Ohun Tí Àwọn Áńgẹ́lì Ń Ṣe fún Wa
NÍGBÀ tí wòlíì Dáníẹ́lì ń sọ ìran kan tó rí nípa àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run, ó kọ̀wé pé: “Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún [áńgẹ́lì] ń ṣe ìránṣẹ́ fún [Ọlọ́run], ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì ń dúró níwájú rẹ̀ gangan.” (Dáníẹ́lì 7:10) Ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká rídìí tí Ọlọ́run fi dá àwọn áńgẹ́lì. Òun ni pé kí wọ́n máa ṣe ìránṣẹ́ fún un, wọ́n sì wà ní sẹpẹ́ lọ́jọ́kọ́jọ́ láti máa ṣe ohun tí Ọlọ́run bá ní kí wọ́n ṣe.
Nígbà míì, Ọlọ́run máa ń lo àwọn áńgẹ́lì láti ṣe àwọn nǹkan kan fáwa ọmọ èèyàn. A ó sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe ń lò wọ́n láti fún àwọn èèyàn rẹ̀ lókun àti láti dáàbò bò wọ́n, bó ṣe ń lò wọ́n láti jíṣẹ́ fáwa èèyàn, àti bó ṣe ń lò wọ́n láti mú ìdájọ́ ṣẹ lórí àwọn ẹni ibi.
Àwọn Áńgẹ́lì Ń Fúnni Lókun, Wọ́n sì Ń Dáàbò Boni
Látìgbà táwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ti rí bí Ọlọ́run ṣe dá ilẹ̀ ayé àtàwọn ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ ni ọ̀rọ̀ àwa ọmọ èèyàn ti ń jẹ wọ́n lọ́kàn gan-an. Jésù Kristi, ẹni tí Bíbélì ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n, sọ ọ̀rọ̀ kan kó tó wá sórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, ó ní: “Àwọn ohun tí mo . . . ní ìfẹ́ni sí jẹ́ sípa àwọn ọmọ ènìyàn.” (Òwe 8:31) Bíbélì sì fi yé wa pé àwọn ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa Kristi àti ọjọ́ ọlá tí Ọlọ́run fi han àwọn wòlíì rẹ̀ jẹ́ ohun tí “àwọn áńgẹ́lì ń fẹ́ láti wò ní àwòfín.”—1 Pétérù 1:11, 12.
Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn áńgẹ́lì rí i pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára ẹ̀dá èèyàn ni kò sin Ẹlẹ́dàá wọn onífẹ̀ẹ́. Ẹ ò rí i pé èyí ti ní láti ba àwọn áńgẹ́lì rere wọ̀nyí nínú jẹ́! Àmọ́ ṣá o, nígbàkigbà tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà tó sì padà sọ́dọ̀ Jèhófà, ńṣe ni ‘ìdùnnú máa ń sọ láàárín àwọn áńgẹ́lì.’ (Lúùkù 15:10) Ọ̀rọ̀ àwọn tó ń sin Ọlọ́run jẹ àwọn áńgẹ́lì lógún gan-an ni, léraléra sì ni Jèhófà máa ń lò wọ́n láti fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ tó wà lórí ilẹ̀ ayé lókun àti láti dáàbò bò wọ́n. (Hébérù 1:14) Wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀.
Nígbà tí ìparun fẹ́ dé sórí ìlú Sódómù àti Gòmórà tí ìwà búburú pọ̀ sí, àwọn áńgẹ́lì méjì ló ran Lọ́ọ̀tì olódodo àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ lọ́wọ́ tí wọ́n fi lè là á já. Ńṣe làwọn áńgẹ́lì yìí mú wọn jáde kúrò nínú ìlú náà.a (Jẹ́nẹ́sísì 19:1, 15-26) Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn ìgbà yẹn làwọn ọ̀tá ju wòlíì Dáníẹ́lì sínú ihò kìnnìún, ṣùgbọ́n àwọn kìnnìún ò ṣe é ní nǹkan kan. Kí ló mú kó rí bẹ́ẹ̀? Dáníẹ́lì sọ pé: “Ọlọ́run mi rán áńgẹ́lì rẹ̀, ó sì dí ẹnu àwọn kìnnìún náà.” (Dáníẹ́lì 6:22) Àwọn áńgẹ́lì ran Jésù lọ́wọ́ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Máàkù 1:13) Bákan náà, kété ṣáájú ikú Jésù, áńgẹ́lì kan yọ sí i, ó sì “fún un lókun.” (Lúùkù 22:43) Ẹ ò rí i pé ìṣírí ńlá ni ìrànlọ́wọ́ táwọn áńgẹ́lì yẹn ṣe fún Jésù jẹ́ láwọn àkókò pàtàkì yẹn nígbèésí ayé rẹ̀! Bákan náà, áńgẹ́lì kan ló tú àpọ́sítélì Pétérù sílẹ̀ nínú ẹ̀wọ̀n.—Ìṣe 12:6-11.
Ǹjẹ́ àwọn áńgẹ́lì máa ń dáàbò boni lóde òní? Tá a bá ń sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe ní ká máa sìn ín, ó dájú pé àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára tí wọ́n jẹ́ ẹ̀dá àìrí yóò dáàbò bò wá. Bíbélì ṣèlérí pé: “Áńgẹ́lì Jèhófà dó yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.”—Sáàmù 34:7.
Àmọ́, ká fi sọ́kàn pé ohun táwọn áńgẹ́lì dìídì wà fún ni kí wọ́n máa ṣe iṣẹ́ fún Ọlọ́run, kì í ṣe kí wọ́n máa ṣe ìránṣẹ́ fún àwa èèyàn. (Sáàmù 103:20, 21) Ìtọ́ni Ọlọ́run ni wọ́n máa ń tẹ̀ lé, kì í ṣe pé ohun tọ́mọ èèyàn bá kàn fẹ́ ni wọ́n máa ń ṣe. Nítorí náà, Jèhófà Ọlọ́run lẹni tó yẹ ká máa ké pè pé kó ràn wá lọ́wọ́, kì í ṣe àwọn áńgẹ́lì. (Mátíù 26:53) Àmọ́ o, torí pé a kì í rí àwọn áńgẹ́lì, a kò lè mọ bí Ọlọ́run ṣe ń lò wọ́n tó láti ran èèyàn lọ́wọ́ nínú onírúurú nǹkan. Ohun kan tó dá wa lójú ni pé Jèhófà máa ń “fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíróníkà 16:9; Sáàmù 91:11) Ó sì tún dá wa lójú pé, “ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, [Ọlọ́run] ń gbọ́ tiwa.”—1 Jòhánù 5:14.
Ìwé Mímọ́ tún sọ fún wa pé Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni ká máa gbàdúrà sí, òun nìkan la sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn. (Ẹ́kísódù 20:3-5; Sáàmù 5:1, 2; Mátíù 6:9) Kódà, àwọn áńgẹ́lì rere gbà wá níyànjú láti máa ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù fẹ́ jọ́sìn áńgẹ́lì kan, áńgẹ́lì náà bá a wí, ó ní: “Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀! . . . Jọ́sìn Ọlọ́run.”—Ìṣípayá 19:10.
Àwọn Áńgẹ́lì Máa Ń Jíṣẹ́ Ọlọ́run
Ọ̀rọ̀ náà “áńgẹ́lì” túmọ̀ sí “ìránṣẹ́” lédè Hébérù àti Gíríìkì, èyí sì jẹ́ ọ̀nà míì táwọn áńgẹ́lì gbà ń sin Ọlọ́run, ìyẹn ni pé wọ́n lọ ń jíṣẹ́ Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, “a rán áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì jáde láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run sí ìlú ńlá kan ní Gálílì tí a ń pè ní Násárétì.” Fún kí ni? Láti lọ sọ fún ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Màríà pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé wúńdíá ni, ó máa lóyún, ó sì máa bí ọmọkùnrin kan tí yóò sọ ní Jésù. (Lúùkù 1:26-31) Áńgẹ́lì ni Ọlọ́run tún rán láti lọ sọ fáwọn olùṣọ́ àgùntàn tí wọ́n wà ní pápá pé a ti bí “Kristi Olúwa.” (Lúùkù 2:8-11) Bákan náà, Ọlọ́run rán àwọn áńgẹ́lì láti lọ jíṣẹ́ fún Ábúráhámù, Mósè, Jésù àtàwọn míì tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 18:1-5, 10; Ẹ́kísódù 3:1, 2; Lúùkù 22:39-43.
Ọ̀nà wo làwọn áńgẹ́lì gbà ń ṣe ìránṣẹ́ fún Ọlọ́run lóde òní? Ronú nípa iṣẹ́ tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun yóò máa ṣe kí òpin ètò àwọn nǹkan yìí tó dé. Jésù sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:3, 14) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lo ohun tó lé ní bílíọ̀nù kan wákàtí lọ́dọọdún láti fi wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́, ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì náà ń ṣe nínú iṣẹ́ yìí? Àpọ́sítélì Jòhánù tọ́ka sí ìran kan tó rí, ó ní: ‘Mo rí áńgẹ́lì mìíràn, ó sì ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo gẹ́gẹ́ bí làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn.’ (Ìṣípayá 14:6, 7) Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ olórí iṣẹ́ táwọn áńgẹ́lì ń ṣe fáwọn èèyàn lóde òní.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń rí ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì ń darí wọn nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé tí wọ́n ń ṣe. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń dé ọ̀dọ̀ àwọn tó jẹ́ pé, bí wọ́n ṣe ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ káwọn rí ẹnì kan tó máa wá ṣàlàyé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú fún wọn làwọn Ẹlẹ́rìí ń débẹ̀. Ọdọọdún ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ń dẹni tó mọ Jèhófà nítorí pé àwọn áńgẹ́lì ń darí iṣẹ́ ìwàásù náà, àti pé àwọn Ẹlẹ́rìí fúnra wọn ò fi iṣẹ́ ọ̀hún ṣeré. A rọ̀ ọ́ pé kó o jàǹfààní látinú iṣẹ́ ìgbàlà táwọn áńgẹ́lì ń darí yìí.
Àwọn Áńgẹ́lì Ń Mú Ìdájọ́ Ọlọ́run Ṣẹ
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ò fáwọn áńgẹ́lì láṣẹ láti ṣèdájọ́ èèyàn, síbẹ̀ kì í ṣe pé kò kàn wọ́n. (Jòhánù 5:22; Hébérù 12:22, 23) Ọlọ́run lò wọ́n láyé àtijọ́ láti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ, ìyẹn láti pa àwọn kan run. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run lo àwọn áńgẹ́lì láti fìyà àwọn ará Íjíbítì ìgbàanì tó mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbèkùn. (Sáàmù 78:49) Alẹ́ ọjọ́ kan ṣoṣo sì ni “áńgẹ́lì Jèhófà” gbẹ̀mí ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] ọmọ ogún ẹnì kan tó jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run níbi tí wọ́n pàgọ́ sí.—2 Àwọn Ọba 19:35.
Lọ́jọ́ iwájú pẹ̀lú, àwọn áńgẹ́lì yóò mú ìdájọ́ Ọlọ́run tó múná ṣẹ. Jésù yóò wá “tòun ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára nínú iná tí ń jó fòfò, bí ó ti ń mú ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere.” (2 Tẹsalóníkà 1:7, 8) Àmọ́, kìkì àwọn tí kò bá kọbi ara sí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run táwọn áńgẹ́lì ń ti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́yìn láti wàásù kárí ayé nísinsìnyí ni ìparun tó ń bọ̀ náà yóò dé bá. Àwọn tí wọ́n wá Ọlọ́run tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ yóò sì rí ìgbàlà.—Sefanáyà 2:3.
A mà dúpẹ́ o pé àwọn áńgẹ́lì rere tí wọ́n ń ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ fún wọn nígbà gbogbo! Jèhófà máa ń lò wọ́n láti ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ tó wà lórí ilẹ̀ ayé lọ́wọ́ àti láti dáàbò bò wọ́n. Ìtùnú gbáà lọ̀rọ̀ yìí jẹ́ fún wa nítorí pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú kan wà tá à ń pè ní ẹ̀mí èṣù tí wọ́n fẹ́ ba tiwa jẹ́.
Àwọn Wo Làwọn Ẹ̀mí Èṣù?
Lẹ́yìn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ọdún tí Sátánì ti tan Éfà jẹ ní ọgbà Édẹ́nì, àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ara ìdílé Ọlọ́run ṣàkíyèsí pé Sátánì Èṣù ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mú kí gbogbo ẹ̀dá èèyàn kẹ̀yìn sí Ọlọ́run tán àyàfi àwọn díẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́, irú bí Ébẹ́lì, Énọ́kù àti Nóà. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-7; Hébérù 11:4, 5, 7) Àwọn áńgẹ́lì kan sì fara mọ́ Sátánì pẹ̀lú. Bíbélì sọ pé àwọn ni àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó ṣàìgbọràn “ní àwọn ọjọ́ Nóà.” (1 Pétérù 3:19, 20) Báwo ni àìgbọràn wọn ṣe fara hàn?
Nígbà ayé Nóà, àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ kan tí Bíbélì ò sọ iye wọn fi ipò wọn nínú ìdílé Ọlọ́run tí ń bẹ lọ́run sílẹ̀, wọ́n wá sórí ilẹ̀ ayé, wọ́n sì para dà di èèyàn. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé wọ́n fẹ́ máa ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Bí wọ́n ṣe bí àwọn ọmọ tí wọ́n ń pè ní Néfílímù nìyẹn, ìyẹn àwọn tó di òmìrán oníwà ipá. Yàtọ̀ síyẹn, “ìwà búburú ènìyàn pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ ayé, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ sì jẹ́ kìkì búburú ní gbogbo ìgbà.” Àmọ́, Jèhófà Ọlọ́run ò gba ìwàkiwà táwọn èèyàn ń hù yìí láyè kó máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi fi Ìkún Omi pa ayé rẹ́, tí gbogbo àwọn èèyàn búburú àtàwọn Néfílímù sì ṣègbé. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ nìkan ni kò pa run.—Jẹ́nẹ́sísì 6:1-7, 17; 7:23.
Àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yìí fẹsẹ̀ fẹ nígbà tí Ìkún Omi dé láti pa ayé run. Wọ́n bọ́ ara èèyàn sílẹ̀, wọ́n para dà di ẹ̀dá ẹ̀mí, wọ́n sì padà sí ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí. Látìgbà yẹn la ti ń pè wọ́n ní ẹ̀mí èṣù. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ lé Sátánì Èṣù, ẹni tí Bíbélì pè ní “olùṣàkóso àwọn ẹ̀mí èṣù.” (Mátíù 12:24-27) Bí olùṣàkóso wọn ṣe fẹ́ káwọn èèyàn máa jọ́sìn òun làwọn ẹ̀mí èṣù wọ̀nyí náà ṣe fẹ́ káwọn èèyàn máa jọ́sìn àwọn.
Eléwu làwọn ẹ̀mí èṣù, àmọ́ ìyẹn ò ní ká máa bẹ̀rù wọn o. Ó níbi tágbára wọn mọ. Nígbà táwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn yẹn padà dé ọ̀run, wọn ò gbà wọ́n padà sáàárín àwọn áńgẹ́lì rere tó jẹ́ ara ìdílé Ọlọ́run. Dípò ìyẹn, ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá kò dé ọ̀dọ̀ wọn mọ́ rárá, ọjọ́ ọ̀la wọn sì ṣókùnkùn. Àní inú òkùnkùn tẹ̀mí tí Bíbélì pè ní Tátárọ́sì ni Ọlọ́run fi wọ́n sí. (2 Pétérù 2:4) Jèhófà fi “ìdè ayérayé” dè wọ́n kí wọ́n lè wà nínú òkùnkùn biribiri nípa tẹ̀mí. Yàtọ̀ síyẹn, kò tún ṣeé ṣe fún wọn mọ́ láti para dá di èèyàn.—Júúdà 6.
Kí Ló Yẹ Kó O Ṣe?
Ǹjẹ́ àwọn ẹ̀mí èṣù ṣì máa ń nípa lórí àwọn èèyàn? Bẹ́ẹ̀ ni o, wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípa lílo “ètekéte,” irú èyí tí Sátánì Èṣù olùṣàkóso wọn ń lò. (Éfésù 6:11, 12) Àmọ́, tá a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwọn ẹ̀mí èṣù ò ní lè rí wa gbéṣe. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn áńgẹ́lì alágbára máa ń dáàbò bo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.
O ò ri pé ó ṣe pàtàkì gan-an kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìlànà Ọlọ́run tó wà nínú Ìwé Mímọ́ kó o sì máa fi àwọn ohun tó ò ń kọ́ sílò! O lè túbọ̀ mọ̀ sí i nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó o bá kàn sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè rẹ̀ tàbí tó o bá kọ̀wé sáwọn tó tẹ ìwé ìròyìn yìí. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́, ní àsìkò tó bá rọ̀ ọ́ lọ́rùn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Géńdé ọkùnrin ni Bíbélì fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì jẹ́ ní gbogbo ìgbà tó sọ̀rọ̀ wọn. Ọkùnrin sì ni gbogbo áńgẹ́lì tó fara han àwọn èèyàn nínú Bíbélì.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
BÍ ỌLỌ́RUN ṢE ṢÈTÒ ÀWỌN ÁŃGẸ́LÌ
Báyìí ni Jèhófà ṣe ṣètò ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì rẹ̀:
Áńgẹ́lì tó ní agbára àti ọlá àṣẹ tó ga jù lọ ni Máíkẹ́lì tí í ṣe olú áńgẹ́lì, ìyẹn Jésù Kristi. (1 Tẹsalóníkà 4:16; Júúdà 9) Abẹ́ rẹ̀ làwọn Séráfù, Kérúbù àtàwọn áńgẹ́lì mìíràn wà.
Ipò ńlá làwọn Séráfù dì mú nínú ìṣètò Ọlọ́run. Ibi ìtẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n ti ń ṣiṣẹ́. Lára iṣẹ́ wọn sì ni pé kí wọ́n máa polongo pé Ọlọ́run jẹ́ mímọ́ kí wọ́n sì máa rí sí i pé àwọn èèyàn Ọlọ́run wà ní mímọ́ nípa tẹ̀mí.—Aísáyà 6:1-3, 6, 7.
Àyíká ìtẹ́ Ọlọ́run làwọn Kérúbù máa ń wà, wọ́n sì máa ń gbé ọlá ńlá Jèhófà ga.—Sáàmù 80:1; 99:1; Ìsíkíẹ́lì 10:1, 2.
Aṣojú Jèhófà làwọn áńgẹ́lì yòókù, wọ́n sì máa ń mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Àwọn áńgẹ́lì mú Lọ́ọ̀tì àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ jáde lọ síbi tó láàbò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù fẹ́ jọ́sìn áńgẹ́lì kan, áńgẹ́lì náà sọ fún un pé: “Má ṣe bẹ́ẹ̀!”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn áńgẹ́lì máa ń mú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ǹjẹ́ ò ń jàǹfààní látinú iṣẹ́ ìwàásù táwọn áńgẹ́lì ń darí?