Ohun Táwọn Áńgẹ́lì Ń ṣe Fọ́mọ Aráyé
“Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, mo rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, pẹ̀lú ọlá àṣẹ ńlá . . . Ó sì ké jáde pẹ̀lú ohùn líle, pé: ‘Ó ti ṣubú! Bábílónì Ńlá ti ṣubú!’”—ÌṢÍPAYÁ 18:1, 2.
1, 2. Kí ló fi hàn pé Jèhófà máa ń lo àwọn áńgẹ́lì láti ṣe ohun tó ní lọ́kàn?
NÍGBÀ tí wọ́n fí àpọ́sítélì Jòhánù tó ti darúgbó sígbèkùn ní erékùṣù Pátímọ́sì, Jèhófà fún un láǹfààní láti rí àwọn ìran kan tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀. “Nípa ìmísí,” ó wà ní “ọjọ́ Olúwa” ó sì rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amóríyá tí yóò wáyé ní ọjọ́ Olúwa yìí, tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914 nígbà tí Jésù Kristi gorí ìtẹ́, tí yóò sì parí ní òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso rẹ̀.—Ìṣípayá 1:10.
2 Kì í ṣe Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló fún Jòhánù ní ìṣípayá yìí o. Àwọn kan ló lò. Ìṣípayá 1:1 sọ pé: “Ìṣípayá láti ọ̀dọ̀ Jésù Kristi, èyí tí Ọlọ́run fi fún un, láti fi han àwọn ẹrú rẹ̀, àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́. Ó sì rán áńgẹ́lì rẹ̀ jáde, ó sì gbé e kalẹ̀ nípa àwọn àmì nípasẹ̀ rẹ̀ fún ẹrú rẹ̀ Jòhánù.” Jèhófà fi ìṣípayá àwọn ohun àgbàyanu tí yóò máa wáyé ní “ọjọ́ Olúwa” yìí fún Jésù pé kó fi rán áńgẹ́lì kan sí Jòhánù. Nígbà tó yá, Jòhánù tún “rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, pẹ̀lú ọlá àṣẹ ńlá.” Iṣẹ́ wo ni áńgẹ́lì náà fẹ́ jẹ́? Ìṣípayá sọ pé: “Ó . . . ké jáde pẹ̀lú ohùn líle, pé: ‘Ó ti ṣubú! Bábílónì Ńlá ti ṣubú!’” (Ìṣípayá 18:1, 2) Áńgẹ́lì alágbára yìí láǹfààní láti kéde ìṣubú Bábílónì Ńlá, ìyẹn gbogbo ìsìn èké ayé lápapọ̀. Èyí fi hàn dájú pé Jèhófà máa ń lo àwọn áńgẹ́lì lọ́nà pàtàkì láti ṣe àwọn ohun tó ní lọ́kàn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ó ṣe àgbéyẹ̀wò tó kún rẹ́rẹ́ lórí ipa táwọn áńgẹ́lì ń kó nínú mímú àwọn ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe ṣẹ, àti bí wọ́n ṣe ń ràn wá lọ́wọ́. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo bó ṣe di pé wọ́n wà.
Báwo Làwọn Áńgẹ́lì Ṣe Wà?
3. Èrò tí kò tọ̀nà wo lọ̀pọ̀ èèyàn ní nípa àwọn áńgẹ́lì?
3 Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lóde òní gbà gbọ́ pé àwọn áńgẹ́lì wà. Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló ní èrò tí kò tọ̀nà nípa wọn àti bó ṣe di pé wọ́n wà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹlẹ́sìn kan rò pé tẹ́nì kan bá kú, ńṣe ni Ọlọ́run mú ẹni náà lọ sọ́run láti di áńgẹ́lì. Ǹjẹ́ ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi kọ́ni nìyẹn nípa bí àwọn áńgẹ́lì ṣe wà, ìgbà tí wọ́n ti wà àti iṣẹ́ wọn?
4. Kí ni Bíbélì sọ fún wa nípa bó ṣe di pé àwọn áńgẹ́lì wà?
4 Bíbélì pe áńgẹ́lì tó ní agbára àti àṣẹ tó ga jù lọ ní Máíkẹ́lì olú-áńgẹ́lì, òun ni olórí àwọn áńgẹ́lì. (Júúdà 9) Kò sí àní-àní pé Jésù Kristi ni Máíkẹ́lì olú-áńgẹ́lì yìí. (1 Tẹsalóníkà 4:16) Ní ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún sẹ́yìn, nígbà tí Jèhófà gbèrò láti dá àwọn nǹkan, olú-áńgẹ́lì yìí tó jẹ́ Ọmọ rẹ̀ ló kọ́kọ́ dá kó tó dá ohunkóhun. (Ìṣípayá 3:14) Nígbà tó ṣe, Jèhófà lo àkọ́bí rẹ̀ yìí láti dá gbogbo àwọn áńgẹ́lì tó kù. (Kólósè 1:15-17) Nígbà tí Jèhófà ń bá Jóòbù babańlá nì sọ̀rọ̀, ó pe àwọn áńgẹ́lì wọ̀nyí ní ọmọ òun, ó ní: “Ibo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀? Sọ fún mi, bí o bá mòye. . . . Ta ní fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀, nígbà tí àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ ń fi ìdùnnú ké jáde, tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí hó yèè nínú ìyìn?” (Jóòbù 38:4, 6, 7) Nítorí náà, Ọlọ́run ló dá àwọn áńgẹ́lì, wọ́n sì ti wà tipẹ́ ṣáájú kó tó dá èèyàn.
5. Báwo ni Jèhófà ṣe ṣètò àwọn áńgẹ́lì?
5 Ìwé 1 Kọ́ríńtì 14:33 sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run rúdurùdu, bí kò ṣe ti àlàáfíà.” Nítorí náà, Jèhófà pín àwọn áńgẹ́lì, ìyẹn àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tí í ṣe ọmọ rẹ̀, sí ẹgbẹ́ mẹ́ta. Ẹgbẹ́ àkọ́kọ́ ni àwọn séráfù tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ níbi ìtẹ́ Ọlọ́run, tí wọ́n ń kéde pé Ọlọ́run jẹ́ mímọ́, tí wọ́n sì ń rí sí i pé àwọn èèyàn Ọlọ́run wà ní mímọ́ nípa tẹ̀mí. Ẹgbẹ́ kejì ni àwọn kérúbù tí wọ́n ń kọ́wọ́ ti Jèhófà lẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. Ẹgbẹ́ kẹta sì ni àwọn áńgẹ́lì tó kù tí wọ́n tún máa ń mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. (Sáàmù 103:20; Aísáyà 6:1-3; Ìsíkíẹ́lì 10:3-5; Dáníẹ́lì 7:10) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yìí ń ṣe fún ọmọ aráyé?—Ìṣípayá 5:11.
Kí Ni Iṣẹ́ Àwọn Áńgẹ́lì?
6. Báwo ni Jèhófà ṣe lo àwọn kérúbù ní ọgbà Édẹ́nì?
6 Ibi tí Bíbélì ti kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ní tààràtà ni Jẹ́nẹ́sísì 3:24, tó kà pé: “[Jèhófà] lé ọkùnrin náà jáde, ó sì yan àwọn kérúbù sí ìlà-oòrùn ọgbà Édẹ́nì àti abẹ idà tí ń jó lala, tí ń yí ara rẹ̀ láìdáwọ́ dúró láti máa ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ síbi igi ìyè náà.” Àwọn kérúbù yìí kò jẹ́ kí Ádámù àti Éfà lè padà sínú ọgbà tí Ọlọ́run ti lé wọn jáde. Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ẹ̀dá èèyàn lèyí ṣẹlẹ̀. Kí làwọn áńgẹ́lì wá ń ṣe látìgbà yẹn wá?
7. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò fún “áńgẹ́lì” nínú èdè Hébérù àti èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ nípa ọ̀kan lára iṣẹ́ àwọn áńgẹ́lì?
7 Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó irínwó [400] ìgbà tí Bíbélì mẹ́nu kan àwọn áńgẹ́lì. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò fún “áńgẹ́lì” nínú èdè Hébérù àti èdè Gíríìkì túmọ̀ sí “òjíṣẹ́.” Èyí fi hàn pé Ọlọ́run ti máa ń lo àwọn áńgẹ́lì láti gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ fún ọmọ aráyé. Bí àpẹẹrẹ, ìpínrọ̀ kìíní àti ìkejì nínú àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà fiṣẹ́ rán áńgẹ́lì kan sí àpọ́sítélì Jòhánù.
8, 9. (a) Kí ni ipa tí wíwá tí áńgẹ́lì kan wá sọ́dọ̀ Mánóà àti ìyàwó rẹ̀ ní lórí wọn? (b) Kí làwọn òbí lè rí kọ́ nínú ohun tí Mánóà ṣe tó mú kí áńgẹ́lì wá sọ́dọ̀ rẹ̀?
8 Ọlọ́run tún máa ń lo àwọn áńgẹ́lì láti ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé lọ́wọ́ àti láti sọ̀rọ̀ tó máa fún wọn níṣìírí. Bí àpẹẹrẹ, lákòókò àwọn Onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un, ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn Mánóà àti ìyàwó rẹ̀ tó yàgàn láti bímọ. Jèhófà rán áńgẹ́lì rẹ̀ sí ìyàwó Mánóà pé kó sọ fún un pé á bí ọmọkùnrin kan. Bíbélì sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe lọ, ó ní: “Wò ó! dájúdájú, ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, kí abẹ fẹ́lẹ́ má sì kan orí rẹ̀, nítorí pé Násírì Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò dà bí ó bá ti jáde láti inú ikùn wá; òun sì ni ẹni tí yóò mú ipò iwájú nínú gbígba Ísírẹ́lì là kúrò ní ọwọ́ àwọn Filísínì.”—Àwọn Onídàájọ́ 13:1-5.
9 Nígbà tó ṣe, ìyàwó Mánóà bí ọmọkùnrin kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Sámúsìnì. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ ìtàn rẹ̀ nínú Bíbélì bí ẹní mowó. (Àwọn Onídàájọ́ 13:24) Kí wọ́n tó bí ọmọ náà, Mánóà bẹ Jèhófà pé kó rán áńgẹ́lì náà padà láti sọ báwọn ṣe máa tọ́ ọmọ náà. Mánóà béèrè pé: “Kí ni ọ̀nà ìgbésí ayé ọmọ náà àti iṣẹ́ rẹ̀ yóò jẹ́?” Ni áńgẹ́lì Jèhófà bá sọ ohun tó ti sọ fún ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ fún un. (Àwọn Onídàájọ́ 13:6-14) Kò sí àní-àní pé ìṣírí ńlá lèyí jẹ́ fún Mánóà! Lóde òní, àwọn áńgẹ́lì kì í wá sọ́dọ̀ àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, síbẹ̀, àwọn òbí lè bẹ Jèhófà bíi ti Mánóà pé kó kọ́ àwọn báwọn á ṣe tọ́ ọmọ àwọn.—Éfésù 6:4.
10, 11. (a) Nígbà tí Èlíṣà àti ìránṣẹ́ rẹ̀ rí àwọn ọmọ ogun Síríà tó gbógun wá, ipa wo lèyí ní lórí wọn? (b) Báwo ni ríronú nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣe lè ṣe wá láǹfààní?
10 Àpẹẹrẹ kan tó pabanbarì nípa bí àwọn áńgẹ́lì ṣe ń ran èèyàn lọ́wọ́ ni ti ìgbà ayé wòlíì Èlíṣà. Ìlú Dótánì nílẹ̀ Ísírẹ́lì ni Èlíṣà ń gbé. Lọ́jọ́ kan, bí ìránṣẹ́ Èlíṣà ṣe jí láàárọ̀ kùtù, ó rí i pé ẹgbẹ́ ogun ọ̀tá pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ́kẹ̀ ẹṣin wọn ti yí Dótánì ká. Ọba Síríà ló rán ẹgbẹ́ ogun tó lágbára yẹn pé kí wọ́n lọ mú Èlíṣà. Kí ni ìránṣẹ́ Èlíṣà ṣe nígbà tó rí wọn? Ẹ̀rù bà á gan-an, ó sì kígbe pé: “Págà, ọ̀gá mi! Kí ni àwa yóò ṣe?” Lójú rẹ̀, kò sí bí wọ́n ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ológún náà. Àmọ́ Èlíṣà dá a lóhùn pé: “Má fòyà, nítorí àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ.” Kí ni Èlíṣà ní lọ́kàn?—2 Àwọn Ọba 6:11-16.
11 Èlíṣà mọ̀ pé ẹgbàágbèje àwọn áńgẹ́lì wà nítòsí láti ran òun lọ́wọ́. Àmọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ò rí nǹkan kan. Nítorí náà, “Èlíṣà . . . bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà, ó sì wí pé: ‘Jèhófà, jọ̀wọ́, là á ní ojú, kí ó lè ríran.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèhófà la ojú ẹmẹ̀wà náà, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ríran; sì wò ó! ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá náà kún fún àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun oníná yí Èlíṣà ká.” (2 Àwọn Ọba 6:17) Àdúrà tí Èlíṣà gbà yìí mú kí ìránṣẹ́ rẹ̀ rí ẹgbàágbèje àwọn áńgẹ́lì náà. Àwa náà lè fojú ìgbàgbọ́ rí i pé àwọn áńgẹ́lì ń ran àwa èèyàn Jèhófà lọ́wọ́ wọ́n sì ń dáàbò bò wá. Jèhófà àti Kristi ló sì ń darí gbogbo wọn.
Báwọn Áńgẹ́lì Ṣe Ṣèrànwọ́ Nígbà Ayé Kristi
12. Báwo ni áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ṣe fi Màríà lọ́kàn balẹ̀?
12 Wo bí áńgẹ́lì kan ṣe ṣèrànlọ́wọ́ fún wúńdíá kan tí í ṣe Júù tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Màríà. Ọlọ́run rán áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì pé kó lọ sọ fún un pé: “Ìwọ yóò lóyún nínú ilé ọlẹ̀ rẹ, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù.” Àmọ́ kó tó sọ̀rọ̀ tó yà á lẹ́nu yìí fún un, ó kọ́kọ́ sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, Màríà, nítorí ìwọ ti rí ojú rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run.” (Lúùkù 1:26, 27, 30, 31) Ẹ ò rí i pé bó ṣe kọ́kọ́ fi dá a lójú pé Ọlọ́run ṣojúure sí i yìí á fi í lọ́kàn balẹ̀ gan-an á sì jẹ́ ìṣírí fún un!
13. Báwo làwọn áńgẹ́lì ṣe ran Jésù lọ́wọ́?
13 A rí àpẹẹrẹ mìíràn nípa báwọn áńgẹ́lì ṣe ń ṣèrànlọ́wọ́. Èyí wáyé lẹ́yìn tí Sátánì ti dán Jésù wò lẹ́ẹ̀mẹ́ta nínú aginjù tí Jésù sì borí rẹ̀. Àkọsílẹ̀ náà sọ fún wa pé lẹ́yìn tí Èṣù ti dán an wò tán, “Èṣù fi í sílẹ̀, sì wò ó! àwọn áńgẹ́lì wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìránṣẹ́ fún un.” (Mátíù 4:1-11) Áńgẹ́lì tún ṣe irú ìrànlọ́wọ́ yìí fún Jésù lóru ọjọ́ tó ku ọ̀la kí wọ́n pa Jésù. Bí ìdààmú ọkàn ṣe bá Jésù, ó kúnlẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà pé: “‘Baba, bí ìwọ bá fẹ́, mú ife yìí kúrò lórí mi. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ìfẹ́ mi ni kí ó ṣẹ, bí kò ṣe tìrẹ.’ Nígbà náà ni áńgẹ́lì kan láti ọ̀run fara hàn án, ó sì fún un lókun.” (Lúùkù 22:42, 43) Àmọ́, báwo làwọn áńgẹ́lì ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ lónìí?
Báwọn Áńgẹ́lì Ṣe Ń Ṣèrànlọ́wọ́ Lóde Òní
14. Inúnibíni wo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fara dà lóde òní, ibo ni gbogbo rẹ̀ sì wá já sí?
14 Tá a bá wo àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ látìgbà táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní ti ń bá iṣẹ́ ìwàásù wa bọ̀, ǹjẹ́ a ò rí i pé àwọn áńgẹ́lì ń ràn wá lọ́wọ́ lẹnu iṣẹ́ náà? Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe fáwa èèyàn Jèhófà láti fara da inúnibíni ìjọba Násì ní Jámánì àti ní Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù nígbà Ogun Àgbáyé Kejì tó jà lọ́dún 1939 sí 1945 àti ṣáájú kí ogun náà tó jà. Iye ọdún tá a fi fara da inúnibíni pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ nígbà ìjọba aláṣẹ oníkùmọ̀ ti Kátólíìkì ní ilẹ̀ Ítálì, Sípéènì àti Potogí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún la sì fi fara dà inúnibíni lórílẹ̀-èdè tó ń jẹ́ Soviet Union látijọ́ àtàwọn orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ rẹ̀. Kò mọ síbẹ̀ o, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún fara da inúnibíni láwọn orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà.a Láìpẹ́ yìí, wọ́n ṣenúnibíni rírorò sáwa èèyàn Jèhófà lórílẹ̀-èdè Georgia. Sátánì ti ṣe gbogbo ohun tó wà ní agbára rẹ̀ láti dá iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe dúró. Àmọ́, ètò àwa Ẹlẹ́rìí borí inúnibíni wọ̀nyẹn ó sì ń gbilẹ̀ sí i. Ọ̀kan lára àwọn ohun tó mú kó rí bẹ́ẹ̀ ni ààbò látọwọ́ àwọn áńgẹ́lì.—Sáàmù 34:7; Dáníẹ́lì 3:28; 6:22.
15, 16. Báwo làwọn áńgẹ́lì ṣe ń ran àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe jákèjádò ayé?
15 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wa lọ́wọ́, ìyẹn iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run jákèjádò ayé àti iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn nípa fífi ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì kọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí i níbi gbogbo. (Mátíù 28:19, 20) Àmọ́ ṣá o, a mọ̀ pé a ò lè ṣe èyí yọrí láìsí ìrànlọ́wọ́ àwọn áńgẹ́lì. Ìdí nìyẹn tí ohun tí Ìṣípayá 14:6, 7 sọ fi máa ń jẹ́ ìṣírí fún wa. Ó kà pé: “Mo [ìyẹn àpọ́sítélì Jòhánù] sì rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run, ó sì ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo gẹ́gẹ́ bí làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn, ó ń sọ ní ohùn rara pé: ‘Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé, nítorí náà, ẹ jọ́sìn Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti àwọn ìsun omi.’”
16 Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn kedere pé àwọn áńgẹ́lì ń ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe jákèjádò ayé, wọ́n sì ń darí wa. Jèhófà máa ń lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti darí àwọn tó dìídì fẹ́ mọ òtítọ́ sọ́dọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí rẹ̀. Àwọn áńgẹ́lì tún máa ń darí àwa Ẹlẹ́rìí lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹni yíyẹ. Abájọ tó fi máa ń ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà pé bí ìṣòro bá ṣe ń bá ẹnì kan fínra lọ́wọ́ tó sì nílò ìrànlọ́wọ́ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run làwa Ẹlẹ́rìí á dé ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bó ṣe jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà lèyí ń ṣẹlẹ̀, kò lè jẹ́ pé ó ń ṣèèṣì rí bẹ́ẹ̀, àwọn áńgẹ́lì ló ń darí wa lọ síbẹ̀.
Wọ́n Á Ṣe Iṣẹ́ Akọni Kan Láìpẹ́
17. Kí ni áńgẹ́lì kan ṣoṣo ṣe fún àwọn ọmọ ogun Ásíríà?
17 Yàtọ̀ sí jíjíṣẹ́ Ọlọ́run fún àwọn olùjọsìn Jèhófà àti fífún wọn lókun, àwọn nǹkan míì tún wà táwọn áńgẹ́lì máa ń ṣe. Láyé ọjọ́un, Ọlọ́run máa ń lò wọ́n láti mú ìparun wá sórí àwọn tó dájọ́ ìparun fún. Bí àpẹẹrẹ, ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ ogun Ásíríà fẹ́ gbógun ja Jerúsálẹ́mù. Kí wá ni Jèhófà ṣe? Ó ní: “Dájúdájú, èmi yóò gbèjà ìlú ńlá yìí láti gbà á là nítorí tèmi àti nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ mi.” Bíbélì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà, ó ní: “Ó sì ṣẹlẹ̀ ní òru yẹn pé áńgẹ́lì Jèhófà tẹ̀ síwájú láti jáde lọ, ó sì ṣá ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n balẹ̀ nínú ibùdó àwọn ará Ásíríà. Nígbà tí àwọn ènìyàn dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, họ́wù, òkú ni gbogbo wọn jẹ́ níbẹ̀.” (2 Àwọn Ọba 19:34, 35) Àbẹ́ ò rí nǹkan, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọmọ ogun èèyàn ò jẹ́ nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ áńgẹ́lì kan péré!
18, 19. Iṣẹ́ akọni wo làwọn áńgẹ́lì máa ṣe láìpẹ́, kí ló sì máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ fún aráyé?
18 Láìpẹ́, Ọlọ́run máa lo àwọn áńgẹ́lì láti pa àwọn èèyàn búburú run. Kò ní pẹ́ mọ́ tí Jésù á wá “tòun ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára nínú iná tí ń jó fòfò.” Wọ́n á wá láti mú “ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.” (2 Tẹsalóníkà 1:7, 8) Dájúdájú, nǹkan kékeré kọ́ ni àbájáde èyí máa jẹ́ fún aráyé! Àwọn tí kò kọbi ara sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tá à ń wàásù jákèjádò ayé yóò pa run. Kìkì àwọn tí wọ́n bá wá Jèhófà, tí wọ́n wá òdodo àti ọkàn tútù la ó “pa . . . mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.”—Sefanáyà 2:3.
19 Ó yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún bó ṣe ń lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti ṣèrànlọ́wọ́ fún àwọn olùjọsìn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé àti láti fún wọn lókun. Mímọ̀ tá a mọ ipa táwọn áńgẹ́lì ń kó nínú ìmúṣẹ àwọn ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀, nítorí pé àwọn áńgẹ́lì míì wà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà tí wọ́n sì dọmọ ẹ̀yìn Sátánì. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e á sọ ohun táwọn Kristẹni tòótọ́ lè ṣe kí Sátánì Èṣù àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ tí wọn jẹ́ ẹ̀mí èṣù má bàa rí wọn gbé ṣe.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ mọ̀ nípa àwọn inúnibíni yìí lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, wo ìwé ọdọọdún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn Yearbook of Jehovah’s Witnesses ti ọdún 1983 (Àǹgólà), tọdún 1972 (Czechoslovakia), tọdún 2000 (Czech Republic), tọdún 1992 (Etiópíà), tọdún 1982 (Ítálì), tọdún 1974 àti 1999 (Jámánì), tọdún 1999 (Màláwì), tọdún 2004 (Moldova), tọdún 1996 (Mòsáńbíìkì), tọdún 1994 (Poland), tọdún 1983 (Potogí), tọdún 2006 (Sáńbíà), tọdún 1978 (Sípéènì), àti tọdún 2002 (Ukraine).
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?
• Báwo ló ṣe di pé àwọn áńgẹ́lì wà?
• Báwo ni Jèhófà ṣe lo àwọn áńgẹ́lì láyé ìgbà tí wọ́n ṣì ń kọ Bíbélì lọ́wọ́?
• Kí ni Ìṣípayá 14:6, 7 jẹ́ ká mọ̀ nípa ohun táwọn áńgẹ́lì ń ṣe láyé òde òní?
• Iṣẹ́ akọni wo làwọn áńgẹ́lì máa ṣe láìpẹ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Áńgẹ́lì kan sọ̀rọ̀ tó fún Mánóà àti aya rẹ̀ níṣìírí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
“Àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ”