ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 3/15 ojú ìwé 32
  • “Ó Sáà Mú Kí A Wá”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ó Sáà Mú Kí A Wá”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 3/15 ojú ìwé 32

“Ó Sáà Mú Kí A Wá”

WỌN kì í fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ṣíṣàlejò láwọn orílẹ̀-èdè tó wà lápá ìlà oòrùn ayé. Bí àpẹẹrẹ, nílẹ̀ Íńdíà, bàbá, ìyá àtàwọn ọmọ lè yááfì oúnjẹ wọn torí kí àlejò tó dé láìròtẹ́lẹ̀ lè rí oúnjẹ jẹ. Lórílẹ̀-èdè Iran, àwọn ìyàwó ilé máa ń kó ọ̀pọ̀ oúnjẹ sínú ẹ̀rọ amú-nǹkan-tutù nítorí àlejò tó lè dé bá wọn láìròtẹ́lẹ̀.

Ó hàn gbangba pé ọ̀pọ̀ àwọn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn jẹ́ ọ̀làwọ́ bíi tàwọn tá a sọ yìí. Ọ̀kan pàtàkì lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Lìdíà tó ṣeé ṣe kó jẹ́ aláwọ̀ṣe Júù, tó ń gbé ní ìlú Fílípì, ìyẹn ìlú tó gbawájú lágbègbè Makedóníà. Lọ́jọ́ sábáàtì kan, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò rí Lìdíà àtàwọn obìnrin kan tí wọ́n kóra jọ níbi odò kan nítòsí ìlú Fílípì. Pọ́ọ̀lù bá àwọn obìnrin náà sọ̀rọ̀, Jèhófà sì ṣí ọkàn Lìdíà kó lè fiyè sí nǹkan tí Pọ́ọ̀lù ń sọ. Bóun àtàwọn ará ilé rẹ̀ ṣe dẹni tó ṣèrìbọmi nìyẹn. Lẹ́yìn ìrìbọmi náà, ó bẹ Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò pé: “Bí ẹ bá kà mí sí olùṣòtítọ́ sí Jèhófà, ẹ wọ ilé mi.” Lúùkù tó bá Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò nígbà yẹn sọ pé: “Ó sáà mú kí a wá.”—Ìṣe 16:11-15.

Bíi ti Lìdíà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní máa ń ṣe àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn tó bá wá sọ́dọ̀ wọn lálejò, irú bí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àti ìyàwó wọn. Wọ́n máa ń rí i pé àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣe lálejò wá sọ́dọ̀ àwọn ṣáá ni. Àwọn àlejò máa ń gbádùn ara wọn, àwọn tó ń ṣàlejò pẹ̀lú sì máa ń jàǹfààní látinú ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró tí wọ́n bá jọ sọ àti ìfararora tí wọ́n jọ ní. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ọlọ́rọ̀, síbẹ̀, wọ́n máa ń ṣe “aájò àlejò.” (Róòmù 12:13; Hébérù 13:2) Ìwà ọ̀làwọ́ wọn máa ń mú kí wọ́n láyọ̀. Dájúdájú, òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́