ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 9/15 ojú ìwé 15-20
  • “Ẹ Gbé Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìhámọ́ra Ogun Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Wọ̀”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Gbé Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìhámọ́ra Ogun Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Wọ̀”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Dídáàbò Bo Abẹ́nú, Àyà àti Ẹsẹ̀ Wa
  • Apata, Àṣíborí àti Idà
  • Máa Gbàdúrà Nígbà Gbogbo
  • “Ẹ Gbé Gbogbo Ìhámọ́ra Ọlọrun Wọ̀”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Jèhófà Máa Dáàbò Bò Ẹ́—Lọ́nà Wo?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́ Ẹ Dúró Gbọn-In Lòdì sí Èṣù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Kí La Lè Ṣe Táwọn Ẹ̀mí Èṣù Ò Fi Ní Lè Borí wa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 9/15 ojú ìwé 15-20

“Ẹ Gbé Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìhámọ́ra Ogun Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Wọ̀”

“Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ bàa lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.”—ÉFÉSÙ 6:11.

1, 2. Ṣàpèjúwe ìhámọ́ra tẹ̀mí táwọn Kristẹni ní láti gbé wọ̀, kó o sọ ọ́ bó ṣe yé ọ gẹ́lẹ́.

Ọ̀RÚNDÚN kìíní Sànmánì Tiwa ni ìṣàkóso ilẹ̀ ọba Róòmù gbilẹ̀ jù lọ. Àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Róòmù pọ̀ wọ́n sì lágbára gan-an, èyí ló mú kí ìlú Róòmù lè ṣàkóso ibi tó pọ̀ jù lọ láyé ìgbà yẹn. Òpìtàn kan sọ pé “kò sí ẹgbẹ́ ológun tó dà bíi tiwọn.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn jagunjagun tó ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó le gan-an ló wà nínú ẹgbẹ́ ológun Róòmù, ohun mìíràn tó tún jẹ́ kí wọ́n lè máa ja àjàṣẹ́gun ni ìhámọ́ra wọn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo ìhámọ́ra àwọn jagunjagun Róòmù láti fi ṣàkàwé ìhámọ́ra táwa Kristẹni nílò kó lè ṣeé ṣe fún wa láti kọjúùjà sí Èṣù, ká sì ja àjàṣẹ́gun.

2 Àlàyé nípa ìhámọ́ra tẹ̀mí yìí wà ní Éfésù 6:14-17. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ dúró gbọn-in gbọn-in pẹ̀lú abẹ́nú yín tí a fi òtítọ́ dì lámùrè, kí ẹ sì gbé àwo ìgbàyà ti òdodo wọ̀, àti pẹ̀lú ẹsẹ̀ yín tí a fi ohun ìṣiṣẹ́ ìhìn rere àlàáfíà wọ̀ ní bàtà. Lékè ohun gbogbo, ẹ gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́, èyí tí ẹ ó lè fi paná gbogbo ohun ọṣẹ́ oníná ti ẹni burúkú náà. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹ tẹ́wọ́ gba àṣíborí ìgbàlà, àti idà ẹ̀mí, èyíinì ni, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Ní tòdodo, ìhámọ́ra àwọn ọmọ ogun Róòmù tí Pọ́ọ̀lù wò fi ṣe àkàwé yìí máa ń dáàbò bò wọ́n gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún máa ń lo idà, tó jẹ́ olórí ohun ìjà wọn tí wọ́n fi ń bá àwọn ọ̀tá jà.

3. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣègbọràn sáwọn ìtọ́ni Jésù Kristi ká sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?

3 Yàtọ̀ sí ohun ìjà táwọn jagunjagun ilẹ̀ Róòmù ń lò àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń gbà, wọ́n ní láti ṣègbọràn sí olórí ogun tí wọ́n bá máa ṣe àṣeyọrí. Bíi tiwọn, àwa Kristẹni náà gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Jésù Kristi, ẹni tí Bíbélì pè ní “aláṣẹ fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.” (Aísáyà 55:4) Òun tún ni “orí ìjọ.” (Éfésù 5:23) Jésù ń fún wa ní ìtọ́ni nípa ogun tẹ̀mí tá à ń jà, ó sì fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ fún wa nípa bá a ṣe lè wọ ìhámọ́ra tẹ̀mí. (1 Pétérù 2:21) Níwọ̀n bí àwọn ìhámọ́ra tẹ̀mí wa ti jọ àkópọ̀ ìwà Kristi gan-an, Ìwé Mímọ́ gbà wá nímọ̀ràn pé ká fi ìrònú Kristi ‘di ara wa ní ìhámọ́ra.’ (1 Pétérù 4:1) Látàrí èyí, bí a ó ṣe máa ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó para pọ̀ jẹ́ ìhámọ́ra tẹ̀mí wa lọ́kọ̀ọ̀kan, a óò lo àpẹẹrẹ Jésù láti fi ṣàlàyé bí ìhámọ́ra yìí ti ṣe pàtàkì tó àti bó ṣe wúlò tó.

Dídáàbò Bo Abẹ́nú, Àyà àti Ẹsẹ̀ Wa

4. Báwo ni àmùrè ṣe wúlò tó nínú ìhámọ́ra jagunjagun kan, kí sì ni èyí ṣàpèjúwe?

4 Abẹ́nú tí a fi òtítọ́ dì lámùrè. Lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn jagunjagun máa ń lo bẹ́líìtì tàbí àmùrè aláwọ tó fẹ̀ tó nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà márùn-ún sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Àwọn olùtumọ̀ èdè kan sọ pé bó ṣe yẹ kí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí kà ni pé, “fi òtítọ́ wé ìbàdí rẹ pinpin.” Bẹ́líìtì jagunjagun máa ń dáàbò bo abẹ́nú rẹ̀, ó sì tún lè fi idà rẹ̀ há a. Bí jagunjagun kan bá di abẹ́nú rẹ̀ lámùrè, ó ń gbára dì fún ìjà nìyẹn. Pọ́ọ̀lù lo bẹ́líìtì àwọn jagunjagun láti ṣàkàwé bó ṣe yẹ kí òtítọ́ Ìwé Mímọ́ máa darí wa nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe nígbèésí ayé wa. Ó yẹ kí ìgbànú yìí, ìyẹn òtítọ́, wé mọ́ wa lára pinpin, torí pé ìyẹn ló máa jẹ́ ká lè máa ṣe ohun tó bá òtítọ́ mu, a ó sì lè gbèjà rẹ̀ nígbàkigbà. (Sáàmù 43:3; 1 Pétérù 3:15) Kí èyí lè ṣeé ṣe, a ní láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tọkàntara, ká sì máa ṣàṣàrò lórí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀. Jésù jẹ́ kí òfin Ọlọ́run ‘wà ní ìhà inú’ òun. (Sáàmù 40:8) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà táwọn alátakò da ìbéèrè bò ó, ńṣe ló ń fi Ìwé Mímọ́ tó ti mọ̀ sórí fèsì ọ̀rọ̀ wọn.—Mátíù 19:3-6; 22:23-32.

5. Ṣàlàyé bí ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro tàbí nígbà ìdẹwò.

5 Bá a bá ń jẹ́ kí òtítọ́ Bíbélì ṣamọ̀nà wa, á dáàbò bò wá lọ́wọ́ èrò tí kò tọ̀nà, á sì jẹ́ ká máa ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Nígbà ìdẹwò tàbí nígbà ìṣòro, ìlànà Bíbélì á fún wa lókun láti ṣe ohun tó tọ́. Ńṣe ló máa dà bíi pé à ń rí Jèhófà, Olùkọ́ni wa Atóbilọ́lá, àti pé etí wa ń gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn wa tí ń sọ pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.”—Aísáyà 30:20, 21.

6. Kí nìdí tí ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa fi nílò ààbò, báwo sì ni òdodo ṣe lè dáàbò bò ó bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ?

6 Àwo ìgbàyà ti òdodo. Àwo ìgbàyà àwọn jagunjagun ń dáàbò bo ẹ̀yà ara pàtàkì kan, ìyẹn ọkàn. Bákan náà, ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa, ìyẹn irú ẹni tá a jẹ́ gan-an nínú lọ́hùn-ún, nílò ààbò àrà ọ̀tọ̀ torí pé ohun búburú ló máa ń fẹ́ ṣe ṣáá. (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé a gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìlànà òdodo Jèhófà, ká sì nífẹ̀ẹ́ wọn. (Sáàmù 119:97, 105) Bí a bá nífẹ̀ẹ́ òdodo, a óò kọ èrò ayé tó lòdì sáwọn ìtọ́ni tí Jèhófà ń fún wa, a ò sì ní fàyè gba àwọn èrò tó bá máa sọ àwọn ìtọ́ni tó ń fún wa di yẹpẹrẹ. Yàtọ̀ síyẹn, bá a bá nífẹ̀ẹ́ ohun tó tọ́ tá a sì kórìíra ohun tí kò tọ́, a ò ní máa hùwà tó lè ba ayé wa jẹ́. (Sáàmù 119:99-101; Ámósì 5:15) Jésù jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wa nínú èyí, nítorí pé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa rẹ̀ ni pé: “Ìwọ nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà àìlófin.”—Hébérù 1:9.a

7. Kí nìdí táwọn jagunjagun Róòmù fi nílò bàtà tó nípọn, kí sì ni èyí ṣàpèjúwe?

7 Ẹsẹ̀ tí a fi ohun ìṣiṣẹ́ ìhìn rere àlàáfíà wọ̀ ní bàtà. Àwọn jagunjagun Róòmù nílò bàtà tó nípọn, torí pé nígbà tí wọ́n bá ń jagun, wọ́n sábà máa ń rìn tó ọgbọ̀n kìlómítà lóòjọ́, tí wọ́n á tún wọ ìhámọ́ra tó wúwo gan-an, ìyẹn nǹkan bíi kìlógíráàmù mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe lo bàtà láti ṣàpèjúwe ìmúratán wa láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ gbọ́ bá a mu gan-an. Èyí ṣe pàtàkì torí pé báwo làwọn èèyàn ṣe lè mọ Jèhófà bá ò bá múra tán, tí kò sì wù wá láti wàásù?—Róòmù 10:13-15.

8. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere?

8 Iṣẹ́ wo ló ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé Jésù? Ó sọ fún gómìnà ará Róòmù náà, Pọ́ńtíù Pílátù pé: ‘Mo wá sí ayé kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.’ Jésù máa ń wàásù níbikíbi táwọn èèyàn bá ti fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì fẹ́ràn iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ débi pé ó fi ṣáájú àwọn ohun ti ara. (Jòhánù 4:5-34; 18:37) Bíi ti Jésù, bí àwa náà bá ń hára gàgà láti polongo ìhìn rere, a óò wá onírúurú ọ̀nà láti wàásù fún àwọn èèyàn. Síwájú sí i, jíjẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ á mú ká jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí.—Ìṣe 18:5.

Apata, Àṣíborí àti Idà

9. Báwo ni apata ńlá ṣe lè dáàbò bo ọmọ ogun Róòmù kan?

9 Apata ńlá ti ìgbàgbọ́. Ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tí a tú sí “apata ńlá” túmọ̀ sí apata tó tóbi gan-an débi pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ lè bo gbogbo ara tán. Òun ni kò ní jẹ́ kí “ohun ọṣẹ́ oníná” tí Éfésù orí kẹfà ẹsẹ ìkẹrìndínlógún sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pani lára. Lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn jagunjagun máa ń lo ọfà oníná lójú ogun. Ọ̀pá esùsú tó ní ihò ni wọ́n fi ń ṣe ọfà náà, wọ́n á wá ki irin ṣóńṣó tó ní epo tó ń gbiná bọ ẹnu ọ̀pá esùsú náà. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé ọfà oníná “jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun ìjà tó léwu jù lọ nínú ogun ayé àtijọ́.” Bí jagunjagun kan kò bá ní apata tó tóbi tó láti dáàbò bo ara rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ irú àwọn ohun ọṣẹ́ bẹ́ẹ̀, ó lè fara pa yánnayànna tàbí kí wọ́n ṣekú pa á.

10, 11. (a) Àwọn “ohun ọṣẹ́ oníná” Sátánì wo ló lè jin ìgbàgbọ́ wa lẹ́sẹ̀? (b) Báwo ni àpẹẹrẹ Jésù ṣe fi hàn pé ó ṣe pàtàkì pé kí ìgbàgbọ́ wa lágbára nígbà ìṣòro?

10 Àwọn “ohun ọṣẹ́ oníná” wo ni Sátánì ń lò láti jin ìgbàgbọ́ wa lẹ́sẹ̀? Ó lè rúná sí inúnibíni tàbí àtakò nínú ìdílé, níbi iṣẹ́ tàbí nílé ẹ̀kọ́. Àwọn ohun mìíràn tó ti lò láti fi ṣèpalára nípa tẹ̀mí fún àwọn Kristẹni kan ni ìfẹ́ láti kó ohun ìní tara jọ àti ìṣekúṣe. Tá a bá fẹ́ dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ irú àwọn ewu bẹ́ẹ̀, “lékè ohun gbogbo, [a gbọ́dọ̀] gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́.” Ká tó lè ní ìgbàgbọ́, a ní láti máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, ká máa gbàdúrà sí i déédéé, ká sì máa fòye mọ bó ṣe ń dáàbò bò wá tó sì ń bù kún wa.—Jóṣúà 23:14; Lúùkù 17:5; Róòmù 10:17.

11 Nígbà tí Jésù wà láyé, ó jẹ́ kó hàn pé ó ṣe pàtàkì pé kí ìgbàgbọ́ ẹni lágbára nígbà ìṣòro. Tọkàntọkàn ló fi gbà láti jẹ́ kí ìfẹ́ Baba rẹ̀ ṣẹ, inú rẹ̀ sì máa ń dùn láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. (Mátíù 26:42, 53, 54; Jòhánù 6:38) Kódà nígbà tí ìnira Jésù dé góńgó nínú ọgbà Gẹtisémánì, ó sọ fún Baba rẹ̀ pé: “Kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí èmi tí fẹ́, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fẹ́.” (Mátíù 26:39) Jésù ò fìgbà kan gbàgbé pé ó ṣe pàtàkì pé kí òun jẹ́ oníwà títọ́, kí òun sì máa múnú Baba òun dùn. (Òwe 27:11) Bí àwa náà bá fi gbogbo ọkàn gbára lé Jèhófà bíi tirẹ̀, a ò ní jẹ́ kí àríwísí tàbí àtakò sọ ìgbàgbọ́ wa di ahẹrẹpẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ wa á máa lágbára sí i tá a bá gbára lé Ọlọ́run, tá a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tá a sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́. (Sáàmù 19:7-11; 1 Jòhánù 5:3) Kò sí ohun tara tàbí ìgbádùn onígbà kúkúrú kankan tá a lè fi wé ìbùkún tí Jèhófà máa fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.—Òwe 10:22.

12. Ẹ̀yà ara pàtàkì wo ni àṣíborí ìṣàpẹẹrẹ wa ń dáàbò bò, kí nìdí tí irú ààbò bẹ́ẹ̀ sì fi ṣe kókó?

12 Àṣíborí ìgbàlà. Àṣíborí ń dáàbò bo orí àti ọpọlọ àwọn jagunjagun, èyí sì ṣe pàtàkì nítorí ọpọlọ lèèyàn fi ń ronú. Pọ́ọ̀lù fi ìrètí táwa Kristẹni ní wé àṣíborí torí pé ó ń dáàbò bo agbára ìrònú wa. (1 Tẹsalóníkà 5:8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti fi ìmọ̀ tó péye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yí èrò inú wa padà, ẹ̀dá aláìpé tó ń ṣe àṣìṣe ṣì ni wá. Èròkerò lè tètè gbà wá lọ́kàn. Bí a bá kó àwọn nǹkan ayé yìí láyà, èyí lè pín ọkàn wa níyà tàbí ká tiẹ̀ fi wọ́n rọ́pò ìrètí tí Ọlọ́run fún wa. (Róòmù 7:18; 12:2) Èṣù sọ pé òun á fún Jésù ní “gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn,” àmọ́ pàbó ni ìsapá Èṣù yìí láti pín ọkàn Jésù níyà já sí. (Mátíù 4:8) Ojú ẹsẹ̀ ni Jésù kọ ohun tó fi lọ̀ ọ́. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa Jésù pé: “Nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀, ó fara da òpó igi oró, ó tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.”—Hébérù 12:2.

13. Báwo la ṣe lè rí i pé ìgbọ́kànlé tá a ní nínú ìrètí ọjọ́ iwájú kò yẹ̀?

13 Kì í ṣe pé Jésù kàn ṣàdédé gbọ́kàn lé àwọn ìlérí ọjọ́ iwájú. Bó bá jẹ́ pé àwọn àlá tí ò lè ṣẹ àtàwọn ohun táráyé ń lépa nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ló gbà wá lọ́kàn dípò ká pọkàn pọ̀ sórí ìrètí ọjọ́ iwájú, ìgbàgbọ́ tá a ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run ò ní fi bẹ́ẹ̀ lágbára mọ́. Ìrètí náà tiẹ̀ lè máà sí lọ́kàn wa mọ́ bó bá yá. Àmọ́, bí a bá ń ṣàṣàrò déédéé lórí àwọn ìlérí Ọlọ́run, ìrètí tó wà níwájú wa yóò máa fún wa láyọ̀.—Róòmù 12:12.

14, 15. (a) Kí ni idà ìṣàpẹẹrẹ wa, báwo la sì ṣe lè lò ó? (b) Ṣàlàyé bí idà ẹ̀mí ṣe lè ṣèrànwọ́ fún wa láti ṣẹ́gun ìdẹwò.

14 Idà ẹ̀mí. Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ nínú Bíbélì dà bí idà olójú méjì tó lè ṣá àwọn ẹ̀kọ́ èké balẹ̀, kí ó sì ran àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́wọ́ láti rí òmìnira tẹ̀mí. (Jòhánù 8:32; Hébérù 4:12) Idà tẹ̀mí yìí tún lè dáàbò bò wá nígbà tí ìdẹwò bá yọjú tàbí táwọn apẹ̀yìndà bá ń gbìyànjú láti jin ìgbàgbọ́ wa lẹ́sẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 10:4, 5) A mà dúpẹ́ o pé ‘gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ń mú wa gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo’!—2 Tímótì 3:16, 17.

15 Nígbà tí Sátánì ń dán Jésù wò nínú aginjù, Jésù lo idà ẹ̀mí bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ láti fi dojú èrò tí kò tọ̀nà àtàwọn ètekéte rẹ̀ dé. Ohun tí Jésù fi ń fèsì ìdánwò kọ̀ọ̀kan tí Sátánì gbé kò ó lójú ni pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé.” (Mátíù 4:1-11) Bíi ti Jésù, Ìwé Mímọ́ ṣèrànwọ́ fún David, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Sípéènì, láti ṣẹ́gun ìdẹwò. Nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mọ́kàndínlógún, ọmọbìnrin òrékelẹ́wà kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ní iléeṣẹ́ kan náà sọ fún un pé kó jẹ́ káwọn méjèèjì “jọ lọ gbádùn ara wọn.” Àmọ́, David ò gbà fún obìnrin yìí, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé kó gbé òun lọ sí apá ibòmíràn níléeṣẹ́ náà kí ìṣòro yìí má bàa jẹ yọ mọ́. David sọ pé: “Àpẹẹrẹ Jósẹ́fù wá sí mi lọ́kàn. Ó kọ ìṣekúṣe, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló sì sá kúrò lọ́dọ̀ obìnrin náà. Èmi náà sì ṣe bíi tiẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 39:10-12.

16. Ṣàlàyé ìdí tá a fi ní láti máa dá ara wa lẹ́kọ̀ọ́ déédéé ká bàa lè ‘fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.’

16 Jésù tún lo idà ẹ̀mí láti fi ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè bọ́ nínú ìgbèkùn Sátánì. Jésù sọ pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.” (Jòhánù 7:16) Ká tó lè di ọ̀jáfáfá olùkọ́ bíi ti Jésù, a ní láti máa dá ara wa lẹ́kọ̀ọ́ déédéé. Òpìtàn Júù náà, Josephus sọ̀rọ̀ kan nípa àwọn jagunjagun Róòmù nínú ìwé tó kọ, ó ní: “Ojoojúmọ́ ni jagunjagun kọ̀ọ̀kan máa ń ṣe eré ìmárale, tọkàntara ni wọ́n sì máa ń fi ṣe é, bíi pé wọ́n wà lójú ogun. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé kì í fi bẹ́ẹ̀ nira fún wọn láti fàyà rán àwọn ìnira ojú ogun.” Nínú ogun tẹ̀mí tí à ń jà, a ní láti máa lo Bíbélì. Síwájú sí i, a gbọ́dọ̀ ‘sa gbogbo ipá wa láti fi ara wa hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, bí aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.’ (2 Tímótì 2:15) Ká sòótọ́, ayọ̀ tá a máa ń rí nígbà tá a bá fi Ìwé Mímọ́ dáhùn ìbéèrè àtọkànwá tí olùfìfẹ́hàn kan béèrè kò ṣeé fẹnu sọ!

Máa Gbàdúrà Nígbà Gbogbo

17, 18. (a) Báwo ni àdúrà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ kí ọwọ́ Sátánì má bàa tẹ̀ wá? (b) Sọ ìrírí kan nípa bí àdúrà ti ṣe pàtàkì tó.

17 Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra tẹ̀mí, ó tún fún wa ní ìmọ̀ràn pàtàkì mìíràn. Bí àwa Kristẹni ò bá fẹ́ kí ọwọ́ Sátánì tẹ̀ wá, a ní láti máa gba “gbogbo oríṣi àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀.” Báwo ló ṣe yẹ kí àdúrà wa ṣe lemọ́lemọ́ tó? Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ máa bá a lọ ní gbígbàdúrà ní gbogbo ìgbà nínú ẹ̀mí.” (Éfésù 6:18) Nígbà ìdẹwò, tá a bá ní ìṣòro, tàbí tí a rẹ̀wẹ̀sì, àdúrà lè fún wa lókun gan-an. (Mátíù 26:41) Jésù “ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àti ìtọrọ pẹ̀lú sí Ẹni tí ó lè gbà á là kúrò nínú ikú, pẹ̀lú igbe ẹkún kíkankíkan àti omijé, a sì gbọ́ ọ pẹ̀lú ojú rere nítorí ìbẹ̀rù rẹ̀ fún Ọlọ́run.”—Hébérù 5:7.

18 Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Milagros, ẹni tó ń tọ́jú ọkọ rẹ̀ tó ti ń ṣàìsàn láti ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn, sọ pé: “Mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà nígbà tí mo bá rẹ̀wẹ̀sì. Kò sẹ́ni tó tún lè ràn mí lọ́wọ́ bíi tiẹ̀. Lóòótọ́ o, àwọn ìgbà kan wà tí mo máa ń wò ó pé mi ò lè fara dà á mọ́. Àmọ́, mo sábà máa ń rí i pé tí mo bá ti gbàdúrà sí Jèhófà, mo máa ń lókun sí i, ara mi á sì yá gágá.”

19, 20. Kí la ní láti ṣe tá a bá fẹ́ jagun mólú nínú ìjà tí à ń bá Sátánì jà?

19 Èṣù mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ ló kù fún òun láti lò, ìdí nìyẹn tó fi ń sapá lójú méjèèjì láti ṣẹ́gun wa. (Ìṣípayá 12:12, 17) A ní láti gbógun ti ọ̀tá wa alágbára yìí, ká sì “ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́.” (1 Tímótì 6:12) A nílò okun tó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá tá a bá fẹ́ ṣe èyí ní àṣeyọrí. (2 Kọ́ríńtì 4:7) A tún nílò ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, torí náà ó yẹ ká máa gbàdúrà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́. Jésù sọ pé: “Bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ ẹni burúkú, bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”—Lúùkù 11:13.

20 Dájúdájú, ó ṣe pàtàkì pé ká gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun tí Jèhófà ń pèsè wọ̀. Bí a bá fẹ́ gbé ìhámọ́ra tẹ̀mí yìí wọ̀, a ní láti ní àwọn ànímọ́ tí inú Ọlọ́run dùn sí, irú bí ìgbàgbọ́ àti òdodo. A ní láti nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ bíi pé a wé e mọ́ra pinpin, ká múra tán láti wàásù ìhìn rere ní gbogbo ìgbà, ká sì máa fi ìrètí wa ọjọ́ iwájú sọ́kàn nígbà gbogbo. A gbọ́dọ̀ mọ bá a ṣe lè máa lo idà ẹ̀mí bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Bí a bá gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun látọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, a ó lè jagun mólú nínú gídígbò tí à ń báwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú jà, a ó sì lè mú kí orúkọ mímọ́ Jèhófà di èyí tí à ń yìn lógo ní tòótọ́.—Róòmù 8:37-39.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Bíbélì sọ pé Jèhófà “gbé òdodo wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wù tí a fi àdàrọ irin ṣe.” Látàrí èyí, ó fẹ́ káwọn alábòójútó nínú ìjọ máa ṣe ìdájọ́ òdodo, kí wọ́n sì máa hùwà òdodo.—Aísáyà 59:14, 15, 17.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Àpẹẹrẹ ta ló dára jù lọ fún wa láti tẹ̀ lé nínú gbígbé ìhámọ́ra tẹ̀mí wọ̀, kí nìdí tó sì fi yẹ ká fara balẹ̀ gbé àpẹẹrẹ rẹ̀ yẹ̀ wò?

• Báwo la ṣe lè dáàbò bo agbára ìrònú wa àti ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa?

• Báwo la ṣe lè di ọ̀jáfáfá nínú lílo idà ẹ̀mí?

• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà ní gbogbo ìgbà?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Fífi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè sún wa láti máa wàásù ìhìn rere ní gbogbo ìgbà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ìrètí tó dájú tá a ní ń ràn wá lọ́wọ́ láti fàyà rán ìṣòro

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ǹjẹ́ ò ń lo “idà ẹ̀mí” nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́