ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 3/15 ojú ìwé 26-30
  • Kí La Lè Ṣe Táwọn Ẹ̀mí Èṣù Ò Fi Ní Lè Borí wa?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí La Lè Ṣe Táwọn Ẹ̀mí Èṣù Ò Fi Ní Lè Borí wa?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Sátánì Àtàwọn Ẹ̀mí Èṣù Ṣe Dẹni Tó Wà?
  • Báwo Ni Sátánì Ṣe Lágbára Tó?
  • Ohun Tá A Lè Ṣe Tí Wọn Ò Fi Ní Borí Wa
  • Báwo La Ṣe Lè “Dúró Gbọn-in Gbọn-in”?
  • “Ẹ Máa Bá A Lọ ní Gbígbàdúrà ní Gbogbo Ìgbà”
  • “Ẹ Gbé Gbogbo Ìhámọ́ra Ọlọrun Wọ̀”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • “Ẹ Gbé Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìhámọ́ra Ogun Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Wọ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ohun Tó Jẹ́ Òótọ́ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • “Ẹ Máa Bá a Lọ Ní Gbígba Agbára Nínú Olúwa”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 3/15 ojú ìwé 26-30

Kí La Lè Ṣe Táwọn Ẹ̀mí Èṣù Ò Fi Ní Lè Borí wa?

“Àwọn áńgẹ́lì tí kò . . . dúró ní ipò wọn ìpilẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣá ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu tì ni [Ọlọ́run] ti fi pa mọ́ de ìdájọ́ ọjọ́ ńlá náà pẹ̀lú àwọn ìdè ayérayé lábẹ́ òkùnkùn biribiri.”—JÚÚDÀ 6.

1, 2. Àwọn ìbéèrè wo ló jẹ yọ nípa Sátánì Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù?

ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pétérù kìlọ̀ pé: “Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” (1 Pétérù 5:8) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀mí èṣù, ó ní: “Èmi kò . . . fẹ́ kí ẹ di alájọpín pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù. Ẹ kò lè máa mu ife Jèhófà àti ife àwọn ẹ̀mí èṣù; ẹ kò lè máa ṣalábàápín ‘tábìlì Jèhófà’ àti tábìlì àwọn ẹ̀mí èṣù.”—1 Kọ́ríńtì 10:20, 21.

2 Ta ni Sátánì Èṣù, àwọn wo sì ni ẹ̀mí èṣù? Báwo ni wọ́n ṣe dẹni tó wà, ìgbà wo ni wọ́n sì ti wà? Ǹjẹ́ Ọlọ́run ló dá wọn? Báwo ni agbára tí wọ́n ní lórí àwọn èèyàn ṣe pọ̀ tó? Ǹjẹ́ ohun kan wà tá a lè ṣe tí wọn ò fi ní lágbára lórí wa? Tó bá wà, kí ni?

Báwo Ni Sátánì Àtàwọn Ẹ̀mí Èṣù Ṣe Dẹni Tó Wà?

3. Báwo ni ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ṣe di Sátánì Èṣù?

3 Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, nígbà táwọn èèyàn tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá wà nínú ọgbà Édẹ́nì, ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run di ọlọ̀tẹ̀. Kí nìdí tó fi di ọlọ̀tẹ̀? Ìdí ni pé kò jẹ́ kí àyè tí Jèhófà fi òun sí nínú ètò Jèhófà tó wà lókè ọ̀run tẹ́ òun lọ́rùn. Nígbà tí Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà, áńgẹ́lì yìí wò ó pé àǹfààní nìyẹn jẹ́ fóun láti mú ìfẹ́ ọkàn òun ṣẹ, ló bá wá ọ̀nà láti mú kí wọ́n máa ṣègbọràn sóun kí wọ́n sì máa jọ́sìn òun dípò Ọlọ́run. Ọ̀tẹ̀ tó ṣe sí Ọlọ́run yìí àti títàn tó tan ọkùnrin àtobìnrin àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀ ló fi sọ ara rẹ̀ di Sátánì Èṣù. Nígbà tó ṣe, àwọn áńgẹ́lì míì di ọlọ̀tẹ̀ bíi tiẹ̀. Báwo ni wọ́n ṣe di ọlọ̀tẹ̀?—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; Róòmù 5:12; Ìṣípayá 12:9.

4. Kí làwọn áńgẹ́lì kan tí wọ́n di ọlọ̀tẹ̀ ṣe ṣáájú Ìkún Omi ìgbà ayé Nóà?

4 Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí sọ fún wa pé nígbà kan ṣáájú Ìkún Omi ńlá ìgbà ayé Nóà, ọkàn àwọn áńgẹ́lì kan bẹ̀rẹ̀ sí í fà sáwọn obìnrin tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé, èyí tí kò tọ́ fáwọn áńgẹ́lì láti ṣe. Bíbélì fi hàn pé nítorí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn “àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́” wọ̀nyí, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì, wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí kíyè sí àwọn ọmọbìnrin ènìyàn, pé wọ́n dára ní ìrísí; wọ́n sì ń mú aya fún ara wọn, èyíinì ni, gbogbo ẹni tí wọ́n bá yàn.” Níwọ̀n bí Ọlọ́run ò ti dá a pé kí áńgẹ́lì àti èèyàn máa fẹ́ra, àdàmọ̀dì ọmọ ni wọ́n ń bí, àwọn àkòtagìrì èèyàn tí Bíbélì pè ní Néfílímù. (Jẹ́nẹ́sísì 6:2-4) Àwọn áńgẹ́lì wọ̀nyí tipa bẹ́ẹ̀ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà bíi ti Sátánì.

5. Nígbà tí Jèhófà fi Ìkún Omi ńlá pa àwọn ẹni ibi run, kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀?

5 Nígbà tí Jèhófà fi Ìkún Omi pa aráyé run, àwọn Néfílímù náà àtàwọn ìyá wọn tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn ṣègbé. Ìkún Omi yẹn mú kó di dandan fáwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ náà láti bọ́ àwọ̀ èèyàn sílẹ̀ kí wọ́n sì padà sí ibùgbé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí. Àmọ́ nígbà tí wọ́n dé ọ̀hún, wọn ò lè padà sí “ipò wọn” tí Ọlọ́run fi wọ́n sí ní “ìpilẹ̀ṣẹ̀.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Ọlọ́run jù wọ́n sínú “òkùnkùn biribiri [nípa tẹ̀mí],” tí Bíbélì pè ní Tátárọ́sì.—Júúdà 6; 2 Pétérù 2:4.

6. Báwo làwọn ẹ̀mí èṣù ṣe ń tan àwọn èèyàn jẹ?

6 Látìgbà táwọn áńgẹ́lì búburú ti pàdánù “ipò wọn ìpilẹ̀ṣẹ̀” ni wọ́n ti di ẹ̀mí èṣù àti ọmọ ẹ̀yìn Sátánì, tí Sátánì ń lò láti máa bá a ṣe iṣẹ́ ibi rẹ̀. Látìgbà yẹn wá, àwọn ẹ̀mí èṣù ò lè gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀ mọ́. Àmọ́, wọ́n lè tan àwọn èèyàn láti máa lọ́wọ́ nínú onírúurú ìbálòpọ̀ tó gbòdì. Wọ́n tún máa ń lo ìbẹ́mìílò gan-an láti tan àwọn èèyàn jẹ, ara ìbẹ́mìílò sì ni sísa oògùn síni, bíbọ irúnmọlẹ̀, àti lílọ sọ́dọ̀ àwọn adáhunṣe. (Diutarónómì 18:10-13; 2 Kíróníkà 33:6) Ìparun ayérayé ló máa gbẹ̀yìn Èṣù àtàwọn áńgẹ́lì búburú rẹ̀. (Mátíù 25:41; Ìṣípayá 20:10) Àmọ́ ní báyìí ná, a gbọ́dọ̀ dúró gbọn-in ká sì ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kí wọ́n lè tàn wá jẹ. Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé ká ṣàgbéyẹ̀wò bí Sátánì ṣe lágbára tó ká sì mọ ohun tá a lè ṣe tọ́wọ́ òun àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ò fi ní lè tẹ̀ wá.

Báwo Ni Sátánì Ṣe Lágbára Tó?

7. Agbára wo ni Sátánì ní lórí ayé?

7 Látìgbà ayé ọkùnrin àti obìnrin tí Jèhófà kọ́kọ́ dá, Sátánì ò yéé ba Jèhófà lórúkọ jẹ́. (Òwe 27:11) Ó sì ti mú kí ọ̀pọ̀ ọmọ aráyé máa ṣe ohun tóun fẹ́. Ìwé 1 Jòhánù 5:19 sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” Abájọ tí Èṣù fi dán Jésù wò, tó sọ fún un pé òun á fún un ní àṣẹ àti ògo “gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé.” (Lúùkù 4:5-7) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa Sátánì, ó ní: “Wàyí o, bí ìhìn rere tí àwa ń polongo bá wà lábẹ́ ìbòjú, ó wà lábẹ́ ìbòjú láàárín àwọn tí ń ṣègbé, láàárín àwọn tí ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí ti fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú, kí ìmọ́lẹ̀ ìhìn rere ológo nípa Kristi, ẹni tí ó jẹ́ àwòrán Ọlọ́run, má bàa mọ́lẹ̀ wọlé.” (2 Kọ́ríńtì 4:3, 4) Sátánì jẹ́ “òpùrọ́ . . . àti baba irọ́,” àmọ́ ó máa ń fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí “áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.” (Jòhánù 8:44; 2 Kọ́ríńtì 11:14) Ó ní agbára, ó sì mọ onírúurú ọ̀nà tó lè gbà sọ ọkàn àwọn alákòóso ayé àtàwọn tó wà lábẹ́ wọn di afọ́jú. Ó ń fi ìkéde èké, ẹ̀kọ́ ìsìn èké àti irọ́ tan àwọn èèyàn jẹ.

8. Kí ni Bíbélì fi hàn nípa agbára tí Sátánì ní láti darí àwọn míì?

8 Agbára tí Sátánì ní láti darí àwọn míì hàn gbangba nígbà ayé wòlíì Dáníẹ́lì, ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún ọdún ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nígbà tí Jèhófà rán áńgẹ́lì olóòótọ́ kan sí Dáníẹ́lì pé kó lọ jíṣẹ́ ìtùnú fún un, “ọmọ aládé ilẹ̀ ọba Páṣíà,” ìyẹn áńgẹ́lì èṣù kan, de áńgẹ́lì náà lọ́nà. Ọjọ́ mọ́kànlélógún ló fi dè é lọ́nà títí tí “Máíkẹ́lì, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ aládé tí ó wà ní ipò iwájú pátápátá” fi lọ ràn án lọ́wọ́. Àkọsílẹ̀ yìí kan náà tún mẹ́nu kan “ọmọ aládé ilẹ̀ Gíríìsì,” ìyẹn ẹ̀mí èṣù kan. (Dáníẹ́lì 10:12, 13, 20) Bákan náà, Ìṣípayá 13:1, 2 fi Sátánì hàn gẹ́gẹ́ bí “dírágónì náà” tó fún ẹranko ẹhànnà, ìyẹn ìjọba ayé ní “agbára rẹ̀ àti ìtẹ́ rẹ̀ àti ọlá àṣẹ ńlá.”

9. Àwọn wo làwọn Kristẹni ń bá wọ̀yáàjà?

9 Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Àwa ní gídígbò kan, kì í ṣe lòdì sí ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, bí kò ṣe lòdì sí àwọn alákòóso, lòdì sí àwọn aláṣẹ, lòdì sí àwọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yìí, lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.” (Éfésù 6:12) Kódà lónìí, àwọn ẹ̀mí èṣù tí wọ́n wà lábẹ́ Sátánì Èṣù ṣì ń ṣiṣẹ́ ibi, wọ́n ń darí àwọn alákòóso àtàwọn èèyàn, wọ́n ń mú kí wọ́n máa ṣe ohun tó burú jáì, irú bíi ìpẹ̀yàrun, ìpániláyà, àti ìpànìyàn. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè ṣe tí wọn ò fi ní lè borí wa.

Ohun Tá A Lè Ṣe Tí Wọn Ò Fi Ní Borí Wa

10, 11. Kí la lè ṣe ká bàa lè borí Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì búburú rẹ̀?

10 A ò lè dá borí Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì búburú rẹ̀. Ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gbà wá ni pé: “Ẹ máa bá a lọ ní gbígba agbára nínú Olúwa àti nínú agbára ńlá okun rẹ̀.” Ọlọ́run la gbọ́dọ̀ gbára lè fún ààbò. Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ bàa lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù . . . Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kí ẹ bàa lè dúró tiiri ní ọjọ́ burúkú náà, lẹ́yìn tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo kínníkínní, kí ẹ sì lè dúró gbọn-in gbọn-in.”—Éfésù 6:10, 11, 13.

11 Ẹ̀ẹ̀mejì ni Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ pé kí wọ́n gbé “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” wọ̀. Ọ̀rọ̀ náà, “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́” tó wà nínú ẹsẹ yìí fi hàn pé èèyàn ò ní lè borí ogun àwọn ẹ̀mí èṣù tí kò bá fi tọkàntọkàn sa gbogbo ipá rẹ̀. Nítorí náà, kí làwọn ohun pàtàkì tó jẹ́ ara ìhámọ́ra ogun tẹ̀mí táwa Kristẹni gbọ́dọ̀ gbé wọ̀ kíákíá ká bàa lè borí àwọn ẹ̀mí èṣù?

Báwo La Ṣe Lè “Dúró Gbọn-in Gbọn-in”?

12. Báwo làwa Kristẹni ṣe lè fi òtítọ́ di abẹ́nú wa lámùrè?

12 Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé rẹ̀, ó ní: “Nítorí náà, ẹ dúró gbọn-in gbọn-in pẹ̀lú abẹ́nú yín tí a fi òtítọ́ dì lámùrè, kí ẹ sì gbé àwo ìgbàyà ti òdodo wọ̀.” (Éfésù 6:14) Ohun ìhámọ́ra méjì tí ẹsẹ Bíbélì yìí mẹ́nu kàn ni àmùrè tàbí bẹ́líìtì, àti àwo ìgbàyà. Ọmọ ogun gbọ́dọ̀ fún bẹ́líìtì rẹ̀ le dáadáa kó lè gba idà rẹ̀ dúró kó sì dáàbò bo abẹ́nú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ la ṣe ní láti wé òtítọ́ Bíbélì mọ́ra bí ìgbà téèyàn fún bẹ́líìtì mọ́dìí pinpin, ká lè máa gbé ìgbé ayé wa níbàámu pẹ̀lú òtítọ́ Bíbélì. Ǹjẹ́ kálukú wa ṣètò láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́? Ṣé à ń kà á pa pọ̀ nínú ìdílé wa? Ǹjẹ́ a ṣètò láti máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ojoojúmọ́ nínú ìdílé wa? Láfikún, ǹjẹ́ à ń gbìyànjú láti mọ àwọn àlàyé tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń ṣe bó ṣe ń jáde nínú àwọn ìwé tí wọ́n ń tẹ̀? (Mátíù 24:45) Ó yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ ká sì tún máa lo àwọn fídíò tí ètò Jèhófà ṣe, èyí tó ń fi Ìwé Mímọ́ tọ́ wa sọ́nà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, à ń fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò nìyẹn. Dídì tá a bá di òtítọ́ mú ṣinṣin yóò jẹ́ ká máa ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu kò sì ní jẹ́ ká ṣe ohun tí kò tọ́.

13. Báwo la ṣe lè dáàbò bo ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa?

13 Tí ọmọ ogun bá lo àwo ìgbàyà, á dáàbò bo àyà rẹ̀, ọkàn rẹ̀ àtàwọn ẹ̀yà ara míì tó ṣe pàtàkì gan-an. Bí Kristẹni ṣe lè dáàbò bo ọkàn ìṣàpẹẹrẹ rẹ̀, ìyẹn irú ẹni tó jẹ́ ní inú lọ́hùn-ún, ni pé kó nífẹ̀ẹ́ òdodo Ọlọ́run kó sì máa rí i pé òun ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo Jèhófà. Àwo ìgbàyà tẹ̀mí máa ń dáàbò bò wá, kì í jẹ́ ká bomi la Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bá a bá “kórìíra ohun búburú” tá a sì “nífẹ̀ẹ́ ohun rere,” a óò máa yí ẹsẹ̀ wa “kúrò nínú gbogbo ipa ọ̀nà búburú,” a ò ní rìn nínú rẹ̀.—Ámósì 5:15; Sáàmù 119:101.

14. Kí ló túmọ̀ sí pé ká ‘fi ohun ìṣiṣẹ́ ìhìn rere àlàáfíà wọ ẹsẹ̀ wa ní bàtà’?

14 Àwọn ọmọ ogun Róòmù sábà máa ń wọ bàtà tó lágbára nítorí ìrìn ọ̀nà jíjìn tí wọ́n máa ń rìn láwọn ojú ọ̀nà tó wà káàkiri ilẹ̀ ọba Róòmù, tó máa ń jẹ́ ọgọ́rọ̀ọ̀rún ibùsọ̀. Àwa Kristẹni ńkọ́? Kí ni ‘fífi ohun ìṣiṣẹ́ ìhìn rere àlàáfíà wọ ẹsẹ̀ wa ní bàtà’ túmọ̀ sí? (Éfésù 6:15) Ó túmọ̀ sí pé a ti gbára dì fún iṣẹ́. A ti múra tán láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní rẹ̀ bá yọ. (Róòmù 10:13-15) Fífi tá à ń fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù máa ń dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ “àwọn ètekéte” Sátánì, ìyẹn ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀.—Éfésù 6:11.

15. (a) Kí ló fi hàn pé apata ńlá ti ìgbàgbọ́ ṣe pàtàkì gan-an? (b) Àwọn “ohun ọṣẹ́ oníná” wo ló lè sọ ìgbàgbọ́ wa di èyí tí kò lágbára?

15 Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Lékè ohun gbogbo, ẹ gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́, èyí tí ẹ ó lè fi paná gbogbo ohun ọṣẹ́ oníná ti ẹni burúkú náà.” (Éfésù 6:16) Kí Pọ́ọ̀lù tó gbà wá nímọ̀ràn pé ká gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́, ó kọ́kọ́ sọ pé, “lékè ohun gbogbo.” Èyí fi hàn pé apata ńlá ti ìgbàgbọ́ ṣe pàtàkì gan-an ni. Ìgbàgbọ́ wa ò gbọ́dọ̀ jẹ́ ahẹrẹpẹ. Ńṣe ni ìgbàgbọ́ dà bí apata ńlá táwọn ológun máa ń lò, kì í jẹ́ kí “ohun ọṣẹ́ oníná” tó ń wá látọ̀dọ̀ Sátánì bà wá. Kí làwọn ohun ọṣẹ́ wọ̀nyí lè jẹ́ lónìí? Wọ́n lè jẹ́ ọ̀rọ̀ ìwọ̀sí tó máa ń dunni wọra, irọ́ tàbí ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ táwọn ọ̀tá àtàwọn apẹ̀yìndà máa ń sọ nípa wa láti fi sọ ìgbàgbọ́ wa di èyí tí kò lágbára. Àwọn “ohun ọṣẹ́” wọ̀nyí tún lè jẹ́ àwọn ohun tó máa ń dẹni wò láti di olùfẹ́ ọrọ̀, èyí tó lè mú ká máa fi gbogbo àkókò wa wá bí a ó ṣe ní ọ̀pọ̀ nǹkan, kódà ó lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í figa gbága pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ń fi ohun tí wọ́n ní ṣe ṣekárími. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kọ́lé àwòṣífìlà tí wọ́n sì ra ọkọ̀ bọ̀gìnnì, tàbí wọ́n ń fi ohun ọ̀ṣọ́ olówó ńlá tàbí aṣọ ìgbàlódé tí wọ́n rà ṣe ṣekárími. Ohun yòówù káwọn ẹlòmíì ṣe, a gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, tí ò ní jẹ́ kí “àwọn ohun ọṣẹ́ oníná” wọ̀nyí lè ṣe wá léṣe. Báwo la ṣe lè ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, kí la sì lè ṣe tí kò fi ní di èyí tí kò lágbára mọ́?—1 Pétérù 3:3-5; 1 Jòhánù 2:15-17.

16. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ tó lágbára?

16 Tá a bá ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé tá a sì ń gbàdúrà taratara, a óò sún mọ́ Ọlọ́run. A lè gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ wa lè lágbára, ó sì yẹ ká ṣe ohun tó bá àdúrà tá a gbà mu. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ a máa ń fara balẹ̀ múra Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ sílẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ká lè lóhùn sí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà? Ìgbàgbọ́ wa á máa lágbára sí i tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ìwé wa tó ń ṣàlàyé Bíbélì.—Hébérù 10:38, 39; 11:6.

17. Báwo la ṣe lè “tẹ́wọ́ gba àṣíborí ìgbàlà”?

17 Ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fi parí àpèjúwe tó ṣe nípa ìhámọ́ra tẹ̀mí ni pé: “Ẹ tẹ́wọ́ gba àṣíborí ìgbàlà, àti idà ẹ̀mí, èyíinì ni, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (Éfésù 6:17) Àṣíborí máa ń dáàbò bo orí ọmọ ogun àti ọpọlọ rẹ̀, èyí tó fi máa ń ronú kó tó ṣèpinnu. Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí táwa Kristẹni ní ṣe máa ń dáàbò bo ìrònú wa. (1 Tẹsalóníkà 5:8) Dípò tí a ó fi máa ronú nípa bá a ṣe máa lépa ohun táráyé ń lé àti bá a ṣe máa kó ọrọ̀ jọ, ńṣe ló yẹ ká máa ronú nípa ìrètí tí Ọlọ́run fi síwájú wa, bí Jésù ṣe ṣe.—Hébérù 12:2.

18. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká pa Bíbélì kíkà déédéé tì?

18 Èyí tó kẹ́yìn lára àwọn ohun tí ò ní jẹ́ kí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ lè darí wa ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì. Ìdí mìíràn nìyí tí kò fi yẹ ká pa Bíbélì kíkà déédéé tì. Tá a bá ní ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, ìyẹn ò ní jẹ́ kí irọ́ Sátánì, àwọn ìkéde èké táwọn ẹ̀mí èṣù wà nídìí rẹ̀, àti ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ tó ń jáde lẹ́nu àwọn apẹ̀yìndà, ṣì wá lọ́nà.

“Ẹ Máa Bá A Lọ ní Gbígbàdúrà ní Gbogbo Ìgbà”

19, 20. (a) Kí ló ń dúró de Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀? (b) Kí ló lè jẹ́ ká lágbára nípa tẹ̀mí?

19 Láìpẹ́, Ọlọ́run á pa Sátánì, àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ àti ayé búburú yìí run. Sátánì mọ̀ pé “àkókò kúkúrú” ló ṣẹ́ kù fóun. Ìdí nìyẹn tí inú fi ń bí i burúkú-burúkú tó sì ń gbógun ti “àwọn ẹni tí ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tí wọ́n sì ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù.” (Ìṣípayá 12:12, 17) Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká ṣe àwọn ohun tí ò ní jẹ́ kí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ lè borí wa.

20 Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká dúpẹ́ fún ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá pé ká gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀! Ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fi parí ìjíròrò rẹ̀ nípa ìhámọ́ra ogun tẹ̀mí ni pé: “Pẹ̀lú gbogbo oríṣi àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀, kí ẹ máa bá a lọ ní gbígbàdúrà ní gbogbo ìgbà nínú ẹ̀mí. Àti pé fún ète yẹn, ẹ wà lójúfò pẹ̀lú gbogbo àìyẹsẹ̀ àti pẹ̀lú ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ nítorí gbogbo ẹni mímọ́.” (Éfésù 6:18) Àdúrà máa jẹ́ ká lágbára nípa tẹ̀mí ká sì wà lójúfò. Ẹ jẹ́ ká fi ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù sọ́kàn ká sì máa gbàdúrà, nítorí èyí á ràn wá lọ́wọ́ láti borí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀.

Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?

• Báwo ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ṣe dẹni tó wà?

• Báwo ni Èṣù ṣe lágbára tó?

• Àwọn ohun wo la lè ṣe kí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ má bàa borí wa?

• Báwo la ṣe lè gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

“Àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ bẹ̀rẹ̀ sí kíyè sí àwọn ọmọbìnrin ènìyàn”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Ǹjẹ́ o lè sọ nǹkan mẹ́fà tó para pọ̀ jẹ́ ìhámọ́ra ogun tẹ̀mí wa?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Báwo ni ṣíṣe àwọn ohun wọ̀nyí ò ṣe ní jẹ́ kí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ lè borí wa?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́