ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 9/15 ojú ìwé 10-15
  • “Ẹ Máa Bá a Lọ Ní Gbígba Agbára Nínú Olúwa”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Máa Bá a Lọ Ní Gbígba Agbára Nínú Olúwa”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • À Ń Bá Agbo Ọmọ Ogun Ẹ̀mí Burúkú Ja Gídígbò
  • A Mọ Ètekéte Sátánì
  • Ó Yẹ Ká Dúró Gbọn-in Gbọn-in
  • A Nílò “Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìhámọ́ra Ogun Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run”
  • Kí La Lè Ṣe Táwọn Ẹ̀mí Èṣù Ò Fi Ní Lè Borí wa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ẹ Kọ Ojú Ìjà Sí Sátánì, Yóò Sì Sá!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • “Ẹ Gbé Gbogbo Ìhámọ́ra Ọlọrun Wọ̀”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • “Ẹ Gbé Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìhámọ́ra Ogun Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Wọ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 9/15 ojú ìwé 10-15

“Ẹ Máa Bá a Lọ Ní Gbígba Agbára Nínú Olúwa”

“Ẹ máa bá a lọ ní gbígba agbára nínú Olúwa àti nínú agbára ńlá okun rẹ̀.”—Éfésù 6:10.

1. (a) Ìjà àrà ọ̀tọ̀ wo ló wáyé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọdún sẹ́yìn? (b) Kí ló jẹ́ kí Dáfídì borí?

NÍ NǸKAN bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] ọdún sẹ́yìn, ọkùnrin méjì látinú ẹgbẹ́ ológun méjì tó fẹ́ bára wọn jà dojú kọra wọn. Èyí tó kéré jù lára àwọn méjèèjì yìí jẹ́ ọ̀dọ́mọdé olùṣọ́ àgùntàn, orúkọ rẹ̀ sì ni Dáfídì. Alátakò rẹ̀ tó fẹ́ bá jà ni Gòláyátì, ṣẹ̀rùbàwọ́n, ọkùnrin fìrìgbọ̀n. Ìhámọ́ra rẹ̀ wúwo gan-an, ó wúwo ju àpò sìmẹ́ǹtì kan lọ. Ó gbé ọ̀kọ̀ àti idà ńlá dání. Ṣùgbọ́n ẹ̀wù fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ lásán ni Dáfídì wọ̀, kò tiẹ̀ dìhámọ́ra kankan àfi kànnàkànnà tó mú dání. Ni orí Gòláyátì, òmìrán yìí, bá gbóná pé wọ́n rán ọmọ kékeré lásánlàsàn wá bá òun jà, wọ́n fẹ̀gbin lọ òun. (1 Sámúẹ́lì 17:42-44) Lójú àwọn òǹwòran ìhà méjèèjì, bíi pé èkúté fẹ́ bá ológbò jà lọ̀ràn Dáfídì rí. Àmọ́ o, akọni a máa kàgbákò lójú ìjà nígbà míì. (Oníwàásù 9:11) Bẹ́ẹ̀ ló di pé Dáfídì borí, torí pé agbára Jèhófà ló gbẹ́kẹ̀ lé tó fi jà. Dáfídì ní: “Ti Jèhófà ni ìjà ogun náà.” Bíbélì sọ pé: “Dáfídì, pẹ̀lú kànnàkànnà àti òkúta, lágbára ju Filísínì náà.”—1 Sámúẹ́lì 17:47, 50.

2. Irú ogun wo làwọn Kristẹni ń jà?

2 Àwọn Kristẹni kì í ja ogun nípa tí ara. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀mí àlàáfíà ni wọ́n ń fi bá gbogbo èèyàn gbé, síbẹ̀, wọ́n ń jagun nípa tẹ̀mí, àwọn ọ̀tá alágbára kan ni wọ́n sì ń bá jà. (Róòmù 12:18) Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe ogun tí gbogbo Kristẹni ń jà yìí nínú orí tó gbẹ̀yìn lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Éfésù. Ó kọ̀wé pé: “Àwa ní gídígbò kan, kì í ṣe lòdì sí ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, bí kò ṣe lòdì sí àwọn alákòóso, lòdì sí àwọn aláṣẹ, lòdì sí àwọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yìí, lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.”—Éfésù 6:12.

3. Gẹ́gẹ́ bí Éfésù 6:10 ṣe wí, kí la ní láti ṣe ká lè rí i dájú pé a ṣàṣeyọrí?

3 Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ni “àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú” náà, ńṣe ni wọ́n sì ń fẹ́ láti ba àjọse wa pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run jẹ́. Níwọ̀n bí wọ́n ti lágbára jù wá lọ fíìfíì, ọ̀ràn wa ò yàtọ̀ sí ti Dáfídì, torí pé a ò lè ṣàṣeyọrí láìjẹ́ pé a gbára lé agbára Ọlọ́run. Ìyẹn gan-an ni Pọ́ọ̀lù fi rọ̀ wá pé ká “máa bá a lọ ní gbígba agbára nínú Olúwa àti nínú agbára ńlá okun rẹ̀.” (Éfésù 6:10) Bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe parí ìmọ̀ràn yìí tán ló ṣàpèjúwe àwọn ìpèsè tẹ̀mí àtàwọn ànímọ́ táwa Kristẹni ní láti ní ká lè ja àjàṣẹ́gun.—Éfésù 6:11-17.

4. Kókó méjì pàtàkì wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 Ẹ jẹ́ ká wá ṣàyẹ̀wò ohun tí Ìwé Mímọ́ wí nípa àwọn ohun tí ọ̀tá wa fi ń ṣe agbára àtàwọn ètekéte rẹ̀. Lẹ́yìn náà, a óò wá wo ọgbọ́n tá a lè dá láti fi dáàbò bo ara wa. Ó dájú pé bá a bá ti ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Jèhófà, àwọn ọ̀tá wa ò ní rí wa gbéṣe.

À Ń Bá Agbo Ọmọ Ogun Ẹ̀mí Burúkú Ja Gídígbò

5. Báwo ni ọ̀rọ̀ náà “gídígbò” tí Éfésù 6:12 lò ṣe jẹ́ ká fòye mọ ọgbọ́n tí Sátánì ń ta?

5 Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé “àwa ní gídígbò kan . . . lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.” Kò sí àní-àní pé Sátánì Èṣù, “olùṣàkóso àwọn ẹ̀mí èṣù,” ni olórí àwọn ẹ̀mí burúkú. (Mátíù 12:24-26) Bíbélì pe ìjà tá à ń bá wọn jà yìí ní “gídígbò,” ìyẹn ìjàkadì. Tí ẹni méjì bá jọ ń ja gídígbò nílẹ̀ Gíríìsì láyé àtijọ́, ńṣe ni èkíní máa ń wá ọ̀nà àtiré ẹnì kejì tó jẹ́ alátakò rẹ̀ lẹ́pa láti lè gbé e ṣubú. Bákan náà ni Èṣù ṣe máa ń fẹ́ ré wa lẹ́pa nípa tẹ̀mí. Báwo ló ṣe lè rí wa ré lẹ́pa?

6. Lo Ìwé Mímọ́ láti fi ṣàlàyé bí Èṣù ṣe lè ta onírúurú ọgbọ́n láti fi jin ìgbàgbọ́ wa lẹ́sẹ̀.

6 Nígbà mìíràn Èṣù á ta ọgbọ́n bí ejò, tàbí bíi kìnnìún tí ń bú ramúramù, tàbí kó tiẹ̀ ṣe bí áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀ pàápàá. (2 Kọ́ríńtì 11:3, 14; 1 Pétérù 5:8) Ó lè lo àwọn èèyàn láti ṣenúnibíni sí wa tàbí láti bu ìrẹ̀wẹ̀sì lù wá. (Ìṣípayá 2:10) Níwọ̀n bí gbogbo ayé ti wà níkàáwọ́ Sátánì, ó lè lo ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àtàwọn ohun fífanimọ́ra inú ayé gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn fún wa. (2 Tímótì 2:26; 1 Jòhánù 2:16; 5:19) Ó lè lo èrò ayé tàbí ti àwọn apẹ̀yìndà láti fi ṣì wá lọ́nà, bó ṣe tan Éfà jẹ.—1 Tímótì 2:14.

7. Kí làwọn nǹkan táwọn ẹ̀mí èṣù ò lè ṣe, ìtìlẹyìn wo la sì ní?

7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun ìjà àti agbára Sátánì àti tàwọn ẹ̀mí èṣù lè fẹ́ kani láyà, àwọn nǹkan kan wà tí wọn ò lè ṣe. Àwọn ẹ̀mí burúkú wọ̀nyí ò lè fipá mú wa ṣe àwọn ohun burúkú tínú Bàbá wa ọ̀run ò dùn sí. Ẹ̀dá amọnúúrò ni wá, a lè darí ìrònú wa, a sì lè yan ohun tá a fẹ́ ṣe. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ogun àdájà kọ́ là ń jà, a lẹ́ni lẹ́yìn. Bíi ti ìgbà ayé Èlíṣà logun wa òde òní ṣe rí, nítorí pé: “Àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ.” (2 Àwọn Ọba 6:16) Bíbélì mú un dá wa lójú pé bá a bá fi ara wa sábẹ́ Ọlọ́run, tá a sì kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sá kúrò lọ́dọ̀ wa.—Jákọ́bù 4:7.

A Mọ Ètekéte Sátánì

8, 9. Àwọn àdánwò wo ni Sátánì fi gbógun ti Jóòbù kó lè ba ìwà títọ́ rẹ̀ jẹ́, àwọn ohun wo ló sì jẹ́ ewu nípa tẹ̀mí fún wa lóde òní?

8 A kò ṣàìmọ ètekéte Sátánì nítorí Ìwé Mímọ́ táṣìírí àwọn ọgbọ́n tó ń ta. (2 Kọ́ríńtì 2:11) Àwọn ohun tí Èṣù fi gbógun ti Jóòbù olódodo ni pé ó dojú ọrọ̀ ajé rẹ̀ dé, ó ṣekú pa àwọn ọmọ ẹ̀, ó gbé ogun ìdílé dìde sí i, ó kó o sí ìnira tó ga, ó tún sún àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù láti fẹ̀sùn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ kàn án. Ni ìdààmú ọkàn bá bá Jóòbù, ó rò pé Ọlọ́run ti kọ òun sílẹ̀. (Jóòbù 10:1, 2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro wọ̀nyí lè wáyé lóde òní láìjẹ́ pé Sátánì dojú rẹ̀ kọni, irú àwọn ìnira bẹ́ẹ̀ máa ń bá ọ̀pọ̀ Kristẹni, Èṣù sì lè gùn lé wọn láti fi gbógun tì wá.

9 Àwọn ewu nípa tẹ̀mí gbòde kan lákòókò òpin yìí. Ìlépa ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ti gbapò àwọn ohun tẹ̀mí lọ́kàn àwọn èèyàn láyé ìsinsìnyí. Lemọ́lemọ́ làwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ń fi ìṣekúṣe hàn bí ohun ìdùnnú dípò ohun tí ń kó ìbànújẹ́ báni. Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn sì ti di “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Tímótì 3:1-5) Èrò àwọn èèyàn yìí lè ṣàkóbá fún wa nípa tẹ̀mí bá ò bá “máa ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́.”—Júúdà 3.

10-12. (a) Ìkìlọ̀ wo ni Jésù ṣe fún wa nínú àpèjúwe afúnrúgbìn? (b) Ṣàpèjúwe bí àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí ṣe lè di fífún pa.

10 Ìdẹkùn kan tí Sátánì ń rí lò jù ni mímú ká dẹni tí ayé àti ìlépa ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì rẹ̀ gbà lọ́kàn. Nígbà tí Jésù ń fi afúnrúgbìn ṣàpèjúwe, ó kìlọ̀ pé, ní ti àwọn kan, ń ṣe ni “àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀ fún ọ̀rọ̀ náà [ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run] pa.”—Mátíù 13:18, 22.

11 A máa ń rí igi àfòmọ́ ọ̀pọ̀tọ́ nínú igbó. Ńṣe ni àfòmọ́ yìí máa ń dàgbà díẹ̀díẹ̀, tí yóò sì máa gbilẹ̀ lára igi tó fò mọ́. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọwọ́ àfòmọ́ yìí yóò wá bo ara igi náà yí ká, ìtàkùn rẹ̀ yóò sì máa lágbára sí i. Àfòmọ́ yìí á wá máa fi ìtàkùn púpọ̀ tó ní fa ọ̀pọ̀ jù lọ ọ̀rá ilẹ̀ tó wà láyìíká igi tó fò mọ́, ewé rẹ̀ yóò sì ṣíji bo igi náà lókè tí igi náà kò fi ní rí ìmọ́lẹ̀ oòrùn gbà mọ́. Bí yóò ṣe fún igi tó fò mọ́ pa níkẹyìn nìyẹn.

12 Lọ́nà kan náà, àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti lílépa ọrọ̀ òun ìgbádùn ayé lè máa gba àkókò àti okun wa lọ díẹ̀díẹ̀. Tí àwọn nǹkan inú ayé bá sì ti wá gba ẹnì kan lọ́kàn, àtimáa ráyè dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì á dìṣòro, onítọ̀hùn á sì máa pa ìpàdé jẹ. Yóò tipa báyìí dẹni tó ń pàdánù àwọn ohun agbẹ́mìíró nípa tẹ̀mí. Ìlépa ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì á wá gbapò ìgbòkègbodò tẹ̀mí, bí ọwọ́ Sátánì yóò ṣe tẹ onítọ̀hún nìyẹn.

Ó Yẹ Ká Dúró Gbọn-in Gbọn-in

13, 14. Kí ló yẹ ká ṣe bí Sátánì bá gbé àtakò kò wá lójú?

13 Pọ́ọ̀lù rọ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n “dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.” (Éfésù 6:11) A mọ̀ pé ẹ̀dá èèyàn ò lágbára láti rẹ́yìn Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù. Jésù Kristi ni Ọlọ́run gbé iṣẹ́ náà lé lọ́wọ́. (Ìṣípayá 20:1, 2) Àmọ́ kí Jésù tó mú Sátánì kúrò, a ní láti “dúró gbọn-in gbọn-in” kí Sátánì má bàa borí wa.

14 Àpọ́sítélì Pétérù pẹ̀lú tẹnu mọ́ ọn pé a ní láti dúró gbọn-in ká lè dojú ìjà kọ Sátánì. Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ. Ṣùgbọ́n ẹ mú ìdúró yín lòdì sí i, ní dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, ní mímọ̀ pé àwọn ohun kan náà ní ti ìyà jíjẹ ní ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará yín nínú ayé.” (1 Pétérù 5:8, 9) Ní tòdodo, a nílò ìtìlẹyìn àwọn ará wa gidigidi láti lè dúró gbọn-in gbọn-in nígbà tí Èṣù bá kọjú ìjà sí wa bíi kìnnìún tí ń ké ramúramù.

15, 16. Mú àpẹẹrẹ wá látinú ìwé Mímọ́ láti jẹ́ ká rí bí ìtìlẹyìn àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè dúró gbọn-in.

15 Nínú ọ̀dàn ilẹ̀ Áfíríkà, bí kìnnìún bá ké ramúramù, ẹtu tó bá wà nítòsí rẹ̀ lè kiré mọ́lẹ̀, kò sì ní dúró títí á fi sá jìnnà sí i. Àmọ́ o, ní tàwọn erin, bí òṣùṣù ọwọ̀ làwọn ń ṣe, torí pé ńṣe ni wọ́n máa ń ṣètìlẹyìn fún ara wọn. Ìwé náà Elephants—Gentle Giants of Africa and Asia ṣàlàyé pé: “Ọ̀nà kan tí agbo erin sábà máa ń gbà dáàbò bo ara wọn ni pé wọ́n máa ń para pọ̀, wọ́n á fi àwọn kéékèèké inú wọn sáàárín láti dáàbò bò wọ́n, àwọn àgbà àárín wọn á wá kọjú síhà ibi tí ewu náà wà.” Nítorí bí gbogbo wọn ṣe para pọ̀ bí òṣùṣù ọwọ̀ yìí, àpapọ̀ agbára wọn kì í jẹ́ kí kìnnìún sábà wá kọ lu èyíkéyìí lára wọn títí kan àwọn kéékèèké àárín wọn.

16 Bí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù bá gbógun tì wá, bákan náà ló ṣe yẹ ká ṣe bí òṣùṣù ọwọ̀, ká dúró ti àwọn ará wa tó dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ òun kan jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” fún òun nígbà tóun wà lẹ́wọ̀n ní Róòmù. (Kólósè 4:10, 11) Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “àrànṣe afúnnilókun” fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Gẹ́gẹ́ bí ìwé Expository Dictionary of New Testament Words látọwọ́ Vine ṣe sọ, ‘ọ̀rọ̀ ìṣe tó wà fún ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a lò yìí túmọ̀ sí egbòogi tó ń mára tuni.’ Ńṣe ni ìtìlẹyìn àwọn olùjọsìn Jèhófà tó dàgbà dénú máa ń dà bí oògùn ìwọ́ra tí ǹ mára tuni. Ó lè bá wa pẹ̀rọ̀ sí ìrora tá à ń jẹ nítorí àìlera tàbí ìdààmú ọkàn.

17. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run?

17 Lóde òní, ìṣírí látọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa lè mú ká túbọ̀ rọ̀ mọ́ ìpinnu wa láti sin Ọlọ́run láìyẹhùn. Ní pàtàkì, àwọn Kristẹni alàgbà máa ń hára gàgà láti ràn wá lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. (Jákọ́bù 5:13-15) Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé àti lílọ sí àwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ Kristẹni jẹ́ ara àwọn ohun tó ń mú ká jẹ́ olóòótọ́. Àjọṣe tímọ́tímọ́ tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run tún ń mú ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí i. Ní tòdodo, yálà à ń jẹ ni o, à ń mu ni o, tàbí à ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ó yẹ ká máa rí i pé à ń ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 10:31) Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ ọ́, ó ṣe pàtàkì pé ká gbára lé Jèhófà ká sì máa gbàdúrà sí i, ká lè máa ṣe àwọn ohun tó dùn mọ́ ọn.—Sáàmù 37:5.

18. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ juwọ́ sílẹ̀ àní bí àwọn ìṣòro tó le koko kò bá jẹ́ ká fi bẹ́ẹ̀ lókun nípa tẹ̀mí?

18 Nígbà mìíràn, ìgbà tá ò bá lókun tó nípa tẹ̀mí ni Sátánì máa ń gbógun tì wá. Kìnnìún a máa bẹ́ mọ́ ẹranko tára ẹ̀ ò le. Ìṣòro ìdílé, ọrọ̀ ajé tí ò lọ déédéé tàbí àìsàn lè sọ wá dẹni tí ò fi bẹ́ẹ̀ lókun nípa tẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe jẹ́ ká juwọ́ sílẹ̀ nínú ṣíṣe ohun tó dùn mọ́ Ọlọ́run, nítorí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.” (2 Kọ́ríńtì 12:10; Gálátíà 6:9; 2 Tẹsalóníkà 3:13) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn? Ohun tó ń sọ ni pé agbára Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ lórí àwọn ìṣòro wa, ìyẹn bá a bá ti lè yíjú sí Jèhófà fún okun àti agbára. Ṣíṣẹ́gun tí Dáfídì ṣẹ́gun Gòláyátì fi hàn pé Ọlọ́run lè fún àwọn èèyàn rẹ̀ lágbára, ó sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní lè jẹ́rìí sí i pé nígbà ìṣòro líle koko, Ọlọ́run kì í dá wa dá a, pé ó ń fún wa lókun.—Dáníẹ́lì 10:19.

19. Sọ àpẹẹrẹ kan tó fi bí Jèhófà ṣe lè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lókun hàn.

19 Tọkọtaya kan kọ̀wé nípa bí Ọlọ́run ṣe tì wọ́n lẹ́yìn, wọ́n ní: “A ti jọ ń sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọkọ àti aya láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, a sì ti jàǹfààní gidigidi. A ti mọ àwọn ọmọlúwàbí èèyàn tó pọ̀ gan-an. Jèhófà kọ́ wa bá a ṣe lè fara da ìnira ó sì tún fún wa lókun láti fara dà á délẹ̀. Bíi ti Jóòbù, ọ̀pọ̀ ìgbà la kì í mọ ìdí táwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ fi ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n a mọ̀ pé Jèhófà ò kúrò lẹ́yìn wa nígbàkigbà.”

20. Nínú Ìwé Mímọ́, ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Jèhófà máa ń ti àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́yìn nígbà gbogbo?

20 Ọwọ́ Jèhófà ò kúrú tí kò fi ní lè ran àwọn èèyàn rẹ̀ olóòótọ́ lọ́wọ́ kó sì fún wọn lókun. (Aísáyà 59:1) Olórin náà Dáfídì kọrin pé: “Jèhófà ń fún gbogbo àwọn tí ó ṣubú ní ìtìlẹyìn, ó sì ń gbé gbogbo àwọn tí a tẹ̀ lórí ba dìde.” (Sáàmù 145:14) Láìsí àní-àní, Bàbá wa ọ̀run “ń bá wa gbé ẹrù [wa] lójoojúmọ́,” ó sì ń pèsè ohun tá a nílò fún wa.—Sáàmù 68:19.

A Nílò “Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìhámọ́ra Ogun Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run”

21. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe tẹnu mọ́ ìdí tó fi yẹ ká dìhámọ́ra nípa tẹ̀mí?

21 A ti ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára ọgbọ́n tí Sátánì ń ta, a sì ti rí ìdí tó fi yẹ ká dúró gbọn-in bó ti wù kó gbógun tó. Wàyí o, ó tún yẹ ká wo ohun pàtàkì mìíràn tá a lè lò láti fi dáàbò bo ìgbàgbọ́ wa. Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Éfésù, ẹ̀ẹ̀mejì ló mẹ́nu kan kókó pàtàkì kan tó lè mú ká dúró gbọn-in lójú gbogbo ètekéte Sátánì ká sì borí nínú gídígbò tá à ń bá àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú jà. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ bàa lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù . . . Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kí ẹ bàa lè dúró tiiri ní ọjọ́ burúkú náà, lẹ́yìn tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo kínníkínní, kí ẹ sì lè dúró gbọn-in gbọn-in.”—Éfésù 6:11, 13.

22, 23. (a) Kí làwọn ohun tó wà lára ìhámọ́ra wa nípa tẹ̀mí? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?

22 Láìsí àní-àní, ó yẹ ká gbé “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” wọ̀. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí àwọn ará Éfésù, ọmọ ogun Róòmù kan ń ṣọ́ ọ, ó sì ṣeé ṣe kí ọmọ ogun náà máa wọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun nígbà mìíràn. Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run ló mí sí Pọ́ọ̀lù tó fi sọ̀rọ̀ nípa ìhámọ́ra tẹ̀mí tó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà ní.

23 Lára ohun tó jẹ́ ìhámọ́ra látọ̀dọ̀ Ọlọ́run yìí ni ànímọ́ tí olúkúlùkù Kristẹni gbọ́dọ̀ ní àtàwọn ìpèsè tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a óò gbé àwọn ohun tó para pọ̀ di ìhámọ́ra tẹ̀mí yìí yẹ̀ wò lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan. Èyí a jẹ́ ká mọ bá a ṣe máa gbára dì tó fún ogun tẹ̀mí tá à ń jà. Bákan náà, a óò tún rí bí àpẹẹrẹ àtàtà tí Jésù Kristi fi lélẹ̀ yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́ kí Sátánì Èṣù má bàa rí wa gbéṣe.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Ìjà wo ni gbogbo Kristẹni ní láti jà?

• Ṣàpèjúwe díẹ̀ lára ọgbọ́n tí Sátánì ń ta.

• Báwo ni ìtìlẹyìn àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa ṣe lè fún wa lókun?

• Agbára ta ni a ní láti gbára lé, kí sì nìdí?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Àwa Kristẹni ‘ní gídígbò kan lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú’

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí lè fún ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run pa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa lè jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Ǹjẹ́ o máa ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ẹ lókun?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́