Ẹ̀yin Èwe—Ẹ̀kọ́ Ta Ni Ẹ Ń Kọbiara Sí?
“Àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn ó máa fiyèsí . . . ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí-èṣù.”—1 TIMOTEU 4:1.
1. (a) Yíyàn wo ni àwọn èwe ní? (b) Báwo ni Jehofa ṣe ń kọ́ni?
ÌBÉÈRÈ náà tí a dojú rẹ̀ kọ àwọn èwe níhìn-ín ni pé, Ẹ̀kọ́ ta ni ẹ ń kọbiara sí? Èyí túmọ̀sí pé ẹ̀yin èwe ní yíyàn kan. Yíyàn náà jẹ́ láàárín dídáhùnpadà sí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá àti títẹ̀lé ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí-èṣù. Jehofa ń kọ́ni nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, àti nípasẹ̀ iṣẹ́-òjíṣẹ́ àwọn wọnnì tí òun ń lò gẹ́gẹ́ bí aṣojú rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé. (Isaiah 54:13; Iṣe 8:26-39; Matteu 24:45-47) Ṣùgbọ́n ó ha yà yín lẹ́nu pé àwọn ẹ̀mí-èṣù pẹ̀lú ń kọ́ni bí?
2. Èéṣe tí ó fi ṣekókó ní pàtàkì ní àkókò yìí láti ṣọ́ra fún ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí-èṣù?
2 Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn ó máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí-èṣù.” (1 Timoteu 4:1) Níwọ̀n bí a ti ń gbé nínú àwọn “ìkẹyìn ọjọ́” nígbà tí Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ ń gbékánkánṣiṣẹ́ ní pàtàkì, ẹ ha rí ìdí tí a fi béèrè ìbéèrè náà pé, Ẹ̀kọ́ ta ni ẹ ń kọbiara sí? (2 Timoteu 3:1-5; Ìfihàn 12:7-12) Nítorí pé Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ jẹ́ alálùmọ̀kọ́rọ́yí tóbẹ́ẹ̀, tí ọ̀nà wọn sì kún fún ọgbọ́n ìyíniléròpadàdẹ́ṣẹ̀ gan-an, ó ṣekókó pé kí ẹ farabalẹ̀ gbé ìbéèrè yìí yẹ̀wò.—2 Korinti 11:14, 15.
Àwọn Ẹ̀mí-Èṣù àti Àwọn Ẹ̀kọ́ Wọn
3. Àwọn wo ni ẹ̀mí-èṣù, kí ni ète wọn, báwo sì ni wọ́n ṣe ń wá ọ̀nà láti ṣàṣeparí rẹ̀?
3 Àwọn ẹ̀mí-èṣù ti fìgbàkan rí jẹ́ angẹli Jehofa, ṣùgbọ́n wọ́n ṣọ̀tẹ̀ lòdìsí Ẹlẹ́dàá wọn, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ fún Satani. (Matteu 12:24) Ète wọn ni láti sọ àwọn ènìyàn dìbàjẹ́ kí wọ́n sì yí wọn padà kúrò nínú ṣíṣiṣẹ́sin Ọlọrun. Láti ṣàṣeparí èyí, àwọn ẹ̀mí-èṣù ń lo àwọn ènìyàn bí olùkọ́ láti ṣe ìgbélárugẹ ọ̀nà ìgbésí-ayé onímọtara-ẹni-nìkan, àti oníwà pálapàla tí Jehofa dálẹ́bi. (Fiwé 2 Peteru 2:1, 12-15.) Àtúnyẹ̀wò nípa bí àwọn angẹli tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ tẹ́lẹ̀rí ṣe di ẹ̀mí-èṣù yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dá ẹ̀kọ́ wọn àti ọ̀nà ìgbésí-ayé tí àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí ń gbé lárugẹ mọ̀.
4. (a) Èéṣe tí àwọn angẹli aláìgbọràn fi wá sórí ilẹ̀-ayé ní ọjọ́ Noa? (b) Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn angẹli búburú náà àti àwọn ọmọ wọn nígbà Ìkún-Omi?
4 Ní àwọn ọjọ́ Noa, àwọn arẹwà ọmọbìnrin ènìyàn fa àwọn angẹli pàtó kan mọ́ra tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí wọ̀nyí fi ipò wọn sílẹ̀ ní ọ̀run láti wá sórí ilẹ̀-ayé. Ìbálòpọ̀ takọtabo wọn pẹ̀lú àwọn obìnrin yọrísí àwọn àdàmọ̀dì ọmọ tí a ń pè ní Nefilimu. Níwọ̀n bí kò ti bá ìwà-ẹ̀dá mu fún àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí láti gbé papọ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya pẹ̀lú àwọn ènìyàn, ohun tí àwọn angẹli aláìgbọràn náà ṣe pẹ̀lú àwọn obìnrin wọ̀nyí wulẹ̀ burú lọ́nà kan náà bíi ti ìwà ìbálòpọ̀ takọtabo láàárín ẹ̀yà kan náà tí àwọn ọkùnrin àti àwọn ọmọdékùnrin Sodomu hù lẹ́yìn náà. (Genesisi 6:1-4; 19:4-11; Juda 6, 7) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alábàáṣègbéyàwó àwọn angẹli náà ṣègbé sínú omi ìkún-omi náà pẹ̀lú àwọn àdàmọ̀dì ọmọ wọn, àwọn angẹli búburú náà bọ́ ẹran-ara tí wọ́n gbéwọ̀ sílẹ̀ wọ́n sì padà sí ọ̀run níbi tí wọ́n ti di ẹ̀mí-èṣù alábàákẹ́gbẹ́ Satani Eṣu.—2 Peteru 2:4.
5. Irú ẹ̀dá wo ni àwọn ẹ̀mí-èṣù jẹ́, báwo ni wọ́n sì ṣe ń gbìyànjú láti sojú àwọn òfin Ọlọrun dé?
5 Lójú ìwòye ipò àtilẹ̀wá ọlọ́rọ̀ ìtàn yìí, ìwọ ha rí irú ẹ̀dá tí àwọn ẹ̀mí-èṣù jẹ́ níti gidi bí? Wọ́n jẹ́ oníwà ìbálòpọ̀ tí a gbégbòdì àwọn ni ẹni àìrí tí ń dọ́gbọ́n darí ayé tí ìbálòpọ̀ ń sínníwín yìí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò yọ̀ọ̀da fún wọn mọ́ láti gbé ara ènìyàn wọ̀, wọ́n ń rí ìgbádùn láti inú ìbálòpọ̀ tí àwọn wọnnì tí wọ́n lè sọdìbàjẹ́ lórí ilẹ̀-ayé ń gbégbòdì. (Efesu 6:11, 12) Àwọn ẹ̀mí-èṣù ń gbìyànjú láti dojú àwọn òfin Jehofa nípa ipò-ìwàmímọ́ àti ìwàrere dé nípa mímú kí wọ́n dàbí èyí tí ń kánilọ́wọ́kò láìnídìí. Àwọn angẹli búburú wọ̀nyí ń ṣe alágbàwí fún ìwàpálapàla ìbálòpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìgbésí-ayé tí ó wà déédéé, tí ó sì ládùn.
Gbígbé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ẹ̀mí-Èṣù Lárugẹ
6. Èéṣe tí kò fi gbọ́dọ̀ yà wá lẹ́nu pè àwọn ẹ̀mí-èṣù ń gbé ẹ̀kọ́ wọn lárugẹ lọ́nà àyínìke?
6 Pé àwọn ẹ̀mí-èṣù yóò fi ọgbọ́n àyínìke gbé àwọn ẹ̀kọ́ wọn lárugẹ kò gbọ́dọ̀ yà wá lẹ́nu, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé èyí ni ọ̀nà tí aṣáájú wọn, Satani Eṣu, lò láti tan Efa jẹ. Rántí pé ó bá a sọ̀rọ̀ bí ẹni pé ó fẹ́ láti ṣèrànlọ́wọ́ fún un. Satani béèrè pé, “[Ṣe] òótọ́ ni Ọlọrun wí pé, Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ gbogbo èso igi ọgbà?” Lẹ́yìn náà ni ó wá fi àrékérekè gbìyànjú láti sọ ẹ̀kọ́ Ọlọrun di yẹpẹrẹ nípa sísọ fún Efa pé òun yóò jàǹfààní láti inú jíjẹ nínú igi tí a kàléèwọ̀ náà. Eṣu ṣèlérí pé, “Ní ọjọ́ tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀, nígbà náà ni ojú yín yóò là, ẹ̀yin ó sì dàbí Ọlọrun, ẹ ó mọ rere àti búburú.” (Genesisi 3:1-5) Nípa báyìí a tan Efa jẹ, bẹ́ẹ̀ni a yí i léròpadà, láti ṣàìgbọ́ràn sí Ọlọrun.—2 Korinti 11:3; 1 Timoteu 2:13, 14.
7. Kí ni ó ti jẹ́ ìyọrísí ẹ̀kọ́ àyínìke àwọn ẹ̀mí-èṣù, ìkìlọ̀ wo sì ni èyí pèsè?
7 Ní ẹnu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, pẹ̀lú, ọ̀pọ̀ ni a ti yíléròpadà. Àwọn ẹ̀mí-èṣù ti gbé ìwàpálapàla ìbálòpọ̀ lárugẹ lọ́nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n dá a lẹ́bi nígbà kan rí ti wá tẹ́wọ́gbà á. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí olùgbaninímọ̀ràn kan tí ó jẹ́ akọ̀ròyìn tí a mọ̀-bí-ẹni-mowó ní United States fèsì lẹ́tà kan lórí ọ̀ràn àwọn ènìyàn tí wọn kò tíì ṣègbéyàwó tí wọ́n ń ní ìbálòpọ̀, ó kọ̀wé pé: “Nkò ronú pé èmi yóò yí ojú-ìwòye mi padà lórí ọ̀ràn yìí, ṣùgbọ́n mo gbàgbọ́ nísinsìnyí pé àwọn tọkùnrin tobìnrin tí wọn kò fi ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó ṣeré níláti jọ́ rìnrìn-àjò ráńpẹ́ mélòókan ní òpin ọ̀sẹ̀ láti dán bí wọ́n ṣe bá araawọn mu tó yẹ̀wò.” Lẹ́yìn náà ni ó fikún un pé: “Nkò lè gbàgbọ́ pé èmi ni mo kọ ìyẹn!” Àní kò tilẹ̀ gbàgbọ́ pé òun ti dámọ̀ràn àgbèrè, ṣùgbọ́n ó ti ṣe bẹ́ẹ̀! Ní kedere, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí-èṣù máṣe nípalórí ojú-ìwòye wa nípa àwọn àṣà tí Ọlọrun dẹ́bi fún.—Romu 1:26, 27; Efesu 5:5, 10-12.
8. (a) Báwo ní a ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “ayé” nínú Bibeli? (b) Ta ni ń ṣàkóso ayé, ojú wo ni ó sì yẹ kí àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu fi wo ayé?
8 A kò gbọ́dọ̀ gbàgbé láé pé Satani ni “aládé ayé yìí.” Níti tòótọ́, aposteli Johannu wí pé “gbogbo ayé ni ó wà [lábẹ́] agbára ẹni búburú nì.” (Johannu 12:31; 1 Johannu 5:19) Nítòótọ́, nígbà mìíràn Jesu máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ayé” ní ìtọ́kasí gbogbo aráyé. (Matteu 26:13; Johannu 3:16; 12:46) Bí ó ti wù kí ó rí, ní ìgbà púpọ̀ jùlọ, ó lo ọ̀rọ̀ náà “ayé” láti tọ́kasí gbogbo ẹgbẹ́ àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tí a ṣètòjọ tí wọ́n wà lẹ́yìn òde ìjọ Kristian tòótọ́. Fún àpẹẹrẹ, Jesu sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun kò gbọ́dọ̀ jẹ́ “ti ayé” (ẹgbẹ́ àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn aláìṣòdodo) àti pé nítorí pé wọn kìí ṣe apákan ayé, ayé yóò kórìíra wọn. (Johannu 15:19; 17:14-16) Bibeli kìlọ̀ síwájú síi pé a gbọ́dọ̀ yẹra fún dídi ọ̀rẹ́ ayé tí Satani ń ṣàkóso yìí.—Jakọbu 4:4.
9, 10. (a) Àwọn nǹkan ti ayé wo ní ń ru ìfẹ́-ọkàn tí kò yẹ sókè fún ìbálòpọ̀? (b) Báwo ni ó ṣe jẹ́ ohun tí ó ṣeéṣe láti dá ẹni tí ó wà lẹ́yìn ohun tí eré-ìnàjú ayé fi ń kọ́ni mọ̀?
9 Aposteli Johannu rọni pé: “Ẹ máṣe fẹ́ràn ayé, tàbí ohun tí ń bẹ nínú ayé.” Ó tún sọ pé: “Ohun gbogbo tí ń bẹ ní ayé, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú, àti ìrera ayé, kìí ṣe ti Baba.” (1 Johannu 2:15, 16) Ronú nípa èyí. Kí ni ń bẹ nínú ayé lónìí tí ń ru ìfẹ́-ọkàn tí kò dára sókè, bíi fún ìbálòpọ̀ tí kò bófinmu? (1 Tessalonika 4:3-5) Ọ̀pọ̀ nínú àwọn orin ayé ń kọ́? Ọ̀gá ọlọ́pàá kan tí ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùṣèwádìí àwọn ọ̀daràn ní California wí pé: “Ohun ṣíṣekókó kan ni pé àwọn orin ń kọ́ni pé kò yẹ kí o fetísílẹ̀ sí àwọn òbí rẹ, àti pé o gbọ́dọ̀ gbé ìgbésí-ayé ní ọ̀nà tí o bá fẹ́.” Ìwọ ha mọ orísun ẹ̀kọ́ tí irú àwọn orin bẹ́ẹ̀ ń kọ́ni bí?
10 Rántí pé, lọ́nà yìí, Satani sọ fún Efa pé: ‘O ń pàdánù ohun kan tí ó ṣàǹfààní fún ọ. Gbé ìgbésí-ayé bí o bá ti fẹ́. Dá ìpinnu ṣe nípa ohun tí ó dára àti ohun tí ó burú. Ìwọ kò níláti fetísílẹ̀ sí Ọlọrun.’ (Genesisi 3:1-5) Ìyẹn ha kọ ni irú ìhìn-iṣẹ́ kan náà tí a rí nínú ọ̀pọ̀ àwọn orin ayé? Ṣùgbọ́n kìí ṣe nípasẹ̀ orin nìkan ni àwọn ẹ̀mí-èṣù gbà ń kọ́ni. Wọ́n tún ń lo àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpolówó ọjà orí tẹlifíṣọ̀n, àwòrán sinimá, àti àwọn fídíò láti kọ́ni. Báwo ni ó ṣe rí bẹ́ẹ̀? Ó dára, àwọn ọ̀nà tí ayé ń gbà pèsè ìsọfúnni ń gbé àwọn eré-ìnàjú tí ó mú kí àwọn ẹ̀kọ́ ìwàrere ti Ọlọrun farahàn bí èyí tí ó lekoko jù jáde. Wọ́n ń ṣe alágbàwí fún àgbèrè nípa títẹnumọ́ ọn àti gbígbé e kalẹ̀ bí èyí tí ó fanimọ́ra.
11. Níti ìwàrere, kí ni tẹ́lifíṣọ̀n sábà máa ń kọ́ni?
11 Ìwé-ìròyìn náà U.S.News & World Report wí pé: “Ní 1991, àwọn ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n alásokọ́ra mẹ́ta tí ń bẹ ní [U.S.] ṣe ìgbéjáde àwọn ọ̀ràn ìbálòpọ̀ tí ó ju 10,000 lọ ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́; nínú ìran kọ̀ọ̀kan tí ń fi ìbálòpọ̀ takọtabo hàn láàárín ẹni méjì tí ó ti ṣègbéyàwó, àwọn ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n alásọkọ́ra náà fi ìran 14 tí ó jẹ́ ti ìbálòpọ̀ lẹ́yìn òde ìgbéyàwó hàn.” Nípa fífi iye tí ó ju 9,000 àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ hàn níti ìbálòpọ̀ tí kò bófinmu ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ní ọdún kan, kí ni ìwọ yóò sọ pé tẹlifíṣọ̀n fi ń kọ́ni? Barry S. Sapolsky, alájùmọ̀ jẹ́ olóòtú ìròyìn náà “Ìbálòpọ̀ Lórí Tẹlifíṣọ̀n Ọwọ́ Ìrọ̀lẹ́: 1979 ní Ìfiwéra Pẹ̀lú 1989,” sọ pé: “Bí àgùnbánirọ̀ kan bá ń wo tẹlifíṣọ̀n fún ọ̀pọ̀ ọdún nínú èyí tí àwọn ènìyàn ti ń kópa nínú ìwà ìbálòpọ̀ tí ó kún fún ìbánitage tàbí èyí tí a fihàn ní kedere, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn àwòrán láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá yóò kọ́ wọn pé ìbálòpọ̀ ládùn—àti pé kò ní àbájáde èyíkéyìí.” Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n kankan nínú èyí: Eré-ìnàjú ayé ń kọ́ àwọn ọ̀dọ́ pé kò sí òfin kankan, pé àgbèrè ṣètẹ́wọ́gbà, àti pé kò sí àwọn àbájáde búburú kankan fún gbígbé ní ọ̀nà kan tí Ọlọrun dẹ́bi fún.—1 Korinti 6:18; Efesu 5:3-5.
12. Èéṣe tí eré-ìnàjú ayé fi ń halẹ̀ mọ́ àwọn èwe Kristian ní pàtàkì?
12 Orin ayé, àwọn àwòrán sinimá, fídíò, àti tẹlifíṣọ̀n ní a wéwèé láti fa àwọn ọ̀dọ́ mọ́ra. Wọ́n ń ṣe ìtànkálẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ asọnidìbàjẹ́ ti àwọn ẹ̀mí-èṣù! Ṣùgbọ́n èyí ha níláti yanilẹ́nu bí? Ronú nípa rẹ̀. Bí ìsìn èké àti ìṣèlú bá jẹ́ apákan ayé Satani—wọ́n sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ ní kedere—ó ha mọ́gbọ́ndání láti gbàgbọ́ pé eré-ìnàjú tí ayé ń gbélárugẹ kò sí lábẹ́ agbára ìdarí àwọn ẹ̀mí-èṣù bí? Ẹ̀yin ọ̀dọ́ ní pàtàkì gbọ́dọ̀ ṣọ́ra láti máṣe “jẹ́ kí ayé tí ó yíi yín ká sọ yín di dàbí mo ṣe dà.”—Romu 12:2, The New Testament in Modern English, láti ọwọ́ J. B. Phillips.
Yẹ Araàrẹ Wò
13. Àyẹ̀wò wò ni o níláti ṣe nípa araàrẹ?
13 Ọ̀ràn náà nípa ẹ̀kọ́ ta ni ìwọ ń kọbiara sí ni a lè pinnu rẹ̀ kìí ṣe kìkì nípa ọ̀rọ̀ rẹ ṣùgbọ́n nípa ìṣe rẹ pẹ̀lú. (Romu 6:16) Nítorí náà bí araàrẹ léèrè pé, ‘Ǹjẹ́ a ti nípa lórí ìṣarasíhùwà àti ọ̀nà ìgbésí-ayé mi lọ́nà tí kò yẹ nípa ohun tí mo ń kọ́ nípa àwọn ọ̀nà tí ayé ń gbé ìgbékèéyíde rẹ̀ gbà bí? Ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí-èṣù ha ti ń gbọ̀nà ẹ̀bùrú wọnú ìgbésí-ayé mi bí?’ Láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dáhùn irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀, èéṣe tí ìwọ kò fi ṣèfiwéra iye àkókò àti ìsapá tí o ń lò fún kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, lílọ sí àwọn ìpàdé Kristian, àti sísọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa Ìjọba Ọlọrun pẹ̀lú èyí tí o fi ń wo tẹlifíṣọ̀n, fetísílẹ̀ sí orin, kópa nínú eré ìdárayá tí o yànláàyò, tàbí kópa nínú irú àwọn ìgbòkègbodò tí ó farapẹ́ ẹ? Níwọ̀n bí ohun púpọ̀—nítòótọ́, ìwàláàyè rẹ gan-an—ti wà nínú ewu, fi òtítọ́-inú yẹ araàrẹ wò.—2 Korinti 13:5.
14. Kí ni yóò nípa lórí ìlera tẹ̀mí wa, èrò tí ń múniṣewọ̀ọ̀ wo ni a sì níláti ní lọ́kàn?
14 Ìwọ mọ̀ dáradára pé oúnjẹ ti ara tí o ń jẹ yóò nípalórí ìlera ara rẹ. Bákan náà, ìlera tẹ̀mí rẹ ni ohun tí o fi ń bọ́ iyè-inú àti ọkàn-àyà rẹ ń nípa lélórí. (1 Peteru 2:1, 2) Nígbà tí o lè tan araàrẹ jẹ nípa ohun tí o lọ́kàn-ìfẹ́ sí níti gidi, o kò lè tan Onídàájọ́ wa, Jesu Kristi jẹ. (Johannu 5:30) Nítorí náà bí araàrẹ léèrè pé, ‘Bí Jesu bá wà lórí ilẹ̀-ayé, ara mi yóò ha kó tìọ̀ láti jẹ́ kí ó wọlé wá kí ó sì gbọ́ orin mi tàbí kí ó rí ohun tí èmi ń wò bí?’ Òtítọ́ tí ń múniṣewọ̀ọ̀ náà ni pé Jesu ń wò wá ó sì mọ ìṣe wa.—Ìfihàn 3:15.
Kọjúùjàsí Ẹ̀kọ́ Àwọn Ẹ̀mí-Èṣù
15. Èéṣe tí àwọn Kristian fi níláti jà fitafita láti kọjúùjà sí ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí-èṣù?
15 Ìkìmọ́lẹ̀ tí àwọn ẹ̀mí-èṣù ń múwá sórí àwọn ọ̀dọ́ kí wọ́n lè kọbiara sí àwọn ẹ̀kọ́ wọn gadabú. Ó jọ pé àwọn ẹ̀mí búburú wọ̀nyí ń nawọ́ ìgbésí-ayé ìtẹ́ralọ́rùn ojú-ẹsẹ̀ síni—ọ̀kan tí ó kún fún ayé-jíjẹ àti ìgbádùn. Kí ó baà lè tẹ́ Ọlọrun lọ́rùn, Mose ìgbàanì kọ “fàájì ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀” gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ḿbà yíyọrí ọlá kan nínú agbo-ilé Farao. (Heberu 11:24-27) Kò rọrùn láti kọ ohun tí àwọn ẹ̀mí-èṣù fi ń lọni, nítorí náà o gbọ́dọ̀ jà fitafita láti ṣe ohun tí ó tọ́. Ní pàtàkì ni èyí jẹ́ òtítọ́ nítorí pé a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ ọkàn wa sì sábà máa ń fà sí ṣíṣe ohun tí ó burú. (Genesisi 8:21; Romu 5:12) Nítorí àwọn ìtẹ̀sí-èrò ẹlẹ́ṣẹ̀, àní aposteli Paulu pàápàá níláti lekoko mọ́ araarẹ̀ kí ó má sì ṣe gba ìfẹ́-ọkàn ti ẹran-ara rẹ̀ láàyè láti jọba lé e lórí.—1 Korinti 9:27; Romu 7:21-23.
16. Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ ṣe lè kọjúùjà sí ìkìmọ́lẹ̀ láti lọ́wọ́ nínú ìwàpálapàla?
16 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè dán ọ wò láti “tọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lẹ́yìn láti ṣe ibi,” Ọlọrun lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kọjúùjàsí ìkìmọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ojúgbà rẹ láti tẹ̀lé ipa ọ̀nà búburú wọn. (Eksodu 23:2; 1 Korinti 10:13) Ṣùgbọ́n o gbọ́dọ̀ fetísí àwọn ìtọ́sọ́nà Ọlọrun, ní pípa àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́ sínú ọkàn-àyà rẹ. (Orin Dafidi 119:9, 11) Ó gbọ́dọ̀ mọ̀ pé nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ bá ya araawọn sọ́tọ̀, ìfẹ́-ọkàn fún ìbálòpọ̀ lè kórajọ kí ó sì jálẹ̀ sí rírú òfin Ọlọrun. Ọ̀dọ́ kan gbà pé, “Nígbà tí mo bá wà ní èmi nìkan pẹ̀lú ọ̀rẹ́kùnrin mi, ara mi yóò fẹ́ láti ṣe ohun kan ọpọlọ mi yóò sì sọ fún mi láti ṣe ohun mìíràn.” Nítorí náà mọ ààlà rẹ kí o sì mọ̀ pé ọkàn-àyà rẹ jẹ́ aládàkàdekè. (Jeremiah 17:9) Máṣe ya araàrẹ sọ́tọ̀. (Owe 18:1) Pààlà sí àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ni rẹ. Èyí tí ó sì tún ṣe pàtàkì jù, máa kẹ́gbẹ́pọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú kìkì àwọn wọnnì tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jehofa tí wọ́n sì ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún àwọn òfin rẹ̀.—Orin Dafidi 119:63; Owe 13:20; 1 Korinti 15:33.
17. Kí ni ó lè ran àwọn èwe Kristian lọ́wọ́ láti jèrè okun tí wọn yóò fi kọjúùjà sí ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí-èṣù?
17 Ìfarabalẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìtẹ̀jáde Kristian tí a ṣètò láti fún ọ lókun nípa tẹ̀mí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́. Fún àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò ìwé náà Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ àti orí náà “Ijakadi lati Ṣe Ohun Ti Ó Tọ́” nínú ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Jẹ́ kí àwọn ìtọ́ni Ìwé Mímọ́ tí a pèsè wọlé ṣinṣin sínú iyè-inú àti ọkàn-àyà rẹ, yóò sì fún ọ lókun. Òtítọ́ kan tí o kò gbọ́dọ̀ gbàgbé ni pé nínú ayé tí àwọn ẹ̀mí-èṣù ń darí yìí ṣíṣe ohun tí ó tọ́ kò rọrùn. Nítorí náà jà fitafita. (Luku 13:24) Jẹ́ kí okun tẹ̀mí rẹ máa pọ̀ síi. Máṣe ṣàfarawé àwọn aláìlera, àti oníbẹ̀rù tí wọ́n ń tọ ọ̀pọ̀ ènìyàn lẹ́yìn.
Jàǹfààní Láti Inú Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá
18. Kí ni àwọn àǹfààní díẹ̀ tí ó wà nínú kíkọbiara sí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá?
18 Rántí, pẹ̀lú, pé ìwọ kò jẹ́ pàdánù ohunkóhun tí ó níláárí nípa kíkọbiara sí ẹ̀kọ́ Jehofa. Òun nífẹ̀ẹ́ rẹ nítòótọ́, ìdí rẹ̀ sì nìyẹn tí ó fi “ń kọ́ ọ láti ṣe ara rẹ ní àǹfààní.” (Isaiah 48:17, NW) Nítorí náà kọbiara sí ẹ̀kọ́ Jehofa, kí o sì yẹra fún ìrora ọkàn ti ẹ̀rí-ọkàn tí a bàjẹ́, ìpàdánù ọ̀wọ̀ ara-ẹni, àwọn oyún tí a kò fẹ́, àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré, tàbí àwọn ọ̀ràn ìbìnújẹ́ tí ó farajọ ọ́. Inú Jehofa máa ń dùn nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá mú kí ó rí ìdáhùn sí àwọn ìpèníjà Satani pé àwọn ènìyàn kò ní dúró bí olùṣòtítọ́ sí Ọlọrun lábẹ́ àdánwò. (Jobu 1:6-12) Bí o bá mú inú Jehofa dùn nípa jíjẹ́ olùṣòtítọ́ síi, ìwọ yóò làájá nígbà tí ó bá mú ìparun tí kò báradé wá lòdìsí ayé yìí, tí àwọn tí wọ́n tàpásí òfin rẹ̀ yóò sì ṣègbé.—Owe 27:11; 1 Korinti 6:9, 10; 1 Johannu 2:17.
19. Kí ni ìníyelórí kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn wọnnì tí wọ́n mọrírì àwọn àǹfààní ẹ̀kọ́ Jehofa?
19 Bí ìwọ bá ń kẹ́gbẹ́pọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn wọnnì tí wọ́n mọrírì ohun tí Jehofa ti ṣe fún wọn, ìwọ lè kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ìrírí wọn. Ẹnìkan tí ìjòògùnyó ti di bárakú fún tí ó sì ti hùwà pálapàla tẹ́lẹ̀rí ṣàlàyé pé: “Bí èmi kò bá ti fetísílẹ̀ sí Jehofa ni, ǹ bá ti kú. Àfẹ́sọ́nà mi ni àrùn AIDS ti pa. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mí tímọ́tímọ́ tẹ́lẹ̀rí nínú ayé ni àrùn AIDS ti pa tàbí ni wọ́n máa tó kú. Nígbà gbogbo ni mo máa ń rí wọn ní òpópónà, lójoojúmọ́ ni mo sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa fún àwọn òfin rẹ̀ tí ń darí àwọn ènìyàn rẹ̀ tí yóò sì mú kí a wà ní mímọ́ kìkì bí a bá fi wọ́n sílò. Èmi kò tíì ní ayọ̀, ìtẹ́lọ́rùn, àti àìléwu nínú ìgbésí-ayé mi tó ti ìsinsìnyí rí.” Nítòótọ́, kíkọbiara sí ẹ̀kọ́ Jehofa máa ń fìgbà gbogbo ṣàǹfààní fún wa!
Ṣe Yíyàn tí Ó Tọ́
20, 21. (a) Yíyàn méjì wo ni àwọn èwe ní? (b) Àǹfààní wíwàpẹ́títí wo ni yóò jẹ́ ìyọrísí kíkọbiara sí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá?
20 A rọ ẹ̀yin ọ̀dọ́ pé: Ẹ ṣe yíyàn tí ó tọ́ nípa ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa. Lẹ́yìn náà ẹ jẹ́ aláìyẹsẹ̀ nínú rírọ̀mọ́ ìpinnu yẹn. (Joṣua 24:15) Nítòótọ́, yíyàn kanṣoṣo ni ìwọ lè ṣe láàárín méjì. Jesu wí pé ọ̀nà gbígbòòrò àti ọ̀nà tóóró ni ó wà—ọ̀kan tí ó rọrùn fún ṣíṣe ohun tí ó bá tẹ́nilọ́rùn. Ọ̀nà yẹn forílé ibi ìpẹ̀kun, sí ìparun. Ọ̀nà kejì há. Ó jẹ́ ọ̀nà tí ó ṣòro láti rìn nínú rẹ̀ nínú ayé oníwàkiwà, tí àwọn ẹ̀mí-èṣù ń darí yìí. Ṣùgbọ́n nígbẹ̀yìn gbẹ́yín ọ̀nà yẹn yóò mú àwọn wọnnì tí ń rìn nínú rẹ̀ dé inú ayé titun àgbàyanu ti Ọlọrun. (Matteu 7:13, 14) Ọ̀nà wo ni ìwọ yóò tọ̀? Ẹ̀kọ́ ta ní ìwọ yóò kọbiara sí?
21 Jehofa fi yíyàn náà sílẹ̀ fún ọ. Òun kò gbìyànjú láti fipá mú ọ láti sin òun. “Èmi fi ìyè àti ikú . . . síwájú rẹ,” ni wòlíì Ọlọrun Mose sọ, ní rírọni pé: “Yan ìyè.” Yíyàn yìí ni ìwọ ń ṣe ‘nípa fífẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, gbígba ohùn rẹ̀ gbọ́, àti fífaramọ́ ọn.’ (Deuteronomi 29:2; 30:19, 20) Ǹjẹ́ kí ìwọ lè fi pẹ̀lú ọgbọ́n yàn láti kọbiara sí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá kí o sì gbádùn ìwàláàyè tí kò lópin nínú ayé titun ológo ti Ọlọrun.
Báwo ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Àwọn wo ni ẹ̀mí-èṣù, kí ni wọ́n sì ń kọ́ni?
◻ Báwo ni àwọn ẹ̀mí-èṣù ṣe ń gbé ẹ̀kọ́ wọn lárugẹ lónìí?
◻ Báwo ni ó ṣe jẹ ohun tí ó ṣeéṣe láti kọjúùjà sí ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí-èṣù?
◻ Kí ni àwọn àǹfààní tí ń bẹ nínú kíkọbiara sí ẹ̀kọ́ Jehofa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ṣáájú Ìkún-Omi, àwọn angẹli aláìgbọràn náà àti àwọn ọmọ wọn gbé ìwà-ipá àti ìwà-wọ̀bìà lárugẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ara rẹ yóò ha kó tìọ̀ bí Jesu bá gbọ́ orin tí o yànláàyò bí?