn apẹ̀yìndà àti ìgbékèéyíde wọn?

13 Jesu wí pé: “Èso wọn ni ẹ̀yin ó fi mọ̀ wọ́n.” (Matteu 7:16) Nísinsìnyí, kí ni èso àwọn apẹ̀yìndà àti ti àwọn ìtẹ̀jáde wọn? Ohun mẹ́rin ni ó sàmìsí ìgbékèéyíde wọn. (1) Ọgbọ́n bérébéré. Efesu 4:14 (NW) sọ pé wọ́n jẹ́ “àlùmọ̀kọ́rọ́yí ninu dídọ́gbọ́nhùmọ̀ ìṣìnà.” (2) Ọgbọ́n tí ó kún fún ìgbéraga. (3) Àìní ìfẹ́. (4) Ìwà-àbòsí ní onírúurú ọ̀nà. Ìwọ̀nyí ni àwọn èròjà náà gan-⁠an tí ń bẹ nínú oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì àwọn ẹ̀mí-èṣù, gbogbo èyí tí a wéwèé láti tẹ ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn Jehofa rì.

14 Apá-ìhà mìíràn sì tún wà. Inú kí ni àwọn apẹ̀yìndà padà sí? Nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀ràn, wọ́n tún ti padà wọnú òkùnkùn Kristẹndọm àti àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ rẹ̀, irú bí èrò ìgbàgbọ́ náà pé gbogbo àwọn Kristian ni ó ń lọ sọ́run. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọ̀pọ̀ jùlọ ti ṣíwọ́ mímú ìdúró fífìdímúlẹ̀gbọnyin tí a gbékarí Ìwé Mímọ́ nípa ẹ̀jẹ̀, àìdásí tọ̀túntòsì, àti àìní náà láti jẹ́rìí nípa Ìjọba Ọlọrun. Ṣùgbọ́n, àwa ti bọ́ kúrò nínú òkùnkùn Babiloni Ńlá, a kò sì tún fẹ́ láti padà sínú rẹ̀ mọ́. (Ìfihàn 18:​2, 4) Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ adúróṣinṣin ti Jehofa, èéṣe tí àwa yóò tilẹ̀ fi fẹ́ láti bojúwo ìgbékèéyíde tí àwọn olùkọ tábìlì Jehofa sílẹ̀ wọ̀nyí ń gbéjáde, àwọn tí wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ na àwọn wọnnì tí ń ràn wá lọ́wọ́ láti gba àwọn “ọ̀rọ̀ tí ó yèkooro” lẹ́gba nísinsìnyí?​—⁠2 Timoteu 1:⁠13.

15. Ìlànà Bibeli wo ni ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti tọ ipa ọ̀nà ọgbọ́n nígbà tí a bá gbọ́ nípa ẹ̀sùn tí àwọn apẹ̀yìndà fi sùn?

15 Àwọn kan lè máa ṣòfíntótó nípa ẹ̀sùn tí àwọn apẹ̀yìndà fi ń sùn. Ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ fi ìlànà tí ó wà nínú Deuteronomi 12:​30, 31 sọ́kàn. Níhìn-⁠ín Jehofa tipasẹ̀ Mose kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israeli nípa ohun tí wọ́n níláti yẹra fún ní gbàrà tí wọ́n bá ti gba Ilẹ̀ Ìlérí náà kúrò lọ́wọ́ àwọn abọ̀rìṣà tí ń gbé níbẹ̀. “Máa ṣọ́ araàrẹ kí ìwọ má baà bọ́ sí ìdẹkùn àti tẹ̀lé wọn lẹ́yìn, lẹ́yìn ìgbà tí a ti run wọ́n kúrò níwájú rẹ; kí ìwọ kí ó má sì béèrè òrìṣà wọn, wí pé, Báwo ni àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ti ń sin òrìṣà wọn? èmi ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun rẹ.” Bẹ́ẹ̀ni, Jehofa Ọlọrun mọ bí ìfẹ́ ìtọpinpin ènìyàn ti ń ṣiṣẹ́. Rántí Efa, àti aya Loti! (Luku 17:32; 1 Timoteu 2:14) Ẹ máṣe jẹ́ kí a fetísí ohun tí àwọn apẹ̀yìndà ń sọ tàbí tí wọ́n ń ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí ọwọ́ wa dí fún gbígbé àwọn ènìyàn ró àti fífi pẹ̀lú ìdúróṣinṣin jẹun nídìí tábìlì Jehofa!

Tábìlì Jehofa Nìkanṣoṣo Ni Yóò Dúró

16. (a) Kí ni ó máa tó ṣẹlẹ̀ sí Satani, àwọn ẹ̀mí-èṣù, àti tábìlì ìṣàpẹẹrẹ náà lórí èyí tí àwọn orílẹ̀-èdè ayé ti ń jẹun? (b) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n bá ń báa lọ láti jẹun lórí tábìlì àwọn ẹ̀mí-èṣù?

16 Ní àkókò díẹ̀ si, ìpọ́njú ńlá náà yóò bẹ́sílẹ̀ lójijì, ní yíyárakánkán lọ sí òtéńté rẹ̀ nínú “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọrun Olodumare.” (Ìfihàn 16:​14, 16) Yóò dé ògógóró bí Jehofa ti ń pa ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí àti tábìlì ìṣàpẹẹrẹ lórí èyí tí àwọn orílẹ̀-èdè ayé ti ń jẹun run. Jehofa yóò tún bi gbogbo ètò-àjọ Satani Eṣu tí a lè fojúrí àti ẹgbàágbèje àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ ṣubú. Àwọn wọnnì tí wọ́n ti ń baa lọ láti máa jẹun lórí tábìlì tẹ̀mí ti Satani, tábìlì àwọn ẹ̀mí-èṣù, ni a óò fipá mú láti pésẹ̀ síbi oúnjẹ gidi kan, rárá, kìí ṣe gẹ́gẹ́ bí alábàápín, bíkòṣe gẹ́gẹ́ bí ohun náà tí a ó jẹ gan-⁠an​—⁠sí ìparun wọn!​—⁠Wo Esekieli 39:4; Ìfihàn 19:​17, 18.

17. Àwọn ìbùkún wo ní ń wá sọ́dọ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n ń jẹun lórí tábìlì Jehofa nìkanṣoṣo?

17 Tábìlì Jehofa nìkanṣoṣo ni yóò dúró. Àwọn wọnnì tí wọ́n ń fìmọrírì jẹun lórí rẹ̀ ni a óò pa mọ́ wọn yóò sì ní àǹfààní láti jẹun níbẹ̀ títíláé. Irú àìtó oúnjẹ èyíkéyìí kò tún ní wu wọ́n léwu mọ́ láé. (Orin Dafidi 67:6; 72:16) Wọn yóò fi ìlera pípé ṣiṣẹ́sin Jehofa Ọlọrun nínú Paradise! Ní ìgbẹ̀yìngbẹ́yín àwọn ọ̀rọ̀ arunisókè ti Ìfihàn 21:4 ni a óò múṣẹ lọ́nà títóbilọ́lá: “Ọlọrun yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn; kì yóò sì sí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ìrora mọ́: nítorí pé ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” Pẹ̀lú àtakò tí ó ti di ohun àtijọ́, ipò ọba aláṣẹ àgbáyé Jehofa Ọlọrun yóò fìdímúlẹ̀ níbi gbogbo láé àti títíláé bí ojúrere àtọ̀runwá tí kò lópin ti ń tú dà sórí aráyé tí a ràpadà tí ń gbé nínú Paradise ilẹ̀-ayé náà. Láti gba èrè yìí, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa pinnu láti ṣalábàápín tábìlì Jehofa nìkanṣoṣo, èyí tí ń kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún oúnjẹ tẹ̀mí dídára jùlọ!

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

◻ Báwo ni a ṣe lè yẹra fún dídi ẹni tí ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí-èṣù ṣìlọ́nà?

◻ Èéṣe tí a kò fi lè jẹun lórí tábìlì Jehofa àti lórí tábìlì àwọn ẹ̀mí-èṣù lọ́nà yíyọrísírere?

◻ Irú oúnjẹ wo ni àwọn apẹ̀yìndà ń pínfúnni?

◻ Èéṣe tí ó fi léwu láti ní ìfẹ́ ìtọpinpin nípa ẹ̀sùn àwọn apẹ̀yìndà?

◻ Kí ni èso àwọn apẹ̀yìndà?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Tábìlì Jehofa ń kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún oúnjẹ tẹ̀mí dídára jùlọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́