ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 1/1 ojú ìwé 4-7
  • Bí Ire Ṣe Máa Borí Ibi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Ire Ṣe Máa Borí Ibi
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Ń Mú Kéèyàn Hùwà Ibi
  • Àìmọ̀kan Máa Ń Mú Káwọn Èèyàn Hùwà Ibi
  • Ọ̀dọ̀ Ẹni Tí Ibi Ti Wá
  • Bá A Ṣe Máa Mú Èrò Ibi Kúrò Pátápátá
  • Ìmọ̀ Pípéye Máa Ń Mú Kí Ìwà Rere Gbilẹ̀
  • Bá A Ṣe Máa Ṣẹ́gun Ibi Pátápátá
  • Ire Yoo Ha Bori Ibi Lae Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ire Ní Ìdojú-ìjà Kọ Ibi—Ijakadi Àtọjọ́mọ́jọ́ Kan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Kí Ló Máa Ń Mú Ká Hùwà Rere Tàbí Búburú?
    Jí!—2010
  • Bíbélì Jẹ́ Ká Mọ Bí Ìwà Ibi Ṣe Bẹ̀rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 1/1 ojú ìwé 4-7

Bí Ire Ṣe Máa Borí Ibi

Èèyàn rere ni Dáfídì Ọba. Ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn, ó kórìíra ìrẹ́jẹ, ó sì máa ń gba tàwọn aláìní rò. Síbẹ̀, ọba rere kan náà yìí bá ìyàwó ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin tó fọkàn tán ṣe panṣágà. Nígbà tí Dáfídì sì rí i pé obìnrin náà, ìyẹn Bátí-ṣébà, ti lóyún fóun, ó ṣètò bí wọ́n ṣe máa pa ọkọ rẹ̀. Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá fi Bátí-ṣébà ṣaya kí àṣírí ìwà ìkà tó hù má bàa tú.—2 Sámúẹ́lì 11:1-27.

Ó HÀN gbangba pé ó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti ṣe ohun tó dára gan-an. Kí ló wá dé tó jẹ́ pé àwọn kan náà ló tún máa ń hùwà ibi tó burú jáì? Bíbélì mẹ́nu kan àwọn ohun bíi mélòó kan tó dìídì fà á. Ó tún jẹ́ ká rí i bí Ọlọ́run ṣe máa tipasẹ̀ Kristi Jésù mú ìwà ibi kúrò pátápátá.

Ohun Tó Ń Mú Kéèyàn Hùwà Ibi

Dáfídì Ọba fúnra rẹ̀ mẹ́nu kan ọ̀kan lára ohun tó ń mú kéèyàn máa hùwà ibi. Lẹ́yìn tí àṣírí ìwà ibi tó hù tú, ó gbà pé òun jẹ̀bi ọ̀ràn náà. Ó wá fi ẹ̀mí ìrònúpìwàdà kọ̀wé pé: “Wò ó! Pẹ̀lú ìṣìnà ni a bí mi nínú ìrora ìbímọ, nínú ẹ̀ṣẹ̀ sì ni ìyá mi lóyún mi.” (Sáàmù 51:5) Ọlọ́run ò fìgbà kan ní i lọ́kàn pé káwọn ìyá máa lóyún àwọn ọmọ tí yóò máa dẹ́ṣẹ̀. Àmọ́, nígbà tí Éfà yàn láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run tí Ádámù náà sì tún ṣe bẹ́ẹ̀, kò wá ṣeé ṣe fún wọn láti bí àwọn ọmọ tí kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀. (Róòmù 5:12) Bí àwọn èèyàn aláìpé ṣe ń pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń hàn gbangba pé “ìtẹ̀sí èrò ọkàn-àyà ènìyàn jẹ́ búburú láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.”—Jẹ́nẹ́sísì 8:21.

Tá ò bá wá nǹkan ṣe sí i, èrò tó ń mú kéèyàn hùwà ibi yìí lè yọrí sí “àgbèrè, . . . ìṣọ̀tá, gbọ́nmi-si omi-ò-to, owú, ìrufùfù ìbínú, asọ̀, ìpínyà, ẹ̀ya ìsìn, ìlara,” àtàwọn ìwà búburú mìíràn tí Bíbélì pè ní “àwọn iṣẹ́ ti ara.” (Gálátíà 5:19-21) Ní ti Dáfídì Ọba, ó fàyè gba àìpé ẹ̀dá, ó sì ṣàgbèrè, èyí tó wá dá wàhálà sílẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 12:1-12) Dáfídì ì bá ti dènà èrò tó fẹ́ mú un hùwà pálapàla yẹn. Àmọ́, ó jẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó ní fún Bátí-ṣébà gba òun lọ́kàn, ìyẹn sì mú kí ohun tó ṣe bá ọ̀rọ̀ tí Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn Jésù wá sọ lẹ́yìn náà mu pé: “Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀; ẹ̀wẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a bá ti ṣàṣeparí rẹ̀, a mú ikú wá.”—Jákọ́bù 1:14, 15.

Pípa ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́ẹ̀kan náà, fífipá-báni-lòpọ̀, àti mímúni-lóǹdè tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú yẹn jẹ́ àwọn àpẹẹrẹ tó gàgaàrá tá a fi mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn èèyàn bá gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ láyè láti darí wọn.

Àìmọ̀kan Máa Ń Mú Káwọn Èèyàn Hùwà Ibi

Ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ ìdí kejì táwọn èèyàn fi máa ń hùwà ibi. Kí Pọ́ọ̀lù tó kú, ó ti dẹni tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí èèyàn jẹ́jẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Ó ti ṣe gudugudu méje láti ran àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni lọ́wọ́. (1 Tẹsalóníkà 2:7-9) Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, nígbà tó wà ní ọ̀dọ́kùnrin, táwọn èèyàn mọ̀ ọ́n sí Sọ́ọ̀lù, ńṣe ló máa “ń mí èémí ìhalẹ̀mọ́ni àti ìṣìkàpànìyàn” sí àwọn tó jẹ́ Kristẹni yìí. (Ìṣe 9:1, 2) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù ò fi ta ko ìwà ibi táwọn èèyàn hù sáwọn Kristẹni ìjímìjí, tó tiẹ̀ tún lọ́wọ́ nínú ìwà ibi náà pàápàá? Ó sọ pé: “Nítorí tí mo jẹ́ aláìmọ̀kan.” (1 Tímótì 1:13) Dájúdájú, Pọ́ọ̀lù ti fìgbà kan rí ní “ìtara fún Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye.”—Róòmù 10:2.

Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó lọ́kàn rere ló ti lọ́wọ́ nínú ìwà ibi nítorí pé wọn ò ní ìmọ̀ pípéye nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀ nígbà tí olúkúlùkù ẹni tí ó bá pa yín yóò lérò pé òun ti ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run.” (Jòhánù 16:2) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní ti rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ọ̀rọ̀ Jésù yìí. Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè làwọn èèyàn tó sọ pé Ọlọ́run làwọn ń sin ti ṣenúnibíni sáwọn èèyàn Jèhófà, tí wọ́n tiẹ̀ pa lára wọn pàápàá. Ó hàn gbangba pé irú ìtara òdì tí wọ́n ní yìí kò múnú Ọlọ́run tòótọ́ dùn.—1 Tẹsalóníkà 1:6.

Ọ̀dọ̀ Ẹni Tí Ibi Ti Wá

Jésù sọ olórí ìdí tí ìwà ibi fi wà. Nígbà tó ń bá àwọn olórí ẹ̀sìn tí wọ́n ti pinnu láti pa á sọ̀rọ̀, ó ní: “Láti ọ̀dọ̀ Èṣù baba yín ni ẹ ti wá, ẹ sì ń fẹ́ láti ṣe àwọn ìfẹ́-ọkàn baba yín. Apànìyàn ni ẹni yẹn nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀.” (Jòhánù 8:44) Sátánì lẹni tó tìtorí ìmọtara ẹni nìkan mú kí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Ọ̀tẹ̀ yẹn ló kó gbogbo èèyàn sínú ẹ̀ṣẹ̀, tó sì wá fa ikú níkẹyìn.

Ẹ̀mí ìpànìyàn tí Sátánì ní yìí tún hàn gbangba nínú ohun tó ṣe sí Jóòbù. Nígbà tí Jèhófà fàyè gba Sátánì láti dán ìgbàgbọ́ Jóòbù wò, Sátánì mú kí Jóòbù pàdánù gbogbo ohun ìní rẹ̀ pátá, síbẹ̀ ìyẹn ò tẹ́ ẹ lọ́rùn. Ó tún pa ọmọ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí Jóòbù bí. (Jóòbù 1:9-19) Láwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí, ìràn ènìyàn ti fojú winá ìwà ibi tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i nítorí àìpé ẹ̀dá àti àìmọ̀kan àti nítorí pé Sátánì túbọ̀ ń dá sí ọ̀ràn aráyé. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “a fi [Èṣù] sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, a sì fi àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.” Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tún sọ ọ́ ní kedere pé wíwà tí Sátánì wà lórí ilẹ̀ ayé yóò fa “ègbé” tí irú rẹ̀ ò wáyé rí “fún ilẹ̀ ayé.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sátánì ò lè fagbára mú àwọn èèyàn hùwà ibi, síbẹ̀ ọ̀gá ni nínú bó ṣe “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.”—Ìṣípayá 12:9, 12.

Bá A Ṣe Máa Mú Èrò Ibi Kúrò Pátápátá

Kí ìwà ibi tó lè kásẹ̀ nílẹ̀ pátápátá láàárín ọmọ aráyé, èrò ibi tá a bí mọ́ èèyàn, àìní ìmọ̀ pípéye, àti ipa tí Sátánì ń ní lórí àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ kásẹ̀ nílẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, báwo ni èrò tá a bí mọ́ èèyàn tó ń mú kí wọ́n máa hùwà ibi ṣe máa kúrò lọ́kàn wọn?

Kò sí oníṣẹ́ abẹ kankan tó lè ṣe iṣẹ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni kò sí oògùn ìwòsàn tí èèyàn kankan lè ṣe tó lè mú èrò yìí kúrò lọ́kàn ọmọ aráyé. Àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run ti pèsè ìwòsàn fún ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé tá a jogún. Ìwòsàn náà sì wà fún gbogbo ẹni tó bá múra tán láti tẹ́wọ́ gbà á. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ẹ̀jẹ̀ Jésù . . . ń wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀.” (1 Jòhánù 1:7) Nígbà tí Jésù, ọkùnrin pípé nì, fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ láìbojú wẹ̀yìn, ó “fi ara rẹ̀ ru àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí òpó igi, kí a lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀, kí a sì wà láàyè sí òdodo.” (1 Pétérù 2:24) Ikú ìrúbọ tí Jésù kú yẹn ni yóò mú ohun tí ìwà ibi Ádámù dá sílẹ̀ kúrò. Pọ́ọ̀lù sọ pé Kristi Jésù di “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tímótì 2:6) Ó dájú pé ikú Jésù ti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún gbogbo èèyàn láti rí ìjẹ́pípé tí Ádámù sọnù gbà padà.

Ṣùgbọ́n, o wá lè béèrè pé, ‘bí ikú tí Jésù kú ní nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn bá ti mú kó ṣeé ṣe fún ìran èèyàn láti padà di ẹni pípé, kí ló wá dé tí ìwà ibi àti ikú ṣì wà títí dòní olónìí?’ Rírí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí lè ṣèrànwọ́ láti mú ohun kejì tó ń fa ìwà ibi kúrò, ìyẹn àìní ìmọ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe.

Ìmọ̀ Pípéye Máa Ń Mú Kí Ìwà Rere Gbilẹ̀

Níní ìmọ̀ pípéye nípa ohun tí Jèhófà àti Jésù ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí láti mú ìwà ibi kúrò kò ní jẹ́ kí ẹni tó bá jẹ́ ọlọ́kàn rere lọ́wọ́ nínú ìwà ibi láìmọ̀, tàbí kó tiẹ̀ wá ṣe ohun tó burú jùyẹn lọ, ìyẹn ni pé kó wá dẹni “tí ń bá Ọlọ́run jà.” (Ìṣe 5:38, 39) Jèhófà Ọlọ́run múra tán láti gbójú fo gbogbo àṣìṣe téèyàn ṣe nígbà tó jẹ́ aláìmọ̀kan. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn ará Áténì sọ̀rọ̀, ó ní: “Ọlọ́run ti gbójú fo irúfẹ́ àwọn àkókò àìmọ̀ bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ nísinsìnyí, ó ń sọ fún aráyé pé kí gbogbo wọn níbi gbogbo ronú pìwà dà. Nítorí pé ó ti dá ọjọ́ kan nínú èyí tí ó pète láti ṣèdájọ́ ilẹ̀ ayé tí a ń gbé ní òdodo nípasẹ̀ ọkùnrin kan tí ó ti yàn sípò, ó sì ti pèsè ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà fún gbogbo ènìyàn ní ti pé ó ti jí i dìde kúrò nínú òkú.”—Ìṣe 17:30, 31.

Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ mọ̀ dájú pé Ọlọ́run ti jí Jésù dìde kúrò nínú ikú, nítorí pé Jésù tó jíǹde náà fúnra rẹ̀ bá Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ ó sì ní kó jáwọ́ nínú inúnibíni tó ń ṣe sáwọn Kristẹni ìjímìjí. (Ìṣe 9:3-7) Gbàrà tí Pọ́ọ̀lù ní ìmọ̀ pípéye nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe, ó yí padà, ó sì di èèyàn rere tó ń fara wé Kristi. (1 Kọ́ríńtì 11:1; Kólósè 3:9, 10) Yàtọ̀ síyẹn, Pọ́ọ̀lù tún fìtara wàásù “ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run. (Mátíù 24:14) Láti nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún tí Jésù ti kú tó sì ti jíǹde ni Kristi ti ṣa àwọn èèyàn kan jọ láàárín ọmọ aráyé, ìyẹn àwọn èèyàn bíi Pọ́ọ̀lù, tó máa bá a ṣàkóso nínú Ìjọba rẹ̀.—Ìṣípayá 5:9, 10.

Láti gbogbo ọ̀rúndún tó kọjá títí di ìsinsìnyí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń fìtara mú àṣẹ Jésù ṣẹ, èyí tó sọ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Àwọn tó fi ọkàn tó dáa gba ìhìn rere yìí yòó láǹfààní àtigbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé lábẹ́ Ìjọba ọ̀run tí Kristi yóò ṣàkóso. Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti jèrè ìmọ̀ yìí ni oore tó ga jù lọ téèyàn lè ṣe fún ọmọnìkejì rẹ̀.

Àwọn tó tẹ́wọ́ gba ìhìn rere Ìjọba yìí máa ń fi àwọn ànímọ́ bíi “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, [àti] ìkóra-ẹni-níjàánu” hàn láìka gbogbo ìwà ibi tó yí wọn ká sí. (Gálátíà 5:22, 23) Wọ́n ń fara wé Jésù, wọn ò “fi ibi san ibi fún ẹnì kankan.” (Róòmù 12:17) Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ló ń sapá láti “máa fi ire ṣẹ́gun ibi.”—Róòmù 12:21; Mátíù 5:44.

Bá A Ṣe Máa Ṣẹ́gun Ibi Pátápátá

Kò sọ́gbọ́n tí ẹ̀dá èèyàn lè dá tí wọ́n fi lè ṣẹ́gun ẹni tó jẹ́ agbátẹrù ìwà ibi, ìyẹn Sátánì Èṣù. Àmọ́, láìpẹ́, Jèhófà yóò lo Jésù láti fọ́ orí Sátánì. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; Róòmù 16:20) Jèhófà yóò tún darí Kristi Jésù láti ‘fọ́ gbogbo ètò ìṣèlú túútúú kó sì fi òpin sí wọn,’ nítorí pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ètò ìṣèlú náà ló fa èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ìwà ibi tó ti ń ṣẹlẹ̀ bọ̀ látayébáyé. (Dáníẹ́lì 2:44; Oníwàásù 8:9) Nígbà ọjọ́ ìdájọ́ tó ń bọ̀ yìí, gbogbo àwọn tí “kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa . . . yóò fara gba ìyà ìdájọ́ ìparun àìnípẹ̀kun.”—2 Tẹsalóníkà 1:8, 9; Sefanáyà 1:14-18.

Ní gbàrà tí Jésù bá ti mú Èṣù àtàwọn tó ń tì í lẹ́yìn kúrò tán, látòkè ọ̀run ni yóò ti máa ran àwọn tó bá là á já lọ́wọ́ láti yí ayé padà sí bó ṣe wà ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Gbogbo àwọn tí àǹfààní gbígbé nínú ayé tá a yí padà náà bá tọ́ sí ni Kristi yóò tún jí dìde kúrò nínú ikú. (Lúùkù 23:32, 39-43; Jòhánù 5:26-29) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, yóò mú díẹ̀ lára ohun tí ìwà ibi ti ṣe fáwọn èèyàn kúrò.

Jèhófà kì í fagbára mú àwọn èèyàn láti ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù. Àmọ́, ó ń fún àwọn èèyàn láǹfààní láti gba ìmọ̀ tó ń sinni lọ sí ìyè. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kó o lo àǹfààní yẹn nísinsìnyí! (Sefanáyà 2:2, 3) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá kọ́ bó o ṣe lè fara da ìwà ibi èyíkéyìí tó o lè máa fojú winá rẹ̀ báyìí. Wàá tún rí i bí Kristi ṣe máa mú ipò iwájú láti mú ìwà ibi kúrò pátápátá.—Ìṣípayá 19:11-16; 20:1-3, 10; 21:3, 4.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Sọ́ọ̀lù ò ta ko ìwà ibi nítorí pé kò ní ìmọ̀ pípéye

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run ni oore tó ga jù lọ téèyàn lè ṣe fún ẹnì kejì rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́