ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 6/1 ojú ìwé 4-7
  • Bíbélì Jẹ́ Ká Mọ Bí Ìwà Ibi Ṣe Bẹ̀rẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bíbélì Jẹ́ Ká Mọ Bí Ìwà Ibi Ṣe Bẹ̀rẹ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwà Ibi Gbayé Kan
  • Bíbélì Fi Ẹni Ibi Náà Hàn
  • “Fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Ọkàn-Àyà Rẹ”
  • Bá Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Sátánì Lágbára Lórí Wa
  • Ìwà Ibi Kò Ní Pẹ́ Dópin!
  • Àwọn Okùnfà Ibi
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Bí Ire Ṣe Máa Borí Ibi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Sátánì
    Jí!—2013
  • Àwọn Olùṣàkóso Ní Ilẹ̀-Àkóso Ẹ̀mí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 6/1 ojú ìwé 4-7

Bíbélì Jẹ́ Ká Mọ Bí Ìwà Ibi Ṣe Bẹ̀rẹ̀

NÍ Ọ̀RÚNDÚN kìíní, ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù ló ń retí ìgbà tí Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí máa dé. (Jòhánù 6:14) Nígbà tí Jésù wá dé sáyé, ó fún àwọn èèyàn ní ìtùnú ó sì fi òye Ìwé Mímọ́ yé wọn. Ó wo àwọn aláìsàn sàn, ó bọ́ àwọn tí ebi ń pa, ó kápá ìjì, kódà ó jí òkú dìde. (Mátíù 8:26; 14:14-21; 15:30, 31; Máàkù 5:38-43) Ó tún sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ó sì ṣèlérí ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 3:34) Nípa ohun tí Jésù sọ àtohun tó ṣe, ó fi hàn lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pé òun ni Mèsáyà yẹn, ẹni tó máa dá aráyé nídè kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti gbogbo aburú tí ẹ̀ṣẹ̀ fà.

Àwọn olórí ìsìn tí wọ́n jẹ́ Júù ló yẹ kó kọ́kọ́ tẹ́wọ́ gba Jésù, kí wọ́n tẹ́tí sí i, kí wọ́n sì fara mọ́ ìtọ́sọ́nà rẹ̀ tayọ̀tayọ̀. Àmọ́ wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n kórìíra rẹ̀, wọ́n ṣenúnibíni sí i, wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á!—Máàkù 14:1; 15:1-3, 10-15.

Jésù tọ̀nà nígbà tó bẹnu àtẹ́ lu àwọn èèyànkéèyàn yẹn. (Mátíù 23:33-35) Àmọ́ Jésù mọ̀ pé ẹnì kan wà tó jẹ́ káwọn èèyàn wọ̀nyẹn máa ní èrò ibi lọ́kàn. Ó sọ fún wọn pé: “Láti ọ̀dọ̀ Èṣù baba yín ni ẹ ti wá, ẹ sì ń fẹ́ láti ṣe àwọn ìfẹ́-ọkàn baba yín. Apànìyàn ni ẹni yẹn nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀, kò sì dúró ṣinṣin nínú òtítọ́, nítorí pé òtítọ́ kò sí nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń pa irọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìtẹ̀sí-ọkàn ara rẹ̀, nítorí pé òpùrọ́ ni àti baba irọ́.” (Jòhánù 8:44) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù gbà pé àwọn èèyàn lè ṣe ohun tó burú jáì, síbẹ̀ ó sọ ẹni náà gan-an tó dá ibi sílẹ̀, ìyẹn ni Sátánì Èṣù.

Nígbà tí Jésù sọ pé Sátánì ‘kò dúró ṣinṣin nínú òtítọ́,’ ó tipa báyìí jẹ́ ká rí i pé ẹ̀dá ẹ̀mí yìí ti jẹ́ olóòótọ́ àti ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà kan rí àmọ́ ńṣe ló kúrò ní ọ̀nà títọ́ yẹn. Kí nìdí tí Sátánì fi ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà? Nítorí pé ó jọ ara rẹ̀ lójú ni, ó sì bá a débi pé ó fẹ́ kí ìjọsìn tó jẹ́ ti Ọlọ́run nìkan ṣoṣo di tòun.a—Mátíù 4:8, 9.

Inú ọ̀gbà Édẹ́nì ni ọ̀tẹ̀ Sátánì ti wá hàn kedere, nígbà tó tan Éfà láti jẹ èso tí Ọlọ́run ní wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ. Sátánì sọ ara rẹ̀ di “baba irọ́” nítorí pé òun lẹni àkọ́kọ́ tó parọ́ tó sì ba Jèhófà lórúkọ jẹ́. Ìyẹn nìkan kọ́, nígbà tó tan Ádámù àti Éfà láti ṣàìgbọràn, ó mú kí ẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í jọba lé wọn lórí, èyí tó wá yọrí sí ikú wọn àti ikú àwọn ìran tó dé lẹ́yìn wọn. Nípa báyìí, Sátánì tún sọ ara rẹ̀ di “apànìyàn,” àní, apààyàn tó burú jù lọ!—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; Róòmù 5:12.

Sátánì tiẹ̀ tún gbé ìwà ibi rẹ̀ dé ọ̀run, nígbà tó mú káwọn áńgẹ́lì mìíràn dara pọ̀ mọ́ òun láti máa ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. (2 Pétérù 2:4) Bíi ti Sátánì, ọkàn àwọn ẹ̀mí búburú wọ̀nyí fà sáwọn èèyan lọ́nà tí kò yẹ. Àmọ́ ní táwọn áńgẹ́lì wọ̀nyí, ìfẹ́ ìbálòpọ̀, èyí tí kò tọ́ sí wọn rárá ni wọ́n ní sọ́mọ èèyàn, àbájáde rẹ̀ sì burú jáì, ó tún fa ọ̀pọ̀ jàǹbá.

Ìwà Ibi Gbayé Kan

Bíbélì sọ fún wa pé: “Nígbà tí àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ ní iye . . . tí a sì ń bí àwọn ọmọbìnrin fún wọn, nígbà náà ni àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ bẹ̀rẹ̀ sí kíyè sí àwọn ọmọbìnrin ènìyàn, pé wọ́n dára ní ìrísí; wọ́n sì ń mú aya fún ara wọn, èyíinì ni, gbogbo ẹni tí wọ́n bá yàn.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:1, 2) Ta ni “àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́” wọ̀nyí? Ẹ̀dá ẹ̀mí ni wọ́n, wọn kì í ṣe èèyàn. (Jóòbù 1:6; 2:1) Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Kókó kan ni pé, láti bí ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ ọdún làwọn èèyàn ti ń gbéra wọn níyàwó ṣáájú àkókò yẹn, kò sì sídìí tí Bíbélì á fi ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó wọn. Nítorí náà, nígbà tí Bíbélì pe àfiyèsí sí ìbálòpọ̀ tó wáyé láàárín “àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́” tí wọ́n sọ ara wọn di èèyàn àti “àwọn ọmọbìnrin èèyàn” tí wọ́n gbé níyàwó, ó hàn kedere pé nǹkan tí kò ṣẹlẹ̀ rí tó sì lòdì ni àkọsílẹ̀ náà ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

Irú ọmọ táwọn áńgẹ́lì àtàwọn èèyàn tí wọ́n jọ fẹ́ra wọn bí, jẹ́rìí sí i pé ohun tí wọ́n ṣe lòdì lóòótọ́. Bíbélì pe àwọn àdàmọ̀dì ọmọ náà ní Néfílímù, wọ́n sì di òmìrán nígbà tí wọ́n dàgbà. Wọ́n tún jẹ́ ìkà paraku. Àní sẹ́, ìtúmọ̀ “Néfílímù” ni, “Àwọn Abiniṣubú,” tàbí “àwọn tó ń ti àwọn mìíràn ṣubú.” Bíbélì pe àwọn ẹni ibi wọ̀nyí ní àwọn “alágbára ńlá tí wọ́n wà ní ìgbà láéláé, àwọn ọkùnrin olókìkí.”—Jẹ́nẹ́sísì 6:4.

Àwọn Néfílímù àtàwọn bàbá wọn hùwà ibi lọ́nà tírú rẹ̀ ò ṣẹlẹ̀ rí ṣáájú àkókò yẹn. Jẹ́nẹ́sísì 6:11 sọ pé: “Ilẹ̀ ayé sì wá bàjẹ́ ní ojú Ọlọ́run tòótọ́, ilẹ̀ ayé sì wá kún fún ìwà ipá.” Kódà àwọn èèyàn pàápàá bẹ̀rẹ̀ sí í hu ìwà ipa àti ìwàkiwà táwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sáàárín wọn ń hù.

Ọ̀nà wo làwọn Néfílímù àtàwọn bàbá wọn gbà mú káwọn èèyàn máa hùwà ibi bíi tiwọn? Wọ́n lo èrò ẹ̀ṣẹ̀ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó máa ń wà lọ́kàn èèyàn. Kí ni àbájáde rẹ̀? “Gbogbo ẹlẹ́ran ara . . . ba ọ̀nà ara rẹ̀ jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé.” Níkẹyìn, Jèhófà fi Àkúnya Omi tó kárí ayé pa ayé ìgbà náà run, kìkì Nóà àti ìdílé rẹ̀ ló dá sí. (Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 12-22) Àmọ́ o, àwọn áńgẹ́lì tó sọ ara wọn di èèyàn yẹn fìtìjú padà sọ́run. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ò gbà wọ́n láyè láti padà sípò tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀ wọ́n sì di ẹ̀mí èṣù tó ń ta ko Ọlọ́run àtàwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ ìdílé rẹ̀. Ó dà bíi pé àtìgbà yẹn ni Ọlọ́run ò ti gba àwọn ẹ̀mí burúkú wọ̀nyí láyè mọ́ láti sọ ara wọn di èèyàn. (Júúdà 6) Síbẹ̀, wọn ò yéé nípa lórí ọmọ aráyé.

Bíbélì Fi Ẹni Ibi Náà Hàn

Nínú 1 Jòhánù 5:19, a rí i bí Sátánì ṣe ń darí ayé lọ́nà burúkú tó, ẹsẹ yìí sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” Ńṣe ni Èṣù ń ti ọmọ aráyé sínú yánpọnyánrin tó ń mú kí ègbé wọn túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Ká sòótọ́, ó ti wá tẹra mọ́ iṣẹ́ ibi yìí gan-an ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jésù lé òun àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jáde lọ́run lẹ́yìn tí ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀run lọ́dún 1914. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa lílé tí wọ́n lé wọn jáde yìí, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé . . . , nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣípayá 12:7-12) Ọ̀nà wo wá ni Sátánì ń gbà darí ọmọ aráyé lónìí?

Ọ̀nà kan pàtàkì tí Sátánì ń gbà ṣe èyí jẹ́ nípa dídarí ìrònú àti ìwà àwọn èèyàn. Abájọ tí Éfésù 2:2 fi pe Èṣù ní “olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́, ẹ̀mí [tàbí, ìwà tó gbilẹ̀] tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn.” Dípò kí “afẹ́fẹ́” táwọn ẹ̀mí èṣù ń darí rẹ̀ yìí mú káwọn èèyàn bẹ̀rù Ọlọ́run kí wọ́n sì máa ṣe ohun tó dára, ńṣe ló ń mú kí wọ́n máa ṣe ohun tó lòdì sí Ọlọ́run àtàwọn ìlànà rẹ̀. Nípa báyìí, Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ló wà lẹ́yìn ìwà ibi táwọn èèyàn ń hù, wọ́n sì tún ń jẹ́ kí ìwà ibi náà máa peléke sí i.

“Fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Ọkàn-Àyà Rẹ”

Ọ̀nà kan tí “afẹ́fẹ́” yìí gbà ń fara hàn ni wíwò táwọn èèyàn ń wo àwòrán oníhòòhò, èyí tó ti wá di àjàkálẹ̀ àrùn báyìí, tó sì ń mú káwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ìbálòpọ̀ lọ́nà òdì, kí ìwà tó burú jáì sì dà bí ohun tó dára lójú wọn. (1 Tẹsalóníkà 4:3-5) Díẹ̀ lára àwọn ohun tí wọ́n máa ń gbé jáde nínú àwòrán oníhòòhò tí wọ́n sì ń pè ní ohun ìnàjú ni ìfipábáni-lòpọ̀, híhùwà ìkà bíburú jáì sí ẹni tí wọ́n ń bá lò pọ̀, píparapọ̀ bá ẹnì kan ṣoṣo lò pọ̀, bíbá ẹranko lòpọ̀, àti níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọdé. Bí àwòrán oníhòòhò kan bá tiẹ̀ dà bí èyí tí kò burú, ó máa ń di bárakú síni lára, ó sì máa ń ṣàkóbá fáwọn tó ń wò ó àtàwọn tó ń kà á nínú ìwé nítorí pé ńṣe ni wọ́n á fẹ́ máa wo ìhòòhò àwọn èèyàn ṣáá.b Ó jẹ́ ìwà ibi tó ń ba àjọṣe àárín àwọn èèyàn jẹ́, ó sì tún máa ń ba àjọṣe ẹni pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Àwòrán oníhòòhò jẹ́ ká rí i bí èrò ibi ọkàn àwọn ẹ̀mí èṣù tó ń gbé ìwà yìí lárugẹ ti burú jáì tó, ìyẹn àwọn ọlọ̀tẹ̀ tó jẹ́ pé ṣáájú ìkún-omi ọjọ́ Nóà ni wọ́n ti ní ìfẹ́ ìṣekúṣe.

Ìdí rèé tí Sólómọ́nì ọkùnrin ọlọgbọ́n náà fi gbà wá níyànjú pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ, nítorí láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.” (Òwe 4:23) Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, dídáàbò bo ọkàn rẹ lọ́wọ́ ìdẹkùn àwòrán oníhòòhò lè gba pé kó o yí ibi tí ò ń wò lọ́wọ́ lórí tẹlifíṣọ̀n padà tàbí kó o pa kọ̀ǹpútà pátápátá táwọn àwòrán tó lè mú kí ìbálòpọ̀ máa wá sí ọ lọ́kàn bá fara hàn. Ó sì ṣe pàtàkì kó o ṣe bẹ́ẹ̀ láìjáfara, láìrò ó lẹ́ẹ̀mejì! Wo ara rẹ bíi sójà kan tó ń gbìyànjú láti yẹ ọfà tí ọ̀tá fẹ́ ta lù ú. Ọkàn rẹ gan-an ni Sátánì ń wá, ìyẹn ibi tí ohun tó o fẹ́ ṣe àtohun tó nífẹ̀ẹ́ sí ti ń wá. Ó fẹ́ láti sọ ọkàn rẹ dìdàkudà.

Ó tún pọn dandan kó o dáàbò bo ọkàn rẹ kó o má bá a dẹni tó nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá nítorí Èṣù mọ̀ pé “dájúdájú, [Jèhófà] kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” (Sáàmù 11:5) Kò dìgbà tí Sátánì bá sọ ẹ́ dẹni tó ń hu ìwà ipá kó tó sọ ẹ́ di ọ̀tá Ọlọ́run. Ohun tó kàn máa ṣe ò ju pé yóò jẹ́ kó o máa nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá. Kì í ṣe pé ìwà ipá, tó sábà máa ń ní iṣẹ́ òkùnkùn nínú, tí wọ́n ń gbé jáde lórí tẹlifíṣọ̀n nígbà gbogbo, ṣàdédé ń ṣẹlẹ̀. Àwọn Néfílímù ti kú wọ́n sì ti lọ, àmọ́ iṣẹ́ ọwọ́ wọn ṣì ń jà ràn-ìn nílẹ̀! Ṣé àwọn ohun tó o fi ń dá ara rẹ lára yá fi hàn pé ò ń yẹra fáwọn ọgbọ́nkọ́gbọ́n Sátánì?—2 Kọ́ríńtì 2:11.

Bá Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Sátánì Lágbára Lórí Wa

Agbára àwọn ẹ̀mí búburú lè dà bí ohun tó ṣòro gan-an láti borí. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó ń sapá láti múnú Ọlọ́run dùn “ní gídígbò kan . . . lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú” láfikún sí ìjàkadì tí wọ́n ń ba ẹran ara wọn aláìpé jà. Ká tó lè borí nínú ìjàkadì yìí ká sì rí ojú rere Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ máa lo ọ̀pọ̀ ohun tí Ọlọ́run pèsè fún wa.—Éfésù 6:12; Róòmù 7:21-25.

Lára àwọn ìpèsè yìí ni ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, tó jẹ́ ipá tó lágbára jù lọ láyé àtọ̀run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní pé: “Kì í ṣe ẹ̀mí ayé ni àwa gbà, bí kò ṣe ẹ̀mí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.” (1 Kọ́ríńtì 2:12) Àwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń darí máa ń nífẹ̀ẹ́ ohun tí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́, wọ́n sì máa ń kórìíra ohun tó kórìíra. (Ámósì 5:15) Báwo lèèyàn ṣe lè rí ẹ̀mí mímọ́ gbà? Àdúrà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni olórí ọ̀nà téèyàn fi lè rí i gbà, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ ni wọ́n kọ Bíbélì fúnra rẹ̀. A tún lè rí i gbà nípa bíbá àwọn èèyàn dáadáa tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gan-an kẹ́gbẹ́.—Lúùkù 11:13; 2 Tímótì 3:16; Hébérù 10:24, 25.

Bó o bá ń mú àwọn ohun tí Jèhófà pèsè yìí lò, o ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbé “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” wọ̀ nìyẹn, nítorí pé òun ni ohun tó dájú tó lè gbà wá lọ́wọ́ “àwọn ètekéte Èṣù.” (Éfésù 6:11-18) Lílo àwọn ìpèsè wọ̀nyí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ti di kánjúkánjú báyìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Kí nìdí?

Ìwà Ibi Kò Ní Pẹ́ Dópin!

Ọ̀kan lára àwọn tó kọ Sáàmù sọ pé: “Nígbà tí àwọn ẹni burúkú bá rú jáde bí ewéko, tí gbogbo àwọn aṣenilọ́ṣẹ́ bá sì yọ ìtànná, kí a lè pa wọ́n rẹ́ ráúráú títí láé ni.” (Sáàmù 92:7) Ó dájú pé, gẹ́gẹ́ bó ṣe rí lọ́jọ́ Nóà, ìwà ibi tó gbayé kan yìí jẹ́ ẹ̀rí pé ìdájọ́ Ọlọ́run ti sún mọ́lé. Kì í ṣe lórí àwọn ẹni ibi nìkan o, àmọ́ lórí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ tí a óò jù sí ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, níbi tí wọn ò ti ní lè ṣe ohunkóhun. Ohun tó máa kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ sí wọn nìyí kí wọ́n tó wá pa run yán-ányán-án. (2 Tímótì 3:1-5; Ìṣípayá 20:1-3, 7-10) Ta lẹni tí yóò mú ìdájọ́ yìí wá sórí wọn? Kì í ṣe ẹlòmíràn bí kò ṣe Jésù Kristi, ẹni tá a kà nípa rẹ̀ pé: “Fún ète yìí ni a ṣe fi Ọmọ Ọlọ́run hàn kedere, èyíinì ni, láti fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.”—1 Jòhánù 3:8.

Ǹjẹ́ ó wù ọ́ kí ìwà ibi dópin? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí àwọn ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì tù ọ́ nínú. Kò sí ìwé mìíràn ju Bíbélì lọ tó jẹ́ ká mọ ẹni tó pilẹ̀ ibi, ìyẹn Sátánì, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìwé mìíràn tó jẹ́ ká rí i bí òun àti gbogbo iṣẹ́ ibi rẹ̀ yóò ṣe pa run níkẹyìn. A rọ̀ ọ́ pé kó o ní ìmọ̀ pípéye tó wà nínú Bíbélì kó o ba lè dáàbò bo ara rẹ nísinsìnyí lọ́wọ́ àwọn ohun búburú tí Sátánì ń lò kó o sì lè ní ìrètí láti gbé nínú ayé tí kò ti ní sí ibi mọ́.—Sáàmù 37:9, 10.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kò sẹ́ni tó mọ orúkọ tí áńgẹ́lì tó di Sátánì ń jẹ́ níbẹ̀rẹ̀. Ohun tí “Sátánì” túmọ̀ sí ni “Alátakò,” “Èṣù” sì túmọ̀ sí “Afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́.” Láwọn ọ̀nà kan, ìgbésẹ̀ tí Sátánì gbé jọ ti ọba Tírè ayé ọjọ́un. (Ìsíkíẹ́lì 28:12-19) Àwọn méjèèjì ló ń ṣe dáadáa níbẹ̀rẹ̀ àmọ́ wọ́n di onígbèéraga nígbà tó yá.

b Wo àwọn àpilẹ̀kọ tó wà lábẹ́ àkòrí náà, “Àwọn Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-sókè—Ǹjẹ́ Wọ́n Lè Pani Lára Tàbí Wọn Kò Lè Pani Lára?” nínú Jí! ti August 8, 2003. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é jáde.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn Ìtàn Àtẹnudẹ́nu Tó Ní Òótọ́ Díẹ̀ Nínú

Láyé ọjọ́un, àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu tí wọ́n máa ń sọ níbi gbogbo láyé máa ń ní ìtàn àwọn tí wọ́n pè ní ṣènìyàn-ṣọlọ́run nínú, àwọn òmìrán, àti ìkún-omi kan tó ṣẹlẹ̀ tó sì pa gbogbo ayé rẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nínú Ìtàn Akọni ti Gilgamesh táwọn èèyàn kan tó ń jẹ́ Akkad máa ń sọ, wọ́n máa ń mẹ́nu kan ìkún-omi, ọkọ̀ ojú omi, àtàwọn tó la ìkún-omi náà já. Wọ́n ní Gilgamesh fúnra rẹ̀ jẹ́ oníṣekúṣe àti oníwà ipá, pé ṣènìyàn-ṣọlọ́run ni, ìyẹn apá kan èèyàn apá kan ọlọ́run. Ìtàn ìwáṣẹ̀ ti àwọn Aztec sọ pé àwọn òmìrán kan gbé ayé láyé ọjọ́un àti pé ìkún-omi ńlá kan ṣẹlẹ̀. Ìtàn àtẹnudẹ́nu ti àwọn ará Norway sọ nípa àwọn òmìrán àti ọkùnrin ọlọgbọ́n kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bergelmir. Wọ́n ní ó ṣe ọkọ̀ ojú omi ńlá kan tó fi gba ara rẹ̀ àti ìyàwó rẹ̀ là. Gbogbo ohun táwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu wọ̀nyí sọ fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé lohun tí Bíbélì sọ pé, àtọ̀dọ̀ àwọn tó la ìkún-omi kan já, èyí tó pa ayé burúkú kan run, ni gbogbo èèyàn ti ṣẹ̀ wá.

[Àwòrán]

Òkúta tí wọ́n kọ Ìtàn Akọni ti Gilgamesh sí lára

[Credit Line]

The University Museum, University of Pennsylvania (neg. # 22065)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

À ń rí i lónìí tàwọn èèyàn ń hu irú ìwà táwọn Néfílímù hù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ìmọ̀ pípéye kò ní jẹ́ kí Sátánì lágbára lórí wa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́