ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 4/15 ojú ìwé 16-18
  • Pápá Tó Ti ‘Funfun Tó Láti Kórè’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Pápá Tó Ti ‘Funfun Tó Láti Kórè’
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Fífi Èdè Ìlú Wọn Wàásù
  • Ó “Ti Funfun fún Kíkórè”
  • Gbígbé Ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Jáde ní Èdè Wayuunaiki
  • Àwọn Èèyàn Ń Di Ẹlẹ́rìí
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 4/15 ojú ìwé 16-18

Pápá Tó Ti ‘Funfun Tó Láti Kórè’

Ìpẹ̀kun ìhà àríwá Amẹ́ríkà ti Gúúsù ni ilẹ̀ Guajira wà. Apá kan rẹ̀ wà ní àríwá orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà, ó sì wá gbòòrò dé àríwá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà. Olórí ìṣòro wọn níbẹ̀ ni pé oòrùn máa ń mú gan-an, ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan lòjò sì máa ń rọ̀. Bí ajere ni ibẹ̀ máa ń gbóná. Àmọ́ pẹ̀lú ìyẹn náà, àwọn ará ibẹ̀ ṣì máa ń ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ lójú méjèèjì, wọ́n sì ń kórè ọ̀pọ̀ nǹkan. Afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ wá látinú òkun nígbà gbogbo àti afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ wá láti apá àríwá ìlà oòrùn ló ń gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ ooru. Òun ló ń jẹ́ káwọn tó bá rìnrìn àjò afẹ́ wá síbẹ̀ gbádùn wíwo ojú ilẹ̀ tó fani mọ́ra àti etíkun tó wuni.

Ẹ̀YÀ Íńdíà tí wọ́n ń pè ní Wayuu làwọn èèyàn ilẹ̀ Guajira tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Wọ́n tó nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [305,000], àwọn tó sì ń gbé lórílẹ̀-èdè Kòlóńbíà lára wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́fà ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [135,000]. Ẹ̀yà Wayuu ti ń gbé nílẹ̀ Guajira tipẹ́tipẹ́ ṣáájú káwọn ará ilẹ̀ Sípéènì tó wá gba àkóso ibẹ̀.

Iṣẹ́ àgbẹ̀ àti ẹran sísìn ni olórí iṣẹ́ àwọn Wayuu. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń ṣe iṣẹ́ ẹja pípa, òwò sì máa ń gbé wọn láti ilẹ̀ wọn lọ sí orílẹ̀-èdè míì. Àwọn obìnrin wọn máa ń hun onírúurú nǹkan tó láwọ̀ mèremère, èyí táwọn tó gbafẹ́ wá síbẹ̀ máa ń rà gan-an.

Àwọn èèyàn mọ ẹ̀yà Wayuu mọ́ ẹ̀mí àlejò ṣíṣe, wọ́n sì mọ̀ pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́ èèyàn. Àmọ́, àkókò tá a wà yìí tó jẹ́ “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” kò ṣàì kan àwọn náà. (2 Tímótì 3:1) Ọ̀kan lára ìṣòro ńlá tí wọ́n ní ni pé tálákà ni wọ́n. Èyí sì ti kó wọn sí ìṣòro mìíràn, irú bí àìrówó rán ọmọ nílé ìwé, àìrówó ra oúnjẹ aṣaralóore fáwọn ọmọ wọn kéékèèké, àìrówó tọ́jú àìsàn, jíjẹ́ tí wọ́n sì jẹ́ tálákà láwọn ibì kan ti mú káwọn ọmọ wọn ya ìpáǹle.

Ọjọ́ pẹ́ táwọn olórí ṣọ́ọ̀ṣì ti máa ń rán àwọn míṣọ́nnárì wọn lọ láti máa gbé láàárín àwọn Wayuu yìí. Ìyẹn ló fà á tó fi jẹ́ pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ló ń darí ọ̀pọ̀ jù lọ ilé ìwé tí wọ́n ti ń kọ́ni níṣẹ́ olùkọ́ àtàwọn ilé ìwé tó ní ibùgbé fáwọn akẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn Wayuu wá gba àṣà àwọn tó pera wọn ní Kristẹni, irú bí àṣà jíjúbà ère àti ṣíṣe ìrìbọmi fọ́mọ ọwọ́. Àmọ́, wọn ò jáwọ́ nínú ìgbàgbọ́ àtàwọn ààtò kan tó jẹ́ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí wọ́n bá lọ́wọ́ àwọn babańlá wọn.

Tá a bá ní ká wò ó lápapọ̀, ẹ̀yà Wayuu ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí ń kọ́ àwọn èèyàn. Ní nǹkan bí ọdún 1980, méje péré làwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ ẹ̀yà Wayuu ní ilẹ̀ Guajira, mẹ́ta lára wọn ń gbé nílùú Ríohacha tí í ṣe olú ìlú ilẹ̀ náà. Yàtọ̀ sáwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí tó jẹ́ ọmọ ibẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí míì tí iye wọn jẹ́ ogún tún wà níbẹ̀ tí wọ́n ń fi èdè Sípéènì wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.

Fífi Èdè Ìlú Wọn Wàásù

Yàtọ̀ sédè ìlú wọn, ìyẹn Wayuunaiki, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó jẹ́ Wayuu tó wà nílùú Ríohacha lè sọ èdè Sípéènì táátààtá. Níbẹ̀rẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù táwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe níbẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ láṣeyọrí. Ńṣe làwọn ọmọ ibẹ̀ máa ń fẹ́ sá fáwọn tí wọ́n máa ń pè ní arijunas, ìyẹn àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà Wayuu. Táwọn Ẹlẹ́rìí bá wàásù délé wọn, èdè ìlú wọn ni ọ̀pọ̀ jù lọ wọn máa ń sọ sáwọn Ẹlẹ́rìí náà, wọn ò ní sọ èdè Sípéènì táwọn Ẹlẹ́rìí náà gbọ́. Làwọn Ẹlẹ́rìí náà á bá kọjá sílé tó kàn.

Àmọ́, níparí ọdún 1994, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí tó wà nílẹ̀ Kòlóńbíà rán àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe lọ síjọ Ríohacha. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà náà ní kí Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ ẹ̀yà Wayuu kọ́ àwọn lédè Wayuunaiki. Táwọn aṣáájú-ọ̀nà wọ̀nyí bá ti há ìwọ̀nba ọ̀rọ̀ díẹ̀ tí wọ́n lè fi wàásù sórí, wọn á lọ fi wàásù, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi rí ìyàtọ̀ ńlá nínú báwọn èèyàn ṣe ń dáhùn sí ìwàásù wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé táátààtá làwọn aṣáájú-ọ̀nà náà ń sọ èdè Wayuunaiki, ó máa ń ya àwọn tí wọ́n ń wàásù fún lẹ́nu pé wọ́n lè sọ èdè náà, wọ́n sì máa ń fẹ́ gbọ́rọ̀ wọn. Nígbà míì, àwọn onílé tiẹ̀ máa ń fi ìwọ̀nba èdè Sípéènì tí wọ́n gbọ́ bá wọn fọ̀rọ̀ wérọ̀.

Ó “Ti Funfun fún Kíkórè”

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọlẹ́yìn wé iṣẹ́ oko, àfiwé náà sì yé àwọn tó jẹ́ ẹ̀yà Wayuu dáadáa torí pé àgbẹ̀ ni wọ́n. (1 Kọ́ríńtì 3:5-9) A lè sọ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ pé pápá àwọn ẹ̀yà Wayuu “ti funfun fún kíkórè.”—Jòhánù 4:35.

Ọkùnrin Íńdíà kan tó jẹ́ ẹ̀yà Wayuu ń gbé nílùú Manaure. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Neil. Àtìgbà tí wọ́n ti bí i ló ti ní àìsàn kan lára. Ó ní Ọlọ́run ló fà á tóun fi níṣòro yìí, ìyẹn sì mú kó bọkàn jẹ́ gan-an débi pé, lọ́jọ́ kan, ó fẹ́ láti para ẹ̀. Ẹlẹ́rìí kan tí iṣẹ́ rẹ̀ mú kó máa lọ sí onírúurú ìlú, kó sì máa lọ láti ilé kan sí òmíràn lo àǹfààní yẹn láti wàásù fún Neil nípa Ìjọba Jèhófà. Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá péré ni Neil lákòókò yẹn. Nígbà tí Ẹlẹ́rìí náà rí i pé Neil nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú Neil dùn gan-an nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà onífẹ̀ẹ́, ìyẹn sì mú kó gbà pé Ọlọ́run kọ́ ni okùnfà ìṣòro òun. Inú rẹ̀ tún dùn gan-an nígbà tó kà nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa sọ ayé di Párádísè níbi tí kò ní sí àìsàn kankan mọ́.—Aísáyà 33:24; Mátíù 6:9, 10.

Lákòókò tá à ń wí yìí, ìjà kan wà láàárín ẹbí Neil àti ìdílé mìíràn. Àwọn ẹbí Neil wá lọ ṣe ètùtù láti fi dáàbò bo ara wọn. Neil sọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Ẹ̀rù kọ́kọ́ ń bà mí láti sọ àwọn ohun tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà gbọ́ fáwọn èèyàn mi, àgàgà àwọn àgbà ẹbí wa tí wọ́n jẹ́ ẹni pàtàkì.” Inú bí àwọn òbí Neil nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Neil ò fẹ́ bá wọn lọ́wọ́ sí àṣà tó la ìbẹ́mìílò lọ àti pé kò fara mọ́ àwọn ìgbàgbọ́ wọn tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Neil bá mú ọ̀nà ìlú Ríohacha pọ̀n, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé níbẹ̀. Nígbà tó yá, ó ṣèrìbọmi. Lọ́dún 1993, ó di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó sì di aṣáájú-ọ̀nà déédéé lọ́dún mẹ́ta lẹ́yìn ìgbà yẹn. Lọ́dún 1997, ó di alàgbà nínú ìjọ. Nígbà tó sì fi máa di ọdún 2000, ó tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ nípa dídi aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.

Àpẹẹrẹ mìíràn ni ti Teresa tó jẹ́ ẹ̀yà Wayuu. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ obìnrin yìí lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Daniel tóun àtiẹ̀ jọ ń gbé tó sì bímọ fún máa ń fi í ṣẹlẹ́yà, ó tún máa ń lu òun àtàwọn ọmọ wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Daniel gbà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé káwọn Ẹlẹ́rìí máa kọ́ òun náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bíi ti Teresa, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń mutí àmuyíràá pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀. Nígbà míì, wọ́n lè yíde ọtí lọ fún ọjọ́ mẹ́rin sí márùn-ún. Ó wá kó àwọn ọmọ ẹ̀ àti ìyá wọn sínú ìṣẹ́. Àmọ́ ṣá, Teresa ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ láìjáwọ́, ó sì ń lọ síìpàdé ìjọ. Èyí jẹ́ kí Daniel rí i pé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe pàtàkì. Lákòókò yẹn, ọkàn lára àwọn ọmọ wọn ṣubú lu kẹ́tùrù omi tó ń hó yaya lórí iná, omi gbígbóná sì jó ọmọ náà débi pé ó kú. Yàtọ̀ sí ọ̀fọ̀ ọmọ tó ṣẹ Teresa, àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ tún kógun tì í láti mú kó lọ́wọ́ sí ààtò ìsìnkú tí Ìwé Mímọ́ lòdì sí.

Lákòókò lílekoko yẹn, àwọn méjèèjì rí ìrànlọ́wọ́ àti ìtùnú lọ́dọ̀ àwọn ará tó wà láwọn ìjọ itòsí wọn. Kódà lẹ́yìn ìsìnkú ọmọ wọn, àwọn ará ìjọ èdè Wayuunaiki ò yéé lọ sílé wọn láti tù wọ́n nínú. Daniel rí i pé àwọn ará nífẹ̀ẹ́ àwọn gan-an, èyí sì mú kó tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó jáwọ́ nínú ọtí mímu, kò sì lu Teresa mọ́. Daniel ṣẹ̀ṣẹ̀ wá fẹ́ Teresa níṣulọ́kà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹpá mọ́ṣẹ́ kó lè gbọ́ bùkátà aya àtàwọn ọmọ rẹ̀. Àwọn méjèèjì tẹ̀ síwájú nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, wọ́n sì ṣèrìbọmi lọ́dún 2003. Kódà àwọn alára ń kọ́ àwọn mélòó kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Teresa máa ń wàásù fáwọn ìbátan rẹ̀, èyí sì ti mú káwọn ìbátan rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí báyìí. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n Daniel obìnrin ti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n ẹ̀ méjì míì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́, wọ́n sì ń lọ sípàdé ìjọ. Ẹ̀gbọ́n ọkọ Teresa, tó pàdánù ọmọkùnrin rẹ̀ nínú jàǹbá kan, àti ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ gbà pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Gbígbé Ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Jáde ní Èdè Wayuunaiki

Lọ́dún 1998, ètò Ọlọ́run ṣe ìwé pẹlẹbẹ Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!a lédè Wayuunaiki. Ìwé yìí ti ran àwọn Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́ gan-an nínú mímú káwọn tó jẹ́ ẹ̀yà Wayuu di Ẹlẹ́rìí, àti nínú ṣíṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ́dún 2003, a ṣètò pé ká dá arákùnrin mélòó kan lẹ́kọ̀ọ́ láti máa túmọ̀ ìwé àwa Ẹlẹ́rìí sí èdè Wayuunaiki. Iṣẹ́ àṣekára táwọn atúmọ̀ èdè tó wà nílùú Ríohacha ṣe mú ká tẹ ọ̀pọ̀ ìwé pẹlẹbẹ jáde, èyí sì mú kí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ èdè Wayuunaiki di Ẹlẹ́rìí.

Nígbà ìpàdé àgbègbè, wọ́n máa ń túmọ̀ díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá sọ lórí pèpéle sí èdè Wayuunaiki, wọ́n sì ti ń ṣe èyí láti ọdún 2001. Ìṣírí ló máa ń jẹ́ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tí wọ́n bá ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ náà ní èdè wọn. Àwọn ará nírètí pé láìpẹ́, a ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi èdè Wayuunaiki ṣe àwòkẹ́kọ̀ọ́ tó dá lórí ìtàn Bíbélì.

Àwọn Èèyàn Ń Di Ẹlẹ́rìí

Ìlú kan wà ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún kìlómítà sí apá àríwá ìlà oòrùn ìlú Ríohacha, wọ́n ń pè é ní Uribia. Akéde mẹ́rìndínlógún ló wà nínú ìjọ tó ń sọ èdè Wayuunaiki níbẹ̀, ọ̀pọ̀ lára wọn sì ń sapá gidigidi láti wàásù fáwọn ẹ̀yà Íńdíà tó wà ní ìgbèríko wọn. Ọ̀kan lára àwọn alàgbà ìjọ náà ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà kan tí wọ́n lọ wàásù ní àgbègbè yẹn, ó ní: “A lọ sí àgbàlá ńlá kan tó ní nǹkan bí ilé méjìlá tí òrùlé wọn ò ga, tí fèrèsé wọn ò sì tó nǹkan kan. Àtíbàbà wà níwájú ilé kọ̀ọ̀kan, ohun tí wọ́n ń pè ní yotojolo, ìyẹn ibi tó le nínú igi ọrọ́, ni wọ́n fi kọ́ àwọn àtíbàbà náà. Ibẹ̀ ni ìdílé kọ̀ọ̀kan àti àlejò tí wọ́n bá ní máa ń jókòó sí nígbà tí oòrùn bá mú janjan. Inú wa dùn pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń gbé níbẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù wa, a sì ṣètò láti padà lọ sọ́dọ̀ wọn, ká lè máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tá a débẹ̀, a rí i pé ọ̀pọ̀ lára wọn ni ò kàwé. Wọ́n sọ fún wa pé ilé ìwé kan wà tí wọ́n ti pa tì nítorí pé kò sówó. Ẹni tó ń ṣe kòkáárí ilé ìwé náà yọ̀ǹda ọ̀kan lára yàrá ìkàwé fún wa ká máa lò ó fún ilé ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà àti fún ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn mẹ́fà tó jẹ́ ẹ̀yà Wayuu ló ti mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà, wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn. Inú wa dùn sí báwọn èèyàn ibẹ̀ ṣe mọyì ẹ̀kọ́ Bíbélì, ìyẹn ló mú ká ṣètò láti máa ṣèpàdé ìjọ nínú àgbàlá ńlá náà.”

Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tí kì í ṣe ẹ̀yà Wayuu ti kọ́ èdè Wayuunaiki, a sì mọrírì ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ń ṣe. Ìjọ mẹ́jọ tí wọ́n ń sọ èdè Wayuunaiki àti àwùjọ méjì tí kò tíì di ìjọ ló wà ní ilẹ̀ Guajira báyìí.

Ó hàn gbangba pé Jèhófà ń bù kún ìsapá àwọn ará yìí. Ó dájú pé iṣẹ́ ìwàásù ṣì máa ṣàṣeyọrí gan-an láàárín àwọn ẹ̀yà Wayuu. A nírètí pé lọ́jọ́ iwájú ìtẹ̀síwájú yóò wà gan-an nítorí pé àwọn tí ohun tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn ń di ọmọlẹ́yìn. Àdúrà wa sì ni pé kí Jèhófà túbọ̀ rán àwọn òjíṣẹ́ sí pápá yìí tó “ti funfun fún kíkórè.”—Mátíù 9:37, 38.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí.

[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 16]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

FẸNẸSÚÉLÀ

KÒLÓŃBÍÀ

LA GUAJIRA

Manaure

Ríohacha

Uribia

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 16]

Abúlé Wayuu tó wà nísàlẹ̀: Victor Englebert

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́