ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 4/1 ojú ìwé 9-14
  • Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Ní Ìdojú Ìjà Kọ Ẹ̀kọ́ Àwọn Ẹ̀mí Èṣù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Ní Ìdojú Ìjà Kọ Ẹ̀kọ́ Àwọn Ẹ̀mí Èṣù
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Ṣí Ẹ̀kọ́ Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Payá
  • Ẹ̀kọ́ Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Lónìí
  • Dídá Ẹ̀kọ́ Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Mọ̀ Yàtọ̀
  • Rírọ̀mọ́ Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá
  • Ẹ̀yin Èwe—Ẹ̀kọ́ Ta Ni Ẹ Ń Kọbiara Sí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àwọn Wo Ni Ọ̀tá Ọlọ́run?
    Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
  • Kí La Lè Ṣe Táwọn Ẹ̀mí Èṣù Ò Fi Ní Lè Borí wa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Mọ Ọ̀tá Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 4/1 ojú ìwé 9-14

Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Ní Ìdojú Ìjà Kọ Ẹ̀kọ́ Àwọn Ẹ̀mí Èṣù

“Àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn óò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù.”​—⁠1 TIMOTEU 4:⁠1.

1. Ní àárín ogun wo ni àwọn Kristian wà?

FINÚRO gbígbé gbogbo ìgbésí-ayé rẹ ní àgbègbè tí ogun ti ń jà. Kí ni yóò jọ láti lọ sùn pẹ̀lú ìró ibọn kí o sì jí sínú ariwo àgbá ìbọn? Ó baninínújẹ́ pé, ní àwọn apá ibi mélòókan ní ayé, ìyẹn ni ìgbésí-ayé tí àwọn ènìyàn ń gbé níti gidi. Bí ó ti wù kí ó rí, lọ́nà tẹ̀mí, gbogbo Kristian ń gbé ìgbésí-ayé lọ́nà yìí. Wọ́n wà láàárín ogun ńlá kan tí ó ti ń jà rànyìn fún nǹkan bi 6,000 ọdún tí ó sì ti gbóná síi ni ọjọ́ wa. Kí ni ogun ọlọ́jọ́ pípẹ́ yìí? Ogun òtítọ́ ní ìdojú ìjà kọ èké ni, ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ní ìdojú ìjà kọ ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù. Kìí ṣe àbùmọ́​—⁠ó kérétán fún ọ̀kan nínú àwọn ìhà tí ń dojúkọra náà​—⁠láti pè é ní ìkọlura aláìláàánú àti aṣekúpani jùlọ nínú ìtàn ìran ènìyàn.

2. (a) Bí Paulu ti sọ, àwọn ìhà méjì wo ni wọn tako araawọn? (b) Kí ni Paulu nílọ́kàn nípa “ìgbàgbọ́”?

2 Aposteli Paulu mẹ́nukan ìhà méjèèjì nínú ìforígbárí náà nígbà tí ó kọ̀wé sí Timoteu: “Ṣùgbọ́n ẹ̀mí ń tẹnumọ́ ọn pé, ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn óò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù.” (1 Timoteu 4:⁠1) Ṣàkíyèsí pé ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù yóò ní agbára ìdarí ní pàtàkì ní “ìgbà ìkẹyìn.” Bí a ṣe fi ojú wò ó láti ọjọ́ Paulu, àwa ń gbé ní irú àkókò bẹ́ẹ̀. Ṣàkíyèsí, pẹ̀lú, ohun tí ó tako ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù, ìyẹn ni, “ìgbàgbọ́.” Níhìn-⁠ín, “ìgbàgbọ́” dúró fún ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá, tí a gbékarí àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ó ní ìmísí àtọ̀runwá tí ó wà nínú Bibeli. Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ afúnniníyè. Ó ń kọ́ Kristian kan láti ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun. Òun ni òtítọ́ tí ń sinni lọ sí ìyè ayérayé.​—⁠Johannu 3:16; 6:⁠40.

3. (a) Kí ní ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn afaragbọgbẹ́ nínú ogun láàárín òtítọ́ àti èké? (b) Ta ni ó wà lẹ́yìn ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù?

3 Ẹnikẹ́ni tí ó bá yẹsẹ̀ kúrò nínú ìgbàgbọ́ yóò pàdánù ìyè àìnípẹ̀kun. Wọ́n jẹ́ afaragbọgbẹ́ lójú ogun náà. Ẹ wo àbájáde bíbaninínújẹ́ tí ó jẹ́ fún ẹnìkan láti jẹ́ kí á fi ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù ṣi òun lọ́nà! (Matteu 24:24) Báwo ni àwa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan ṣe lè yẹra fún jíjẹ́ afaragbọgbẹ́? Nípa kíkọ àwọn ẹ̀kọ́ èké wọ̀nyí, tí ń dá ṣiṣẹ́ fún ète “olórí àwọn ẹ̀mí èṣù,” Satani Èṣù ní àkọ̀délẹ̀ porogodo. (Matteu 12:24) Bí a ti lè retí, àwọn ẹ̀kọ́ Satani jẹ́ irọ́, níwọ̀n bí Satani ti jẹ́ “baba èké.” (Johannu 8:44) Ṣàgbéyẹ̀wò bí òun ti fi ìjáfáfá lo irọ́ láti ṣi àwọn òbí wa àkọ́kọ́ lọ́nà.

A Ṣí Ẹ̀kọ́ Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Payá

4, 5. Irọ́ wo ni Satani pa fún Efa, èésìtiṣe tí èyí fi burú jáì?

4 Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni a kọ sínú Bibeli ni Genesisi 3:​1-⁠5. Ní lílo ejò kan, Satani tọ obìnrin naa Efa wá tí ó sì bi í léèrè pé: “Òótọ́ ni Ọlọrun wí pé, Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ gbogbo èso igi ọgbà?” Ìbéèrè náà dàbí aláìlèpanilára, ṣùgbọ́n wò ó lẹ́ẹ̀kan síi. “Òótọ́ ni?” Ó dàbí ìyàlẹ́nu fún Satani, bíi pé, ‘Èéṣe tí Ọlọrun yóò fi sọ ohun kan bí ìyẹn?’

5 Nínú àìmọ̀kan rẹ̀, Efa fihàn pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí. Ó mọ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá lórí ọ̀ràn yìí, pé Ọlọrun ti sọ fún Adamu pé wọn yóò kú bí wọ́n bá jẹ nínú igi ìmọ̀ rere àti búburú náà. (Genesisi 2:​16, 17) Ó hàn gbangba pe ìbéèrè Satani ru ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ sókè, nítorí náà obìnrin náà fetísílẹ̀ bí ó ti dé orí kókó náà gan-⁠an: “Ejò náà sì wí fún obìnrin náà pé, Ẹ̀yin kì yóò kú ikú kíkú kan.” Ẹ wo bí èyí ti jẹ́ ọ̀rọ̀ búburú tó láti sọ! Satani fẹ̀sùn kan Jehofa, Ọlọrun òtítọ́, Ọlọrun ìfẹ́, Ẹlẹ́dàá, pé ó purọ́ fún àwọn ọmọ Rẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn!​—⁠Orin Dafidi 31:5; 1 Johannu 4:16; Ìfihàn 4:⁠11.

6. Báwo ni Satani ṣe pe ìwàrere-ìṣeun àti ipò ọba aláṣẹ Jehofa níjà?

6 Ṣùgbọ́n Satani sọ púpọ̀ síi. Ó ń báa nìṣó pé: “Nítorí Ọlọrun mọ̀ pé, ní ọjọ́ tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀, nígbà náà ni ojú yín yóò là, ẹ̀yin óò sì dàbí Ọlọrun, ẹ óò mọ rere àti búburú.” Bí Satani ti wí, Jehofa Ọlọrun​—⁠tí o ti pèsè jaburata fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́​—⁠fẹ́ láti dù wọ́n ní ohun àgbàyanu kan. Ó ń fẹ́ láti ṣèdíwọ́ fún wọn láti máṣe dàbí àwọn ọlọrun. Nípa báyìí, Satani pe ìwàrere-ìṣeun Ọlọrun níjà. Ó tún gbé ìtẹ́ra-ẹni lọ́rùn àti ìmọ̀ọ́mọ̀ gbójúfo àwọn òfin Ọlọrun lékè, ní sísọ pé híhùwà ní ọ̀nà yìí yóò ṣàǹfààní. Nídìí èyí, Satani pe ipò ọba aláṣẹ Ọlọrun lórí àwọn ìṣẹ̀dá Rẹ̀ níjà, ní fífẹ̀sùnkàn pé Ọlọrun kò ní ẹ̀tọ́ láti fi ààlà sórí ohun tí ènìyàn bá ṣe.

7. Nígbà wo ni a kọ́kọ́ gbọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù, báwo ni wọn sì ṣe farajọra lónìí?

7 Pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Satani wọ̀nyẹn, a bẹ̀rẹ̀ síí gbọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù. Àwọn ẹ̀kọ́ búburú wọ̀nyí ṣì ń gbé irú àwọn ìlànà tí ó farajọ ọ́ tí kò bọ̀wọ̀ fún Ọlọrun lékè. Gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe nínú ọgbà Edeni, Satani, tí àwọn ọlọ̀tẹ̀ ẹ̀mí ti darapọ̀ mọ́, ṣì ń gbé ìpèníjà dìde sí ẹ̀tọ̀ Ọlọrun láti fi ọ̀pá ìdíwọ̀n lélẹ̀ fún ọ̀nà ìgbàgbégbèésẹ̀. Ó ṣì ń ṣiyèméjì nípa ipò ọba aláṣẹ Jehofa tí ó sì ń gbìyànjú láti darí àwọn ènìyàn láti ṣàìgbọràn sí Baba wọn ọ̀run.​—⁠1 Johannu 3:​8, 10.

8. Kí ni Adamu àti Efa pàdánù ní Edeni, ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe fẹ̀ríhàn pé Jehofa sọ òtítọ́?

8 Nínú ìkọlura òjijì àkọ́kọ́ yẹn nínú ogun láàárín ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù, Adamu àti Efa ṣe ìpinnu tí kò tọ̀nà tí wọn sì pàdánù ìrètí wọn fún ìyè àìnípẹ̀kun. (Genesisi 3:19) Bí ọdún ti ń gorí ọdún tí ara wọn sì bẹ̀rẹ̀ síí jagọ̀, a mú ẹni tí ó purọ́ àti ẹni tí ó sọ òtítọ́ nígbà náà lọ́hùn-⁠ún ni Edeni dá wọn lójú ní kedere. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú kí wọn tó kú nípa ti ara, wọ́n di afaragbọgbẹ́ àkọ́kọ́ nínú ogun láàárín òtítọ́ àti èké nígbà tí wọ́n gba ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò yẹ fún ìwàláàyè láti ọwọ́ Ẹlẹ́dàá wọn, Orísun ìwàláàyè. Ìgbà yẹn ni wọn kú nípa tẹ̀mí.​—⁠Orin Dafidi 36:9; fiwé Efesu 2:⁠1.

Ẹ̀kọ́ Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Lónìí

9. Báwo ni ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù ṣe gbéṣẹ́ tó láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá?

9 Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú ìwé Ìfihàn, aposteli Johannu ni a gbé nínú ẹ̀mí lọ sí “ọjọ́ Oluwa,” tí ó bẹ̀rẹ̀ ní 1914. (Ìfihàn 1:10) Ní àkókò yẹn Satani àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ni a lé láti ọ̀run wá sí sàkáání ilẹ̀-ayé​—⁠ìfàsẹ́yìn ńlá fún alátakò Ẹlẹ́dàá Atóbilọ́lá wa. A kò gbọ́ ohùn rẹ̀ ní ọ̀run mọ́ kí ó máa fẹ̀sùnkan àwọn ìránṣẹ́ Jehofa nígbà gbogbo. (Ìfihàn 12:10) Bí ó ti wù kí ó rí, irú ìtẹ̀síwájú wo ni ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù ti ní lórí ilẹ̀-ayé láti ìgbà ti Edeni? Àkọsílẹ̀ sọ pé: “A sì lé dragoni ńlá náà jáde, ejò láéláé nì, tí a ń pè ní Èṣù, àti Satani, tí ń tan gbogbo ayé jẹ.” (Ìfihàn 12:⁠9) Gbogbo ayé ti jọ̀wọ́ ara wọn fún irọ́ Satani! Abájọ tí a fi pe Satani ni “aládé ayé yìí”!​—⁠Johannu 12:31; 16:⁠11.

10, 11. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Satani àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ fi lágbára lónìí?

10 Satani ha faramọ́ ìfìdírẹmi lẹ́yìn lílé e kúrò ní ọ̀run bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́! Ó pinnu láti máa bá ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá àti àwọn tí wọ́n bá rọ̀mọ́ ọn jagun. Lẹ́yìn tí a lé e kúrò ní ọ̀run, Satani ń bá ogun jíjà rẹ̀ nìṣó: “Dragoni [Satani] náà sì bínú gidigidi sí obìnrin náà, ó sì lọ bá àwọn irú-ọmọ rẹ̀ ìyókù jagun, tí wọn ń pa òfin Ọlọrun mọ́, tí wọn sì di ẹ̀rí Jesu mú.”​—⁠Ìfihàn 12:⁠17.

11 Ní àfikún sí bíbá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun jà, Satani ń fi ìgbékèéyíde rẹ̀ kún ayé, ní lílàkàkà láti mú kí ìwàmú rẹ̀ lórí ìran ènìyàn máa wà nìṣó. Nínú ọ̀kan lára àwọn ìran Ìfihàn nípa ọjọ́ Oluwa, aposteli Johannu rí ẹranko ẹhànnà mẹ́ta tí ó ṣàpẹẹrẹ Satani, ètò-àjọ òṣèlú rẹ̀ orí ilẹ̀-ayé, àti agbára ayé lílágbára jùlọ ní àkókò wa. Láti ẹnu àwọn mẹ́ta wọ̀nyí, ọ̀pọ̀lọ́ jáde wá. Kí ni ìwọ̀nyí ṣàpẹẹrẹ? Johannu kọ̀wé: “Nítorí ẹ̀mí èṣù ni wọ́n, tí ń ṣe iṣẹ́-ìyanu, àwọn tí ń jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba gbogbo ilẹ̀-ayé, láti gbá wọn jọ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọrun Olódùmarè.” (Ìfihàn 16:14) Ní kedere, ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù lágbára nínú ayé. Satani àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ṣì ń bá ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá jà, wọn yóò sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó títí tí Jesu Kristi, Messia Ọba naa, yóò fi fipá dá wọn dúró.​—⁠Ìfihàn 20:⁠2.

Dídá Ẹ̀kọ́ Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Mọ̀ Yàtọ̀

12. (a) Èéṣe tí ó fi ṣeéṣe láti gbéjàko ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù? (b) Báwo ni Satani ṣe ń gbìyànjú láti ṣàṣeparí ète rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun?

12 Àwọn ẹ̀dá ènìyàn olùbẹ̀rù Ọlọrun ha lè gbéjàko ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù bí? Wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ níti tòótọ́, nítorí ìdí méjì. Àkọ́kọ́, nítorí pé ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá lágbára jù ú lọ; àti èkejì, nítorí pé Jehofa ti tú àwọn ọgbọ́n ìgbẹ̀bùrú kọluni Satani fó kí a baà lè gbéjàkò wọ́n. Bí aposteli Paulu ti sọ, “àwa kò ṣe aláìmọ àrékérekè rẹ̀.” (2 Korinti 2:11) Àwa mọ̀ pé Satani ń lo inúnibíni bí ọ̀nà kan láti fi ṣàṣeparí ète rẹ̀. (2 Timoteu 3:12) Bí ó ti wù kí ó rí, lọ́nà tí ó túbọ̀ jáfáfá, ó ń gbìyànjú láti lo agbára ìdarí lórí èrò-inú àti ọkàn-àyà àwọn tí wọ́n ń sin Ọlọrun. Ó ṣi Efa lọ́nà ó sì fi ìdàníyàn òdì sínú ọkàn-àyà rẹ̀. Ó ń gbìyànjú ohun kan náà lónìí. Paulu kọ̀wé sí àwọn ará Korinti pé: “Ẹ̀rù ń bà mí pé, ní ohunkóhun, gẹ́gẹ́ bí ejò ti tan Efa jẹ nípasẹ̀ àrékérekè rẹ̀, kí a máṣe mú èrò-ọkàn yín bàjẹ́ kúrò nínú inú kan àti ìwà mímọ́ yín sí Kristi.” (2 Korinti 11:⁠3) Ronú lórí bí ó ti ba ìrònú aráyé jẹ́ ní gbogbogbòò.

13. Irọ́ wo ni Satani ti pa fún aráyé láti ìgbà ti Edeni?

13 Lójú Efa, Satani fẹ̀sùn irọ́ pípa kan Jehofa tí ó sì sọ pé ẹ̀dá ènìyàn lè dàbí ọlọrun bí wọ́n bá ṣàìgbọràn sí Ẹlẹ́dàá wọn. Ipò ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lónìí ti fẹ̀ríhàn pé Satani ni òpùrọ́, kìí ṣe Jehofa. Àwọn ẹ̀dá ènìyàn lónìí kìí ṣe ọlọrun! Bí ó ti wù kí ó rí, Satani fi irọ́ mìíràn gbe ti àkọ́kọ́ lẹ́sẹ̀. Ó gbé èrò náà kalẹ̀ pé ọkàn ènìyàn jẹ́ àìlèkú, tí kìí tipa báyìí kú. Ó fi ṣíṣeéṣe náà láti dàbí ọlọrun lọ aráyé lọ́nà mìíràn. Nígbà náà, lórí ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ èké yẹn, ó gbé àwọn ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì, pọ́gátórì, ìbẹ́mìílò, àti ìjọ́sìn àwọn babańlá lékè. Àwọn irọ́ wọ̀nyí ṣì mú ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún nígbèkùn.​—⁠Deuteronomi 18:​9-⁠13.

14, 15. Kí ni òtítọ́ nípa ikú àti ìrètí ènìyàn fún ọjọ́ ọ̀la?

14 Dájúdájú, òtítọ́ ni ohun tí Jehofa sọ fún Adamu. Níti gidi Adamu kú nígbà tí ó dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọrun. (Genesisi 5:⁠5) Nígbà tí Adamu àti àtọmọdọ́mọ rẹ̀ kú, wọ́n di òkú ọkàn, aláìnímọ̀lára àti aláìlètapútú. (Genesisi 2:7; Oniwasu 9:​5, 10; Esekieli 18:⁠4) Nítorí jíjogún ẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Adamu, gbogbo ọkàn ẹ̀dá ènìyàn ń kú. (Romu 5:12) Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà náà lọ́hùn-⁠ún ní Edeni, Jehofa ṣèlérí wíwá irú ọmọ kan tí yóò gbógunti àwọn iṣẹ́ Èṣù. (Genesisi 3:15) Irú-ọmọ yẹn ni Jesu Kristi, Ọmọkùnrin bíbí-kanṣoṣo ti Ọlọrun. Jesu kú láìlẹ́ṣẹ̀, ẹbọ ìwàláàyè rẹ̀ sì di ìràpadà tí a fi ra aráyé padà láti inú ipò kíkú. Àwọn tí wọ́n bá fi ìgbọ́ràn lo ìgbàgbọ́ nínú Jesu ní àǹfààní gbígba ìyè àìnípẹ̀kun náà tí Adamu sọnù.​—⁠Johannu 3:36; Romu 6:23; 1 Timoteu 2:​5, 6.

15 Ìràpadà náà, ni ìrètí gidi fún aráyé, kìí ṣe èrò aláìṣekedere kan pé ọkàn ń la ikú já. Èyí ni ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá. Ó jẹ́ òtítọ́. Ó tún jẹ́ àgbàyanu ìfihàn ìfẹ́ àti ọgbọ́n Jehofa. (Johannu 3:16) Ẹ wo bí ó ti yẹ kí a kún fún ọpẹ́ tó pé a ti kọ́ òtítọ́ yìí tí a sì ti dá wa sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù nínú ọ̀ràn yìí!​—⁠Johannu 8:⁠32.

16. Kí ni àwọn àbájáde onígbà gígùn tí ó máa ń wà nígbà tí àwọn ènìyàn bá tẹ̀lé ọgbọ́n ti araawọn?

16 Nípasẹ̀ irọ́ yìí nínú ọgbà Edeni, Satani fún Adamu àti Efa níṣìírí láti lépa òmìnira kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun kí wọ́n sì gbáralé ọgbọ́n tiwọn fúnraawọn. Lónìí, a rí àbájáde onígbà gígùn tí ìyẹn ní nínú ìwà ipá, ìnira ètò ọrọ̀-ajé, ogun, àti àìbáradọ́gba híhàn gbangba tí ó wà nínú ayé lónìí. Abájọ tí Bibeli fi sọ pé: “Ọgbọ́n ayé yìí wèrè ni lọ́dọ̀ Ọlọrun”! (1 Korinti 3:19) Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn fi ìwà òmùgọ̀ yàn láti jìyà ju kí wọ́n fiyèsí àwọn ẹ̀kọ́ Jehofa. (Orin Dafidi 14:1-⁠3; 107:17) Àwọn Kristian, tí wọ́n ti gba ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá, yẹra fún kíkó sínú pàkúté yẹn.

17. “Ohun tí à ń fi èké pè ní ìmọ̀” wo ni Satani gbélékè, kí ni ó sì ti jẹ́ èso rẹ̀?

17 Paulu kọ̀wé sí Timoteu: “Timoteu, ṣọ́ ohun nì tí a fi sí ìtọ́jú rẹ, yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán àti ìjiyàn ohun tí a ń fi èké pè ní ìmọ̀; èyí tí àwọn ẹlòmíràn jẹ́wọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ṣìnà ìgbàgbọ́.” (1 Timoteu 6:​20, 21) “Ìmọ̀” yẹn tún dúró fún ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù. Ní ọjọ́ Paulu, o ṣeéṣe kí ó tọ́kasí èrò àwọn apẹ̀yìndà tí àwọn kan nínú ìjọ ń gbélékè. (2 Timoteu 2:​16-⁠18) Lẹ́yìn náà, èyí tí a fi èké pè ní ìmọ̀, irú bíi Ìmọ̀-Awo àti ìmọ̀-ọ̀ràn Griki, sọ ìjọ di ìbàjẹ́. Nínú ayé lónìí, àìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun, ìgbàgbọ́ Ọlọrun kò-ṣeémọ̀, àbá-èrò orí ẹfoluṣọn, àti àríwísí gíga jù nípa Bibeli jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tí a fi èké pè ni ìmọ̀, bíi ti àwọn èrò aláìbá Ìwé Mímọ́ mu tí àwọn apẹ̀yìndà òde-òní ń gbélékè. Èso gbogbo àwọn ohun tí a fi èké pè ní ìmọ̀ yìí ni a rí nínú ìlọsílẹ̀ ìwàrere, ìtànkálẹ̀ àìbọ̀wọ̀ fún ọlá-àṣẹ, àbòsí, àti ìmọtara-ẹni nìkan tí ó jẹ́ ànímọ́ èto-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti Satani.

Rírọ̀mọ́ Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá

18. Àwọn wo ni wọ́n ń wá ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá lónìí?

18 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Satani ti ń fi àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù kún ayé láti àkókò Edeni, àwọn mélòókan ti fìgbà gbogbo wà tí wọ́n ń wá ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá kiri. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ti wọ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lónìí. Wọ́n ní nínú àṣẹ́kù Kristian ẹni-àmì-òróró tí wọ́n ní ìrètí dídájú ti jíjọba pẹ̀lú Jesu nínú Ìjọba rẹ̀ ọ̀run àti ogunlọ́gọ̀ àwọn “àgùtàn mìíràn” tí ń pọ̀ síi tí ìrètí wọn jẹ́ láti jogún ilẹ̀-ọba Ìjọba náà lórí ilẹ̀-ayé. (Matteu 25:34; Johannu 10:16; Ìfihàn 7:​3, 9) Lónìí, àwọn wọ̀nyí ni a ti kójọpọ̀ sínú ètò-àjọ àgbáyé kanṣoṣo tí ọ̀rọ̀ Isaiah ṣeé lò fún pé: “A óò sì kọ́ gbogbo àwọn ọmọ rẹ láti ọ̀dọ̀ Oluwa wá; àlááfíà àwọn ọmọ rẹ yóò sì pọ̀.”​—⁠Isaiah 54:⁠13.

19. Kí ni ó wémọ́ jíjẹ́ ẹni tí Jehofa kọ́?

19 Jíjẹ́ ẹni tí Jehofa kọ́ túmọ̀sí ju mímọ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tòótọ́​—⁠bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn ṣe pàtàkì. Jehofa ń fún wa ní ìtọ́ni bí ó ṣe yẹ kí a gbé ìgbésí-ayé, bí ó ṣe yẹ kí a lo ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá nínú ìgbésí-ayé ara-ẹni. Fún àpẹẹrẹ, a ń kọ ẹ̀mí ìmọtara-ẹni nìkan, ìwàpálapàla, ẹ̀mí ìdádúró lómìnira tí ó wọ́pọ̀ gidi gan-⁠an nínú ayé tí ó yí wa ká. Àwa mọ ìlépa ọrọ̀ àlùmọ̀ọ́nì láìdáwọ́dúró nínú ayé yìí fún ohun tí ó jẹ́​—⁠aṣekúpani. (Jakọbu 5:​1-⁠3) Àwa kò fìgbàkan gbàgbé ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá tí a sọ nínú ọ̀rọ̀ aposteli Johannu: “Ẹ máṣe fẹ́ràn ayé, tàbí ohun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ràn ayé, ìfẹ́ ti Baba kò sí nínú rẹ̀.”​—⁠1 Johannu 2:⁠15.

20, 21. (a) Kí ni Satani ń lò nínú ìsapá rẹ̀ láti sọ àwọn ènìyàn di afọ́jú? (b) Àwọn ìbùkún wo ni ó jẹ́ ti àwọn tí wọ́n rọ̀mọ́ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá?

20 Àbájáde ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù lórí àwọn òjìyà rẹ̀ ni a rí nínú ọ̀rọ̀ Paulu sí àwọn ara Korinti: “[Satani] ti sọ ọkàn àwọn tí kò gbàgbọ́ di afọ́jú, kí ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere Kristi tí ó lógo, ẹni tíí ṣe àwòrán Ọlọrun, kí ó máṣe mọ́lẹ̀ nínú wọn.” (2 Korinti 4:⁠4) Satani yóò fẹ́ láti sọ àwọn Kristian tòótọ́ di afọ́jú ní ọ̀nà yìí pẹ̀lú. Nígbà náà lọ́hùn-⁠ún ní Edeni, ó lo ejò kan láti ṣi ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun lọ́nà. Lónìí, ó ń lo fídíò oníwà-ipá tàbí oníwà pálapàla àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹlifíṣọ̀n. Ó ń lo rédíò, ìwé, àti orin. Ohun ìjà lílágbára tí ó wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ ni ẹgbẹ́ búburú. (Owe 4:14; 28:7; 29:⁠3) Fi ìgbà gbogbo mọ irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ fún ohun tí wọ́n jẹ́​—⁠àwọn ìhùmọ̀ àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù.

21 Rántí, àwọn ọ̀rọ̀ Satani ní Edeni jẹ́ irọ́; àwọn ọ̀rọ̀ Jehofa jẹ́ òtítọ́. Láti ìgbà ìjímìjí yẹn, ọ̀ràn náà ti ń báa lọ bákan náà. Satani ti fìgbà gbogbo jásí òpùrọ́, tí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá sì ti jẹ́ òtítọ́ láìkùnà. (Romu 3:⁠4) Bí a bá rọ̀mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, àwa yóò fìgbà gbogbo wà ní ìhà tí ń borí nínú ogun láàárín òtítọ́ àti èké. (2 Korinti 10:​4, 5) Nígbà náà, ẹ jẹ́ kí a pinnu láti kọ gbogbo ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù. Ní ọ̀nà yẹn àwa yóò forítì títí di àkókò náà nígbà tí ogun láàárín òtítọ́ àti èké yóò parí. Òtítọ́ yóò ti borí. Satani yóò ti di àfẹ́kù, tí a óò sì máa gbọ́ kìkì ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá lórí ilẹ̀-ayé.​—⁠Isaiah 11:⁠9.

Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?

◻ Nígbà wo ni a kọ́kọ́ gbọ́ ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù?

◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn irọ́ tí Satani àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ gbélékè?

◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni Satani fi jẹ́ aláápọn lọ́nà lílégbákan lónìí?

◻ Kí ni Satani ń lò láti gbé ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù lékè?

◻ Àwọn ìbùkún wo ni ó jẹ́ ti àwọn tí wọ́n rọ̀mọ́ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Nínú ọgbà Edeni ni a ti kọ́kọ́ gbọ ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá nípa ìràpadà àti Ìjọba náà fún aráyé ní ìrètí kanṣoṣo náà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́