Ǹjẹ́ O Rántí?
Ǹjẹ́ o gbádùn àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:
• Kí la lè rí kọ́ látinú àpèjúwe tí Jésù sọ nípa ẹni tí àlejò dé bá tó lọ tẹpẹlẹ mọ́ bíbéèrè nǹkan lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀? (Lúùkù 11:5-10)
Àpèjúwe tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká mọ irú ẹ̀mí tó yẹ ká ní tá a bá ń gbàdúrà. Ńṣe ló yẹ ká tẹpẹlẹ mọ́ àdúrà gbígbà tàbí ká máa bá a nìṣó ní bíbéèrè ohun tá a fẹ́, pàápàá jù lọ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. (Lúùkù 11:11-13)—12/15, ojú ìwé 20 sí 22.
• Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú àpèjúwe tí Jésù sọ nípa opó àti onídàájọ́ kan? (Lúùkù 18:1-8)
Àpèjúwe náà jẹ́ ká mọ̀ pé àdúrà ṣe pàtàkì. Jèhófà ò dà bí onídàájọ́ yẹn, torí pé olódodo ni Jèhófà, ó sì fẹ́ láti ràn wá lọ́wọ́. Ẹ̀kọ́ míì ni pé, ó yẹ ká ní ìgbàgbọ́ bíi ti opó inú àpèjúwe yẹn.—12/15, ojú ìwé 26 sí 28.
• Kí nìdí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ fáwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì pé kí wọ́n “gbòòrò síwájú”? (2 Kọ́ríńtì 6:11-13)
Ó dà bíi pé àwọn kan nínú ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì ò mọyì àwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ bíi tiwọn, ara wọn ò yá mọ́ọ̀yàn, wọn ò sì lẹ́mìí ọ̀làwọ́. Ó yẹ ká sapá láti fi hàn pé a mọyì àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, ká tiẹ̀ gbìyànjú láti máa ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun.—1/1, ojú ìwé 9 sí 11.
• Kí ni èdìdì tí Ìṣípayá 7:3 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
Nígbà tí Ọlọ́run bá fi ẹ̀mí mímọ́ yan Kristẹni kan, ó fi èdìdì ti ìṣáájú dì í nìyẹn. Àmọ́ èdìdì tí Ìṣípayá 7:3 sọ jẹ́ èdìdì ìkẹyìn èyí tí yóò wáyé lẹ́yìn tí irú ẹni àmì òróró bẹ́ẹ̀ ti fi hàn láìkù síbì kankan pé òun jẹ́ adúróṣinṣin.—1/1, ojú ìwé 30 àti 31.
• Kí làwọn òbí lè rí kọ́ látinú ìtàn tí Bíbélì sọ nípa Sámúẹ́lì?
Ẹ̀kọ́ kan ni pé, àwọn òbí ní láti fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ ọmọ wọn, gẹ́gẹ́ bí àwọn òbí Sámúẹ́lì ṣe ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ káwọn òbí fún ọmọ wọn níṣìírí láti fi ìgbésí ayé wọn ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.—1/15, ojú ìwé 16.
• Báwo la ṣe lè fi hàn pé a láyọ̀ láti dúró de Jèhófà?
À ń ‘dúró de ọjọ́ Jèhófà,’ a sì ń retí àtirí ìtura nígbà tó bá pa gbogbo àwọn tó jẹ́ aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run run. (2 Pétérù 3:7, 12) Ó wà lọ́kàn Jèhófà láti fòpin sí gbogbo ohun tó jẹ́ ibi, àmọ́ ìdí tí kò fi tíì ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, ó fẹ́ gba àwọn Kristẹni là lọ́nà tí yóò fògo fún orúkọ rẹ̀. Ó yẹ kí ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà mọ àkókò tó tọ́ láti gbé ìgbésẹ̀, àti pé ní báyìí ná, ńṣe ló yẹ ká máa fìtara ṣe ohun tó máa yin Ọlọ́run lógo. (Sáàmù 71:14, 15)—3/1, ojú ìwé 17 àti 18.
• Mélòó lára irú kọ̀ọ̀kan àwọn ẹranko tó mọ́ ni Nóà mú wọ ọkọ̀ áàkì? Ṣé méje ni, àbí abo méje àti akọ méje?
Jèhófà sọ fún Nóà pé, “kí ìwọ mú méje-méje sọ́dọ̀ ara rẹ” látinú gbogbo ẹranko tí ó mọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 7:1, 2) Ohun tí ọ̀rọ̀ Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ tó wà nínú ẹsẹ yìí túmọ̀ sí ni “méje-méje.” Nínú èdè Hébérù, pé wọ́n sọ iye yẹn lẹ́ẹ̀mejì ò túmọ̀ sí pé ó jẹ́ akọ méje abo méje, gẹ́gẹ́ bí àwọn Bíbélì kan ṣe túmọ̀ rẹ̀. Ó hàn gbangba pé Nóà mú méje lára irú kọ̀ọ̀kan àwọn ẹranko tó mọ́ wọ ọkọ̀ áàkì, ìyẹn akọ mẹ́ta abo mẹ́ta, tí àròpọ̀ rẹ̀ jẹ́ mẹ́fà àti ẹranko keje tó lè fi rúbọ tó bá yá. (Jẹ́nẹ́sísì 8:20)—3/15, ojú ìwé 31.
• Kí nìdí tó fi yẹ káwọn Kristẹni “fẹ̀sọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò” bí ìgbàgbọ́ àwọn alàgbà, ìyẹn àwọn tó ń mú ipò iwájú, ti rí?
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní ká “fẹ̀sọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò,” tàbí ká fara balẹ̀ kíyè sí àbájáde ìṣòtítọ́ àwọn alàgbà ká sì tẹ̀ lé irú àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀. (Hébérù 13:7) Ìdí kan tá a fi ń ṣe èyí ni pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ká ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí mìíràn ni pé a rí i pé ire Ìjọba Ọlọ́run àti ire ti àwa fúnra wa jẹ àwọn alàgbà lógún.—4/1, ojú ìwé 28.