ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 11/15 ojú ìwé 4-7
  • Bí Àwọn Áńgẹ́lì Ṣe Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Àwọn Áńgẹ́lì Ṣe Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bíbá Áńgẹ́lì Pàdé
  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Ké Pe Áńgẹ́lì fún Ìrànwọ́?
  • Kíké Pe Ọlọ́run
  • Àwọn Áńgẹ́lì àti Ìwà Rere
  • Àwọn Áńgẹ́lì Adáàbòboni
  • Iṣẹ́ Tí Àwọn Áńgẹ́lì Ń Jẹ́
  • Ohun Tí Àwọn Áńgẹ́lì Ń Ṣe fún Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àwọn Áńgẹ́lì Jẹ́ “Ẹ̀mí Fún Iṣẹ́ Ìsìn Gbogbo Ènìyàn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àwọn Wo Là Ń Pè Ní Áńgẹ́lì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Bí Àwọn Áńgẹ́lì Ṣe Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 11/15 ojú ìwé 4-7

Bí Àwọn Áńgẹ́lì Ṣe Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́

Ọ̀RỌ̀ Ọlọ́run jẹ́rìí sí i pé àwọn áńgẹ́lì ń bẹ. Ó sọ fún wa pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí wọ̀nyí ló wà. Dáníẹ́lì, ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run, rí ìran àwọn nǹkan ti ọ̀run, ó sì kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: “Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún [Ọlọ́run], ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì ń dúró níwájú rẹ̀ gangan.”—Dáníẹ́lì 7:10.

Ṣàkíyèsí pé ohun tí ọ̀rọ̀ Dáníẹ́lì fi hàn wá ju kìkì pé ọ̀pọ̀ áńgẹ́lì ni ó wà. Ó tún fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì ń ṣe ìrànṣẹ́ fún Ọlọ́run. Ìránṣẹ́ rẹ̀ ni wọ́n. Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, onísáàmù náà kọrin pé: “Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà, ẹ̀yin áńgẹ́lì rẹ̀, tí ẹ tóbi jọjọ nínú agbára, tí ẹ ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́, nípa fífetísí ohùn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, ẹ̀yin òjíṣẹ́ rẹ̀, tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.”—Sáàmù 103:20, 21.

Bíbélì tún ṣàlàyé pé àwọn áńgẹ́lì kò bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé wọn lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ènìyàn. Kí Jèhófà tó dá ilẹ̀ ayé rárá ni ó ti dá àwọn áńgẹ́lì sí ọ̀run. Nígbà tí Ọlọ́run ‘fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀, gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ áńgẹ́lì hó yèè nínú ìyìn.’—Jóòbù 38:4-7.

Àwọn áńgẹ́lì jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí—a kò lè fojú rí wọn, wọ́n lágbára, wọ́n sì jẹ́ olóye. Nínú Bíbélì, a tú ọ̀rọ̀ Hébérù náà, mal·ʼakhʹ, àti ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, agʹge·los, sí “áńgẹ́lì” nígbà tí ó bá ń tọ́ka sí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìgbà 400 tí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fara hàn nínú Bíbélì. Ohun kan náà ni àwọn méjèèjì túmọ̀ sí, tí í ṣe, “ońṣẹ́.”

Bíbá Áńgẹ́lì Pàdé

Lóòótọ́, ońṣẹ́ ni àwọn áńgẹ́lì. O lè mọ àkọsílẹ̀ inú Bíbélì náà dáadáa, èyí tí ó sọ nípa ìgbà tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì fara han Màríà. Ó sọ fún un pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wúńdíá, yóò bí ọmọkùnrin kan tí a óò pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù. (Lúùkù 1:26-33) Áńgẹ́lì kan tún fara han àwọn olùṣọ́ àgùntàn kan tí wọ́n wà ní pápá. Ó kéde pé: “A bí Olùgbàlà kan fún yín lónìí, ẹni tí í ṣe Kristi Olúwa.” (Lúùkù 2:8-11) Bákan náà, áńgẹ́lì jíṣẹ́ fún Hágárì, Ábúráhámù, Lọ́ọ̀tì, Jékọ́bù, Mósè, Gídéónì, Jésù, àti àwọn mìíràn tí Bíbélì sọ nípa wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 16:7-12; 18:1-5, 10; 19:1-3; 32:24-30; Ẹ́kísódù 3:1, 2; Àwọn Onídàájọ́ 6:11-22; Lúùkù 22:39-43; Hébérù 13:2.

Ó yẹ fún àfiyèsí pé gbogbo iṣẹ́ tí àwọn áńgẹ́lì jẹ́ wọ̀nyí jẹ́ láti mú ète Ọlọ́run ṣẹ, kì í ṣe ti àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí ọ̀ràn náà kàn. Àwọn áńgẹ́lì fara hàn gẹ́gẹ́ bí aṣojú Ọlọ́run, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀ àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ̀. Kì í ṣe àwọn ẹ̀dá ènìyàn ló ń pè wọ́n.

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Ké Pe Áńgẹ́lì fún Ìrànwọ́?

Ǹjẹ́ ó yẹ ká ké pe áńgẹ́lì nígbà ìdààmú? Bí ó bá yẹ bẹ́ẹ̀, a óò fẹ́ láti mọ orúkọ áńgẹ́lì náà gan-an tí ó lè ràn wá lọ́wọ́. Lójú ìwòye èyí, àwọn ìwé àfiwówó kan to orúkọ ọ̀pọ̀ àwọn áńgẹ́lì, ipò wọn, oyè wọn, àti iṣẹ́ wọn, lẹ́sẹẹsẹ. Ìwé kan to ohun tí ó pè ní “àwọn òléwájú áńgẹ́lì mẹ́wàá” lẹ́sẹẹsẹ, àwọn wọ̀nyí jẹ́ “àwọn áńgẹ́lì tí ó gbajúmọ̀ jù lọ ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé.” Lára ìmọ̀ràn tí ó bá àkọsílẹ̀ náà rìn ni èyí tí ó sọ pé, di ojú rẹ, máa pe orúkọ áńgẹ́lì náà léraléra, mí kanlẹ̀, rọra máa mí díẹ̀díẹ̀, sì “mú ara rẹ wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti lè kàn sí wọn.”

Ní òdìkejì pátápátá, Bíbélì fún wa ní orúkọ méjì péré lára àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́, Máíkẹ́lì àti Gébúrẹ́lì. (Dáníẹ́lì 12:1; Lúùkù 1:26) Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé, ìdí tí ó fi jẹ́ kí a mọ orúkọ wọ̀nyí ni láti fi hàn pé áńgẹ́lì kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí ọ̀tọ̀ gedegbe tí ó ní orúkọ tirẹ̀, kì í wulẹ̀ ṣe agbára tàbí ipá lásán tí kò ní àkópọ̀ ìwà.

Ó yẹ fún àfiyèsí pé àwọn áńgẹ́lì kan kọ̀ láti sọ orúkọ wọn fún àwọn ènìyàn. Nígbà tí Jékọ́bù ní kí áńgẹ́lì kan sọ orúkọ rẹ̀ fóun, kò ṣe bẹ́ẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 32:29) Nígbà tí Jóṣúà ní kí áńgẹ́lì kan tí ó tọ̀ ọ́ wá sọ orúkọ rẹ̀, kìkì ohun tó sọ ni pé òun ni “olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jèhófà.” (Jóṣúà 5:14) Nígbà tí àwọn òbí Sámúsìnì ní kí áńgẹ́lì kan sọ orúkọ rẹ̀, ó wí pé: “Èé sì ti ṣe tí o fi ń béèrè nípa orúkọ mi, nígbà tí ó jẹ́ pé àgbàyanu ni?” (Àwọn Onídàájọ́ 13:17, 18) Nítorí tí Bíbélì kò pèsè orúkọ àwọn áńgẹ́lì, ó dáàbò bò wá lọ́wọ́ bíbọlá tí kò yẹ fún àwọn áńgẹ́lì àti jíjọ́sìn wọn. Bí a óò ti rí i, kò tún sọ pé kí a máa gbàdúrà sí wọn.

Kíké Pe Ọlọ́run

Gbogbo ohun tí ó yẹ kí a mọ̀ nípa ilẹ̀ àkóso ẹ̀mí ni Bíbélì sọ fún wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, . . . kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (2 Tímótì 3:16, 17) Bí Ọlọ́run bá fẹ́ kí a mọ orúkọ ọ̀pọ̀ áńgẹ́lì, òun ì bá ti ṣí orúkọ wọ̀nyí payá nínú Bíbélì, tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ká ní Ọlọ́run fẹ́ kọ́ wa ní bí a ṣe lè kàn sí àwọn áńgẹ́lì, kí a sì gbàdúrà sì wọn ni, òun ì bá ti pèsè irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́.

Dípò èyí, Jésù Kristi kọ́ni pé: “Nígbà tí o bá ń gbàdúrà, lọ sínú yàrá àdáni rẹ àti, lẹ́yìn títi ilẹ̀kùn rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ tí ń bẹ ní ìkọ̀kọ̀ . . . Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.’” (Mátíù 6:6, 9) Ojú ìwòye Ìwé Mímọ́ nìyí: A kò ní láti ké pe àwọn áńgẹ́lì tàbí kí a gbàdúrà sí wọn, ṣùgbọ́n Ẹlẹ́dàá àwọn áńgẹ́lì, Ọlọ́run fúnra rẹ̀, ni ó yẹ kí a gbàdúrà sí. Orúkọ rẹ̀ kò fara sin rárá, a kò sì nílò aríran kan tí yóò fi hàn wá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ti gbìdánwò láti pa orúkọ Ọlọ́run náà rẹ́, ó fara hàn nínú Bíbélì nígbà tí ó lé ní 7,000. Bí àpẹẹrẹ, Baba ọ̀run náà ni onísàámú ń tọ́ka sí, nígbà tó kọrin pé: “Ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 83:18.

Ọwọ́ Jèhófà kò dí jù láti tẹ́tí sí wa, bí a bá gbàdúrà sí i lọ́nà yíyẹ. Bíbélì fúnni ní ìdánilójú yìí pé: “Ní ti Jèhófà, ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.”—2 Kíróníkà 16:9.

Àwọn Áńgẹ́lì àti Ìwà Rere

Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ohun tí a sábà ń fi hàn nínú ìròyìn, àwọn áńgẹ́lì kì í ṣèdájọ́ àwọn ènìyàn. Ìyẹn bá a mu, nítorí pé a kò fún àwọn áńgẹ́lì láṣẹ láti ṣèdájọ́ ẹ̀dá ènìyàn. Jèhófà ni “Onídàájọ́ gbogbo ènìyàn,” bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé “ó ti fi gbogbo ìdájọ́ ṣíṣe lé Ọmọ” náà, Jésù Kristi, “lọ́wọ́.” (Hébérù 12:23; Jòhánù 5:22) Síbẹ̀síbẹ̀, yóò jẹ́ àṣìṣe láti rò pé àwọn áńgẹ́lì kò bìkítà nípa bí a ti ń gbé ìgbésí ayé wa. Jésù wí pé: “Ìdùnnú máa ń sọ láàárín àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronú pìwà dà.”—Lúùkù 15:10.

Àmọ́ ṣá o, àwọn áńgẹ̀lì kì í kàn ṣe afọwọ́lẹ́rán-wòye. Nígbà àtijọ́, àwọn ni wọ́n ń mú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn áńgẹ́lì ni Ọlọ́run fi bá àwọn ará Íjíbítì ìgbàanì jà. Gẹ́gẹ́ bí Sáàmù 78:49 ti sọ, “ó ń bá a lọ ní rírán ìbínú rẹ̀ jíjófòfò sórí wọn, ìbínú kíkan àti ìdálẹ́bi àti wàhálà, àwùjọ àwọn áńgẹ́lì tí a rán láti mú ìyọnu àjálù wá.” Bákan náà, Bíbélì ròyìn pé ni òru ọjọ́ kan ṣoṣo, áńgẹ́lì kan péré pa 185,000 ọmọ ogun Asíríà.—2 Àwọn Ọba 19:35.

Bákan náà, ní ọjọ́ ọ̀la, àwọn áńgẹ́lì yóò pa àwọn tí ń wu ire àwọn ẹlòmíràn léwu, nípa kíkọ̀ láti tẹ̀ lé ìlànà òdodo Ọlọ́run. Jésù yóò wá “tòun ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára nínú iná tí ń jó fòfò, bí ó tí ń mú ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere.”—2 Tẹsalóníkà 1:7, 8.

Ìwé Mímọ́ tipa báyìí fi hàn pé àwọn olóòótọ́ áńgẹ́lì Ọlọ́run ń fìgbà gbogbo ṣe ìfẹ́ rẹ̀ nípa títẹ̀lé ìtọ́ni rẹ̀ àti gbígbé ìlànà òdodo rẹ̀ lárugẹ. Ó ṣe kedere pé, bí a bá fẹ́ kí àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ mọ́ ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, kí a sì fi taratara làkàkà láti ṣe é.

Àwọn Áńgẹ́lì Adáàbòboni

Àwọn áńgẹ́lì ha bìkítà nípa àwọn ènìyàn, tí wọ́n sì ń dáàbò bò wọ́n bí? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Gbogbo wọn [áńgẹ́lì] kì í ha ṣe ẹ̀mí fún iṣẹ́ ìsìn gbogbo ènìyàn, tí a rán jáde láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà?” (Hébérù 1:14) Ó ṣe kedere pé, bẹ́ẹ̀ ni, ni ìdáhùn sí ìbéèrè Pọ́ọ̀lù.

Nítorí kíkọ̀ tí àwọn Hébérù mẹ́ta, Ṣádírákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dínígò kọ̀ láti tẹrí ba fún ère oníwúrà tí Nebukadinésárì, Ọba Bábílónì, gbé kalẹ̀, a gbè wọn jù sínú ìléru tí a mú gbóná lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Àmọ́, iná kò kan àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run wọ̀nyẹn. Nígbà tí ọba bojú wo ìléru náà, ó rí “abarapá ọkùnrin mẹ́rin,” ó sì wí pé “ìrísí ẹni kẹrin sì jọ ti ọmọ àwọn ọlọ́run.” (Dáníẹ́lì 3:25) Ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, Dáníẹ́lì bá ara rẹ̀ ní ihò kìnnìún nítorí ìṣòtítọ́ rẹ̀. Òun pẹ̀lú yè bọ́ láìfarapa, ó sì polongo pé: “Ọlọ́run mi rán áńgẹ́lì rẹ̀, ó sì dí ẹnu àwọn kìnnìún náà.”—Dáníẹ́lì 6:22.

Nígbà tí a dá ìjọ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi sílẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, àwọn áńgẹ́lì tún fara hàn lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n tú àwọn àpọ́sítélì sílẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. (Ìṣe 5:17-24; 12:6-12) Nígbà tí ìwàláàyè Pọ́ọ̀lù wà nínú ewu lójú òkun, áńgẹ́lì kan fọkàn rẹ̀ balẹ̀ pé yóò dé Róòmù lálàáfíà.—Ìṣe 27:13-24.

Ó dá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run lóde òní lójú gbangba pé agbo àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run tí a kò lè fojú rí wà ní tòótọ́, wọ́n sì lè dáàbò boni, bí wọ́n ti ṣe fún Èlíṣà àti ìránṣẹ́ rẹ̀. (2 Àwọn Ọba 6:15-17) Ní tòótọ́, “áńgẹ́lì Jèhófà dó yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.”—Sáàmù 34:7; 91:11.

Iṣẹ́ Tí Àwọn Áńgẹ́lì Ń Jẹ́

Yàtọ̀ sí pé àwọn áńgẹ́lì ń dàníyàn nípa ire àwọn tí ń sin Jèhófà Ọlọ́run, wọ́n tún ń rí sí i pé kí àwọn ènìyàn kọ́ nípa rẹ̀ àti ète rẹ̀. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Mo sì rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run, ó sì ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo gẹ́gẹ́ bí làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn, ó ń sọ ní ohùn rara pé: ‘Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un.’”—Ìṣípayá 14:6, 7.

Ìwọ ha fẹ́ mọ ohun tí “ìhìn rere àìnípẹ̀kun” yìí ní nínú bí? Bí o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, béèrè lọ́wọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Inú wọn yóò dùn láti ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú rẹ.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Áńgẹ́lì kan ní agbedeméjì ọ̀run ń polongo ìhìn rere àìnípẹ̀kun. Ìwọ ha fẹ́ láti kọ́ nípa rẹ̀ bí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́