Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Mélòó lára irú kọ̀ọ̀kan àwọn ẹranko tó mọ́ ni Nóà mú wọ ọkọ̀ áàkì? Ṣé méje ni, àbí abo méje àti akọ méje?
Lẹ́yìn tí Nóà parí kíkan ọkọ̀ áàkì, Jèhófà sọ fun un pé: “Lọ, ìwọ àti gbogbo agbo ilé rẹ, sínú áàkì náà, nítorí ìwọ ni mo rí pé ó jẹ́ olódodo níwájú mi nínú ìran yìí. Nínú gbogbo ẹranko tí ó mọ́, kí ìwọ mú méje-méje sọ́dọ̀ ara rẹ, àgbà-akọ àti abo rẹ̀; àti méjì péré láti inú gbogbo ẹranko tí kò mọ́, àgbà-akọ àti abo rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 7:1, 2) Àwọn Bíbélì kan, irú bíi The New English Bible àti The New Jerusalem Bible àti Tanakh—The Holy Scriptures, túmọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò níbí yìí ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ sí “akọ méje àti abo méje.”
Ṣùgbọ́n ohun tí ọ̀rọ̀ Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ tó wà nínú ẹsẹ yìí túmọ̀ sí gan-an ni “méje-méje.” (Jẹ́nẹ́sísì 7:2) Nínú èdè Hébérù, pé wọ́n sọ iye kan lẹ́ẹ̀mejì ò túmọ̀ sí pé èèyàn ní láti rò ó pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, 2 Sámúẹ́lì 21:20 sọ pé “ọkùnrin kan báyìí wà tí ó tóbi lọ́nà àrà ọ̀tọ̀,” pé ó “ní ìka mẹ́fà ní ọwọ́ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ mẹ́fà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan.” Nínú èdè Hébérù tí wọ́n fi kọ ẹsẹ yìí ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ńṣe ni wọ́n pè é ní ìka “mẹ́fà-mẹ́fà.” Àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ìka méjìlá ló wà ní ọwọ́ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan àti ẹsẹ̀ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Nínú ìlànà èdè Hébérù, ńṣe ni bí ẹsẹ yìí ṣe sọ iye yẹn lẹ́ẹ̀mejì wulẹ̀ fi hàn pé ìka mẹ́fà ló wà ní ọwọ́ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan àti ìka mẹ́fà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan.
Nítorí náà, iye náà “méje-méje” tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 7:2 kò túmọ̀ sí akọ méje àti abo méje, ìyẹn mẹ́rìnlá, bí iye náà “méjì-méjì” tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 7:9, 15 kò ṣe túmọ̀ sí akọ méjì àti abo méjì, ìyẹn mẹ́rin. Èyí fi hàn pé “méje-méje” ni Nóà mú nínú àwọn ẹranko tó mọ́, ó sì mú “méjì péré,” ìyẹn méjì-méjì, nínú àwọn ẹranko tí kò mọ́.
Àmọ́, kí ni awẹ́ gbólóhùn náà, “àgbà-akọ àti abo rẹ̀,” tí Jẹ́nẹ́sísì 7:2 mẹ́nu kàn tẹ̀ lé iye náà “méje-méje” fi hàn? Àwọn kan rò pé ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé Ọlọ́run ní kí Nóà mú akọ méje àti abo méje lára àwọn ẹranko tó mọ́ kí wọ́n lè mú irú ọmọ jáde. Àmọ́ kì í ṣe nítorí káwọn ẹranko tó mọ́ lè mú irú ọmọ jáde nìkan ni Nóà fi mú wọn wọ ọkọ̀ áàkì. Jẹ́nẹ́sísì 8:20 sọ fún wa pé nígbà tí Nóà jáde kúrò nínú ọkọ̀ áàkì, ó “bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ pẹpẹ kan fún Jèhófà, ó sì mú díẹ̀ lára gbogbo ẹranko tí ó mọ́ àti lára gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń fò tí ó mọ́, ó sì rú ọrẹ ẹbọ sísun lórí pẹpẹ náà.” Bó ṣe jẹ́ pé méje-méje lára àwọn ẹranko tó mọ́ ni Nóà mú wọnú ọkọ̀, á lè fi ìkeje rúbọ, á wá fi mẹ́fà sílẹ̀, ìyẹn akọ mẹ́ta àti abo mẹ́ta, láti bímọ kí irú wọn lè wà lórí ilẹ̀ ayé.